Ní Àwòrán Ọlọ́run Tàbí ti Ẹranko?
ỌKÙNRIN àkọ́kọ́, Ádámù, ni a pè ní “ọmọkùnrin Ọlọ́run.” (Lúùkù 3:38) Kò sí ẹranko tí ó tíì gbádùn irú ìyọsọ́tọ̀ yẹn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bíbélì fi hàn pé ènìyàn ní àwọn ohun kan tí àwọn ẹranko náà ní. Fún àpẹẹrẹ, ènìyàn àti ẹranko jẹ́ ọkàn. Jẹ́nẹ́sísì 2:7 sọ pé, nígbà tí Ọlọ́run ṣẹ̀dá Ádámù, “ọkùnrin náà . . . wá di alààyè ọkàn.” Kọ́ríńtì Kìíní 15:45 fohùn ṣọ̀kan pé: “Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ di alààyè ọkàn.” Ènìyàn jẹ́ ọkàn, nítorí náà, ọkàn kì í ṣe ẹ̀dá kan tí ó dà bí òjìji, tí ń wà lọ lẹ́yìn tí ara bá ti kú.
Jẹ́nẹ́sísì 1:24 sọ nípa àwọn ẹranko pé: “Kí ilẹ̀ ayé mú alààyè ọkàn jáde ní irú tiwọn, ẹran agbéléjẹ̀ àti ẹran tí ń rìn ká àti ẹranko ìgbẹ́ ilẹ̀ ayé ní irú tirẹ̀.” Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì gbé ènìyàn lárugẹ nípa sísọ pé a dá wa ní àwòrán Ọlọ́run, ó tún rán wa létí nípa ipò rírẹlẹ̀ tí a wà bí ọkàn tí ó wà pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹranko lórí ilẹ̀ ayé. Síbẹ̀, ohun kan tún wà tí ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn, tí ó sì ń ṣẹlẹ̀ sí ẹranko pẹ̀lú.
Bíbélì ṣàlàyé pé: “Àtúbọ̀tán kan ni ó wà ní ti àwọn ọmọ aráyé àti àtúbọ̀tán kan ní ti ẹranko, àtúbọ̀tán kan náà sì ni wọ́n ní. Bí èkíní ti ń kú, bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú . . . Ènìyàn kò ní ọlá ju ẹranko lọ . . . Ibì kan náà ni gbogbo wọ́n ń lọ. Inú ekuru ni gbogbo wọ́n ti wá, gbogbo wọ́n sì ń padà sí ekuru.” Òtítọ́ ni, bí ènìyàn ṣe ń kú ni ẹranko ń kú. Àwọn méjèèjì ń padà “sí ilẹ̀,” “sí ekuru,” tí wọ́n ti wá.—Oníwàásù 3:19, 20; Jẹ́nẹ́sísì 3:19.
Àmọ́ kí ló dé tí ikú máa ń pọ́n ènìyàn lójú púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Èé ṣe tí a ń fọkàn fẹ́ láti wà láàyè títí láé? Èé ṣe tí ìgbésí ayé wa sì fi gbọ́dọ̀ ní ète nínú? Dájúdájú, a yàtọ̀ sí ẹranko gan-an!
Bí A Ṣe Yàtọ̀ sí Ẹranko
Ṣé inú rẹ yóò dùn láti wà láàyè láìsí ète mìíràn lẹ́yìn kí o jẹun, kí o sùn, kí o sì bímọ? Èrò náà tilẹ̀ kó àwọn onítara ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n nírìíra. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n náà, T. Dobzhansky, kọ̀wé pé: “Ènìyàn ìwòyí tí í ṣe aláìní ìdánilójú nípa ìsìn àti onígbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀, kò lè ṣàìmáronú, ó kéré tán ní ìkọ̀kọ̀, nípa ìbéèrè tí ó ti pẹ́ náà pé: Ìgbésí ayé mi ha ní ìtumọ̀ àti ète díẹ̀ ní àfikún sí mímú kí n máa wà láàyè, kí n sì máa mú kí ìsokọ́ra ìwàláàyè máa tẹ̀ síwájú bí? Ǹjẹ́ àgbáálá ayé tí mo ń gbé já mọ́ nǹkan kan bí?”
Ní tòótọ́, sísọ pé, Ẹlẹ́dàá kò sí, kò fòpin sí wíwá tí ènìyàn ń wá ohun tí ìgbésí ayé já mọ́ kiri. Richard Leakey fa ọ̀rọ̀ òpìtàn Arnold Toynbee yọ pé: “Ọ̀ràn tẹ̀mí tí a fi jíǹkí [ènìyàn] yìí mú kí ó máa jìjàkadì láti mú ara rẹ̀ bá ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú àgbáálá ayé tí a bí i sí mu títí ayé rẹ̀.”
Síbẹ̀, ìbéèrè pàtàkì tí ó wà nípa àbùdá ènìyàn, orírun wa, àti ipò tẹ̀mí wa kò yí padà. Ó hàn dájú pé, ìyàtọ̀ ńlá kan wà láàárín ènìyàn àti ẹranko. Báwo ni ìyàtọ̀ náà ṣe tó?
Ìyàtọ̀ Tó Pọ̀ Jù Láti Mú Bára Mu Ni Bí?
Ìṣòro pàtàkì kan tí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ní ni ìyàtọ̀ ńlá tó wà láàárín ènìyàn àti ẹranko. Báwo ni ó ṣe pọ̀ tó ní ti gidi? Gbé díẹ̀ lára àwọn ohun tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n fúnra wọn sọ nípa rẹ̀ yẹ̀ wò.
Gbajúmọ̀ kan tí ó jẹ́ alágbàwí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, Thomas H. Huxley, kọ̀wé pé: “Kò sí ẹni tí ó gba ọ̀rọ̀ nípa bí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín . . . ènìyàn àti ẹranko ṣe pọ̀ tó jù mí lọ . . . , nítorí ènìyàn nìkan ni a fi làákàyè àgbàyanu àti ìsọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó ṣeé lóye jíǹkí, [ó sì] . . . wà ní ipò tí ó yọrí ju ẹranko lọ bí pé ó wà ní orí òkè ńlá kan, tí ó ga gan-an ju àwọn ẹranko rírẹlẹ̀ lọ.”
Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n náà, Michael C. Corballis sọ pé, “ìyàtọ̀ ńlá kan wà láàárín ènìyàn àti àwọn ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú onípògíga mìíràn . . . ‘Ọpọlọ wa fi ìlọ́po mẹ́ta tóbi ju èyí tí a lè ronú pé ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú onípògíga kan tí ó jọ wá yóò ní lọ.’” Onímọ̀ nípa ìgbékalẹ̀ àti àrùn iṣan ara náà, Richard M. Restak, pẹ̀lú ṣàlàyé pé: “Ọpọlọ [ènìyàn] ni ẹ̀yà ara kan ṣoṣo tí a mọ̀ tí ń gbìyànjú láti lóye ara rẹ̀ lágbàáyé.”
Leakey sọ pé: “Ọ̀ràn ti mímọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹni ń fún àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní ìṣòro lílekoko kan, tí àwọn kan gbà gbọ́ pé kò ṣeé yanjú. Èrò ti mímọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ síni fúnra ẹni lágbára gan-an débi tí ó ń mú kí a lóye gbogbo ohun tí a ń rò àti èyí tí a ń ṣe.” Ó tún sọ pé: “Ní gidi, èdè mú kí ìyàtọ̀ wà láàárín Homo sapiens [ènìyàn] àti àwọn ẹ̀dá abẹ̀mí yòókù.”
Nígbà tí Peter Russell ń tọ́ka sí ohun tí ó tún jẹ́ àgbàyanu nípa èrò inú ènìyàn, ó kọ̀wé pé: “Láìṣe àní-àní, agbára ìrántí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbára tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí ènìyàn ní. Láìsí i, a kò ní lè kẹ́kọ̀ọ́ . . . , a kò ní ní làákàyè, a kò ní ní èdè, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní ní èyíkéyìí lára àwọn ànímọ́ . . . tí ó sábà máa ń jẹ́ àbùdá ènìyàn.”
Síwájú sí i, kò sí ẹranko tí ń jọ́sìn. Èyí ló mú kí Edward O. Wilson sọ pé: “Ìtẹ̀sí tí ènìyàn ní sí ìgbàgbọ́ ìsìn ni ipá tí ó díjú tí ó sì lágbára jù lọ nínú èrò inú rẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ apá tí kò ṣeé yà sọ́tọ̀ nínú àbùdá ènìyàn.”
Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n náà, Robert Wright, sọ pé: “Ìhùwàsí ènìyàn ń mú kí a gbé ìbéèrè dìde nípa púpọ̀ àwọn àwámáridìí ẹ̀kọ́ èrò orí Darwin mìíràn. Kí ni ipa tí àǹfààní ànímọ́ ìdẹ́rìn-ínpani àti ẹ̀rín kèékèé ń kó? Kí ló dé tí àwọn ènìyàn máa ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kú? . . . Iṣẹ́ wo ni ìbànújẹ́ ń ṣe gan-an? . . . Nísinsìnyí tí ẹni náà ti kú, báwo ni bíbanújẹ́ ṣe ṣàǹfààní fún mímú kí apilẹ̀ àbùdá rẹ̀ máa wà nìṣó?”
Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n náà, Elaine Morgan, sọ pé: “Mẹ́rin lára àwọn ohun àwámáridìí tí ó hàn kedere nípa ènìyàn ni pé: (1) kí ló dé tó jẹ́ ẹsẹ̀ méjì ni wọ́n fi ń rìn? (2) kí ló dé tí wọn kò ní irun lára bí ti ẹranko mọ́? (3) kí ló dé tí wọ́n ní ọpọlọ tí ó tóbi gan-an bẹ́ẹ̀? (4) kí ló dé tí wọ́n kọ́ ọ̀rọ̀ sísọ?”
Báwo ni àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí? Morgan ṣàlàyé pé: “Ìdáhùn tí ó wọ́pọ̀ ni: (1) ‘A kò tíì mọ̀’; (2) ‘A kò tíì mọ̀’; (3) ‘A kò tíì mọ̀’, àti (4) ‘A kò tíì mọ̀.’”
Ahẹrẹpẹ Ẹ̀kọ́
Ẹni tó kọ ìwé The Lopsided Ape sọ pé, ète òun “ni láti ṣe àpèjúwe tí kò ṣe pàtó nípa bí ènìyàn ṣe hú yọ láàárín àkókò kan. Púpọ̀ lára àwọn ìparí èrò rẹ̀ jẹ́ ìméfò, tí a gbé karí ìwọ̀nba ògbólógbòó eyín, egungun, àti òkúta.” Ní ti gidi, ọ̀pọ̀ ènìyàn kò gbà pẹ̀lú àbá èrò orí ti Darwin gan-an fúnra rẹ̀. Richard Leakey sọ pé: “Ohun tí Darwin kọ nípa ọ̀nà tí a gbà hú yọ jọba lórí ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀dá ènìyàn títí di ọdún bí mélòó kan sẹ́yìn, ó sì wá já sí irọ́.”
Gẹ́gẹ́ bí Elaine Morgan ti sọ, ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n “kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìdáhùn tí wọ́n rò pé àwọn ní ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn mọ́.” Nípa bẹ́ẹ̀, kò yani lẹ́nu pé díẹ̀ lára àwọn àbá èrò orí tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ní ti fọ́ yángá.
Àwọn Àbájáde Burúkú
Àwọn ìwádìí kan ti fi hàn pé iye abo ẹranko tí akọ kan ń gùn ní ṣe pẹ̀lú bí ara akọ àti abo ṣe tóbi ju ara wọn lọ sí. Èyí ló mú kí àwọn kan sọ pé, ó yẹ kí àṣà ìbálòpọ̀ ènìyàn bá ti àwọn ọṣà dọ́gba, nítorí pé díẹ̀ ni àwọn akọ ọṣà fi ń tóbi ju àwọn abo lọ, bí ó ti rí ní ti ènìyàn. Nítorí náà, àwọn kan ronú pé, ó yẹ kí a gba ènìyàn láyè láti máa ní alábàálòpọ̀ tí ó ju ẹyọ kan lọ, bí àwọn ọṣà ti ń ṣe. Ohun tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn.
Àmọ́, ohun tó jọ pé ó ń ṣiṣẹ́ dáadáa lára àwọn ọṣà ti fara hàn bí ewu fún àwọn ènìyàn. Ẹ̀rí ti fi hàn pé, ìṣekúṣe ń ṣamọ̀nà sí ìnira tí ó kún fún àìṣọ̀kan ìdílé, ìṣẹ́yún, àrùn, ìdààmú ọpọlọ àti ti ìmọ̀lára, owú, ìwà ipá nínú ìdílé, àti àwọn ọmọ tí a sọ nù tí àwọn náà ń dàgbà di aláìbáwùjọmu, kìkì láti máa bá a lọ nínú àyípoyípo aṣèpalára kan náà. Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ pé àbùdá ènìyàn bá ti ẹranko dọ́gba, kí ló dé tí àwọn nǹkan wọ̀nyí ń fa ìrora fún ènìyàn?
Àwọn èrò ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n tún ń fa iyèméjì nípa ìjẹ́mímọ́ ìwàláàyè ènìyàn. Orí ìpìlẹ̀ wo ni ìwàláàyè ènìyàn fi jẹ́ mímọ́ bí a bá sọ pé kò sí Ọlọ́run, tí a sì ń wo ara wa bí ẹranko ọlọ́pọlọ-pípé lásán? Ṣé lórí ìpìlẹ̀ ti làákàyè wa ni? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, yóò bá a mú láti béèrè ìbéèrè tí a gbé dìde nínú ìwé The Human Difference pé: “Ó ha bójú mu láti bá ènìyàn lò bí ẹni tí ó níyì ju ajá àti ológbò lọ kìkì nítorí pé a ṣoríire [ní ti bí a ṣe hú yọ] bí?”
Ìwé The Moral Animal sọ pé, bí apá ìrònú tuntun nípa ẹfolúṣọ̀n náà ti ń tàn kálẹ̀, “yóò nípa lórí èrò ìwà rere gan-an.” Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìwà rírorò tí ó dá lórí èrò náà pé ńṣe ni a ṣẹ̀dá wa nípasẹ̀ “àṣàyàn àdánidá” tí H. G. Wells sọ pé nípa rẹ̀ ni “àwọn alágbára àti ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ti ń borí àwọn aláìlera àti agbọ́kànléni.”
Ní pàtàkì, ọ̀pọ̀ lára àwọn àbá èrò orí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n tí ó ti ń yọ ìwà rere dà nù díẹ̀díẹ̀ bí ọdún ti ń gorí ọdún ti kùnà níwájú ọ̀wọ́ àwọn onírònú tí ó yọjú lẹ́yìn wọn. Ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ tó wà níbẹ̀ ni pé ìbàjẹ́ tí irú àwọn àbá èrò orí bẹ́ẹ̀ ti ṣe kò kásẹ̀ nílẹ̀.
Ẹ̀dá Ló Yẹ Kí A Jọ́sìn Ni àbí Ẹlẹ́dàá?
Ìṣẹ̀dá ni ẹfolúṣọ̀n ń múni yíjú sí fún ìdáhùn, kì í ṣe Ẹlẹ́dàá. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, Ọlọ́run tòótọ́ náà ni Bíbélì ń múni yíjú sí fún àwọn ìlànà ìwà rere àti ète nínú ìgbésí ayé wa. Ó tún ń ṣàlàyé ìdí tí a fi ní láti làkàkà láti sá fún híhùwà àìtọ́ àti ìdí tí ó fi jẹ́ ènìyàn nìkan ló ń dààmú nípa ikú. Síwájú sí i, àlàyé rẹ̀ nípa ìdí tí a fi ń ní ìtẹ̀sí láti ṣe ohun tí kò dára ń ní ẹ̀rí ìdánilójú nínú èrò inú àti ọkàn-àyà ènìyàn. A rọ̀ ọ́ láti gbé àlàyé tí ó dáni lójú yẹn yẹ̀ wò.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Báwo ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ènìyàn àti ẹranko ṣe pọ̀ tó?