ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/8 ojú ìwé 12-15
  • O Lè Mú Kí Agbára Ìrántí Rẹ Sunwọ̀n Sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Lè Mú Kí Agbára Ìrántí Rẹ Sunwọ̀n Sí I
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Rírántí Orúkọ Àwọn Ènìyàn
  • Bí O Ṣe Lè Há Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Nǹkan Sórí
  • Rírántí Ohun Tí O Bá Kà
  • O Lè Túbọ̀ Máa Rántí Nǹkan!
    Jí!—2009
  • O Lè Mú Kí Agbára Ìrántí Rẹ Já Fáfá
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Bá A Ṣe Lè Dẹni Tó Nífẹ̀ẹ́ sí Ẹ̀kọ́ Kíkọ́
    Jí!—2004
  • A Dá Wa Láti Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Títí Lọ Gbére
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 4/8 ojú ìwé 12-15

O Lè Mú Kí Agbára Ìrántí Rẹ Sunwọ̀n Sí I

“N kò níyè nínú pẹ́ẹ̀pẹ́ẹ̀.” Ìwọ ha ti sọ bẹ́ẹ̀ rí bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, má sọ̀rètí nù. Àwọn àbá bíi mélòó kan lásán àti ìsapá díẹ̀ ti tó láti jẹ́ kí o ní ìmúsunwọ̀nsí i tí ń yani lẹ́nu. Má ṣe fi ojú kéré ọpọlọ rẹ. Agbára rẹ̀ pabambarì.

BÁWO ni ọpọlọ ṣe ń ṣe àwọn ọ̀gá iṣẹ́ rẹ̀ yìí? Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ènìyàn ti ṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ ọpọlọ ju bí ó ti rí tẹ́lẹ̀ lọ. Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé òye ń pọ̀ sí i ni, ohun tí a mọ̀ síbẹ̀ kò pọ̀ nípa bí ọpọlọ ṣe ń ṣàṣeyọrí àwọn nǹkan tí ń ṣe ní ti gidi.

Bí a ṣe ń kọ́ àwọn nǹkan tí a sì ń rántí ìsọfúnni kò yé wa, àmọ́ àwọn olùṣèwádìí ń gbìyànjú láti túdìí gbogbo àràmàǹdà yìí. Lára àwọn nǹkan tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ nǹkan, kí a sì rántí rẹ̀ ni àwọn sẹ́ẹ̀lì iṣan ẹ̀jẹ̀ tí a fojú díwọ̀n sí bílíọ̀nù 10 sí 100 bílíọ̀nù tí ó wà nínú ọpọlọ. Ṣùgbọ́n, ó kéré tán, àwọn ìsokọ́ra tí ó wà láàárín àwọn sẹ́ẹ̀lì iṣan ẹ̀jẹ̀ yẹn lọ́po iye yẹn lọ́nà ẹgbàárùn-ún. Àbá èrò orí kan sọ pé, bí a ti ń fún àwọn ìsokọ́ra náà, tàbí synapses, lókun nípa lílò wọn, bẹ́ẹ̀ ni kíkọ́ nǹkan ń ṣẹlẹ̀.

Bí a ti ń dàgbà sí i, agbára ọpọlọ wa lè máa lọ sílẹ̀; ìṣiṣẹ́ ọpọlọ wa lè máa falẹ̀. Àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ọpọlọ kì í tún ara wọn pààrọ̀, ó sì ṣe kedere pé àwọn àgbàlagbà máa ń pàdánù àwọn sẹ́ẹ̀lì ọpọlọ díẹ̀díẹ̀. Ṣùgbọ́n bí a bá ti lo ọpọlọ wa tó, bẹ́ẹ̀ náà ni a óò dáàbò bo agbára ọpọlọ wa fún ìgbà gígùn tó.

Bí a bá ṣe ń ronú sí máa ń nípa lórí ọpọlọ. Níní ẹ̀mí pé nǹkan yóò dára, àti ẹ̀mí ọ̀yàyà máa ń mú ìṣiṣẹ́ ọpọlọ sunwọ̀n sí i, ìyówù kí ọjọ́ orí ènìyàn jẹ́. Àwọn ìṣàníyàn kan wà tí ó máa ń ṣàǹfààní, àmọ́, ìṣàníyàn àṣejù máa ń dí ìṣiṣẹ́ geerege ọpọlọ lọ́wọ́. Eré ìdárayá lè ran ènìyàn lọ́wọ́ láti mú ìdààmú ọpọlọ kúrò.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsọfúnni yìí lè dún bí ohun tí ń fún ènìyàn ní ìṣírí, síbẹ̀, a ṣì lè gbàgbé àwọn ọ̀ràn ṣíṣe kókó, ìyówù kí ọjọ́ orí wa jẹ́. A ha lè ṣàtúnṣe bí? Agbègbè kan tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti máa ń ní ìṣòro ni rírántí orúkọ àwọn ènìyàn tí wọ́n bá pàdé.

Rírántí Orúkọ Àwọn Ènìyàn

Àwọn àbá bíi mélòó kan lè ràn ọ́ lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti máa rántí orúkọ àwọn ènìyàn lọ́nà tí ó túbọ̀ dára. Fífi ìfẹ́ ọkàn hàn fún ẹni náà máa ń ṣèrànwọ́. Orúkọ ẹnì kan máa ń ṣe pàtàkì sí i. Ohun tí kì í jẹ́ kí a sábà máa rántí orúkọ náà ni pé, a kò gbọ́ ọ dáadáa nígbà tí a kọ́kọ́ gbọ́ ọ. Nítorí náà, nígbà tí ẹnì kan bá sọ orúkọ rẹ̀ fún ọ, gbọ́ orúkọ náà dáadáa. Sọ pé kí ẹni náà tún un pè bí ó bá pọn dandan, tàbí kí ó tilẹ̀ sípẹ́lì rẹ̀ pàápàá. Lò ó lọ́pọ̀ ìgbà nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ rẹ̀. Nígbà tí o bá sọ pé, ó dàbọ̀, pé ẹni náà ní orúkọ rẹ̀. Yóò yà ọ́ lẹ́nu bí àwọn àbá bíi mélòó yìí yóò ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́ tó.

Àbá mìíràn tí ó lè tún jẹ́ kí o máa tètè rántí orúkọ àwọn ènìyàn sí i ni láti so orúkọ ẹnì kan pọ̀ mọ́ ohùn kan tí o lè yàwòrán rẹ̀ lọ́kàn rẹ. Bí o bá ti lè yàwòrán àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ sọ́kàn, nǹkan yóò túbọ̀ rọrùn sí i.

Fún àpẹẹrẹ, ẹnì kan ní ìṣòro láti rántí orúkọ ojúlùmọ̀ kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ sún mọ́ ọn lọ títí, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Òkè. Nítorí náà, nígbà tí ó bá rí ẹnì yìí, ó ronú nípa òkè gidi kan, ó sì tún fọkàn yàwòrán òkè. Ó sábà máa ń ṣèrànwọ́; orúkọ náà, Òkè, kàn wá sọ́kàn rẹ̀ ni.

Ọ̀pọ̀ orúkọ lè máà ní ìtumọ̀ sí ọ, nítorí náà ìwọ yóò ní láti fi ọ̀rọ̀ tí ó jọ orúkọ náà rọ́pò rẹ̀. Kò ṣe nǹkan kan bí ọ̀rọ̀ tí o fi rọ́pò rẹ̀ kò bá bá ohùn orúkọ náà mu rẹ́gí. Agbára ìrántí rẹ lágbára tó láti níran orúkọ náà láti inú ìsokọ́ra ọ̀nà ìgbàrántí nǹkan náà. Nígbà tí o bá mú ọ̀rọ̀ àti ìfinúyàwòrán tìrẹ fúnra rẹ̀ jáde, yóò tẹ nǹkan náà mọ́ ọ lọ́kàn pinpin sí i.

Ìwọ yóò ní láti fi èyí dánra wò taápọntaápọn fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ ó máa ń ṣiṣẹ́. Harry Lorayne ṣàlàyé ọgbọ́n yìí nínú ìwé rẹ̀, How to Develop a Super-Power Memory, ó sì ti lò ó ní àìmọye ìgbà láàárín àwọn ènìyàn. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti jẹ́ pé mo ní láti pàdé ọgọ́rùn-ún kan sí ọgọ́rùn-ún méjì àwọn ènìyàn ní ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tàbí kí ó tilẹ̀ máà tó bẹ́ẹ̀, láìgbàgbé orúkọ kan ṣoṣo.”

Bí O Ṣe Lè Há Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Nǹkan Sórí

Báwo ni o ṣe lè mú agbára rẹ láti rántí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn nǹkan tí kò jọra sunwọ̀n sí i? Ọ̀nà rírọrùn kan ni wọ́n ń pè ní ìlànà alásokọ́ra. Bí òún ṣe rí nìyí: Ìwọ yóò fojú inú yàwòrán nǹkan kọ̀ọ̀kan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, lẹ́yìn náà ni ìwọ yóò so àwòrán tí o yà fún nǹkan àkọ́kọ́ pọ̀ mọ́ àwòrán tí o yà fún nǹkan èkejì, lẹ́yìn náà ìwọ yóò so àwòrán ti èkejì pọ̀ mọ́ ti ẹ̀kẹta, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Fún àpẹẹrẹ, o ní láti ra nǹkan márùn-ún ní ilé ìtajà: mílíìkì, búrẹ́dì, gílóòbù iná, àlùbọ́sà, àti áísìkiriìmù. Kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ nípa síso mílíìkì pọ̀ mọ́ búrẹ́dì. Ronúwòye pé ò ń da mílíìkì sórí ìṣù búrẹ́dì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwòrán náà ń pani lẹ́rìn-ín gan-an ni, yóò tẹ nǹkan náà mọ́ ọ lọ́kàn. Bákan náà, gbìyànjú láti ṣe bí ẹni pé ìwọ gan-an lò ń da mílíìkì náà nínú àwòrán ọpọlọ tí o yà.

Lẹ́yìn tí o bá ti so mílíìkì náà pọ̀ mọ́ búrẹ́dì, bọ́ sórí nǹkan tí ó kàn, gílóòbù iná. O lè so ìṣù búrẹ́dì náà pọ̀ mọ́ gílóòbù iná nípa fífọkàn yàwòrán pé ò ń gbìyànjú láti ki ìṣù búrẹ́dì náà bọ inú sọ́kẹ́ẹ̀tì iná. Lẹ́yìn náà so gílóòbù iná náà pọ̀ mọ́ àlùbọ́sà nípa fífojú inú wo ara rẹ tí o ń bó gílóòbù iná ńlá kan, tí o sì ń sunkún bí o ti ń bó o. Dájúdájú, ó sàn kí ó jẹ́ pé ìwọ ni o ṣe ìsokọ́ra náà fúnra rẹ. Ìwọ ha lè wá ìsokọ́ra èyíkéyìí fún nǹkan tí ó gbẹ̀yìn bí, àlùbọ́sà àti áísìkiriìmù? Bóyá o lè ronú pé ò ń mu áísìkiriìmù tí wọ́n fi àlùbọ́sà ṣe!

Wò ó bí o bá lè níran ìtòlẹ́sẹẹsẹ nǹkan náà. Lẹ́yìn náà fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ nǹkan tìrẹ dán agbára ìrántí rẹ̀ wò. Jẹ́ kí ó pọ̀ tó bí o bá ṣe fẹ́ ẹ tó. Rántí pé, láti lè jẹ́ kí ìsokọ́ra náà jẹ́ èyí tí o lè tètè rántí sí i, o lè jẹ́ kí ó jẹ́ èyí tí ń pani lẹ́rìn-in tàbí tí ó kàmàmà. Gbìyànjú láti ṣe bí ẹni pé ò ń ṣe bẹ́ẹ̀, kí o sì máa fi nǹkan kan rọ́pò òmíràn.

Àwọn kan lè wò ó pé ọ̀nà yìí máa ń pẹ́ ju kí ènìyàn kàn há ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sórí lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, kò yá ṣàlàyé ju pé kí ènìyàn lò ó lọ. Gbàrà tí o bá ti fi dánra wò fún ìgbà mélòó kan, kò ní pẹ́ tí ìwọ yóò fi máa so àwọn nǹkan pa pọ̀, agbára ìsọ̀yè rẹ, pa pọ̀ pẹ̀lú bí o ti máa ń yára kọ́ nǹkan sí, yóò sunwọ̀n sí i lọ́pọ̀lọpọ̀ ju kí a sọ pé o fẹ́ gbìyànjú láti kọ́ nǹkan láìjẹ́ pẹ̀lú ọ̀nà yìí. Nígbà tí a sọ fún àwọn ènìyàn 15 pé kí wọ́n rántí ìtòlẹ́sẹẹsẹ onírúurú nǹkan 15 láìlo ìlànà ìsokọ́ra, ìpíndọ́gba ohun tí wọ́n gbà jẹ́ 8.5. Nígbà tí wọ́n lo ìlànà síso nǹkan kọ́ra nípa fífojú inú yàwòrán nǹkan pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ mìíràn, àwùjọ ènìyàn yìí kan náà gba ìpíndọ́gba 14.3. Dájúdájú, bí o bá rántí láti mú àkọsílẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn nǹkan náà lọ́wọ́ bí o bá ń lọ rajà, gbogbo 15 ni ìwọ yóò gbà tán—àgbàtán porogodo!

Rírántí Ohun Tí O Bá Kà

Nínú ayé onísọfúnni rẹpẹtẹ tí à ń gbé yìí, agbègbè míràn tí ọ̀pọ̀ nínú wa nílò ìrànlọ́wọ́ jẹ́ nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí ó dára. Ọ̀ràn-anyàn ni ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́, ní ibi iṣẹ́ òwò, láti lè dá ara ẹni lẹ́kọ̀ọ́ sí i, àti láti lè múra sílẹ̀ fún sísọ̀rọ̀ ní gbangba. Ní àfikún sí èyíinì, Kristian kan gbọ́dọ̀ ya àkókò sọ́tọ̀ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.—Johannu 17:3.

O lè sọ pé, ‘Mo ní ìṣòro rírántí ohun tí mo bá kà.’ Kí ni o lè ṣe? Kíkọ́ láti lo àkókò tí o fi ń kẹ́kọ̀ọ́ dáradára lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí ohun tí o bá kà. Àwọn àbá mélòó kan nìyí.

Nígbà tí o bá ń kàwé, ṣíṣètò ara rẹ ṣe pàtàkì. Jẹ́ kí ìwé, àwọn nǹkan ìkọ̀wé, àti pépà wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Gbìyànjú láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ní agbègbè tí ó tura, níbi tí ìpinyà ọkàn kò ti pọ̀, tí ó sì ní ìmọ́lẹ̀ tí ó tó. Pa rédíò àti tẹlifiṣọ̀n.

Ní àkókò tí ó ṣe déédéé fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Fún àwọn kan, kíkẹ́kọ̀ọ́ lójoojúmọ́ fún àkókò kúkurú lè jẹ́ ohun tí ó gbéṣẹ́ ju lílo àkókò tí ó gùn gan-an ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan lọ. Ó dára kí o pín àkókò rẹ̀ sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Dípò tí oó fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ láìdáwọ́dúró fún wákàtí méjì, ó lè sàn jù kí o pín àkókò náà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, bíi sí ìṣẹ́jú 25 sí 40 ìṣẹ́jú, pẹ̀lú ìdáwọ́dúró bí ìṣẹ́jú mélòó kan láàárín rẹ̀. Ìwádìí ti fi hàn pé èyí máa ń pakún ìwọ̀n agbára ìrántí tí ó ga.

Yan àkópọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí o fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́. Èyí máa ń ṣèrànwọ́ fún ìpọkànpọ̀. Kí o tó bẹ̀rẹ̀ ìwé kan, fi ìṣẹ́jú bíi mélòó kan ṣàyẹ̀wò rẹ̀. Wo àkọlé rẹ̀. Ṣàyẹ̀wò ojú ewé tí a kọ àwọn àkòrí inú ìwé náà sí, èyí tí ó máa ń ṣàkópọ̀ ìwé náà. Lẹ́yìn náà ka ọ̀rọ̀ ìṣaájú tàbí ìfáárà. Níhìn-ín ni wọ́n máa ń kọ èrò àti ojú ìwòye òǹkọ̀wé náà sí.

Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka àkòrí kan, gbé e yẹ̀ wò. Wo àwọn ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀, àpótí àlàyé, àwọn àwòrán, àwọn àkópọ̀, àti ìpínrọ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀, tí ó sì parí rẹ̀. Wo àkópọ̀ ọ̀rọ̀ ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan gààràgà. Àwọn àkópọ̀ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ló sábà máa ń ní lájorí ọ̀rọ̀ nínú. Mọ ohun tí gbogbo rẹ̀ dá lé lórí. Bi ara rẹ ní àwọn ìbèèrè wọ̀nyí: ‘Kí ni ohun tí òǹkọ̀wé náà fẹ́ fà yọ? Kí ni mo lè rí kọ́ nínú àkópọ̀ ìwé kíkà yìí? Kí ni àwọn kókó inú rẹ̀?’

Ìpọkànpọ̀ ṣe pàtàkì. O ní láti fi gbogbo ara rẹ̀ fún un pátápátá. Àṣírí ibẹ̀ ni pé kí o jẹ́ kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ jẹ́ èyí tí ó gbádùn mọ́ ọ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ru ìtara ọkàn rẹ sókè nípa gbígbé apá tí ó ṣeé fi sílò nínú ìsọfúnni náà yẹ̀wò. Fọkàn yàwòrán rẹ̀. Lo agbára ìmọǹkan rẹ nípa fífinú wòye òórùn, ìtọ́wò, àti ìfọwọ́kàn, bí àkópọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà bá fi ohun kan bí ìwọ̀nyí hàn.

Gbàrà tí o bá ti lóye kókó àkópọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, ó ti yá kí ó máa kọ̀wé ló kù. Kíkọ ohun tí o bá kà sílẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere lè mú kí òye àti ìrántí tí o ní nípa ìsọfúnni náà yára kánkán. Kò di dandan kí ohun tí o kọ jẹ́ gbólóhùn ọ̀rọ̀ tán porogodo, àmọ́ ó ní láti jẹ́ àwọn ògúnná gbòǹgbò ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí lájorí kókó inú rẹ̀.

Lílóye ìsọfúnni náà kò túmọ̀ sí pé, ó di dandan kí o rántí gbogbo rẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, lẹ́yìn nǹkan bíi wákàtí 24 tí ó ti kọ́ nǹkan, o lè ti gbàgbé ohun tí ó pọ̀ tó ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún lára ìsọfúnni náà, ó kéré tán fún ìgbà díẹ̀. Ìyẹn dà bí ohun tí ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni, àmọ́ o lè rántí díẹ̀ tàbí púpọ̀ nínú ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún yẹn padà nípa ṣíṣàtúnyẹ̀wò àkópọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà. Lẹ́yìn àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, ṣàtúnyẹ̀wò fún ìṣẹ́jú bíi mélòó kan. Bí ó bá ṣeé ṣe, tún àyẹ̀wò ṣe ní ọjọ́ kejì, àti ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, àti oṣù kan lẹ́yìn náà. Fífi àwọn kókó wọ̀nyí sọ́kàn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jàǹfààní ní kíkún láti inú àkókò ṣíṣeyebíye tí ó fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àti láti rántí ohun tí ó ti kà.

Nítorí náà má ṣe fojú kéré ọpọlọ rẹ. O lè mú agbára rírántí nǹkan rẹ sunwọ̀n sí i. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan tọ́ka sí ọpọlọ gẹ́gẹ́ bí “ohun tí ó díjú jù lọ tí a tí ì ṣàwárí rẹ̀ rí ní àgbáálá ayé wa.” Ó jẹ́ ẹ̀rí ọgbọ́n àti agbára àgbàyanu tí Ẹlẹ́dàá rẹ̀, Jehofa, ní.—Orin Dafidi 139:14.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Láti rántí ìtòlẹ́sẹẹsẹ nǹkan, ló ìlànà ìsokọ́ra: Fojú inú yàwòrán nǹkan kọ̀ọ̀kan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Lẹ́yìn náà so àwòrán nǹkan àkọ́kọ́ pọ̀ mọ́ èkejì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ohun tí a fẹ́ rà:

1. Mílíìkì A so 1 àti 2 pọ̀

2. Búrẹ́dì A so 2 àti 3 pọ̀

3. Gílóòbù iná A so 3 àti 4 pọ̀

4. Àlùbọ́sà A so 4 àti 5 pọ̀

5. Áísìkiriìmù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́