Lẹ́yìn Ìjì Tó Jà—Ìpèsè Ìrànwọ́ ní Ilẹ̀ Faransé
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ
FRANÇOISE ṣí ilẹ̀kùn pé kí òun lọ kó igi wá sínú ibi ìdáná tí wọ́n fi ń mú ilé móoru. Ó ní òun rántí pé: “Ohun tí mo rí kàn tiẹ̀ yà mí lẹ́nu ni. Omi ti kún débi pèpéle ẹnu ọ̀nà ìta, bẹ́ẹ̀ sì ni ìjì tó lágbára kan ń jà bọ̀ láti ẹnu ọ̀nà oko táa dá.” Omi mu Thierry, ọkọ rẹ̀ dé ọrùn nígbà tó ń lọ gbé àkàsọ̀ kan láti ibi tí wọ́n ń gbé ọkọ̀ sí. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé náà gùnkè lọ sókè àjà ilé wọn, ọkùnrin náà sì dá òrùlé ilé náà lu. Tọkọtaya tí gbogbo ara wọ́n ti rin tí ẹ̀rù sì bà gan-an yìí àti àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dúró fún wákàtí mẹ́rin gbáko níbi tí wọ́n ti ń retí kí wọ́n wá yọ àwọn nínú ewu. Níkẹyìn, hẹlikópútà àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Faransé kan rí wọn, ó sì lọ fà wọ́n jáde nínú ewu náà.
Ọ̀gbàrá òjò ṣàn wọnú àwọn odò wọ́n sì kún àkúnya, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́ àwọn ìsédò, wọ́n sì ń já àwọn afárá. Ọ̀gbàrá omi ẹrẹ̀ tó ń jà gùdù, tó máa ń ga tó mítà mẹ́wàá nígbà míì, bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́ gbogbo nǹkan tí wọ́n bá bá lọ́nà lọ. Àwọn tí ìjì náà pa lé ní ọgbọ̀n—ó pa àwọn kan sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn, ó sì gbé àwọn mìíràn lọ láti ojú oorun. Ẹnì kan tí wọ́n yọ nínú ewu náà fi alẹ́ ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu tí nǹkan náà ṣẹlẹ̀ ní oṣù November wé “àkókò òpin.” Odindi ẹkùn ilẹ̀ kan ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Faransé—tí í ṣe àpapọ̀ ọ̀ọ́dúnrún ó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [329] ìlú àti abúlé—ni wọ́n kéde pé ó ko àgbákò náà.
Ìyẹn Ṣì Kéré Lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ohun Tó Ń Bọ̀
Àgbègbè gúúsù ìwọ̀ oòrùn kò tíì bọ́ nínú àjálù náà tí jàǹbá tún fi ṣẹlẹ̀ níbòmíràn. Ńṣe ni ipò ojú ọjọ́ tún lọ móoru jù lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ lágbègbè Òkun Àtìláńtíìkì, ìyẹn ló wá fa ẹ̀fúùfù líle gan-an. Ẹ̀fúùfù àkọ́kọ́ da àgbègbè àríwá ilẹ̀ Faransé rú ní December 26, 1999, èkejì sì ba gúúsù jẹ́ lálẹ́ ọjọ́ kejì. Ó wà lákọọ́lẹ̀ pé ọwọ́ eré ẹ̀fúùfù náà lé ní igba kìlómítà ní wákàtí kan. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ti fi hàn, ó pẹ́ tí irú ìjì líle bẹ́ẹ̀ ti jà ní ilẹ̀ Faransé kẹ́yìn, ìyẹn ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún.
Oyún oṣù mẹ́jọ ló wà nínú Hélène nígbà tí ìjì náà jà. Ó wí pé: “Ẹ̀rù bà mí gan-an. Ìgbà yẹn lọkọ mi ń gun alùpùpù rẹ̀ bọ̀ nílé, mo sì ń rí i tí ẹ̀ka igi ń ya lọ́tùn-ún lósì níta. Gbogbo ohun tí mo ń rò lọ́kàn ni pé kò ní fojú kan ọmọ tí mo lóyún rẹ̀. Ọkọ mi kò tíì wọlé tán tí omi bẹ̀rẹ̀ sí bo ilé wa. Ojú fèrèsé la gbà jáde.”
Ó kéré tán, àádọ́rùn-ún èèyàn ló kú ní ilẹ̀ Faransé. Àwọn kan kú sómi, ìbòrí òrùlé já pa àwọn mìíràn, ààrò tí ń mú ilé móoru wó lu àwọn kan, nígbà tí igi sì ya lu àwọn mìíràn pa. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn mìíràn ló fara pa yánnayànna, títí kan àwọn aráàlú bíi mélòó kan àti àwọn ọmọ ogun ayọni-nínú-ewu. Ọwọ́ ìjì náà tún dé àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní tòsí, ó lé ní ogójì èèyàn tó pa ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Jámánì, Sípéènì, àti Switzerland.
Lẹ́yìn Àjálù Náà
Lára gbogbo àgbègbè ìlú ńláńlá mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún tí wọ́n pín ilẹ̀ Faransé sí, mọ́kàndínláàádọ́rin ni ìjọba kéde pé ó jẹ́ “àgbègbè tí àjálù bá.” Wọ́n ti díwọ̀n pé àwọn nǹkan tó bàjẹ́ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́rin bílíọ̀nù owó francs (ìyẹn jẹ́ bílíọ̀nù mọ́kànlá dọ́là). Ṣe ni ohun tó bàjẹ́ láwọn ìlú, abúlé, àti àwọn etíkun kan rán àwọn tó rí wọn létí bí pápá ogun ṣe ń rí. Àwọn igi àti àwọn òpó iná gogoro ti wó dí ọ̀nà mọ́tò àti ojú irin. Àwọn òrùlé ṣí kúrò lórí ilé, àwọn ẹ̀rọ ńláńlá tí wọ́n fi ń kọ́lé ṣubú, àwọn ọkọ̀ ojú omi dojú dé sí èbúté. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ń ta ohun ọ̀gbìn pàdánù ohun ìgbọ́bùkátà wọn, nítorí àwọn ilé ewéko àti igi bàjẹ́.
Láàárín wákàtí mélòó kan péré, ẹ̀fúùfù náà ti sọ àwọn igbó kìjikìji àti àwọn ọgbà ohun alààyè ilẹ̀ Faransé dahoro, ó sì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún hẹ́kítà igbó run. Gẹ́gẹ́ bí Ilé Iṣẹ́ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Nípa Igbó Ọba ní Ilẹ̀ Faransé ti sọ, ó tó ọ̀ọ́dúnrún mílíọ̀nù igi tó bàjẹ́. Tigbòǹgbò-tigbòǹgbò ló hú àwọn igi ńláńlá tó ti wà fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tàbí kó dá wọ́n péú bí ìgbà téèyàn dá igi ìṣáná. Ẹ̀fúùfù náà wó àwọn igi lọ rẹ́kẹrẹ̀kẹ nínú igbó Aquitaine àti Lorraine.
Bernard, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó ń ṣiṣẹ́ aṣọ́gbó sọ pé: “Lọ́jọ́ kejì ọjọ́ tí ìjì náà jà, mo lọ sínú igbó. Ó ṣeni ní kàyéfì. Téèyàn bá rí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, kò sọ́gbọ́n kó má sunkún! Níbẹ̀, ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ará ìjọ tí mo wà ló gbára lé igbó náà fún oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ẹ̀rù ba àwọn èèyàn gan-an, ní pàtàkì àwọn arúgbó.” Ní ilẹ̀ Ààfin Versailles, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá igi ló wó. Ọ̀kan lára àwọn olórí àgbẹ̀ níbẹ̀ dárò pé: “Yóò gba ọ̀rúndún méjì kí ọgbà ohun alààyè náà tó lè rí bíi ti tẹ́lẹ̀.”
Bí àwọn òpó iná ti ń ṣubú, ó lé ní ìdá mẹ́fà lára gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ Faransé tó wà nínú òkùnkùn biribiri. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ṣiṣẹ́ ribiribi, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni kò rí iná mànàmáná tàbí tẹlifóònù lò fún ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn ìjì náà. Àwọn abúlé kéékèèké kan kò ṣeé dé mọ́. Àwọn ìdílé tó di ọ̀ranyàn fún láti máa fa omi láti inú kànga àti láti máa tan àbẹ́là wá mọ̀ ọ́n lára bíi pé ìgbésí ayé ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn làwọ́n ń gbé dípò kí wọ́n máa gbé ìgbé ayé àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ ọ̀rúndún kọkànlélógún.
Àwọn ìjì náà kò yọ àwọn ilé tí ó wà fún ìlò ará ìlú ní gbogbo gbòò, àwọn ilé ìjọba, àti àwọn kàtídírà sílẹ̀. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ilé ìjọsìn ńláńlá, títí kan mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lára Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ló bàjẹ́. Ní àwọn ibì kan, ńṣe ni wọ́n tan àbẹ́là tàbí àtùpà ṣèpàdé.
Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìjì náà ba nǹkan wọn jẹ́, àwọn ohun tó bàjẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti orí igi tó wó tàbí òrùlé tó ká lọ dé orí àwọn ilé tó bàjẹ́ pátápátá nígbà tí àwọn odò kún àkúnya. Àwọn Ẹlẹ́rìí bíi mélòó kan tiẹ̀ fara pa. Àjálù burúkú kan ṣẹlẹ̀ ní àgbègbè Charente, Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin kú sómi lójú ìyàwó rẹ̀ tí kò lè ṣe nǹkan kan láti gbà á là. Àwọn mìíràn kófìrí ikú. Gilbert, tó jẹ́ ẹni àádọ́rin ọdún, rántí pé: “Iṣẹ́ ìyanu ni pé mi ò kú o. Omi já ilẹ̀kùn, omi sì rọ́ wọlé yàà. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo rí ara mi nínú omi tó ga tó mítà kan ààbọ̀. Kọ́bọ́ọ̀dù aṣọ mi tí mo rọ̀ mọ́ ló gba ẹ̀mí mi là.”
Pípèsè Ìrànwọ́ Tó Yẹ
Ìjì náà mú kí á rí ìfìmọ̀ṣọ̀kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ilẹ̀ Faransé àti jákèjádò ilẹ̀ Yúróòpù. Ìwé ìròyìn Le Midi libre sọ pé: “Àwọn ìgbà kan máa ń wà tí ọrẹ àánú á fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ dandan, yálà a ṣe é látọkànwá, nítorí pé ẹni náà jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹni, tàbí nítorí ẹ̀rí ọkàn.”
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí ìjì náà rọlẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé àwọn ìgbìmọ̀ tí ń pèsè ìrànwọ́ dìde láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará ìjọ àgbègbè náà àti àwọn mìíràn tí ìjábá náà kàn. Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn, tí iṣẹ́ tiwọn jẹ́ kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣètò ọ̀wọ́ àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni. Lẹ́yìn ìjì tó jà ní àgbègbè gúúsù ìwọ̀ oòrùn yìí lóṣù November, àwọn Ẹlẹ́rìí tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ló kópa nínú iṣẹ́ ìpèsè ìrànwọ́ àti àtúnṣe náà, wọ́n ran àwọn tí ọ̀ràn kàn lọ́wọ́ láti gbọ́n ẹrẹ̀ àti omi tó ya bo ilé wọn dànù. Àwọn Ẹlẹ́rìí wà lára àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tó kọ́kọ́ dé àwọn abúlé kan. Àwọn Ẹlẹ́rìí tún àwọn ilé tí ó wà fún ìlò ará ìlú ní gbogbo gbòò, bí ilé ìwé, ilé ìfìwéránṣẹ́, gbọ̀ngàn ìlú, ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó, àti itẹ́ òkú pàápàá ṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn àjọ tó ń pèsè ìrànwọ́.
Gbogbo èèyàn tí wọ́n rí ni wọ́n ràn lọ́wọ́, láìfi ti ẹ̀sìn wọn pè. Ẹlẹ́rìí kan sọ pé: “A ran àlùfáà abúlé náà lọ́wọ́. A tún abẹ́ ilé rẹ̀ ṣe.” Ó tún sọ nípa àwọn mìíràn tí àwọn Ẹlẹ́rìí ràn lọ́wọ́ pé: “Àwọn èèyàn rò pé ńṣe la já bọ́ láti ọ̀run láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́.” Òṣìṣẹ́ ìjọba kan sọ pé: “Èèyàn lè rò pé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ka ìwé Ìhìn Rere, tí wọ́n sì ń gbà ran ọmọnìkejì wọn lọ́wọ́ nìyẹn. Mo lérò pé àwọn tí wọ́n wá yẹn fi ohun tí Ìhìn Rere àti ẹ̀sìn wọ́n fi kọ́ wọn sílò ni.” Ẹlẹ́rìí kan tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ sọ pé: “Ọkàn èèyàn á sún un láti wá ṣèrànwọ́ lọ́nà yìí. Orísun ìdùnnú gbáà ló jẹ́ láti lè wá ran àwọn aládùúgbò wa lọ́wọ́.”
Lẹ́yìn tí ìjì tó jà lẹ́ẹ̀mejì lóṣù December yẹn jà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí ni kò rí àwọn Kristẹni arákùnrin wọn fún ọjọ́ bíi mélòó kan. Lábẹ́ àbójútó àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn alàgbà láwọn ìjọ àdúgbò, wọ́n ṣètò ìpèsè ìrànwọ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kì í ṣeé ṣe láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ará tó ń gbé ibi tí kò jìnnà síra wọn nítorí àwọn igi tó wó dínà, bẹ́ẹ̀ sì ni tẹlifóònù tí kò ṣiṣẹ́ mọ́ kì í jẹ́ kí wọ́n lè kàn sí wọn. Láti lè ran àwọn ará ìjọ wọn tó wà ní àdádó lọ́wọ́, ńṣe ni àwọn Ẹlẹ́rìí kan fẹsẹ̀ rìn la àárín àwọn igi tó wó léra jánganjàngan nínú igbó tàbí kí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ láìka àwọn igi tí ń ya lulẹ̀ sí. Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni ṣiṣẹ́ kára láti tún àwọn ilé ìwé, ibi ìkówèésí ìlú, ibi ìpàgọ́, àti ilé àwọn aládùúgbò wọn ṣe, wọ́n sì kó àwọn ohun tó dí àwọn ọ̀nà tó lọ sínú igbó kúrò.
Ṣíṣẹ̀dá “Ìfẹ́ Tí Ń Tú Kọ̀ọ́kọ̀ọ́”
Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kó másùnmáwo bá ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú wọ̀nyí kàn, pàápàá àwọn ọmọdé àti àwọn àgbàlagbà. Àwọn tí ilé wọn bàjẹ́ tàbí tí èèyàn wọn kú yóò nílò àkókò púpọ̀ àti ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ láti mú ìgbésí ayé wọn padà bọ̀ sípò. Lẹ́yìn ìkún omi tó ṣẹlẹ̀ ní ẹkùn Aude, Dókítà Gabriel Cottin, mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ọ̀ràn pàjáwìrì nípa ìdààmú ọpọlọ, sọ pé: “Ìtìlẹ́yìn èyíkéyìí tí ẹni tí ọ̀ràn kàn bá rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà tún máa ń ṣèrànwọ́ gidigidi.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí i pé pípèsè irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìwà rere tó pọn dandan, ó sì jẹ́ ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè fún. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí ó má . . . sí ìpínyà kankan nínú ara [àwùjọ àwọn Kristẹni tòótọ́], . . . kí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ lè ní aájò kan náà fún ara wọn. Bí ẹ̀yà ara kan bá sì ń jìyà, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù a bá a jìyà.”—1 Kọ́ríńtì 12:25, 26.
Hélène tí a sọ nípa rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀, tó ti bí ọmọbìnrin rírẹwà kan tó ń ta kébékébé, sọ pé: “Ní wákàtí mélòó kan lẹ́yìn tí ìjì náà jà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wá sí ilé wa láti bá wa tún gbogbo ilé ṣe. Kódà, àwọn Ẹlẹ́rìí tí ìjì náà ba nǹkan tiwọn náà jẹ́ wá ràn wá lọ́wọ́. Ìrànlọ́wọ́ náà kàmàmà—wọ́n ṣe é láìrò ó tẹ́lẹ̀, ó sì wá látọkàn!”
Odette, tí àkúnya omi ba ilé rẹ̀ jẹ́ sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Wọ́n tù mí nínú gan-an. Èèyàn ò lè sọ bó ṣe rí nínú rẹ̀. Gbogbo ohun tí wọ́n ṣe fún mi wú mi lórí gidi gan-an.” Ẹlòmíràn ṣàkópọ̀ bó ṣe rí lára púpọ̀ wọn nípa sísọ̀rọ̀ tìtaratìtara pé: “Inú ìfẹ́ tí ń tú kọ̀ọ́kọ̀ọ́ la wà ní ti gidi!”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
“SÁÀ ÀGBÁKÒ”
Ní àárín oṣù December, láìpẹ́ sígbà tí ìjì yẹn wá jà, ọkọ̀ òkun tó ń jẹ́ Erika, tó gbé epo rì sínú ìgbì alagbalúgbú omi òkun níbi tó ku nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà kó dé etíkun ìhà ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Faransé, ó sì da ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tọ́ọ̀nù epo rọ̀bì sínú omi. Eteetí òkun tó jẹ́ nǹkan bí irinwó kìlómítà láti Brittany títí dé Vendée lo bà jẹ́. Ìjì náà wá mú kí àgbákò tó ṣẹlẹ̀ láyìíká yìí burú sí i nípa kíkó epo náà jọ ṣẹ́ẹ́ṣẹ̀ẹ̀ṣẹ́ kiri ojú omi, wọ́n sì ń ṣe mẹ̀yẹ̀nmẹ̀yẹ̀n, èyí mú kí àyíká náà dọ̀tí sí i, pípalẹ̀ rẹ̀ mọ́ sì wá ṣòro gan-an. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni, lọ́mọdé lágbà, ló wá jákèjádò ilẹ̀ Faransé tí wọ́n wá ṣèrànwọ́ láti palẹ̀ epo tó ń ṣe mẹ̀yẹ̀nmẹ̀yẹ̀n náà mọ́ kúrò lára àwọn àpáta àti yanrìn.
Jàǹbá náà ba àyíká etíkun jẹ́ gan-an. Ó ba iṣẹ́ jẹ́ fún àwọn ilé iṣẹ́ tí ń kó ìsán àti ìṣáwùrú lókun. Àwọn onímọ̀ nípa ẹyẹ sọ pé, ó kéré tán ogún ọ̀kẹ́ [400,000] ẹyẹ òkun—ẹyẹ puffin, grebe, gannet, àti ní pàtàkì ẹyẹ guillemot—ló kú. Ìyẹn tó ìlọ́po mẹ́wàá iye tó kú lẹ́yìn tí ọkọ̀ òkun tó ń jẹ́ Amoco Cadiz, tó gbé epo rì nítòsí etíkun Brittany ní oṣù March ọdún 1978. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹyẹ náà ló wá gbádùn ìgbà òtútù ní etíkun ilẹ̀ Faransé lẹ́yìn tí wọ́n ṣí kúrò ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Ireland, àti Scotland. Ọ̀gá Àjọ Tó Ń Rí sí Ààbò Àwọn Ẹyẹ ní Rochefort sọ pé: “Àjálù gbáà ni ti epo tó dà sójú omi yìí. Òun ló ṣì burú jù lọ lára gbogbo èyí tí a ti rí. . . . Ẹ̀rù ń bà wá pé iye àwọn ẹyẹ tí kò wọ́pọ̀ lè máa dín kù sí i tàbí kí wọ́n tilẹ̀ máà sí mọ́ ní àwọn etíkun ilẹ̀ Faransé.”
[Credit Line]
© La Marine Nationale, France
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Hẹlikópítà ni wọ́n fi gba ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn là, bó ṣe ṣẹlẹ̀ níhìn-ín ní Cuxac d’Aude
[Credit Line]
B.I.M.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Láàárín àwọn ọgbà àjàrà tó bà jẹ́, ojú irin kan tó bà jẹ́ kò wúlò mọ́
[Credit Line]
B.I.M.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó rún wómúwómú wà káàkiri ilẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ní Villedaigne, ọkùnrin yìí ò lè kúrò níbi tó wà fún wákàtí méje
[Credit Line]
J.-M Colombier
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Bí ìgbà téèyàn dá igi ìṣáná ni àwọn igi ahóyaya ń dá péú ní àgbègbè Creuse
[Credit Line]
© Chareyton/La Montagne/MAXPPP
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Ní ọgbà Ààfin Versailles nìkan, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá igi ló wó
[Credit Line]
© Charles Platiau/Reuters/MAXPPP
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ní Saint-Pierre-sur-Dives, Normandy
[Credit Line]
© M. Daniau/AFP
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ọ̀wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń tún ilé arúgbó kan ṣe ní La Redorte (lókè) àti gbọ̀ngàn ìlú ní Raissac d’Aude (lápá ọ̀tún)