ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 8/8 ojú ìwé 22-23
  • Ṣíṣe Ara Lọ́ṣọ̀ọ́—Ìdí Tí A Kò Fi Gbọ́dọ̀ Ṣàṣejù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣe Ara Lọ́ṣọ̀ọ́—Ìdí Tí A Kò Fi Gbọ́dọ̀ Ṣàṣejù
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣà Ayé Àtijọ́
  • Òmìnira Kristẹni
  • Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Yẹ Láti Gbé Yẹ̀ Wò
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Fín Ara?
    Jí!—2003
  • Ṣé Ó Yẹ Kí N Fín Ara?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Fínfín Àmì sí Ara?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ẹ Mú Ìfòyebánilò Dàgbà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 8/8 ojú ìwé 22-23

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣíṣe Ara Lọ́ṣọ̀ọ́—Ìdí Tí A Kò Fi Gbọ́dọ̀ Ṣàṣejù

“OHUN asán ní ń dààmú làákàyè,” ohun tí òǹkọ̀wé kan nílẹ̀ Faransé kọ nìyẹn. Dájúdájú, làákàyè kò fi bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ mọ́ nítorí pé ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan tí àwọn ènìyàn ti ṣe fún ara wọn ní àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá ló jẹ́ ohun asán. Fún àpẹẹrẹ, nínú ìsapá àwọn obìnrin ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún láti jẹ́ kí ìgbáròkó wọn kéré gan-an bó ti lè ṣeé ṣe tó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fìyà jẹ ara wọn nípa fífi aṣọ ìgbànú fún ikùn wọn pinpin tó fi jẹ́ pé agbára káká ni wọ́n fi ń mí. Àwọn kan lára wọn sọ pé ìgbáròkó àwọn kéré gan-an, pé ó jẹ́ sẹ̀ǹtímítà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n péré. Aṣọ ìgbànú táwọn obìnrin kan lò fún wọn pinpin gan-an débi pé ẹfọ́nhà wọn lọ gún ẹ̀dọ̀ wọn, èyí sì ṣekú pa wọ́n.

Bó tilẹ̀ jẹ́ ohun ayọ̀ pé àṣà ìṣoge yẹn ti kógbá wọlé, síbẹ̀ a ṣì ń rí èrò asán tó ṣokùnfà rẹ̀ lónìí bíi tìgbà yẹn. Tọkùnrin tobìnrin ló ṣì ń ṣe àwọn ohun tó le, tó sì léwu gan-an láti lè yí ìrísí wọn padà sí bí Ọlọ́run ṣe dá wọn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ibi tí wọ́n ti ń fín ara àti ibi tí wọ́n ti ń dá ara lu, tó jẹ́ pé àwùjọ àwọn tí ìwà wọn kò ṣeé fi ṣe àwòkọ́ṣe ló ń ná ibẹ̀, ti ń rú yọ láwọn ilé ìtajà ńláńlá àti láwọn ìgbèríko. Kódà, ní ọdún kan láìpẹ́ yìí, àṣà fífín ara ló gba ipò kẹfà lára àwọn òwò tó ń yára gbèrú jù lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.

Oríṣiríṣi ọ̀nà ìṣaralóge láṣerégèé ló tún ti ń pọ̀ sí i, pàápàá láàárín àwọn ọ̀dọ́. Àṣà dídá àwọn ẹ̀yà ara lu rẹpẹtẹ—títí kan orí ọmú, imú, ahọ́n, àti abẹ́ pàápàá—ti ń wọ́pọ̀ gan-an. Ní ti àwùjọ kéréje kan, irú àṣà dídá ẹ̀yà ara lu tó gbalẹ̀ kan bẹ́ẹ̀ kò tiẹ̀ mú wọn lórí yá tó. Wọ́n ti ń gbìyànjú àwọn àṣà àṣejù míì, bíi fífi irin gbígbóná sàmì sára, fífi abẹ la ara,a gbígbẹ́ ọnà sára, èyí tí wọ́n máa ń ṣe nípa kíki nǹkan sábẹ́ awọ ara kó lè wú síta dáadáa, kí ara wọn sì lè yọ oríṣiríṣi igun.

Àṣà Ayé Àtijọ́

Ṣíṣe ara lọ́ṣọ̀ọ́ tàbí títún ìrísí ẹni ṣe kì í ṣe tuntun. Ní àwọn apá ibì kan ní Áfíríkà, fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni wọ́n ti máa ń fi ara lílà àti ara fífín dá àwọn ìdílé tàbí ìran kan mọ̀ yàtọ̀. Ó dùn mọ́ni nínú pé ní ọ̀pọ̀ lára àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí, wọn kò fi ojú rere wo irú àṣà wọ̀nyí mọ́, àwọn àṣà náà sì ti ń kásẹ̀ nílẹ̀.

Àṣà fífín ara, dídá ara lu, àti fífi abẹ la ara wà ní àwọn àkókò tí wọ́n kọ Bíbélì. Àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ló sábà máa ń dá àwọn àṣà náà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀sìn wọn. Abájọ tí Jèhófà ṣe kà á léèwọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀, àwọn Júù, pé kí wọ́n má ṣe fara wé àwọn abọ̀rìṣà wọ̀nyẹn. (Léfítíkù 19:28) Gẹ́gẹ́ bí “àkànṣe dúkìá” Ọlọ́run, ó tipa bẹ́ẹ̀ dáàbò bo àwọn Júù lọ́wọ́ àwọn àṣà ẹ̀sìn èké tí ń rẹni nípò wálẹ̀.—Diutarónómì 14:2.

Òmìnira Kristẹni

Àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin Mósè, síbẹ̀síbẹ̀ ó fi àwọn ìlànà kan lélẹ̀ tí ìjọ Kristẹni ń mú lò. (Kólósè 2:14) Wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ mú ara wọn wà láàlà ohun tó tọ́ tó bá kan ọ̀ràn irú ohun ìṣaralọ́ṣọ̀ọ́ tí wọ́n yàn láti fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́. (Gálátíà 5:1; 1 Tímótì 2:9, 10) Bó ti wù kó rí, òmìnira yìí láàlà.—1 Pétérù 2:16.

Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nínú 1 Kọ́ríńtì 6:12, pé: “Ohun gbogbo ni ó bófin mu fún mi; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní àǹfààní.” Pọ́ọ̀lù lóye pé òmìnira tí òun ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni kò fún òun ní òmìnira láti máa ṣe ohunkóhun tí òun bá fẹ́ láìgba tàwọn ẹlòmíràn rò. Ìfẹ́ tó ní fáwọn ẹlòmíràn ló ń sún un hùwà. (Gálátíà 5:13) Ó pàrọwà pé, kí ẹ “má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Èrò àìnímọtara-ẹni-nìkan rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá fún Kristẹni èyíkéyìí tó bá ń ronú nípa àwọn ọ̀nà ìṣaralóge kan.

Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Yẹ Láti Gbé Yẹ̀ Wò

Ọ̀kan lára àṣẹ tí a pa fún àwọn Kristẹni ni láti wàásù ìhìn rere náà, ká sì fi kọ́ àwọn èèyàn. (Mátíù 28:19, 20; Fílípì 2:15) Kò yẹ kí Kristẹni èyíkéyìí jẹ́ kí ohunkóhun, títí kan ìrísí rẹ̀, dí àwọn mìíràn lọ́wọ́ tí wọn kò fi ní lè tẹ́tí sí iṣẹ́ náà.—2 Kọ́ríńtì 4:2.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn ọ̀nà ìṣaralóge bíi dídá ara lu tàbí fífín ara lè wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn kan, ó yẹ kí Kristẹni kan bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Irú ojú wo làwọn ará àdúgbò tí mo ń gbé yóò fi wo irú oge ṣíṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé wọ́n á kà mí mọ́ ẹgbẹ́ àwọn aláṣejù láwùjọ? Kódà, bí ẹ̀rí ọkàn mi bá fàyè gbà á, ipa wo ni ara dídá lu tàbí ara fífín mi yóò ní lórí àwọn mìíràn nínú ìjọ? Ǹjẹ́ wọ́n á wò ó bí ẹ̀rí pé mo ní “ẹ̀mí ayé”? Ǹjẹ́ ó lè gbé iyè méjì dìde nípa “ìyèkooro èrò inú” mi?’—1 Kọ́ríńtì 2:12; 10:29-32; Títù 2:12.

Oríṣi àwọn ọ̀nà kan tí àwọn èèyàn ń gbà yí ara padà máa ń ní ewu nínú ní ti ìṣègùn. Wọ́n sọ pé fífi àwọn abẹ́rẹ́ tí kò mọ́ fín ara wà lára ohun tó ń mú kí àrùn mẹ́dọ̀wú àti fáírọ́ọ̀sì HIV tó ń di àrùn éèdì máa ràn kálẹ̀. Nígbà mìíràn, àwọn aró tí wọ́n ń lò máa ń fa kòkòrò sára. Ó lè gba ọ̀pọ̀ oṣù kí ara tí wọ́n dá lu tó jiná, ó sì lè máa dunni ní èyí tó pọ̀ jù láàárín àkókò náà. Wọ́n tún lè fa kòkòrò àrùn tí ń ba ẹ̀jẹ̀ jẹ́ sára, ara lè máa ṣẹ̀jẹ̀, ara lè máa dáranjẹ̀, iṣan ara lè bà jẹ́, èèyàn sì lè kó àrùn tó burú. Láfikún sí i, téèyàn bá ti kira bọ oríṣi àwọn ìlànà kan, kì í rọrùn láti yí padà. Fún àpẹẹrẹ, ó lè gba lílo ẹ̀rọ tí ń tan ìtànṣán, tó máa ń dunni kí wọ́n tó lè pa ohun tí èèyàn fín sára rẹ́, bí owó téèyàn á ná sí ìtọ́jú náà ṣe máa pọ̀ tó àti iye ìgbà tí wọ́n á ṣe é sinmi lórí bí ohun tó fín sára bá ṣe fẹ̀ tó àti irú àwọ̀ tó jẹ́. Àpá ibi tí a dá lu lára náà lè wà níbẹ̀ títí ayé.

Yálà ẹnì kan pinnu láti fara mọ́ àwọn ewu wọ̀nyí tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá ń wá láti mú inú Ọlọ́run dùn mọ̀ pé dídi Kristẹni ní í ṣe pẹ̀lú fífi ara ẹni fún Ọlọ́run. Ara wa jẹ́ ẹbọ ààyè tí a fi fún Ọlọ́run láti fi ṣiṣẹ́. (Róòmù 12:1) Nítorí náà, àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú kì í ronú pé ara àwọn jẹ́ ohun ìní àwọn pátápátá tí àwọ́n lè bà jẹ́ tàbí tí àwọ́n lè yí padà bí àwọ́n bá fẹ́. Ní pàtàkì, a mọ àwọn tí wọ́n tóótun láti mú ipò iwájú nínú ìjọ pé ìwà wọ́n wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, wọ́n yè kooro ní èrò inú, wọ́n sì jẹ́ afòyebánilò.—1 Tímótì 3:2, 3.

Níní agbára ìrònú tí a fi Bíbélì kọ́, tí a sì ń lò ó, yóò ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti yẹra fún dídá àṣà àṣejù ti fífi ìyà jẹ ara wọn báwọn èèyàn ayé ti ń ṣe, ìyẹn àwọn tí kò nírètí, ‘tí a sọ di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run.’ (Éfésù 4:18) Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á jẹ́ kí ìfòyebánilò wọn máa tàn níwájú gbogbo ènìyàn.—Fílípì 4:5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fífi abẹ la ara nítorí ìtọ́jú tàbí nítorí aájò ẹwà jẹ́ ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí àṣà fífi abẹ la ara tàbí gígé ẹ̀yà ara dànù láìnídìí tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ń dá, pàápàá àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́langba. Èkejì táa mẹ́nu kàn yẹn sábà máa ń jẹ́ àmì másùnmáwo tó lágbára tàbí ti ìfìyàjẹni, tó lè béèrè pé káwọn amọṣẹ́dunjú ran ẹni náà lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́