ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 6/8 ojú ìwé 26-27
  • Àwọn Olùgbé Inú Hòrò Lóde Òní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Olùgbé Inú Hòrò Lóde Òní
  • Jí!—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Iwe Akajọ Òkun Òkú—Iṣura Ti Kò Lẹ́gbẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Yímíyímí Ilẹ̀ Áfíríkà Yanjú Ọ̀ràn Náà!
    Jí!—1996
Jí!—2000
g00 6/8 ojú ìwé 26-27

Àwọn Olùgbé Inú Hòrò Lóde Òní

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ

ṢÉ PÉ àwọn kan ṣì ń gbé inú hòrò lákòókò tiwa yìí? Bẹ́ẹ̀ kúkú ni, a rí àwọn kan ní Lesotho, àgbègbè ilẹ̀ olókè ní ìhà gúúsù Áfíríkà. Ha Kome, tí í ṣe abúlé wọn, wà ní nǹkan bí ọgọ́ta kìlómítà sí Maseru, tí í ṣe olú ìlú Lesotho, ní àgbègbè olókè tó wà lẹ́bàá Òkè gàgàrà Maluti. Ní àwọn oṣù ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, àwọn òdòdó pupa sábà máa ń bo àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà. Àwọn òdòdó ẹlẹ́wà pípọ́n yòò, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí ọ̀pá ìroná pípọ́n yòò náà, yàtọ̀ gan-an sí àwọn igbó kíkún tó wà lágbègbè náà.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìdílé tó wà níbẹ̀ ló ń gbé ìgbésí ayé bíi tàwọn tó gbé ayé lọ́dún gbọ́nhan. Àárín àwọn hòrò ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ni wọ́n kọ́ àwọn ilé wọn sí. Òpó igi àti àwọn ohun mìíràn, bí esùsú, ni wọ́n fi ṣe férémù ògiri nínípọn iwájú ilé wọn. Ẹrẹ̀ àti ìgbẹ́ màlúù ni wọ́n kó dí àárín àwọn ògiri náà. Àwọn ohun tí wọ́n kó dí àárín ògiri wọ̀nyí ń dènà otútù tó máa ń mú gan-an ní Lesotho nígbà òtútù. Ní àwọn ilé wọn náà, wọ́n gbẹ́ ibì kan tí wọ́n ń pè ní ifo, tó túmọ̀ sí “ààrò,” tí wọ́n ti máa ń yáná tí òtútù bá ń mú.

Òkúta hòrò náà ni ó sábà máa ń di òrùlé, ògiri ẹ̀yìn ilé, àti ògiri ẹ̀gbẹ́ ilé. Wọ́n máa ń ṣán àpòpọ̀ ẹrẹ̀ àti ìgbẹ́ màlúù mọ́ ọn, bí wọ́n sì ṣe ń ṣán an mọ́ ọn lọ́dọọdún nìyẹn. Èyí máa ń fún ara àwọn òkúta náà láwọ̀ mèremère, ó sì ń mú wọn dán sí i. Wọ́n fi awọ màlúù ṣe inú ilé lọ́ṣọ̀ọ́, wọ́n sì tún ń fi í ṣe ibùsùn.

Ohun tuntun, tó yàtọ̀ gbáà ni ọ̀nà ìgbésí ayé wọn níbẹ̀ máa ń jẹ́ fún àwọn àlejò tó wá láti Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Irú ìmúra tó wọ́pọ̀ níbẹ̀ máa ń jẹ́ ti wíwọ kúbùsù aláwọ̀ mèremère àti dídé àkẹtẹ̀ tó rí bí òkòtó. A sábà máa ń rí àwọn ọmọkùnrin tí ò wọ bàtà, tí wọ́n ń da àgùntàn. A ń rí àwọn ọkùnrin abúlé náà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lóko àgbàdo tàbí kí wọ́n máa bá àwọn ọkùnrin míì sọ̀rọ̀ tìtaratìtara.

Wọ́n máa ń kófìrí iṣẹ́ ẹ̀rọ ìgbàlódé níbẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Tọmọdé tàgbà lábúlé náà ló máa ń wòran àwọn ọkọ̀ òfuurufú kéékèèké tó máa ń fò kọjá níbẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àti àwọn mọ́tò arinkòtò-rin-gegele tó ń kó àwọn àlejò wá sí hòrò náà. Ìtagbangba ni wọ́n ti sábà máa ń gbọ́únjẹ, orí ààrò, nínú ìgbékaná onírin dúdú, tó lẹ́sẹ̀ mẹ́ta ni wọ́n ti máa ń sè é. Nítorí àìsí igi ìdáná, ìgbẹ́ màlúù gbígbẹ, esùsú, àti àwọn ẹ̀ka igi mélòó kan ni wọ́n fi ń dáná. Àwọn ohun èlò tó wọ́pọ̀ tí a máa ń rí nínú àwọn ibùgbé inú hòrò wọ̀nyí ni ọlọ tí wọ́n fi ń lọ àgbàdo àti ọmọrogùn tí wọ́n fi ń ro ògì.

Àwọn àwòrán táwọn Bushmen yà pọ̀ gan-an ní Lesotho, wọ́n sì pọ̀ nínú àwọn hòrò àti lára àwọn òkúta káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Àwọn Bushmen ni àwọn èèyàn tó ń gbé inú àwọn hòrò tó wà ní Ha Kome látètèkọ́ṣe. Àwọn àwòrán tí wọ́n yà ṣàpèjúwe onírúurú ìgbòkègbodò, láti orí jíju àwọ̀n pẹja láti inú ọkọ̀, dórí ijó àjódọ́ba, tí àwọn tó ń jó ijó náà si máa ń dé agọ̀ ẹranko. Àwọn àwòrán náà tún ṣàpèjúwe àwọn ẹranko, bí ìrò, kìnnìún, erinmi, àti èsúró, tó tóbi jù lára àwọn oríṣiríṣi ẹtu tó wà. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn àwòrán tó wà nínú àwọn hòrò Ha Kome ló ti pòórá. Àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan ló kù tó ń ránni létí báwọn Bushmen ṣe mọ àwòrán yà sí.

Àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣiṣẹ́ ìwàásù wọn ní àgbègbè kan tí kò jìnnà jù sí Ha Kome. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń lọ bẹ àwọn olùgbé inú hòrò náà wò, wọ́n sì rí i pé àwọn èèyàn náà máa ń ṣaájò àlejò gan-an. Tí àwọn Ẹlẹ́rìí bá dé, wọ́n sábà máa ń fún wọn ní oríṣi ògì wọn, tí wọ́n ń pè ní motoho, mu. Púpọ̀ àwọn ará Ha Kome ló máa ń fẹ́ láti gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń fi ìmoore hàn fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nípa fífi ewébẹ̀, ẹyin, tàbí àwọn ohun mìíràn ṣe ọrẹ ìtìlẹyìn fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe.

Àwọn olùgbé inú hòrò lóde òní ní ọ̀wọ̀ fún Bíbélì, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí bíbéèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ìwàláàyè, ikú, àti àwọn ìgbàgbọ́ àbáláyé wọn. Ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí onítara tó wà lágbègbè yẹn yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi mélòó kan. Lọ́nà yìí, èso òtítọ́ rí ibi tó lọ́ràá balẹ̀ sí lọ́kàn àwọn èèyàn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí.—Mátíù 13:8.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 26]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

HA KOME

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́