Ìdí Táwọn Èèyàn Fi Ń Hùwàkiwà
NÍ OCTOBER ọdún tó kọjá, ẹnì kan kọ̀wé sí wa láti Loja, Ecuador, ó fi ìmọrírì rẹ̀ hàn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Díẹ̀ lára ohun tó sọ ni pé:
“Ọ̀kan lára ìṣòro tó burú jù tó ń bá aráyé jà ni ìwàkiwà táwọn èèyàn ń hù . . . Ó jọ pé àwọn èèyàn ti gbàgbé láti máa fi ohun tó wà nínú Òfin Mẹ́wàá sílò, wọ́n kò sì lo ẹ̀rí-ọkàn wọn mọ́, gbogbo èyí kò sì jẹ́ kí àwọn èèyàn gbọ́ ara wọn lágbọ̀ọ́yé mọ́. Níbi gbogbo àti lójoojúmọ́ ni a ń gbọ́ nípa ìkórìíra, ìwà ipá, ìwà ọ̀daràn, ṣíṣe fàyàwọ́ oògùn olóró, ìpániláyà, àti àìfún ẹ̀dá ní iyì tó tọ́ sí i. . . .
“Láìsí àṣehàn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní tiwọn ń ṣe ojúṣe wọn lọ́nà tó lálàáfíà, ní pẹ̀lẹ́tù, wọ́n ń bẹ àwọn aládùúgbò wọn wò nínú iṣẹ́ ilé dé ilé wọn, wọ́n ń fi àwọn ìwé ìròyìn wọn méjèèjì náà lọ àwọn èèyàn, ìyẹn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, nínú èyí tí wọ́n ti ń gbé àwọn àpilẹ̀kọ tó gbádùn mọ́ni jù lọ jáde. Ní pàtàkì Jí! ń sọ nípa onírúurú àwọn ọ̀rọ̀ tó gbádùn mọ́ni tó jẹ́ ti ojúlówó ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀. Gbogbo rẹ̀ ni a kọ lọ́nà tó ṣe kedere tó sì pé pérépéré.”
Lónìí, gbangba-gbàǹgbà làwọn èèyàn ń hùwàkiwà, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ní ojú ìwé kẹrin ìwé ìròyìn yìí lápá ibi tí a kọ ọ̀rọ̀ náà sí pé “Ìdí Tí A Fi Ń Tẹ Jí! Jáde,” Jí! “ń tọpinpin ré kọjá ohun tó fara hàn lóréfèé, ó sì ń ṣàlàyé ohun tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ túmọ̀ sí ní ti gidi.” Ìwé pẹlẹbẹ náà Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? sọ nípa ìyà tí aráyé ti ń fàyà rán tipẹ́tipẹ́, ṣùgbọ́n ó tún ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó fi ìdí tí àwọn èèyàn ṣe ń hùwàkiwà hàn àti aburú tó ń tìdí rẹ̀ yọ. Ní pàtàkì jù lọ, ó fi bí a óò ṣe rí ìrànlọ́wọ́ gbà láìpẹ́ hàn.
O lè rí ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí gbà tí o bá kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì táa kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tí a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.