Kí Ni Àwa—Ènìyàn Jẹ́?
Ó JỌ pé ènìyàn kò mọ ohun tí wọ́n jẹ́ ní ti gidi. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n náà, Richard Leakey, sọ pé: “Àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí ti lo ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́nu ọ̀ràn ohun tí ènìyàn jẹ́. Ṣùgbọ́n, ó yani lẹ́nu pé wọn kò fẹnu kò sí àlàyé kankan lórí ohun tí jíjẹ́ ènìyàn túmọ̀ sí.”
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọgbà Ẹranko Copenhagen fi èrò rẹ̀ hàn ní gbangba nípasẹ̀ ìpàtẹ kan ní ilé tí wọ́n ń kó àwọn ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú sí. Ìwé 1997 Britannica Book of the Year ṣàlàyé pé: “Tọkọtaya ará Denmark kan kó lọ sí ibùgbé tí wọn óò wà fún ìgbà díẹ̀ nínú ọgbà ẹranko náà pẹ̀lú èrò rírán àwọn tí ń wá wòran létí ìbátan tí ó wà láàárín àwọn àti àwọn ìnàkí.”
Àwọn ìwé ìtọ́kasí gbà pẹ̀lú irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pé ìbátan tímọ́tímọ́ kan wà láàárín ẹranko àti ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ẹ̀dá ènìyàn, papọ̀ pẹ̀lú àwọn ìnàkí, ẹranko lemur, ọ̀bọ, àti ẹranko tarsier, ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ ọ̀wọ́ ẹranko afọ́mọlọ́mú tí a ń pè ní ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú onípògíga.”
Síbẹ̀, òtítọ́ ìdí ọ̀rọ̀ náà ni pé, ènìyàn ní ọ̀pọ̀ ànímọ́ aláìlẹ́gbẹ́ tí ẹranko kò ní. Lára ìwọ̀nyí ni ìfẹ́, ẹ̀rí ọkàn, ìwà rere, jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí, ìdájọ́ òdodo, àánú, ànímọ́ ìdẹ́rìn-ínpani, ìdánúṣe, ìwàlójúfò nípa àkókò, mímọ àbùdá ẹni, ìmọrírì ẹwà, àníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la, agbára láti gba ìmọ̀ láti ìrandíran, àti ìrètí pé ikú kì í ṣe òpin ìwàláàyè wa pátápátá.
Nínú ìgbìdánwò kan láti mú àwọn ànímọ́ wọ̀nyí bára mu pẹ̀lú ànímọ́ ẹranko, àwọn kan tọ́ka sí ìrònú òun ìhùwà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, tí í ṣe àpapọ̀ ẹfolúṣọ̀n, ìrònú òun ìhùwà, àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ìbáṣepọ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Ìrònú òun ìhùwà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ha ti tànmọ́lẹ̀ sórí àdììtú tó wà nípa àbùdá ènìyàn bí?
Ète Wo Ni Ìgbésí Ayé Ní?
Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n náà, Robert Wright, sọ pé: “Ohun tí a gbé ìrònú òun ìhùwà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n karí rẹ̀ rọrùn. Èrò inú ènìyàn, bí ẹ̀yà ara èyíkéyìí mìíràn, ni a ṣe fún ète títàtaré àwọn apilẹ̀ àbùdá sí ìran tí ń bọ̀; ìmọ̀lára àti èrò tí ń tibẹ̀ jáde ni a lè lóye nípasẹ̀ àwọn ohun tí a gbé e karí rẹ̀ wọ̀nyí.” Lọ́rọ̀ mìíràn, gbogbo ète ìgbésí ayé wa, bí àwọn apilẹ̀ àbùdá wa ti tọ́ka rẹ̀, tí ó sì hàn nínú bí èrò inú wa ṣe ń ṣiṣẹ́, jẹ́ láti bímọ.
Gẹ́gẹ́ bí ìrònú òun ìhùwà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ti sọ, ní gidi, “púpọ̀ nípa àbùdá ènìyàn ló jẹ́ ọkàn ìfẹ́ aláìníjàánu nínú apilẹ̀ àbùdá ara ẹni.” Ìwé The Moral Animal sọ pé: “Àṣàyàn àdánidá ‘ń fẹ́’ kí ọkùnrin máa bá àìmọye obìnrin sùn.” Ní ìbámu pẹ̀lú èròǹgbà ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n yìí, ó bá ìwà ẹ̀dá mu kí àwọn obìnrin pẹ̀lú máa hùwà ìṣekúṣe nínú àwọn ipò kan. Kódà, ìfẹ́ tí àwọn òbí ní sí ọmọ ni a tún wò bí ìwéwèé àfìṣọ́raṣe tí àwọn apilẹ̀ àbùdá ń ṣe láti rí i pé àwọn ọmọ ń wà nìṣó. Nípa bẹ́ẹ̀, èrò kan tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ogún apilẹ̀ àbùdá ní rírí i dájú pé ìdílé ènìyàn ń wà lọ láìlópin.
Àwọn ìwé atọ́nà kan wà tí wọ́n dá lórí èrò tuntun ti ìrònú òun ìhùwà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Ọ̀kan lára wọn ṣàpèjúwe àbùdá ènìyàn bí “èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí àbùdá ọṣà, ìnàkí, tàbí ti irò.” Ó tún sọ pé: “Ní ti ẹfolúṣọ̀n, . . . bíbímọ ló jà.”
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Bíbélì kọ́ni pé, Ọlọ́run dá ènìyàn fún ète kan tí ó ju ti wíwulẹ̀ máa bímọ lọ. Ní “àwòrán” Ọlọ́run ni a dá wa, pẹ̀lú agbára láti gbé àwọn ànímọ́ rẹ̀ yọ, pàápàá ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n, àti agbára. Bí o bá pa àwọn ànímọ́ aláìlẹ́gbẹ́ tí ènìyàn ní tí a mẹ́nu kàn lókè pọ̀ mọ́ ọn, ìdí tí Bíbélì fi gbé àwọn ènìyàn ga ju àwọn ẹranko lọ yóò wá yé ọ. Ní tòótọ́, Bíbélì fi hàn pé kì í ṣe kìkì nítorí ìfẹ́-ọkàn àtiwàláàyè títí láé ni Ọlọ́run ṣe dá ènìyàn, àmọ́ pẹ̀lú agbára láti gbádùn ìmúṣẹ ìfẹ́-ọkàn yẹn nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run yóò mú wá.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; Sáàmù 37:9-11, 29; Oníwàásù 3:11; Jòhánù 3:16; Ìṣípayá 21:3, 4.
Ohun Tí A Gbà Gbọ́ Ń Ní Ipa Lórí Wa
Mímọ èrò tí ó tọ̀nà kì í ṣe ọ̀ràn ti ẹ̀kọ́ ìwé, nítorí ohun tí a bá gbà gbọ́ nípa orírun wa lè ní ipa lórí irú ìgbésí ayé tí a ń gbé. Òpìtàn náà, H. G. Wells, sọ nípa ibi tí ọ̀pọ̀ ènìyàn parí èrò sí lẹ́yìn tí ìwé Origin of Species tí Charles Darwin kọ jáde ní 1859.
“Ojúlówó ìsọdìbàjẹ́ ìwà rere kan bẹ̀rẹ̀. . . . Àwọn ènìyàn di aláìgbàgbọ́ ní ti gidi lẹ́yìn ọdún 1859. . . . Àwọn alágbára ènìyàn tí ń gbé ní ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún gbà gbọ́ pé àwọn borí látàrí Ìjàkadì Láti Wà Láàyè, nínú èyí tí àwọn alágbára àti ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ti ń borí àwọn aláìlera àti agbọ́kànléni. . . . Wọ́n pinnu pé, ènìyàn jẹ́ ẹranko akẹ́gbẹ́jẹ̀ bí ajá ọdẹ ilẹ̀ Íńdíà. . . . Ó jọ pé ó tọ́ lójú wọn pé ó yẹ kí àwọn tí wọ́n lágbára jù nínú àwùjọ ènìyàn máa bú mọ́ni, kí nǹkan sì wà ní ìkáwọ́ wọn.”
Ó ṣe kedere pé, ó ṣe pàtàkì pé kí a ní èrò tí ó tọ́ nípa ohun tí a jẹ́ ní ti gidi. Nítorí pé, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n kan béèrè pé, “bí ògbólógbòó ẹ̀kọ́ èrò orí Darwin . . . bá mú okun ìwà rere ọ̀làjú ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ṣákìí, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí abala tuntun [ìrònú òun ìhùwà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n] bá wọ ọkàn dáadáa?”
Níwọ̀n bí ohun tí a gbà gbọ́ nípa orírun wa ti kan lájorí èrò wa nípa ìgbésí ayé àti nípa ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí a gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò dáadáa.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
Òpìtàn H. G. Wells sọ nípa ibi tí ọ̀pọ̀ ènìyàn parí èrò sí lẹ́yìn tí ìwé Origin of Species tí Charles Darwin kọ jáde ní 1859 pé: “Ojúlówó ìsọdìbàjẹ́ ìwà rere kan ṣẹlẹ̀. . . . Àwọn ènìyàn di aláìgbàgbọ́ ní ti gidi lẹ́yìn ọdún 1859”