ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 9/8 ojú ìwé 20-22
  • Bí Loida Ṣe Di Ẹni Tó Ń Sọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Loida Ṣe Di Ẹni Tó Ń Sọ̀rọ̀
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbìyànjú Láti Mú Kó Sọ̀rọ̀ Ní Kékeré
  • Ohùn Rẹ̀ Là
  • Ìtẹ̀síwájú Nípa Tẹ̀mí
  • Ìrànlọ́wọ́ Láti Forí Tì Í
  • Ẹ̀kọ́ Táwọn Èèyàn Kọ́ Látinú Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Loida
    Jí!—2001
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2001
  • Sọ fún Wọn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Wọn
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Jí!—2000
g00 9/8 ojú ìwé 20-22

Bí Loida Ṣe Di Ẹni Tó Ń Sọ̀rọ̀

Gẹ́gẹ́ bí ìyá Loida ṣe sọ ọ́

BÍI ti ìyá èyíkéyìí tó lóyún, mo ń dààmú pé mo lè bímọ náà tán kó ní àwọn àbùkù kan lára. Ṣùgbọ́n, mi ò fẹ́ kí Loida tó jẹ́ ọmọ mi kẹta máa sunkún nítorí ìrora nígbà tó bá dé ayé. Láìmọ̀, dókítà ti fi ẹ̀mú rẹ̀ kán egungun tó gbé èjìká Loida dúró. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ́ láti ṣàtúnṣe rẹ̀, wọ́n dá Loida padà sílé. Ṣùgbọ́n ìdùnnú wa kò tọ́jọ́.

Láàárín oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, ó wá hàn gbangba pé nǹkan burúkú kan ti ṣẹlẹ̀. Àwọn oògùn tí wọ́n fún Loida ti gbòdì lára rẹ̀—ibà, àrunṣu, àti gìrì ń ṣe é—ó sì jọ pé àwọn oògùn tí wọ́n fún un láti wo àwọn àìsàn yìí ń mú kí ìṣòro náà túbọ̀ pọ̀ sí i ni. Láìpẹ́, Loida kò lè dá gbé àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ mọ́. Níkẹyìn, àwọn dókítà sọ fún wa pé ìṣòro Loida ni pé ọpọlọ rẹ̀ kò lè darí ìséraró àti ìsọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n ní kò ní lè rìn, kò ní lè sọ̀rọ̀—ọ̀rọ̀ wa kò sì ní lè yé e.

Ìgbìyànjú Láti Mú Kó Sọ̀rọ̀ Ní Kékeré

Láìka àsọtẹ́lẹ̀ bíbanilẹ́rù náà sí, mo ṣì ronú pé Loida lè lóye nǹkan púpọ̀. Nítorí náà, mo máa ń ka àwọn ìwé tó rọrùn gan-an fún un, mo sì ń gbìyànjú láti kọ́ ọ ní àwọn ábídí. Ṣùgbọ́n Loida kò lè sọ̀rọ̀, kò sì lè fi hàn rárá pé òun ń mọ ohun tí mo ń sọ. Kò sí bí mo ṣe lè mọ ohun tó lè yé e bí ohunkóhun bá tilẹ̀ lè yé e rárá.

Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ó jọ pé gbogbo ìsapá mi láti máa kọ́ Loida kò fi bẹ́ẹ̀ yọrí sí rere. Ṣùgbọ́n mi ò yé kàwé fún un. A tilẹ̀ máa ń jẹ́ kí òun àti ọmọ wa tó kéré jù, Noemí, wà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ìdílé wa tí a ń fi ìwé Fifetisilẹ si Olukọ Nla Na àti Iwe Itan Bibeli Mi ṣe.a Mo ka ọ̀pọ̀ lára àkòrí inú àwọn ìwé náà fún Loida lọ́pọ̀ ìgbà.

Ó máa ń bani nínú jẹ́ gan-an tí a kò bá lè bá ẹni tí a fẹ́ràn sọ̀rọ̀. Tí mo bá gbé Loida lọ sí ọgbà ìtura, ńṣe ló máa ń sunkún tí kò sì sẹ́ni tó lè bẹ̀ ẹ́ kó gbọ́. Kí ló fa ìyẹn? Lójú tèmi, ó jọ pé ara ń ta á pé kò lè sáré kiri kó sì máa ṣeré bíi tàwọn ọmọdé yòókù. Nígbà kan, Loida bú sẹ́kún nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ka ohun kan fún mi láti inú ìwé kan tí wọ́n ń lò nílé ìwé. Ó hàn kedere pé ohun kan ń dà á láàmú, ṣùgbọ́n mi ò mọ ohun tó jẹ́. Ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ tí Loida lè sọ kò ju kó kàn dún nígbà bíi mélòó kan lọ, ìyẹn ló sì fi ń tọ́ka pé òun fẹ́ oúnjẹ, omi, pé òun fẹ́ sùn, tàbí pé òun fẹ́ yàgbẹ́.

Nígbà tí Loida pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, ó bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ilé ìwé kan tó wà fún àwọn ọmọ tí wọ́n nílò àkànṣe ìrànlọ́wọ́. Ṣùgbọ́n láàárín ọdún mẹ́ta tó tẹ̀ lé e, ipò rẹ̀ tún burú sí i. Ẹ̀rù ń bà á láti rìn, kódà láti gbẹ́sẹ̀ nígbà bíi mélòó kan láìjẹ́ pé wọ́n dì í mú, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè dún mọ́ bó ṣe ń dún láti fi hàn pé òun ń sọ nǹkan kan. Èmi àti ọkọ mi pinnu pé yóò dára ká máa kọ́ Loida lẹ́kọ̀ọ́ nílé.

Láàárín oṣù mẹ́fà tó tẹ̀ lé e, mo kọ́ Loida bí mo ṣe lè ṣe tó. Mo máa ń kọ ọ̀rọ̀ sórí pátákó ìkọ̀wé, pẹ̀lú èrò pé Loida á lè dà wọ́n kọ. Pàbó ni ìsapá mi já sí. Ṣé àìlóye nǹkan ni ìṣòro Loida ni, àbí nítorí pé kò lè darí gbígbé ara rẹ̀ ni kò ṣe lè kọ̀wé?

Nígbà tí Loida pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, títọ́jú rẹ̀ ti wá le gan-an débi pé mo gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà, mo bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí èmi àti ọmọ mi lè bá ara wa sọ̀rọ̀. Ọ̀nà àrà ni ìdáhùn sí àdúrà mi gbà wá.

Ohùn Rẹ̀ Là

Àkókò ìyípadà ńlá dé nígbà tí àwọn ọmọ mi ń tún iyàrá wa tò. Kí wọ́n tó ya ògbólógbòó bébà mèremère tí a lẹ̀ mọ́ ara ògiri, Noemí kọ àwọn orúkọ kan sára ògiri náà—àwọn orúkọ inú Bíbélì àti orúkọ àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí wa. Ọmọbìnrin mi Rut fẹ́ tọpinpin, ló bá béèrè lọ́wọ́ Loida bóyá ó mọ ibi tí wọ́n kọ “Jèhófà” sí. Ó yà á lẹ́nu pé Loida lọ sára ògiri, ó sì gbé orí rẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí orúkọ Ọlọ́run wà. Rut fẹ́ mọ̀ bóyá Loida lè mọ àwọn orúkọ yòókù, nítorí náà, ó ṣèdánwò fún un. Ó ya Rut lẹ́nu pé Loida mọ gbogbo wọn, kódà ó mọ àwọn orúkọ tí a kò tíì kọ sílẹ̀ lójú rẹ̀ rí! Rut pe gbogbo wa jọ ká lè fojú ara wa rí i. Loida ti lè kàwé o!

Bí àkókò ti ń lọ, a ṣàgbékalẹ̀ ọ̀nà kan tí Loida yóò lè máa gbà bá wa “sọ̀rọ̀.” A lẹ lẹ́tà ábídí mọ́ ara ògiri ọ̀dẹ̀dẹ̀ wa. Kíkọ àwọn ọ̀rọ̀ tó kéré gan-an sórí pátákó tí a gbé dání kò ṣiṣẹ́, níwọ̀n bí Loida kò ti lè darí gbígbé ọwọ́ rẹ̀ dáadáa láti lè tọ́ka sí ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, nígbà tí Loida bá fẹ́ sọ nǹkan kan, yóò jẹ́ kí a mọ ohun tó fẹ́ nípa lílọ sídìí àwọn lẹ́tà tó para pọ̀ di ọ̀rọ̀ náà níkọ̀ọ̀kan. Bí ẹ̀yin náà ṣe lè finú wòye rẹ̀, ìdààmú gbáà lèyí jẹ́. Ní gidi, ó máa ń gba Loida ní ìrìn ọ̀pọ̀ kìlómítà kó tó lè kọ ọ̀rọ̀ tí yóò gba ojú abala ìwé kan, ó sì lè gbà á ní ọ̀pọ̀ wákàtí láti parí rẹ̀!

Bó ti wù kó rí, inú Loida dùn pé òun ń lè bá wa “sọ̀rọ̀.” Ní ti gidi, ohun tó kọ́kọ́ bá wa sọ ni pé: “Inú mi dùn gan-an pé mo lè báa yín sọ̀rọ̀, ọpẹ́ ni fún Jèhófà.” Ẹnu yà wá gidigidi, a bi Loida léèrè pé: “Kí ni o ń ṣe ní gbogbo ìgbà tí o kàn ń jókòó láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀?” Loida sọ fún wa pé ńṣe lòún máa ń ronú ohun tí òun ì bá fẹ́ pé kí òun lè sọ fún wa. Loida tilẹ̀ sọ pé ó ti pé ọdún méjìdínlógún tí òun ti ń fẹ́ láti bá wa sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: “Nígbà tí Rut bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ilé ìwé, mo ka ìwé ilé ìwé rẹ̀ fúnra mi. Mo la ẹnu, mo sì dún bákan, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kò yé yín. Ìdí nìyẹn tí mo fi máa ń sunkún lọ́pọ̀ ìgbà.”

Mo bẹ̀ ẹ́ tomijé-tomijé nítorí pé n kò lóye rẹ̀ dáadáa. Loida fèsì pé: “Ìyá dáadáa ni yín, ẹ kò juwọ́ sílẹ̀ rárá. Gbogbo ìgbà tí mo bá wà pẹ̀lú yín ni inú mi máa ń dùn. Mo nífẹ̀ẹ́ yín gan-an. Ẹ má sunkún mọ́. Ṣẹ́ẹ gbọ́?”

Ìtẹ̀síwájú Nípa Tẹ̀mí

Loida ti ní ìmọ̀ Bíbélì ná, ó sì ti kọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, ó sọ fún wa pé òun fẹ́ máa dáhùn nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ní ìjọ, ìyẹn ìjíròrò Bíbélì tí a ń ṣe nípasẹ̀ ìbéèrè àti ìdáhùn. Báwo ni yóò ṣe máa ṣe é? Ẹnì kan nínú wa yóò ka àpilẹ̀kọ náà fún un látòkè délẹ̀. Lẹ́yìn náà, Loida á wá mú ọ̀kan tí yóò fẹ́ láti dáhùn lára àwọn ìbéèrè náà. A óò kọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ bó ṣe tọ́ka sí àwọn lẹ́tà rẹ̀ fún wa lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Tí a bá wá dé ìpàdé, ẹnì kan lára wa yóò ka ọ̀rọ̀ Loida jáde. Loida sọ fún wa nígbà kan pé: “Inú mi ń dùn pé mo ń lè kópa nítorí pé ó ń jẹ́ kí ń nímọ̀lára pé mo jẹ́ apá kan ìjọ.”

Nígbà tí Loida wà ní ọmọ ogún ọdún, ó fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti ṣèrìbọmi hàn. Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ Loida bóyá ó mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ya ara ẹni sí mímọ́ fún Jèhófà, ó dáhùn pé òun ti ṣe ìyàsímímọ́ ní ọdún méje sẹ́yìn—nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá. Ó sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì wí fún un pé mo fẹ́ sìn ín títí láé.” Ní August 2, 1997, Loida fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ fún Jèhófà hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi. Loida sọ fún wa pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, ìfẹ́ ọkàn mi tó ga jù lọ ti ṣẹ!”

Loida gbádùn sísọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ẹbí àti aládùúgbò wa. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń tẹ̀ lé wa tí a bá lọ wàásù fún àwọn ènìyàn ní òpópónà. Ó tún ti kọ lẹ́tà kan tí a máa ń fi há ẹnu ọ̀nà àwọn ènìyàn tí wọn kò bá sí nílé. Loida máa ń ṣàníyàn nípa àwọn arúgbó àti àwọn aláìsàn gan-an. Fún àpẹẹrẹ, arábìnrin kan wà ní ìjọ wa tí wọ́n gé ẹsẹ̀ rẹ̀. Loida sọ fún wa pé: “Mo mọ ohun tó túmọ̀ sí tí èèyàn kò bá lè rìn,” nítorí náà, ó kọ lẹ́tà ìṣírí kan sí arábìnrin náà. Bákan náà, ọmọdékùnrin kan wà ní ìjọ mìíràn, orúkọ rẹ̀ ni Jairo, ọmọ náà rọ lọ́wọ́ rọ lẹ́sẹ̀. Nígbà tí Loida gbọ́ nípa ìṣòro ọmọ náà, ó kọ lẹ́tà sí i. Apá kan lẹ́tà náà kà pé: “Láìpẹ́ Jèhófà yóò mú wa lára dá. Kì yóò sí ìrora nínú Párádísè. Tó bá di ìgbà yẹn, a óò jọ fi eré sísá dánra wò. Mo ń rẹ́rìn-ín nítorí a óò gbádùn rẹ̀ gan-an ni. Láti ronú pé a óò wà bí Jèhófà ṣe dá wa, tí a kò ní ṣàìsàn rárá . . . O ò rí i pé nǹkan àgbàyanu ni?”

Ìrànlọ́wọ́ Láti Forí Tì Í

Mo ti wá lóye ọ̀pọ̀ nǹkan nípa bí Loida ṣe ń hùwà tẹ́lẹ̀ tó máa ń yà mí lẹ́nu. Fún àpẹẹrẹ, Loida sọ pé nígbà tí òun ṣì kéré, òun kì í fẹ́ kí wọ́n gbá òun mọ́ra nítorí pé kò sí ohun tó ń ṣí òun lórí. Ó sọ pé: “Ó jọ pé ojúsàájú ni pé àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi lè sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì máa kẹ́kọ̀ọ́ àwọn nǹkan, kí èmi máà sì lè ṣe bẹ́ẹ̀. Inú máa ń bí mi gan-an. Àwọn ìgbà kan tilẹ̀ wà tí mo máa ń ronú pé ì bá dára kí n ti kú.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Loida ti ń lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ó ṣì ní ọ̀pọ̀ ìṣòro. Fún àpẹẹrẹ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé oṣooṣù ni gìrì máa ń gbé e, tí yóò dà bíi pé nǹkan ń fún un lọ́rùn, ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ á sì máa gbọ̀n. Ní àfikún sí i, tó bá ní àrùn èyíkéyìí—kódà bó jẹ́ òtútù lásán—ńṣe ló máa sọ ọ́ di ahẹrẹpẹ. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, Loida máa ń kárí sọ nítorí ohun tó ń ṣe é. Kí ló ń ràn án lọ́wọ́ láti forí tì í? Ẹ tilẹ̀ jẹ́ kó fúnra rẹ̀ sọ ọ́ fún yín:

“Àdúrà ti ṣèrànwọ́ púpọ̀ jọjọ. Inú mi máa ń dùn láti bá Jèhófà sọ̀rọ̀, láti mọ̀ pé mo sún mọ́ ọn. Mo tún mọrírì ìfẹ́ àti àfiyèsí tí àwọn mìíràn ń fún mi ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Mo nímọ̀lára pé mo ṣoríire bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní àbùkù ara, àwọn òbí àtàtà méjì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi gan-an ló tọ́ mi. N kò ní gbàgbé bí àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi ṣe ràn mí lọ́wọ́. Àwọn ẹyọ ọ̀rọ̀ dáradára tó wà lórí bébà mèremère ara ògiri wa tẹ́lẹ̀ yẹn gba ẹ̀mí mi là. Láìsí ìfẹ́ tí Jèhófà àti ìdílé mi ní sí mi, ìgbésí ayé mi ì bá máà já mọ́ nǹkan kan.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe. A kò tẹ ìwé Fifetisilẹ si Olukọ Nla Na mọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Loida àti ìdílé rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́