“Ó Bọ́ Sákòókò Gẹ́lẹ́”
OHUN tí ọkùnrin kan láti ìlú Abákáliki sọ nínú lẹ́tà tó kọ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà nìyẹn. Ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú tí wọ́n fún un lẹ́nu àìpẹ́ yìí ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó ṣàlàyé pé:
“Bí Tochi, aya mi ọ̀wọ́n, ṣe bímọ tán ní June 18, ọdún 2000 ló kú. Lẹ́yìn tí oṣù kan kọjá, mo ṣì wà bí aláìsí tí ayé sì sú mi pátápátá. Àní sẹ́, bí àlá lọ̀ràn àjálù yìí rí lára mi. Kò tíì sí ohun tó tíì gbò mí tó bẹ́ẹ̀ rí láyé mi. Nígbà tó di oṣù July, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá fún mi ní ìwé yín kan, ìyẹn ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. Bí oògùn ajẹ́bíidán ló rí lára mi. Ní báyìí, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ èèyàn padà díẹ̀díẹ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ìmọ̀ràn inú rẹ̀. Ìrètí tó fún mi kì í ṣe kékeré. Ó jẹ́ kí n mọ̀ pé bí ẹkún bá pẹ́ di alẹ́, ayọ̀ ń bọ̀ lówùúrọ̀.”
Ìwọ tàbí ẹnì kan tó o mọ̀ náà lè rí ìtùnú nípa kíka ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí. O lè béèrè fún ẹ̀dà kan lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.