ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 6/22 ojú ìwé 8-11
  • Yíyíjú sí Ọlọ́run fún Ìdáhùn, Kì Í Ṣe Ènìyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yíyíjú sí Ọlọ́run fún Ìdáhùn, Kì Í Ṣe Ènìyàn
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àbùdá Ẹranko Tàbí Àbùdá Tó Lábùkù?
  • Ìdí Tí A Kì Í Ṣeé Fẹ́ Kú
  • A Dá Wa Láti Wà Láàyè Títí Láé
  • Ayé Tuntun Kan Tí Ó Dá Lórí Ìfẹ́
  • Ìyè Àìnípẹ̀kun Ha Ṣeé Ṣe Lóòótọ́ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • A Dá Wa Láti Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Títí Lọ Gbére
    Jí!—2004
  • O Lè Wà Láàyè Títí Láé Lórí Ilẹ̀ Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
  • Ṣé Ẹní Bá Ti Kú Lè Pa Dà Wà Láàyè?
    Jí!—2008
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 6/22 ojú ìwé 8-11

Yíyíjú sí Ọlọ́run fún Ìdáhùn, Kì Í Ṣe Ènìyàn

ẸFOLÚṢỌ̀N fi kọ́ni pé ọ̀wọ́ àwọn ìyípadà kan tí ó ṣẹlẹ̀ ní díẹ̀díẹ̀ ló mú kí a jẹ́ irú ẹranko ọlọ́pọlọ-pípé kan. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Bíbélì sọ pé a dá wa ní pípé, ní àwòrán Ọlọ́run, àmọ́ pé láìpẹ́ lẹ́yìn náà, àìpé wọnú ọ̀ràn wa, nǹkan sì bẹ̀rẹ̀ sí burú fún ìran ènìyàn.

Àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, kó ara wọn sínú yọ́ọ́yọ́ọ́ yìí nígbà tí wọn kò fẹ́ wà lábẹ́ ìdarí ní ti ìwà rere mọ́, wọ́n sì ba ẹ̀rí-ọkàn wọn jẹ́ nípa mímọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ó jọ pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ré kọjá ààlà òfin Ọlọ́run, wọ́n sì ṣubú sí ibi tí a wà lónìí, tí àìsàn, ọjọ́ ogbó, àti ikú ń pọ́n wa lójú, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ti ẹ̀tanú ẹ̀yà, ìkórìíra nítorí ìsìn, àti àwọn ogun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:6, 7.

Àbùdá Ẹranko Tàbí Àbùdá Tó Lábùkù?

Dájúdájú, Bíbélì kò lo èdè onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti ṣàlàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ara pípé Ádámù àti Éfà nígbà tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀. Bíbélì kì í ṣe ìwé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, bí ìwé ìléwọ́ kan tí wọ́n fún ẹnì kan tí ó ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kì í ti ṣe ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí ìmọ̀ ẹ̀rọ nípa ọkọ̀ ìrìnnà. Ṣùgbọ́n bí ìwé ìléwọ́ tí a fún òǹrajà kan, Bíbélì péye; kì í ṣe ìtàn àròsọ.

Nígbà tí Ádámù àti Éfà ré kọjá ààlà òfin Ọlọ́run, àwọn ẹ̀yà ara wọ́n bàjẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ sípa ikú. Nípasẹ̀ òfin ànímọ́ àjogúnbá, àwọn ọmọ wọn, ìdílé ènìyàn, jogún àìpé. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn pẹ̀lú ń kú.—Jóòbù 14:4; Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12.

Lọ́nà tó bani nínú jẹ́, ìtẹ̀sí sípa ẹ̀ṣẹ̀, tí ń fara hàn bí ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwà pálapàla, wà lára ohun tí a jogún. Lóòótọ́ ni ìbálòpọ̀ bẹ́tọ̀ọ́ mu láyè tirẹ̀. Ọlọ́run pàṣẹ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Àti pé bí Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́, ó mú kí mímú àṣẹ yẹn ṣẹ jẹ́ orísun ìdùnnú fún tọkọtaya. (Òwe 5:18) Ṣùgbọ́n àìpé ènìyàn ti ṣamọ̀nà sí ìṣekúṣe. Ní gidi, àìpé kan gbogbo apá ìgbésí ayé wa, títí kan bí èrò inú àti ara wa ṣe ń ṣiṣẹ́, bí gbogbo wa ṣe mọ̀.

Ṣùgbọ́n àìpé kò tíì paná ìmòye ìwà rere wa. Ní ti gidi, bí a bá fẹ́ “darí ìṣísẹ̀” wa, kí a sì yẹra fún àwọn ọ̀fìn ìgbésí ayé nípa bíbá ìtẹ̀sí láti dẹ́ṣẹ̀ jà, a lè ṣe é. Ó dájú pé kò sí ènìyàn aláìpé tí ó lè bá ẹ̀ṣẹ̀ jà tán pẹ̀lú àṣeyọrísírere, Ọlọ́run sì ń fi ìfẹ́ gba èyí rò.—Sáàmù 103:14; Róòmù 7:21-23.

Ìdí Tí A Kì Í Ṣeé Fẹ́ Kú

Bíbélì tún tànmọ́lẹ̀ sórí àdììtú mìíràn tí ẹfọlúṣọ̀n kò ṣàlàyé yékéyéké: bí ènìyàn kì í ṣeé fẹ́ láti kú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú lè dà bí ohun àdánidá, tí a kò sì lè mú jẹ.

Bí Bíbélì ṣe fi hàn, ẹ̀ṣẹ̀ ṣíṣàìgbọràn sí Ọlọ́run ló fa ikú. Ká ní àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣe onígbọràn délẹ̀ ni, wọn ì bá wà láàyè títí láé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Nídìí èyí, Ọlọ́run ti fi ìfẹ́-ọkàn láti máa wà láàyè títí láé sí inú ènìyàn. Oníwàásù 3:11 sọ pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lú, ó fi ayérayé sí ènìyàn ní àyà” ní ìbámu pẹ̀lú New International Version. Nítorí náà, ẹ̀bi ikú tí a dá wọn gbé àìfararọ kan dìde nínú ènìyàn, àìfararọ tí kò kásẹ̀ nílẹ̀.

Láti yanjú àìfararọ inú lọ́hùn-ún yìí àti láti tu ìfẹ́ àdánidá yìí láti máa wà láàyè nìṣó lójú, ènìyàn ti gbé onírúurú ìgbàgbọ́ kalẹ̀, láti orí ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn sí ìgbàgbọ́ àtúnwáyé. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàyẹ̀wò nípa àdììtú ọjọ́ ogbó, àwọn náà fẹ́ mú ikú kúrò tàbí kí wọ́n mú un falẹ̀. Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n tí wọn kò gbà pé Ọlọ́run wà fọwọ́ rọ́ ìfẹ́-ọkàn láti wà láàyè títí láé sẹ́yìn, wọ́n pè é ní ìtànjẹ, tàbí èrú ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n, nítorí pé ó forí gbárí pẹ̀lú èrò tí wọ́n ní pé ènìyàn wulẹ̀ jẹ́ ẹranko ọlọ́pọlọ-pípé. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀rọ̀ Bíbélì náà pé, ikú jẹ́ ọ̀tá, bá ìfẹ́ àdánidá tí a ní láti máa wà láàyè nìṣó mu.—1 Kọ́ríńtì 15:26.

Nígbà náà, ẹ̀rí ha wà ní ara wa pé a ṣẹ̀dá wa láti wà láàyè títí láé bí? Bẹ́ẹ̀ ni! Ọpọlọ ènìyàn nìkan fún wa ní ẹ̀rí pé a ṣẹ̀dá wa láti pẹ́ láyè ju bí a ti ń wà lọ.

A Dá Wa Láti Wà Láàyè Títí Láé

Ọpọlọ kò ju nǹkan bí 1.4 kìlógíráàmù lọ, ó sì ní iṣan bílíọ̀nù 10 sí 100 bílíọ̀nù, ìròyìn sì sọ pé, ọ̀kankòjọ̀kan ni wọ́n. Iṣan ọpọlọ kọ̀ọ̀kan lè gbé ìsọfúnni lọ sọ́dọ̀ nǹkan bí 200,000 iṣan ọpọlọ mìíràn, ó sì ń mú kí iye ipa ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà nínú ọpọlọ pọ̀ jọjọ. Ìwé Scientific American sì sọ láfikún sí ìyẹn pé, “iṣan ọpọlọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tí ó díjú.”

Ọpọlọ ń lo ọ̀pọ̀ ìṣiṣẹ́ kẹ́míkà tí ń nípa lórí bí àwọn iṣan ọpọlọ ṣe ń ṣiṣẹ́. Ọpọlọ sì díjú díẹ̀ ju kọ̀ǹpútà tí ó lágbára jù lọ pàápàá. Tony Buzan àti Terence Dixon kọ̀wé pé: “Orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ilé ohun àmúṣagbára kíkọyọyọ kan, ẹ̀yà jíjáfáfá tí ó kì pọ̀ kan tí ó jọ pé agbára rẹ̀ ń pọ̀ sí i bí ohun tí a ń mọ̀ nípa rẹ̀ ti ń pọ̀ sí i.” Wọ́n fa ọ̀rọ̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n Pyotr Anokhin yọ pé: “Kò tíì sí ẹ̀dá kan láyé tí ó lè lo gbogbo agbára tí ọpọlọ rẹ̀ ní tán. Òun ló fà á tí a kò ṣe tẹ́wọ́ gba ìdíyelé elérò òdì èyíkéyìí nípa bí ọpọlọ ènìyàn ṣe lágbára tó. Kò lópin.”

Òtítọ́ yíyanilẹ́nu wọ̀nyí ta ko ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Àbí kí ló dé tí ẹfolúṣọ̀n fi máa “ṣẹ̀dá” ẹ̀yà tí ó ní agbára láti ṣiṣẹ́ fún gbogbo mílíọ̀nù kan tàbí bílíọ̀nù kan ọdún tí àwọn olùgbé inú hòrò lásánlàsàn lò, tàbí tí àwọn ọ̀mọ̀wé òde òní pàápàá yóò lò láyé? Lótìítọ́, ìyè àìnípẹ̀kun nìkan ló bọ́gbọ́n mu! Àmọ́, ara wa ń kọ́?

Ìwé Repair and Renewal—Journey Through the Mind and Body sọ pé: “Ọ̀nà tí àwọn egungun, ẹran ara, àti àwọn ẹ̀yà ara tí a fi pa ń gbà sàn jẹ́ ìyanu ní tòótọ́. Bí a bá sì lè ronú nípa rẹ̀, a óò rí i pé àtúnṣe wọ́ọ́rọ́wọ́ nínú awọ ara àti irun àti èékánná—àti àwọn ẹ̀yà ara mìíràn—jẹ́ ohun àgbàyanu gidigidi: Ó ń báṣẹ́ lọ lójoojúmọ́, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ní lílo ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà nínú ohun alààyè, ó ń tún wa dá lọ́pọ̀ ìgbà ní gbogbo àkókò tí a fi wà láàyè.”

Ní àkókò tí Ọlọ́run bá fẹ́, kò ní jẹ́ ìṣòro fún un láti mú kí ọ̀nà ìṣiṣẹ́ ìyanu ìṣàtúnṣe ara ẹni yìí máa bá a lọ láìlópin. Nígbà náà, níkẹyìn, “ikú ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́ríńtì 15:26) Ṣùgbọ́n láti láyọ̀ ní ti gidi, a nílò ju ìyè ayérayé lọ. A nílò àlàáfíà—àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa. Irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀ lè wáyé kìkì bí àwọn ènìyàn bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn.

Ayé Tuntun Kan Tí Ó Dá Lórí Ìfẹ́

Jòhánù Kìíní 4:8 sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Ìfẹ́ lágbára gan-an—ní pàtàkì ìfẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run—tí ó fi jẹ́ pé tìtorí rẹ̀ gan-an ni a fi lè retí láti wà láàyè títí láé. Jòhánù 3:16 sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”

Ìyè àìnípẹ̀kun tán! Ẹ wo irú ìfojúsọ́nà àgbàyanu tí èyí jẹ́! Àmọ́ níwọ̀n bí a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, a kò ní ẹ̀tọ́ láti wà láàyè. Bíbélì sọ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó dùn mọ́ni nínú pé ìfẹ́ mú kí Ọmọ Ọlọ́run, Jésù Kristi, kú fún wa. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé nípa Jésù pé: “Ẹni yẹn fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ fún wa.” (1 Jòhánù 3:16) Bẹ́ẹ̀ ni, ó fi ẹ̀mí ènìyàn pípé rẹ̀ lélẹ̀ bí “ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,” kí a bàa lè fagi lé ẹ̀ṣẹ̀ àwa tí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, kí a sì gbádùn ìyè ayérayé. (Mátíù 20:28) Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.”—1 Jòhánù 4:9.

Nígbà náà, báwo ni ó ṣe yẹ kí a hùwà padà sí ìfẹ́ tí Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ fi hàn sí wa? Bíbélì ń bá a lọ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, nígbà náà àwa fúnra wa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Jòhánù 4:11) A gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ láti nífẹ̀ẹ́, nítorí pé ànímọ́ yẹn ni yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ ayé tuntun Ọlọ́run. Lónìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti mọyì ìjẹ́pàtàkì ìfẹ́, gan-an bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe tẹnu mọ́ ọn nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì.

Ìwé Love and Its Place in Nature sọ pé, tí kò bá sí ìfẹ́ “ó jọ pé àwọn ọmọdé máa ń kú.” Síbẹ̀, àìní yẹn fún ìfẹ́ kì í tán nígbà tí a bá dàgbà. Olókìkí onímọ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn kan sọ pé, ìfẹ́, “ló ṣe pàtàkì jù lọ lára gbogbo ohun tí ènìyàn nílò gan-an gẹ́gẹ́ bí oòrùn wa ti ṣe pàtàkì jù lọ lára oòrùn àti àwọn ọ̀wọ́ rẹ̀ . . . Ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà nínú ara, ìṣe òun ìgbòkègbodò àti ìrònú òun ìhùwà ọmọ tí a kò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ yàtọ̀ gidigidi sí ti èyí tí a nífẹ̀ẹ́. Bí ọmọ tí a kò nífẹ̀ẹ́ tilẹ̀ ṣe ń dàgbà yàtọ̀ sí bí èyí tí a nífẹ̀ẹ́ ṣe ń dàgbà.”

O ha lè finú wòye bí ìgbésí ayé yóò ṣe rí nígbà tí gbogbo àwọn tó wà lórí ilẹ̀ ayé bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn? Kódà, ẹnikẹ́ni kò ní gbin ẹ̀tanú sọ́kàn mọ́ nítorí pé ẹnì kan jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn, pé ó wá láti inú ẹ̀yà mìíràn, tàbí pé ó ní àwọ̀ tí ó yàtọ̀ sí tirẹ̀! Lábẹ́ ìṣàkóso Ọba tí Ọlọ́run yàn sípò, Jésù Kristi, àlàáfíà àti ìfẹ́ yóò kún ilẹ̀ ayé, ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ onímìísí sáàmù nínú Bíbélì pé:

“Ọlọ́run, fi àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ fún ọba . . . Kí ó ṣe ìdájọ́ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ nínú àwọn ènìyàn, kí ó gba àwọn ọmọ òtòṣì là, kí ó sì tẹ àwọn oníjìbìtì rẹ́. . . . Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́. Òun yóò sì ní àwọn ọmọ abẹ́ láti òkun dé òkun àti láti Odò dé òpin ilẹ̀ ayé. Nítorí tí òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.”—Sáàmù 72:1, 4, 7, 8, 12, 13.

A kò ní jẹ́ kí àwọn ẹni búburú gbé inú ayé tuntun Ọlọ́run, gẹ́lẹ́ bí a ṣe ṣèlérí rẹ̀ nínú sáàmù mìíràn nínú Bíbélì pé: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé. Àti pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:9-11.

Nígbà náà, èrò inú àti ara gbogbo ènìyàn onígbọràn, títí kan àwọn tí a óò gbé dìde kúrò nínú sàréè nípasẹ̀ àjíǹde kúrò nínú ikú, ni a óò ti wò sàn. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n wà láàyè yóò gbé àwòrán Ọlọ́run yọ lọ́nà pípé. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ìjàkadì lílágbára náà láti ṣe ohun tí ó tọ́ yóò ti dópin. Àìṣọ̀kan tí ó wà láàárín ìfẹ́ tí a ní fún ìwàláàyè àti bí ikú ṣe wà lọ́nà tí ń le koko mọ́ni kì yóò sí mọ́ pẹ̀lú! Bẹ́ẹ̀ ni, ìlérí tí ó dájú tí Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ ṣe ni pé: “Ikú kì yóò . . . sí mọ́.”—Ìṣípayá 21:4; Ìṣe 24:15.

Nítorí náà, kí ó má ṣe ṣẹlẹ̀ pé o jọ̀gọ nù nínú ìjàkadì láti máa ṣe ohun tí ó tọ́. Ṣègbọràn sí ìṣílétí àtọ̀runwá náà pé: “Ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí.” Ìgbésí ayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run yẹn ni Bíbélì pè ní “ìyè tòótọ́.”—1 Tímótì 6:12, 19.

Kí ó ṣẹlẹ̀ pé o mọrírì òtítọ́ tí a sọ jáde nínú Bíbélì pé: “Jèhófà ni Ọlọ́run. Òun ni ó ṣẹ̀dá wa, kì í sì í ṣe àwa fúnra wa.” Mímọrírì òtítọ́ yẹn jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì sípa títóótun fún ìwàláàyè nínú ayé tuntun onífẹ̀ẹ́ àti òdodo ti Jèhófà.—Sáàmù 100:3; 2 Pétérù 3:13.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

Ìgbésí ayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run ni Bíbélì pè ní “ìyè tòótọ́.”—1 Tímótì 6:19

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ènìyàn ti ré kọjá ààlà àwọn òfin Ọlọ́run, ó sì ń yọrí sí ìjábá fún wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ìran ènìyàn yóò gbádùn ayé tuntun alálàáfíà kan lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́