ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 12/8 ojú ìwé 13-14
  • Ǹjẹ́ Ẹsẹ̀ Máa Ń Rìn ọ́ Wìnnìwìnnì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ẹsẹ̀ Máa Ń Rìn ọ́ Wìnnìwìnnì?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Tó Ń Ṣe
  • Wíwá Ìwòsàn Kiri
  • Fífara Da Àrùn Ẹsẹ̀ Rírinni Wìnnìwìnnì
  • Bí O Ṣe Lè Túbọ̀ Máa Sùn Dáadáa
    Jí!—2003
  • Báa Ṣe Lè Dá Àwọn Àmì Ìsoríkọ́ Mọ̀
    Jí!—2001
  • Mímọ Àwọn Ìṣòro Líle Koko Tí Kì Í Jẹ́ Kéèyàn Rí Oorun Sùn
    Jí!—2004
  • Dídá Àwọn Àmì Àrùn Mọ̀ àti Ṣíṣiṣẹ́ Lé Wọn Lórí
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 12/8 ojú ìwé 13-14

Ǹjẹ́ Ẹsẹ̀ Máa Ń Rìn ọ́ Wìnnìwìnnì?

ILẸ̀ ti ṣú. Orí ibùsùn rẹ tí o fẹ̀gbẹ́ lé rọ̀ ọ́ lọ́rùn, ó sì tù ọ́ lára. Ni kinní náà bá bẹ̀rẹ̀—bíi pé kòkòrò kan ń mẹ́sẹ̀ rìn ọ́ wìnnìwìnnì. O kò lè pa á mọ́ra bíi pé nǹkan kan ò ṣe ọ́. Ọ̀nà kan ṣoṣo tí o fi lè rí ìtura ni láti dìde kí o sì rìn kiri. Rírìn kiri á jẹ́ kí ara tù ọ́, ṣùgbọ́n gbàrà tí o bá tún ti dùbúlẹ̀, á tún bẹ̀rẹ̀ sí rìn ẹ́ wìnnìwìnnì. Oorun á máa kùn ẹ́, ṣùgbọ́n o kò ní lè sùn. Bí ohun tí a ń sọ yìí bá dà bí ohun tó ń ṣe ọ́, ìwọ nìkan kọ́ ló ń ṣe o. Fún àpẹẹrẹ, ó jọ pé nǹkan bí ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo àwọn olùgbé Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló ń ṣe.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ dókítà lónìí ni kò mọ ohun tó ń fa àrùn yìí tí wọn ò sì lè wo ẹni tó ń ṣe sàn, kì í ṣe àrùn tuntun. Ní ọdún 1685, dókítà kan kọ̀wé nípa àwọn tó jẹ́ pé tí wọ́n bá ti bọ́ sórí ibùsùn ńṣe ni “ara wọn kì í Balẹ̀ rárá,” tí ọwọ́ àti ẹsẹ̀ á máa já wọn jẹ débi tí wọn “ò ní lè sùn mọ́ tó jẹ́ pé ńṣe ló máa dà bí ìgbà tí wọ́n wà ní Ibi Ìdálóró tó burú jù lọ.”

Díẹ̀ lára ohun tí kì í jẹ́ kí wọ́n mọ irú àrùn tó jẹ́ ni pé kò sí àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe níbi àyẹ̀wò ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tó lè fi hàn bí ó bá ń ṣe ẹnì kan. Bó ṣe ń ṣe èèyàn ni wọ́n fi ń mọ̀ pé òun ni. Dókítà kan tó bá mọ̀ nípa rẹ̀ lè béèrè pé: ‘Ṣé ẹsẹ̀ kan tàbí méjèèjì ló máa ń rìn ọ́ wìnnìwìnnì? Ṣé ọwọ́ náà máa ń rìn ọ́ bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ àìfararọ náà máa ń lọ tí o bá dìde tí o sì rìn káàkiri, tàbí tí o lọ wẹ̀, tàbí tí o wọ́ ẹsẹ̀ rẹ? Ǹjẹ́ ó máa ń rìn ọ́ nígbà mìíràn tí o bá ní láti jókòó fún àkókò pípẹ́, bí ìgbà tí o bá wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí ọkọ̀ òfuurufú? Ṣé alẹ́ ló máa ń yọ ẹ́ lẹ́nu jù? Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ ń ní irú ìṣòro kan náà? Ǹjẹ́ ọkọ rẹ tàbí ìyàwó rẹ sọ pé o máa ń ja ẹsẹ̀ lójú oorun?’ Bí ìdáhùn rẹ sí díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè yìí bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, dókítà náà lè parí èrò sí pé ohun tó ń ṣe ọ́ ni àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì.

Àwọn Tó Ń Ṣe

Fún àwọn kan, àrùn tí kò le, tó máa ń ṣeni lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì. Ní ti àwọn ẹlòmíràn, ó túbọ̀ le gan-an, ó máa ń fa ìṣòro àìróorunsùntó tó di bára kú, èyí tó ń fa àárẹ̀ lójú ọ̀sán tó máa ń ní ipa gidigidi lórí ìgbésí ayé ẹni lójoojúmọ́. Ẹnì kan tó ń ṣe sọ pé: “Ńṣe ló ń dà bíi pé kòkòrò ń rìn mì lẹ́sẹ̀ wìnnìwìnnì. Mo sì ní láti mi ẹsẹ̀ mi jìgìjìgì kó lè yé ṣe mí.”

Tọkùnrin tobìnrin ni àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì ń ṣe, ó sì máa ń le lára àwọn àgbàlagbà jù. Lọ́pọ̀ ìgbà, ara àwọn tí wọ́n ti lé ní àádọ́ta ọdún ni wọ́n ti máa ń ṣàwárí rẹ̀ jù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó sábàmáa ń ṣẹlẹ̀ pé èèyàn á ti máa rí àmì pé ó ń ṣeni ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ṣáájú ìgbà yẹn. Nígbà mìíràn, a lè tọpa àwọn àmì rẹ̀ lọ sí ìgbà tí èèyàn wà lọ́mọdé. Lọ́pọ̀ ìgbà, a kì í mọ̀ pé àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì ń ṣe ọmọdé. Nítorí pé àwọn ọmọdé tí àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì ń ṣe kì í jókòó sójú kan, wọ́n sì máa ń bẹ́ kiri, àwọn èèyàn sábà máa ń pè wọ́n ní “ẹ̀gbọ̀nrigbọ̀n.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ògbógi mọ̀ pé àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì jẹ́ àrùn tó ní í ṣe pẹ̀lú ètò iṣan ara, ó ṣòro fún wọn láti ṣàlàyé ohun tó ń fà á. Wọn kò mọ ohun tó fà á fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe. Bó ti wù kó rí, wọ́n sọ pé àwọn ohun kan ló ń fa àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì. Fún àpẹẹrẹ, àrùn yìí máa ń gbèèràn nínú ìdílé, àwọn ọmọ máa ń kó o lára àwọn òbí wọn. Àwọn obìnrin kan tí wọ́n lóyún máa ń rí àmì àrùn náà, pàápàá láàárín àwọn oṣù tó kẹ́yìn ìgbà ìlóyún wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n bá bímọ, àrùn náà sábà máa ń pòórá. Nígbà mìíràn, àwọn àìsàn bí àìtó èròjà iron tàbí àìtó àwọn fítámì kan lára máa ń ṣokùnfà ìṣòro àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì. Àrùn bára kú pẹ̀lú lè fa àwọn àmì àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì—ní pàtàkì kíndìnrín tí kò ṣiṣẹ́ mọ́, àrùn àtọ̀gbẹ, oríkèé ríroni gógó, àti ètò iṣan ara tó lábùkù, àwọn iṣan ọwọ́ àti ti ẹsẹ̀ tó ti bà jẹ́.

Wíwá Ìwòsàn Kiri

Ó bani nínú jẹ́ pé kò sí ìwòsàn fún àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì, bí ọdún ti ń gorí ọdún sì ni àwọn àmì tó ń gbé wá máa ń burú sí i. Ṣùgbọ́n, ìròyìn ayọ̀ kan ni pé wọ́n lè ṣètọ́jú àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì dáadáa, lọ́pọ̀ ìgbà láìlo oògùn sí i. Kò sí ojútùú kan ṣoṣo; ohun tó ṣiṣẹ́ fún ẹnì kan lè má ṣiṣẹ́ fún ẹlòmíràn. Àwọn tí àrùn náà ń ṣe ní láti wádìí bóyá àṣà, ìgbòkègbodò, tàbí àwọn oògùn kan ń mú kí ó le sí i tàbí wọ́n ń mú kí ó rọlẹ̀.

Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ fún títọ́jú àrùn náà ni láti pinnu bó bá jẹ́ pé àwọn àìlera kan tí a lè fi oògùn wò ló ń fa àwọn àmì tí àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì ń gbé yọ. Ní ti àwọn tí wọn kò ní èròjà iron tàbí fítámì tó lára, ó lè jẹ́ pé fífún wọn ní oògùn tó lè fi kún èròjà iron tàbí fítámì B12 tó wà lára wọn kàn ni wọ́n nílò láti mú àwọn àmì àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì kúrò. Ṣùgbọ́n kíkó fítámì àti èròjà mineral tó pọ̀ jù jẹ lè ṣàkóbá fún ìlera ẹni. Nípa bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a pe olùtọ́jú aláìsàn sí ọ̀ràn náà nígbà tí a bá fẹ́ pinnu bóyá ó yẹ kí a lo àwọn àfikún èròjà iron tàbí fítámì.

Ní ti àwọn èèyàn kan, kaféènì ló máa ń mú àwọn àmì àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì burú sí i. Kọfí, tíì, ṣokoléètì, àti ọ̀pọ̀ ọtí ẹlẹ́rìndòdò ló ní èròjà kaféènì nínú. Dídín ìwọ̀n èròjà kaféènì tí èèyàn ń mu kù tàbí kí ó má tilẹ̀ mu ún mọ́ lè mú kí àwọn àmì àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì dín kù tàbí kó mú un kúrò pátápátá. Mímu ọtí líle pẹ̀lú sábà máa ń mú kí á máa rí àwọn àmì àrùn náà fúngbà pípẹ́ tàbí kó máa le sí i. Kò ṣe àwọn kan mọ́ nígbà tí wọ́n dín bí wọ́n ṣe ń mu ọtí líle kù tàbí tí wọn kò tilẹ̀ mu ún mọ́.

Fífara Da Àrùn Ẹsẹ̀ Rírinni Wìnnìwìnnì

Bí o bá ní àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì, yíyí ọ̀nà tí o ń gbà gbé ìgbésí ayé rẹ padà lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Níwọ̀n bí àárẹ̀ àti ìtòògbé ti sábà máa ń mú kí àmì àrùn náà le sí i, sísùn dáadáa lè ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an. Bó bá ṣeé ṣe, ó dára jù láti sùn níbi tó pa rọ́rọ́, tó tutù, tó sì tuni lára. Lílọ sùn lálẹ́ ní àkókò kan náà lójoojúmọ́ àti jíjí ní òwúrọ̀ ní àkókò kan náà lójoojúmọ́ pẹ̀lú yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.

Ṣíṣe eré ìdárayá déédéé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sùn dáadáa lóru. Àmọ́, ṣíṣe eré ìdárayá tó le gan-an láàárín wákàtí mẹ́fà ṣáájú kí o tó lọ sùn lè yọrí sí ohun tí o kò fẹ́. Àwọn kan tí wọ́n ní àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì rí i pé ṣíṣe eré ìdárayá níwọ̀nba ṣáájú kí àwọn tó lọ sùn máa ń jẹ́ kí àwọn sùn dáadáa. Gbìyànjú onírúurú eré ìdárayá kí o lè mọ èyí tó bá ọ lára mu jù lọ.

Má ṣe kọ̀ láti dìde. Bí o bá kọ̀ tí o kò dìde, ńṣe ni àwọn àmì àrùn náà sábà máa ń pọ̀ sí i. Lọ́pọ̀ ìgbà, ojútùú tó dára jù lọ ni láti dìde lórí ibùsùn rẹ kí o sì rìn káàkiri. Àwọn kan ti rí i pé ara máa ń tu àwọn díẹ̀ tí àwọn bá rìn kiri, tí àwọn na ara, tí àwọn fi omi gbígbóná tàbí omi tútù wẹ̀, tàbí tí àwọn wọ́ ẹsẹ̀ àwọn. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé o ní láti jókòó fún àkókò gígùn, bí ìgbà tí o bá ń rìnrìn àjò, ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ bí o bá ń kàwé, tí o sì pọkàn pọ̀ sórí rẹ̀.

Tí èèyàn bá lo oògùn sí i ńkọ́? Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Àrùn Ẹsẹ̀ Rírinni Wìnnìwìnnì, tí wọ́n fi Raleigh, ní North Carolina, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe ibùjókòó wọn, sọ pé, “bíbẹ̀rẹ̀ sí lo oògùn sí i lè wá pọndandan.” Níwọ̀n bí kò ti sí oríṣi oògùn kan ṣoṣo tó ń ṣiṣẹ́ fún gbogbo ẹni tí àrùn ẹsẹ̀ rírinni wìnnìwìnnì ń ṣe, ó lè di dandan pé kí ẹni tó ń tọ́jú rẹ wá èyí tí yóò ṣiṣẹ́ fún ọ kàn. Àwọn kan ṣàwárí pé lílo àwọn oògùn mélòó kan pọ̀ ló gbéṣẹ́ jù. Nígbà mìíràn, oògùn kan tó ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀ lè má ṣiṣẹ́ mọ́. Níwọ̀n bí lílo oògùn àti ní pàtàkì lílo àwọn oògùn mélòó kan pọ̀ ti lè pani lára, ó ṣe pàtàkì láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹni tó ń tọ́jú rẹ láti pinnu ohun tí yóò ṣiṣẹ́ fún ọ jù lọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́