A Dá Wa Láti Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Títí Lọ Gbére
“Ilé iṣẹ́ ńlá tó ń pèsè agbára ló wà lágbárí ẹnì kọ̀ọ̀kan, ìyẹn ẹ̀yà ara láńkó tó ń ṣiṣẹ́ lọ́nà tó já fáfá, tó dà bí ẹni pé bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa rẹ̀, ńṣe lagbára rẹ̀ ń pọ̀ síwájú àti síwájú sí i.”—TONY BUZAN ÀTI TERENCE DIXON, TÍ WỌ́N JẸ́ ÒǸKỌ̀WÉ ÌMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ NI WỌ́N SỌ̀RỌ̀ YÌÍ.
BÁWO ni ohun tí ọpọlọ èèyàn lè kọ́ ṣe pọ̀ tó? Ìbéèrè yẹn ò tíì yé ya àwọn olùṣèwádìí lẹ́nu kò sì tíì yé ṣe wọ́n ní kàyéfì. Nínú ìwé rẹ̀ The Brain Book, Peter Russell kọ̀wé pé: “Bá a ṣe ń mọ púpọ̀ sí i tó nípa ọpọlọ ẹ̀dá èèyàn, bẹ́ẹ̀ là ń rí i pé agbára tó ní àtèyí tó ṣeé ṣe kó tún ní pọ̀ ju bá a ṣe rò pé ọ̀ràn rí tẹ́lẹ̀.”
Bí àpẹẹrẹ, ní ti ká rántí nǹkan, agbára tí ọpọlọ wa ní ò láàlà. Russell sọ pé: “Agbára ìrántí ò dà bí agolo tí nǹkan lè kún inú ẹ̀, bí igi tó máa ń pẹ̀ka ló rí, ara ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan sì ni agbára ìrántí so rọ̀ sí. Bó o bá ti rántí ohun kan báyìí, bí ìgbà tí ọ̀wọ́ àwọn ẹ̀ka míì rú yọ ni, o sì tún lè rántí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn nǹkan míì látara àwọn ẹ̀ka tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rú yọ yìí. Nítorí náà, ńṣe lagbára ọpọlọ ń gbòòrò sí i. Bí ohun tó o mọ̀ bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ohun tó o ṣì lè mọ̀ ṣe pọ̀ tó.” Ìyẹn lá á mú wa padà sórí ìbéèrè tá a ti béèrè tẹ́lẹ̀ pé, Kí ló fà á tí agbára tí ọpọlọ wa ní, tí ò tíì lò rárá, fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀?
Ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ò fún wa ní ìdáhùn kankan tó bọ́gbọ́n mu. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé orí ẹ̀kọ́ pé ẹ̀dá-ṣèèṣì-hú-yọ ni wọ́n gbé e kà, ńṣe ló da ọ̀rọ̀ rú mọ́ àwọn ọ̀mọ̀ràn èèyàn lójú nípa ohun tó fà á tí ọpọlọ ẹ̀dá èèyàn fi ní agbára tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, èwo làbùrọ̀ kan ọkọ akẹ́rù gbàgbàrà bó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tá a fẹ́ gbé ò kọjá yanrìn ẹ̀kún ṣọ́bìrì kan?
Bó ti wù kó rí, Bíbélì fún wa ní ìdáhùn atura, tí kò díjú, tó sì lọ́gbọ́n nínú. Àkọ́kọ́, ó sọ fún wa pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, la dá ní àwòrán Ọlọ́run, wọ́n sì lágbára láti fi àwọn àgbàyanu ànímọ́ Ọlọ́run hàn. Èkejì, ó ṣàlàyé pé Ọlọ́run dá ènìyàn láti wà láàyè, àti nítorí náà wọ́n lè máa kẹ́kọ̀ọ́ títí lọ gbére. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; 2:16, 17) A lè rí àpẹẹrẹ ète Ọlọ́run yẹn nínú ọ̀nà tí ọpọlọ gbà ń ṣiṣẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ní báyìí ná, kò tíì máa ṣiṣẹ́ lọ́nà pípé nítorí pé gbogbo ìdílé ẹ̀dá ènìyàn ti di ẹlẹ́ṣẹ̀.—Róòmù 5:12.
Ṣùgbọ́n, ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣì máa nímùúṣẹ pé kí orí ilẹ̀ ayé kún fún àwọn èèyàn pípé tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run tí wọn yóò máa gbé nínú Párádísè. Ní tòótọ́, torí tiwa ni Jèhófà ṣe yọ̀ǹda Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, Jésù Kristi, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà ká bàa lè jèrè ìyè ayérayé.—Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16.
Oúnjẹ Tó Dáa Jù Lọ fún Ọpọlọ
Jèhófà tún fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí, Bíbélì Mímọ́. (2 Tímótì 3:16; 2 Pétérù 1:21) Nítorí pé nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run la fi kọ ìwé ṣíṣeyebíye yìí, kò sí àbùmọ́ níbẹ̀ tá a bá sọ pé nínú rẹ̀ la ti lè rí oúnjẹ tó dáa jù lọ fún ọpọlọ àti oúnjẹ tẹ̀mí tó dáa jù lọ fún ìran ènìyàn. (Sáàmù 19:7-10) Kódà, Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.”—Mátíù 4:4.
Nítorí náà, yálà o jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, o ò ṣe kúkú máa ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ lójoojúmọ́ fún kíka ‘àwọn àsọjáde’ ṣíṣeyebíye ti Ọlọ́run? Àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò yóò jàǹfààní nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n lè gbádùn ìrètí wíwà láàyè títí láé àti kíkẹ́kọ̀ọ́ títí gbére, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣèlérí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ìrètí àgbàyanu mà nìyẹn o!—Oníwàásù 3:11; Jòhánù 17:3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ní ìṣàpẹẹrẹ ète Ọlọ́run, a dá ọpọlọ ẹ̀dá ènìyàn láti máa kẹ́kọ̀ọ́ títí lọ gbére
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Oúnjẹ tó dára jù lọ fún ọpọlọ rẹ ló wà nínú Bíbélì