ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 12/1 ojú ìwé 21-25
  • Ayọ Tí Ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa Ti Mú Wá Fun Mi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayọ Tí Ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa Ti Mú Wá Fun Mi
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídàgbà ni United States
  • Lati Ori Iṣẹ́ Redio Lọ Si Ẹ̀wọ̀n
  • Iṣẹ-ojiṣẹ Alakooko Kikun
  • Ipo Jíjẹ́ Obi ati Wiwaasu Labẹ Ifofinde
  • Titọ Awọn Ọmọ Wa ni United States
  • Ṣiṣiṣẹsin ni Peru
  • Ecuador Ṣẹ́wọ́ Sí Wa
  • Igbesi-aye Dídọ́ṣọ̀, Ti Ó Lérè Ninu
  • Wíwá Ìjọba náà Lákọ̀ọ́kọ́ Ló Jẹ́ Kí Ìgbésí Ayé Wa Kún fún Ìfọ̀kànbalẹ̀ àti Ayọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Pípa Gbogbo Àfiyèsí Pọ̀ Sórí Ẹ̀bùn náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Lilepa Gongo Kan Ti Mo Ti Gbekalẹ Ní Ọmọ Ọdun Mẹfa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • “Inú Rere Rẹ Onífẹ̀ẹ́ Sàn Ju Ìyè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 12/1 ojú ìwé 21-25

Ayọ Tí Ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa Ti Mú Wá Fun Mi

GẸGẸ BI GEORGE BRUMLEY TI ṢE SỌ Ọ

Mo ṣẹṣẹ pari kíkọ́ awọn ọ̀dọ́ ọlọpaa ti Olu-ọba Haile Selassie tí ń kẹkọọ lati di ọ̀gá ọlọpaa lẹ́kọọ́ nipa redio ni nigba ti ọ̀kan lara awọn wọnyi sọ fun mi nikọkọ pe oun mọ̀ pe ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni mi. “Ǹjẹ́ iwọ yoo ha kẹkọọ Bibeli pẹlu mi?” ni o fi ìháragàgà beere.

NIWỌN bi iṣẹ́ wa ti wà labẹ ifofinde ni ilẹ̀ Ethiopia nigba yẹn, a kìbá ti lé mi kuro ni orilẹ-ede naa, bi a ti ṣe si awọn Ẹlẹ́rìí yooku, bi awọn alaṣẹ bá mọ̀ nipa mi. Mo ṣe kayeefi nipa boya ọmọ ile-ẹkọ naa ń sọ ọ pẹlu otitọ-inu tabi oun jẹ ikọ̀ ijọba ti a rán lati kẹdẹ mu mi. Gẹgẹ bi olori idile kan pẹlu awọn ọmọ keekeeke mẹta lati tọ́ dagba, ironu ti pipadanu iṣẹ́ mi ati didi ẹni ti a fi tipatipa mú lati fi orilẹ-ede naa ati awọn ọ̀rẹ́ ti mo ti dagba lati nifẹẹ silẹ dáyàfò mi.

‘Ṣugbọn,’ ni iwọ le beere, ‘bawo ni ara America kan pẹlu idile kan lati bojuto ṣe wá yàn lati gbé ni iha ariwa ila-oorun Africa, ni ọ̀nà jíjìn si ilé ati awọn ẹbí?’ Jẹ ki ń ṣalaye.

Dídàgbà ni United States

Ni awọn ọdun 1920, nigba ti mo ṣì wà ni ile-ẹkọ alakọọkọbẹrẹ, baba mi ṣe asansilẹ fun iwe irohin Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹẹsi) o si gba ọ̀wọ́ awọn iwe Studies in the Scriptures. Baba gbadun iwe kíkà, o si fi ìháragàgà ka awọn iwe naa. Ó ni animọ ti jijẹ ẹlẹ́nu-ún-dùn-juyọ̀ ati aláwàdà líle, bi o ti hàn gbangba lati inu ọ̀nà ti oun maa ń gbà fẹ̀tàn mú awọn alejo tí oun ti késí wá sile lọjọ Sunday. O ni iwe ẹlẹ́wà kan ti a fi awọ bò ti a wa fi omi goolu kọ “Bibeli Mimọ” si niwaju ati lẹgbẹẹ. Oun yoo dá ijumọsọrọpọ kan silẹ nipa wiwi pe, “Wayi o, òní jẹ Sunday. Ṣe iwọ yoo ka ẹṣẹ Bibeli melookan fun wa?”

Alejo naa sábà maa ń gbà bẹẹ, ṣugbọn nigba ti o bá ti ṣí iwe naa, eyikeyii ninu awọn oju-iwe naa kò ni ohunkohun ti a kọ si i lara! Bi o ti sábà maa ń rí, kayeefi yoo ṣe ẹni naa. Baba yoo sọ wi pe ‘awọn oniwaasu kò mọ ohunkohun nipa Bibeli’ oun yoo sì mú ẹ̀dà Bibeli kan jade yoo sì ka Genesisi 2:7. Nibẹ, ni ṣiṣapejuwe iṣẹda ọkunrin akọkọ, Bibeli wi pe: “Eniyan sì di alaaye ọkàn.”—Genesisi 2:7.

Baba yoo ṣalaye pe eniyan kan kò ní ọkàn kan ṣugbọn o jẹ́ ọkàn kan, pe iku ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ati pe nigba ti eniyan kan bá ku, oun ku niti tootọ ni, kò mọ ohunkohun mọ rara. (Oniwasu 9:5, 10; Esekieli 18:4; Romu 6:23) Àní ṣaaju ki n tó mọ̀ bi a ti ṣe ń kàwé daradara, mo ti kọ́ Genesisi 2:7 sori. Iwọnyi jẹ awọn iranti ti mo ni nipa idunnu gidi ti o jẹ́ lati mọ awọn otitọ Bibeli ati lati ṣajọpin wọn pẹlu awọn ẹlomiran.

Niwọn bi a ti ń rí Ilé-Ìṣọ́nà gbà ni ile wa, idile lapapọ bẹrẹsii gbadun ounjẹ aṣaraloore nipa tẹmi. Iya mama mi ń gbe pẹlu wa, ó sì di akede ihinrere akọkọ ninu idile wa. Kò si ijọ ni ilu Carbondale, Illinois, nibi ti a ń gbe, ṣugbọn a ń ṣe awọn ipade lọna ti kìí ṣe bi àṣà. Mama yoo mú awa ọmọ maraarun lọ siha keji ilu nibi ti awọn àgbà obinrin ti ń dari ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà. A bẹrẹsii lọwọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ pápá pẹlu.

Lati Ori Iṣẹ́ Redio Lọ Si Ẹ̀wọ̀n

Mo ṣegbeyawo ni 1937 nigba ti mo jẹ ọmọ ọdun 17 péré. Mo gbiyanju lati gbọ bùkàtá araami nipa titun awọn redio ṣe ati kikọni ni òye-iṣẹ́ yii. Lẹhin bíbí awọn ọmọ meji, Peggy ati Hank, igbeyawo mi dopin. Ikọsilẹ naa jẹ ẹ̀bi mi; emi kò gbe igbesi-aye Kristian. Kókó naa pe emi kò tọ́ awọn ọmọ mi meji ti o dagba julọ ti jẹ irora ọkàn ti ó wà fun akoko gigun.

Ogun Agbaye II wọlédé o si fa ironu nipa ohun pupọ bá mi. Awọn ẹgbẹ́ ologun nawọ anfaani naa sí mi lati di ọ̀gágun kan ki n sì kọ́ awọn ti a ṣẹṣẹ fi ofin mú wọnu iṣẹ́ ologun ni imọ nipa redio, ṣugbọn idaniyan mi nipa ohun ti Jehofa rò nipa ogun sun mi lati bẹrẹsii gbadura lojoojumọ. Asansilẹ-owo fun Ilé-Ìṣọ́nà ti mo ṣe ti tán, Lucille Haworth si rí isọfunni naa pe o ti tán gbà o sì ṣe ibẹwo sọdọ mi. Perry Haworth, ẹni ti o jẹ baba Lucille, tí eyi ti o pọju ninu idile rẹ̀ ti o tobi sì jẹ Ẹlẹ́rìí lati awọn ọdun 1930. Emi ati Lucille nifẹẹ araawa, ti a si ṣegbeyawo ni December 1943.

Ni 1944, a baptisi mi mo sì darapọ pẹlu aya mi ninu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun gẹgẹ bi aṣaaju-ọna kan. Laipẹ a fi ofin késí mi lati wọnu iṣẹ́ ologun ṣugbọn mo kọ̀ lati gba ẹkọ iṣẹ́ ologun. Ni abajade rẹ̀, mo gba idajọ ọdun mẹta ninu ẹ̀wọ̀n amúnipàwàdà ti ijọba apapọ ni El Reno, Oklahoma. Ayọ ni o jẹ lati jiya fun Jehofa. Láràárọ̀ ti mo bá ti ji ti mo si ranti ibi ti mo wà ati eredi rẹ̀, mo maa ń ní itẹlọrun ńláǹlà ti emi yoo si dupẹ lọwọ Jehofa. Lẹhin ogun naa awa ti a rekọja ọmọ ọdun 25 ni a bẹrẹsii fun laaye lati jade lọ kuro lọgba ẹ̀wọ̀n ki a si tun pada pẹlu ẹ̀jẹ́ pe a kò ni hùwàkiwà. A dá mi silẹ ni February 1946.

Iṣẹ-ojiṣẹ Alakooko Kikun

Nigba ti mo pada darapọ mọ Lucille, oun ń ṣe aṣaaju-ọna ni ilu kekere naa Wagoner, ni Oklahoma. Awa kò ni ọkọ̀ ayọkẹlẹ, nitori naa a ń fi ẹsẹ̀ rin ibi gbogbo, ni kikari gbogbo ilu naa. Nigba ti o yá, a ṣí lọ si Wewoka, ni Oklahoma. Laipẹ mo ri iṣẹ́ kan ni ilé iṣẹ́ redio ti o wà nitosi ti mo si bẹrẹ iṣẹ́ agbé-ọ̀rọ̀ sáfẹ́fẹ́. Ṣiṣiṣẹ fun wakati mẹfa lojumọ pẹlu lílé akoko aṣaaju-ọna bá kò rọrun, ṣugbọn a layọ nipa anfaani ti a ní ní ṣiṣiṣẹsin Jehofa. A tiraka lati ra ògbólógbòó ọkọ̀ ayọkẹlẹ kan ni kete ṣaaju apejọpọ agbegbe ti Los Angeles ni 1947. Nibẹ ni a ti bẹrẹsii ronu nipa kikọwe beere fun wiwọ inu ile-ẹkọ Watchtower Bible School of Gilead fun idanilẹkọọ gẹgẹ bi ojihin-iṣẹ Ọlọrun.

A mọ̀ pe eyi yoo jẹ igbesẹ nla kan, a kò si fẹ fi ìwàǹwára ṣe ipinnu lati fi United States silẹ. Mo sì ń kerora lori pipadanu awọn ọmọ mi, nitori naa a gbiyanju lẹẹkansii lati ri wọn gbà sọdọ labẹ ofin. Nititori akọsilẹ igbesi-aye mi ti iṣaaju ati ti lilọ ti mo lọ si ẹ̀wọ̀n, o jasi pàbó. Nitori naa a gbiyanju lati di ojihin-iṣẹ Ọlọrun. A kesi wa si kilaasi Kejila ti Gilead.

A kẹkọọyege ni ile-ẹkọ ni ọdun 1949, ṣugbọn lakọọkọ naa a yanṣẹ fun wa lati bẹ awọn ijọ Tennessee wò. Lẹhin ọdun mẹta ninu iṣẹ́ arìnrìn-àjò ni United States, a gba lẹta kan lati ọ́fíìsì ààrẹ Watch Tower Society ti o ń beere lọwọ wa bi awa yoo bá fẹ lati lọ ṣe olukọni ilè-ẹ̀kọ́ ni Ethiopia ni afikun si ṣiṣe iṣẹ iwaasu. Ọkan lara ohun ti ijọba ibẹ beere fun lọwọ awọn ojihin-iṣẹ Ọlọrun ni lati ṣe olukọni. A faramọ ọ, ati ni ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdun 1952, a gbera lọ si Ethiopia.

Nigba ti a de Ethiopia, a ń kọ awọn awọn ọmọ ile-ẹkọ alakọọkọbẹrẹ ni àràárọ̀ ti a si ń dari kilaasi ti ẹ̀kọ́ Bibeli lọfẹẹ ni ọ̀sán. Laipẹ awọn ti wọn pọ̀ gan-an bẹrẹsii wá fun ikẹkọọ Bibeli ti o fi jẹ pe a sábà maa ń kọni lẹkọọ Bibeli fun wakati mẹta si mẹrin lojoojumọ. Awọn kan lara awọn akẹkọọ naa jẹ ọlọpaa; awọn miiran jẹ olukọni tabi diakoni ni awọn ile-ẹkọ ti awọn ojihin-iṣẹ Ọlọrun ati ile-ẹkọ ṣọọṣi Orthodox ti Ethiopia. Nigba miiran a ń ní 20 eniyan tabi ju bẹẹ lọ fun kilaasi ikẹkọọ kọọkan! Ọpọlọpọ lara awọn ọmọ ile-ẹkọ naa ni wọn fi isin èké silẹ ti wọn si bẹrẹsii ṣiṣẹsin Jehofa. Ayọ wa pọ̀ jọjọ. Lẹẹkansii, ti mo bá ti ji láràárọ̀, mo maa ń fi ọpẹ́ fun Jehofa.

Ipo Jíjẹ́ Obi ati Wiwaasu Labẹ Ifofinde

Ni ọdun 1954 a gbọ pe a o di òbí, nitori naa a nilati pinnu boya lati pada si United States tabi ki a duro ni Ethiopia. Diduro nibẹ, niti tootọ, yoo sinmi lori bi mo bá rí iṣẹ́ ounjẹ oojọ ṣe. Mo gba iṣẹ́ kan gẹgẹ bi onimọ iṣẹ́-ẹ̀rọ fun ilé-iṣẹ́ redio, ti ń bojuto ilé-iṣẹ́ redio kan fun Olu-ọba Haile Selassie. Nitori naa a duro.

Ni September 8, 1954, a bi ọmọbinrin wa Judith. Mo ro pe mo ni ifọkanbalẹ lẹnu iṣẹ́ nitori pe mo ń ṣiṣẹ fun olu-ọba, ṣugbọn lẹhin ọdun meji mo padanu iṣẹ́ yẹn. Bi o ti wu ki o ri, ni ohun ti o dín si oṣu kan, Ẹka Ilé-iṣẹ́ awọn Ọlọpaa háyà mi—pẹlu owó oṣù ti o ga sii—lati kọ́ kilaasi awọn ọdọmọkunrin nipa bi a ti ṣe ń tún awọn redio ti o lè sọrọ ki o si gba èsì ṣe. Laaarin ọdun mẹta ti o tẹle e, awọn ọmọkunrin wa Philip ati Leslie ni a bí.

Laaarin akoko yii ominira wa lati lọwọ ninu iṣẹ́ wiwaasu ti ń yipada. Ṣọọṣi Orthodox ti Ethiopia ti yí ijọba lọ́kàn padà lati le gbogbo awọn ojihin-iṣẹ Ọlọrun ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kuro ni orilẹ-ede naa. Loju imọran Society, mo yí iwe àṣẹ-ìwọ̀lú mi pada lati ojihin-iṣẹ Ọlọrun si ti ṣiṣe iṣẹ́ ounjẹ òòjọ́. Iṣẹ́ ijihin-iṣẹ Ọlọrun wa ni a fofinde, nitori naa a nilati gbe igbesẹ pẹlu ironujinlẹ ati ọgbọn-inu. Gbogbo awọn ipade ijọ ṣì ń baa lọ, ṣugbọn a ń pade ni awọn awujọ keekeeke.

Awọn ọlọpaa ṣewakiri ninu ọpọlọpọ ilé awọn ti wọn fura sí pe wọn jẹ Ẹlẹ́rìí. Bi o ti wu ki o ri, laijẹ pe wọn mọ̀, ọ̀gá ọlọpaa kan ti o jẹ olujọsin Jehofa sábà maa ń ta wá lólobó nipa ìgbà ti wọn pinnu lati wá fipá ṣayẹwo ilé. Ni iyọrisi eyi, kò si iwe ti wọn rí fipa gbà ni awọn ọdun wọnni. A ń ṣe awọn Ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà ni awọn ọjọ Sunday nipa lilọ si ilé ounjẹ kan ti o wà ni opin ilu nibi ti awọn tabili ìjẹun wà fun jijẹun lode.

O jẹ ni akoko yii, nigba ti mo ń kọ́ awọn ọ̀dọ̀ ọlọpaa ti ń kẹkọọ lati di ọ̀gá ọlọpaa ni ẹkọ nipa redio, ni ọmọ ile-ẹkọ naa ti mo mẹnukan ni ibẹrẹ beere fun kikẹkọọ Bibeli lọdọ mi. Mo tànmọ́-ọ̀n pe otitọ-inu ni o fi sọ ọ, nitori naa a bẹrẹ. Lẹhin ikẹkọọ nigba meji péré, ọmọ ile-ẹkọ keji bá a wá, lẹhin naa ẹkẹta. Mo kilọ fun wọn lati maṣe sọ fun ẹnikẹni rara pe wọn ń kẹkọọ lọdọ mi, wọn kò si ṣe bẹẹ rara.

Ni ọdun 1958 a ṣe Ipade Agbaye ti Ifẹ Atọrunwa ni Yankee Stadium ati Polo Grounds ti New York. Laaarin akoko yii Peggy ati Hank, ati ọpọlọpọ awọn mẹmba miiran ninu idile mi nla, ti di Ẹlẹ́rìí ti ń ṣe deedee. Ẹ wo bi mo ti layọ tó lati pesẹ sibẹ! Kìí ṣe kiki pe mo gbadun ipadepọ lẹẹkansii pẹlu awọn ọmọ mi meji ti wọn dagba ju ati awọn mẹmba idile mi yooku nikan ni ṣugbọn ori mi wú pẹlu lati rí ogidigbo nla ti eyi ti o ju idamẹrin aadọta-ọkẹ kan eniyan ti wọn pejọ ni ọjọ ti o kẹhin apejọpọ naa!

Ni ọdun ti o tẹle e ààrẹ Society, Nathan H. Knorr, wá ṣe ibẹwo sọdọ wa ni Ethiopia. Oun ni awọn àbá ti o dara fun biba iṣẹ́ naa lọ labẹ ifofinde o si nifẹẹ ninu idile wa ati bi a ti ń ṣe si nipa tẹmi. Mo ṣalaye pe a ń kọ́ awọn ọmọ lati maa gbadura. Mo beere bi yoo bá fẹ lati gbọ ki Judith gbadura. O sọ pe bẹẹni, ati lẹhin naa o sọ fun un pe: “Iyẹn dara gan an ni, Judith.” Nigba ounjẹ mo beere lọwọ Arakunrin Knorr bi yoo ba fẹ lati gbadura, nigba ti o si pari, Judith sọ pe: “Iyẹn dara gan an ni, Arakunrin Knorr!”

Titọ Awọn Ọmọ Wa ni United States

Àdéhùn iṣẹ́ ti mo ṣe pẹlu Ẹka Ilé-iṣẹ́ awọn Ọlọpaa dopin lọdun 1959. A fẹ́ lati duro, ṣugbọn ijọba ko fọwọ si adehun iṣẹ́ titun eyikeyii fun mi. Nitori naa nibo ni a lè lọ? Mo gbiyanju lati lọ si awọn orilẹ-ede miiran nibi ti aini fun arakunrin wà pupọ ṣugbọn ti ko ṣeeṣe fun mi. Pẹlu ibanujẹ bákanbákan ṣá, a pada si United States. Bi a ti gunlẹ, a ni itunpadepọ idile ti o kun fun idunnu; gbogbo awọn ọmọ mi maraarun mọ araawọn ti wọn sì nifẹẹ araawọn lẹsẹkẹsẹ. Wọn ti wà papọ timọtimọ lati ìgbà naa wá.

A fidikalẹ si Wichita, ni Kansas, nibi ti mo ti ri iṣẹ́ gẹgẹ bi onimọ iṣẹ́-ẹ̀rọ nipa redio ati ṣiṣe ajáyọ̀sórin. Lucille ṣatunṣebọsipo lẹnu iṣẹ́ ilé, ti awọn ọmọ si ń lọ si ile-ẹkọ lẹbaa ilé. Mo ń dari ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà ti idile ni alaalẹ́ Monday, ti mo si ń gbiyanju lati mu ki o jẹ alarinrin ti o si gbadunmọni. Ojoojumọ ni a ń ṣayẹwo bi awọn iṣoro eyikeyii bá wà ni ile-ẹkọ.

Bi ọkọọkan ninu awọn ọmọ naa ti ń bẹrẹ ninu Ilé-ẹ̀kọ́ Iṣẹ-ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun, idanilẹkọọ yii ṣeranwọ fun wọn ninu lilọ si ile-ẹkọ wọn. Lati ìgbà ọmọde ni a ti dá wọn lẹkọọ ninu iṣẹ-isin pápá. Wọn ti kọ bi a ti ń fi awọn iwe-ikẹkọọ Bibeli lọni ni awọn ẹnu-ọna, wọn si ń ba wa lọ fun siṣe awọn ikẹ̀kọ́ Bibeli inu ilé.

A gbiyanju pẹlu lati kọ́ awọn ọmọ ni awọn nǹkan ti o ṣekoko nipa igbesi-aye, ni ṣiṣalaye pe olukuluku wọn ko lè figbagbogbo ni ohun ti ọ̀kan ninu awọn iyooku bá ní. Fun apẹẹrẹ, ohun ẹbun kan-naa kìí figbagbogbo wà fun gbogbo wọn kari. “Bi arakunrin rẹ tabi arabinrin rẹ bá ri ohun iṣere kan gbà,” ni awa yoo jẹ ki o yé wọn, “ti kò si sí ọ̀kan fun ọ, o ha tọ fun ọ lati ráhùn bi?” Ni awọn ìgbà miiran, bi a ti lè reti rẹ̀, awọn ọmọ yooku a maa rí nǹkan gbà, nitori naa kò si ẹni ti a patì. A fẹran gbogbo wọn nigba gbogbo, a kò si ṣojuṣaaju ọ̀kan lékè awọn meji ti o kù rara.

Awọn ọmọ miiran ni wọn fayegba lati ṣe awọn nǹkan ti awa ko fayegba awọn ọmọ wa lati ṣe. Mo sábà maa ń gbọ́, “Lágbájá lè ṣe e, eeṣe tí awa kò fi le ṣe bẹẹ?” Mo ń gbiyanju lati ṣalaye, ṣugbọn ni ìgbà miiran idahun naa wulẹ nilati jẹ, “Iwọ kò si ninu idile yẹn; Brumley ni iwọ jẹ. Awa ni awọn ofin ti o yatọ.”

Ṣiṣiṣẹsin ni Peru

Lati ìgbà ti a ti pada sile lati Ethiopia, Lucille ati emi ti ń yánhànhàn lati nipin in ninu iṣẹ́ ojihin-iṣẹ Ọlọrun lẹẹkansii. Lẹhin-ọ-rẹhin, ni ọdun 1972, anfaani naa de lati lọ si Peru, ni Guusu America. Kò si ibi ti ìbá tun dara ju iyẹn lọ fun wa lati yàn lati tọ́ awọn ọmọ wa dagba lakooko ìgbà ọdọlangba wọn. Ifararora ti wọn gbadun pẹlu awọn ojihin-iṣẹ Ọlọrun, awọn aṣaaju-ọna akanṣe, ati awọn miiran ti wọn ti wá si Peru lati ṣiṣẹsin ṣeranwọ fun wọn lati jẹ ki wọn ríi funraawọn bi awọn ti wọn ń wá ire Ijọba naa lakọọkọ ti layọ tó. Philip pe ibakẹgbẹpọ rẹ̀ ni ikimọlẹ ojúgbà ti ń gbéniró.

Lẹhin ìgbà diẹ awọn ọ̀rẹ́ atijọ diẹ lati Kansas gbọ nipa bi aṣeyọri ti a ń ṣe ninu iṣẹ-ojiṣẹ Ijọba ti pọ̀ tó, wọn sì darapọ mọ wa ni Peru. Mo ṣeto ilé wa bii ibugbe awọn ojihin-iṣẹ Ọlọrun. Olukuluku ni iṣẹ́ ti a yàn fun un ti o fi jẹ pe ẹni gbogbo yoo ni ààyè lati gbadun iṣẹ-isin pápá. A ń ṣe ijiroro ẹṣẹ-iwe Bibeli kan nidii tabili láràárọ̀. O ti jẹ akoko alayọ gidigidi fun gbogbo wa. Lẹẹkan sii, bi mo ba ti ń jí láràárọ̀ ti mo ń ranti ibi ti mo wà ati eredi rẹ̀, mo maa ń rọra fi ọpẹ́ jijinlẹ fun Jehofa.

Nigba ti o yá Judith ṣegbeyawo, ó sì pada sí States, nibi ti ó ti ń baa lọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun. Lẹhin ọdun mẹta ti iṣẹ-isin aṣaaju-ọna akanṣe, Philip kọwe beere fun iṣẹ-isin ni Beteli ti ó wà ni Brooklyn, New York a si tẹwọgba a. Nikẹhin, Leslie pẹlu pada si United States. Wọn lọ pẹlu imọlara ti o ga, wọn sì ti sọ fun wa lọpọ ìgbà pe mimu awọn lọwọ lọ si Peru jẹ ohun ti o dara julọ ti a tíì ṣe fun wọn rí.

Bi ipo ọrọ̀-ajé Peru ti ń buru sii, a mọ̀ pe awa pẹlu nilati fi ibẹ silẹ. Nigba ti a pada si Wichita ni 1978, a rí awujọ kan ti awọn Ẹlẹ́rìí ti ń sọ ede Spanish. Wọn sọ fun wa pe ki a duro lati ran awọn lọwọ, a si fi tayọtayọ ṣe bẹẹ. A dá ijọ kan silẹ, ati laipẹ o di ayanfẹ fun wa gan an bii ti awọn tí a ti ṣiṣẹsin ni iṣaaju.

Ecuador Ṣẹ́wọ́ Sí Wa

Laika àrùn arọnilápárọnilẹ́sẹ̀ ti o fẹrẹẹ sọ mi di alárùn ẹ̀gbà sí, mo fi idaniyan yánhànhàn fun pe ki emi ati Lucille tun lè ṣiṣẹsin ni orilẹ-ede miiran. Ni 1984 alaboojuto arìnrìn-àjò kan sọ fun wa nipa idagbasoke ti o wà ni Ecuador ati aini naa ti o wà fun awọn alagba Kristian. Mo ṣalaye pe iwọnba diẹ ni mo lè ṣe ninu iṣẹ-isin pápá nitori ti imúkùn-ún mi, ṣugbọn o mu un dá mi lójú pe koda ẹni ọlọjọ-ori 65 kan, ti o yarọ de ààyè ìwọ̀n kan ṣì lè wulo.

Lẹhin ti o lọ tan awa kò le sun ní gbogbo òru, ni sisọrọ nipa ṣiṣeeṣe naa lati lọ si Ecuador. Lucille ni iru ifẹ gbigbona janjan kan-naa lati lọ bi iru eyi ti mo ni. Nitori naa a ṣe ìpolówó iṣẹ́-òwò oogun apakòkòrò kekere ti a ní a sì tà á laaarin ọ̀sẹ̀ meji. A ta ile wa laaarin ọjọ mẹwaa pere. Nipa bayii, ni awọn ọdun ogbó wa, a tun pada si idunnu giga julọ wa, ti ṣiṣe iṣẹ́ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ̀ ajeji.

A fidikalẹ si Quito, a si gbadun iṣẹ-isin pápá, pẹlu ọjọ kọọkan ti ń mu iriri tabi ìgbìdánwò titun kan wa. Ṣugbọn ṣá, ni 1987, àwárí fihàn pe mo ni àrùn jẹjẹrẹ inu ifun; iṣẹ́-abẹ oju-ẹsẹ ni mo nilo. A pada si Wichita fun iṣẹ́-abẹ naa, eyi ti o yọrisirere. Ni kiki ọdun meji pere lẹhin ti a pada si Quito ni wọn tun ṣawari aarun jẹjẹrẹ lẹẹkansii, a nilati ṣí pada si United States patapata laitun pada lọ mọ́. A fidikalẹ si Ariwa Carolina, nibi ti a ń gbe lọwọlọwọ bayii.

Igbesi-aye Dídọ́ṣọ̀, Ti Ó Lérè Ninu

Ọjọ-ọla mi niti ara ìyára kò daju. O di dandan pe ki a fi iṣẹ́-abẹ lu ihò-ìdí miiran fun mi ni ọdun 1989. Àní bi o tilẹ jẹ bẹẹ, mo ṣi le ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alagba kan ti mo si ń dari awọn ikẹkọọ Bibeli melookan pẹlu awọn wọnni ti wọn wá si ilé mi. La awọn ọdun wọnyi ja, a ti ran awọn ọgọrọọrun niti gidi lọwọ nipasẹ fifunrugbin, bibomirin, tabi mimu awọn eso otitọ dagba. Iyẹn jẹ idunnu ti kìí ṣá laelae, laika iye ìgbà yoowu ti a ṣe e ni aṣetunṣe si.

Ni afikun, mo ti ní idunnu nla ninu rírí pe gbogbo awọn ọmo mi ni wọn ń ṣiṣẹsin Jehofa. Fun 30 ọdun Peggy ti ń ba ọkọ rẹ̀, Paul Moske lọ ninu iṣẹ arìnrìn-àjò ni United States. Philip ati aya rẹ̀, Elizabeth, papọ pẹlu Judith ń baa lọ ninu iṣẹ-isin akanṣe ni Beteli ti ó wà ni Brooklyn, New York. Hank ati Leslie ati awọn ẹnikeji wọn ninu igbeyawo jẹ Ẹlẹ́rìí ti ń ṣedeedee, awọn arakunrin ati arabinrin mi mẹrin ati idile wọn, ati papọ pẹlu iye ti o ju 80 ninu ibatan mi nipa ti ara, ni gbogbo wọn ń ṣiṣẹsin Jehofa. Lucille si ti jẹ́ aya Kristian awofiṣapẹẹrẹ kan fun ohun ti o sunmọ 50 ọdun igbeyawo wa. Ni awọn ọdun aipẹ yii oun ti ń fi àìráhùn ṣe awọn iṣẹ́-òpò pupọ ti kò fanimọra rara ni ríràn mi lọwọ lati bojuto araami ti ń jorẹhin sii.

Niti tootọ, igbesi-aye mi ti kun fun idunnu. O ti jẹ alayọ kọja eyi ti a le fẹnusọ lọ. Ṣiṣiṣẹsin Jehofa mu mi layọ tobẹẹ debi pe o jẹ ifẹ atọkanwa mi lati jọsin rẹ̀ titilae lori ilẹ̀-ayé yii. Ìgbà gbogbo ni mo maa ń ranti Orin Dafidi 59:16, ti o sọ pe: “Emi o kọrin agbara rẹ; nitootọ, emi o kọrin aanu rẹ kikan ni òwúrọ̀: nitori pe iwọ ni o ti ń ṣe aabo ati ibi-asala mi ni ọjọ ipọnju mi.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

George Brumley pẹlu olu-ọba Ethiopia Haile Selassie

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

George Brumley ati aya rẹ, Lucille

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́