Iṣẹ́ Ọwọ́ Ẹlẹ́dàá Ni Wọ́n Wò Ṣe É
Kí ló fà á tó fi jẹ́ pé bí gílóòbù iná ṣe jẹ́ ẹlẹgẹ́ tó, kì í fọ́ nígbà téèyàn bá ń tì í bọ ojú ihò tí wọ́n máa ń fi sí láti pèsè ìmọ́lẹ̀? Ìwé How in the World? sọ pé ohun tó mú kí èyí ṣeé ṣe ni ọ̀nà tí a gbà ṣe gílóòbù iná, ìyẹn ni pé “ìrísí ẹyin ni wọ́n wò ṣe é.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèpo ẹyin máa ń fẹ́lẹ́ gan-an, síbẹ̀ kì í fọ́ nígbà tí àgbébọ̀ adìyẹ bá ń sàba lé e lórí, ohun tó sì fa èyí ni bí ẹyin ṣe rí pọlọgun. (Bó bá nípọn jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn òròmọdìyẹ ò ní lè fi àgógó wọn ṣá a láti ráyè jáde). Nípa fífi iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá ṣe àwòkọ́ṣe, wọ́n máa ń ṣe gílóòbù iná kó fẹ́rẹ̀ẹ́ rí róbótó, nípa bẹ́ẹ̀ béèyàn bá dì í mú, “agbára téèyàn fi dì í mú kò ní pọ̀ síbì kan ju ibòmíràn lọ.” Látàrí èyí, bíi ti ẹyin, ńṣe lèèyàn máa ń di gílóòbù mú gẹngẹ, ọwọ́ ẹni kì í sì í tẹ̀wọ̀n jù níbikíbi lára rẹ̀, nípa bẹ́ẹ̀ gílóòbù náà kò ní fọ́. Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ nǹkan ni ẹ̀dá èèyàn ti rí kọ́ látinú àwọn iṣẹ́ ọwọ́ ẹlẹ́dàá!