ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 159
  • Ṣé Àwọn Ẹranko Ń Lọ sí Ọ̀run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Àwọn Ẹranko Ń Lọ sí Ọ̀run?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ṣé ẹranko ní ọkàn?
  • Ṣé ọkàn máa ń kú?
  • Ṣé ẹranko máa ń dẹ́ṣẹ̀?
  • Ṣé ó dáa kéèyàn ṣèkà fún ẹranko?
  • Àwọn Ẹranko
    Jí!—2015
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ǹjẹ́ Ìwà Ìkà sí Àwọn Ẹranko Dára?
    Jí!—1998
  • Ó Ha Lòdì Láti Máa Jẹ Ẹran Bí?
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 159
Ajá

Ṣé Àwọn Ẹranko Ń Lọ sí Ọ̀run?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bíbélì kọ́ni pé nínú gbogbo ẹ̀dá tó wà láyé, àwọn èèyàn díẹ̀ ló máa lọ sí ọ̀run. (Ìfihàn 14:1, 3) Wọ́n ń lọ láti bá Jésù ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà. (Lúùkù 22:28-30; Ìfihàn 5:9, 10) Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ló máa jí dìde sí orí ilẹ̀ ayé nínú Párádísè.—Sáàmù 37:11, 29.

Kò síbì kankan tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run èyíkéyìí tó wà fún ẹran ọ̀sìn tàbí fún ajá, ó sì nídìí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Àwọn ẹranko ò lè ṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n tóótun láti gba “ìpè ti ọ̀run.” (Hébérù 3:1) Lára àwọn ohun náà ni níní ìmọ̀, ìgbàgbọ́ àti pípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́. (Mátíù 19:17; Jòhánù 3:16; 17:3) Àwọn èèyàn nìkan ni Ọlọ́run fún nírètí láti wà láàyè títí láé.—Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:22, 23.

Kí ẹ̀dá ayé tó lè lọ sí ọ̀run, ó gbọ́dọ̀ jíǹde. (1 Kọ́ríńtì 15:42) Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn àjíǹde mélòó kan. (1 Àwọn Ọba 17:17-24; 2 Àwọn Ọba 4:32-37; 13:20, 21; Lúùkù 7:11-15; 8:41, 42, 49-56; Jòhánù 11:38-44; Ìṣe 9:36-42; 20:7-12) Èèyàn ló sì jí dìde nínú gbogbo wọn, kì í ṣe ẹranko.

  • Ṣé ẹranko ní ọkàn?

  • Ṣé ọkàn máa ń kú?

  • Ṣé ẹranko máa ń dẹ́ṣẹ̀?

  • Ṣé ó dáa kéèyàn ṣèkà fún ẹranko?

Ṣé ẹranko ní ọkàn?

Rárá. Bíbélì sọ pé ẹranko àti èèyàn jẹ́ ọkàn. (Nọ́ńbà 31:28) Nígbà tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, kò fún un ní ọkàn torí pé, ẹ̀yìn náà ló “di alààyè ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Torí náà ohun méjì ló wà nínú ọkàn, àwọn ni: “erùpẹ̀ ilẹ̀” àti “èémí ìyè.”

Ṣé ọkàn máa ń kú?

Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì kọ́ni pé ọkàn máa ń kú. (Léfítíkù 21:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé; Ìsíkíẹ́lì 18:20) Tí ikú bá dé, inú ilẹ̀ ni ẹranko àti èèyàn máa ń pa dà sí. (Oníwàásù 3:19, 20) Tàbí ká kúkú sọ pé wọn ò sí mọ́.a

Ṣé ẹranko máa ń dẹ́ṣẹ̀?

Rárá. Ẹ̀ṣẹ̀ dídá túmọ̀ sí pé ká ronú nípa ohun kan, ká mọ ohun kan lára tàbí ká ṣe ohun kan tó lòdì sí ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Kí ẹ̀dá kan tó lè dẹ́ṣẹ̀, ó ní láti ronú, kó sì ṣèpinnu, àmọ́ àwọn ẹranko ò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ọgbọ́n àdámọ́ni tí wọ́n ní ni wọ́n fi ń ṣe nǹkan láàárín ìgbà kúkúrú tí wọ́n fi wà láàyè. (2 Pétérù 2:12) Lópin ọjọ́ ayé wọn, wọ́n á kú bí wọn ò tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀.

Ṣé ó dáa kéèyàn ṣèkà fún ẹranko?

Rárá. Ọlọ́run fún àwọn èèyàn láṣẹ lórí àwọn ẹranko àmọ́ kò fún wọn láṣẹ láti ṣe wọ́n ṣúkaṣùka. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Sáàmù 8:6-8) Ire ẹranko kọ̀ọ̀kan jẹ Ọlọ́run lógún, títí kan àwọn ẹyẹ kékeré. (Jónà 4:11; Mátíù 10:29) Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn tó ń sìn ín pé kí wọ́n máa gba ti àwọn ẹranko rò.—Ẹ́kísódù 23:12; Diutarónómì 25:4; Òwe 12:10.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa ẹranko

Jẹ́nẹ́sísì 1:28: “Ọlọ́run súre fún [àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́], Ọlọ́run sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ máa jọba lórí àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run àti lórí gbogbo ohun alààyè tó ń rìn lórí ilẹ̀.’”

Ìtúmọ̀: Ọlọ́run fún àwọn èèyàn láṣẹ lórí àwọn ẹranko.

Nọ́ńbà 31:28: “Kí o gba ọkàn kọ̀ọ̀kan nínú ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) èèyàn, ọ̀wọ́ ẹran, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti agbo ẹran lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun tí wọ́n lọ jagun, láti fi ṣe ìpín.”

Ìtúmọ̀: Bíbélì sọ pé ẹranko àti èèyàn jẹ́ ọkàn.

Òwe 12:10: “Olódodo ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn rẹ̀.”

Ìtúmọ̀: Àwọn èèyàn dáadáa máa ń tọ́jú àwọn ẹranko títí kan ẹran ọ̀sìn wọn.

Mátíù 10:29: “Ẹyọ owó kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́ méjì, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀, ìkankan nínú wọn ò lè já bọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀.”

Ìtúmọ̀: Ọlọ́run ń kíyè sí àwọn ẹranko, kò sì fọ̀rọ̀ wọn ṣeré títí kan àwọn ẹyẹ kékeré.

a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo orí 6 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́