ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 8/8 ojú ìwé 18-20
  • Ó Ha Lòdì Láti Máa Jẹ Ẹran Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Lòdì Láti Máa Jẹ Ẹran Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èé Ṣe Tí Àwọn Kan Kì í Jẹ Ẹran?
  • Ó Ha Lòdì Láti Pa Ẹran Bí?
  • Jíjẹ Ẹranko
  • Fífi Ọ̀wọ̀ Hàn fún Ìwàláàyè Ẹranko
  • Níní Ìyọ́nú fún Àwọn Ẹranko
  • Kristẹni Kan Ha Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Ẹni Tí Ń Jẹ Ewébẹ̀ Bí?
  • Àwọn Ẹranko
    Jí!—2015
  • Ǹjẹ́ Ìwà Ìkà sí Àwọn Ẹranko Dára?
    Jí!—1998
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ṣé Àwọn Ẹranko Ń Lọ sí Ọ̀run?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 8/8 ojú ìwé 18-20

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ó Ha Lòdì Láti Máa Jẹ Ẹran Bí?

“KÍYÈ SÍ I, MO TI FI GBOGBO EWÉKO TÍ Ń MÚ IRÚGBÌN JÁDE FÚN YÍN, ÈYÍ TÍ Ó WÀ LÓRÍ GBOGBO ILẸ̀ AYÉ, ÀTI GBOGBO IGI LÓRÍ ÈYÍ TÍ ÈSO IGI TI Ń MÚ IRÚGBÌN JÁDE WÁ. KÍ Ó JẸ́ OÚNJẸ FÚN YÍN.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:29, NW.

SUJATA, ọmọ ọdún 18, tí ó wá láti ìdílé ẹlẹ́sìn Hindu tí wọn kì í jẹ ẹran àyàfi ewébẹ̀, gbà láìjanpata pẹ̀lú ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún ọkùnrin àkọ́kọ́ náà, Ádámù, nípa oúnjẹ. Ṣùgbọ́n ó béèrè lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Nígbà náà, kí ló dé tí àwọn ènìyàn fi ń pa àwọn ẹranko jẹ nígbà tí àwọn ohun mìíràn tí wọ́n lè jẹ wà jaburata?”

Ọ̀pọ̀ ènìyàn jákèjádò ayé ní ń sọ àwọn èrò kan náà jáde. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn ní apá Ìlà Oòrùn ní ń jẹ oúnjẹ tí kò ní ẹran. Ní àfikún, ńṣe ni iye àwọn tí kì í jẹ ẹran àyàfi ewébẹ̀ ní apá Ìwọ̀ Oòrùn ń pọ̀ sí i. Ní United States nìkan, nǹkan bíi mílíọ̀nù 12.4 ènìyàn ní ń sọ pé àwọn kì í jẹ ẹran àyàfi ewébẹ̀, ó fi nǹkan bíi mílíọ̀nù 3 ju bí ó ti rí ní ẹ̀wádún kan sẹ́yìn lọ.

Èé ṣe tí àwọn ènìyàn púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fi nífẹ̀ẹ́ sí oúnjẹ tí kò ní ẹran? Kí ni ojú ìwòye títọ́ nípa ìwàláàyè ẹranko? Jíjẹ ẹran ha fi hàn pé a kò bọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè bí? Lójú ohun tí a sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:29, ó ha lòdì láti máa jẹ ẹran bí? Lákọ̀ọ́kọ́, ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tí àwọn kan kì í fi í jẹ ẹran.

Èé Ṣe Tí Àwọn Kan Kì í Jẹ Ẹran?

Ní ti Sujata, irú oúnjẹ tí ó ń jẹ jẹ́ nítorí ìgbàgbọ́ ìsìn rẹ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Wọ́n tọ́ mi dàgbà lọ́nà ẹ̀sìn Hindu, mo gbà gbọ́ nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àtúnwáyé. Níwọ̀n bí ọkàn ènìyàn ti lè tún wáyé gẹ́gẹ́ bí ẹranko kan, mo ka àwọn ẹranko sí ohun kan náà bí èmi. Nítorí náà, ó jọ pé kò tọ̀nà láti máa pa wọ́n jẹ.” Àwọn ìsìn míràn ṣalágbàwí ìlànà májẹran àyàfi ewébẹ̀.

Àwọn kókó abájọ tí ó yàtọ̀ sí ti ìgbàgbọ́ ìsìn pẹ̀lú ń nípa lórí ohun tí àwọn ènìyàn yàn láti jẹ. Fún àpẹẹrẹ, Dókítà Neal Barnard fi ìtẹnumọ́ kéde ní kedere pé: “Kìkì àwọn ìdí tí ó lè múni jẹ ẹran ni àṣà tàbí àìmọ̀kan.” Èrò lílágbára tí ó ní yìí ni a gbé karí ojú ìwòye rẹ̀ nípa àwọn ewu ìlera tí jíjẹ ẹran ní, bí àrùn ọkàn àyà àti àrùn jẹjẹrẹ.a

A ti sọ pé láàárín àwọn ọ̀dọ́langba ni iye àwọn tí kì í jẹ ẹran àyàfi ewébẹ̀ ti ń pọ̀ sí i jù lọ ní United States. Àníyàn tí wọ́n sì ní fún àwọn ẹranko jẹ́ okùnfà kan. Tracy Reiman ti Àwùjọ Àwọn Alátìlẹ́yìn fún Híhùwà Títọ́ sí Àwọn Ẹranko sọ pé: “Àwọn ọmọdé fẹ́ràn ẹranko. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀ nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹranko kí a tó pa wọ́n jẹ, ó wulẹ̀ ń fún ìyọ́nú tí wọ́n ní lókun sí i ni.”

Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n dàníyàn nípa àyíká pẹ̀lú lóye ìsopọ̀ tó wà láàárín oúnjẹ wọn àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun àdánidá tí a nílò láti sin àwọn ẹranko tí a ń pa jẹ. Fún àpẹẹrẹ, nǹkan bí 3,300 lítà omi ló ń gbà láti pèsè kìlógíráàmù kan ẹran màlúù péré, ó sì ń gba 3,100 lítà omi láti pèsè kìlógíráàmù adìyẹ kan péré. Fún àwọn kan, èyí wá ń di ìdí tí wọ́n fi ní láti yẹra fún ẹran.

Ìwọ ńkọ́? Ó ha yẹ kí o yẹra fún jíjẹ ẹran bí? Kí o tó dáhùn ìbéèrè yẹn, ṣàgbéyẹ̀wò ojú ìwòye mìíràn. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú Orin Dáfídì 50:10, 11 (NW), Jèhófà Ọlọ́run, tí í ṣe Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, sọ pé: “Tèmi ni gbogbo ẹran inú igbó, àwọn ẹranko tí ń bẹ lórí ẹgbẹ̀rún òkè ńlá. Èmi mọ olúkúlùkù ẹ̀dá abìyẹ́lápá tí ń bẹ lórí àwọn òkè ńlá ní àmọ̀dunjú, ògídímèje àwọn ẹran pápá gbalasa sì ń bẹ pẹ̀lú mi.” Níwọ̀n bí gbogbo ẹranko ti jẹ́ ti Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì láti lóye bí ìmọ̀lára Ẹlẹ́dàá ti rí nípa ìwàláàyè ẹranko àti bí ènìyàn ṣe ń fi ṣe oúnjẹ.

Ó Ha Lòdì Láti Pa Ẹran Bí?

Bíi Sujata, àwọn kan tí wọ́n kà á sí pé àwọn ẹranko jẹ́ ohun kan náà bí ènìyàn nímọ̀lára gan-an pé gbígbẹ̀mí ẹranko kan fún ète èyíkéyìí lòdì—pàápàá jù lọ pípa wọ́n jẹ. Síbẹ̀síbẹ̀, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Ọlọ́run fìyàtọ̀ sáàárín ìwàláàyè ẹranko àti ti ẹ̀dá ènìyàn, ó sì fàyè gba pípa àwọn ẹranko fún onírúurú ète. Fún àpẹẹrẹ, ní Ísírẹ́lì, a lè pa ẹranko kan tí ó bá ń wu ìwàláàyè ènìyàn tàbí ẹran ọ̀sìn ẹni léwu.—Ẹ́kísódù 21:28, 29; Sámúẹ́lì Kíní 17:34-36.

Láti àtètèkọ́ṣe ni Ọlọ́run ti fọwọ́ sí fífi àwọn ẹranko rúbọ nínú ìjọsìn. (Jẹ́nẹ́sísì 4:2-5; 8:20, 21) Ó tún fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítọ̀ọ́ni láti máa ṣe ìrántí Ìjádekúrò wọn ní Íjíbítì nípa ṣíṣayẹyẹ Ìrékọjá lọ́dọọdún, èyí tí ó ní nínú, fífi ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí àgbò kan rúbọ àti jíjẹ ẹran rẹ̀. (Ẹ́kísódù 12:3-9) Lábẹ́ Òfin Mósè pẹ̀lú, àwọn àkókò kan wà fún fífi ẹranko rúbọ.

Nígbà tí obìnrin ẹlẹ́sìn Hindu kan, tí ó jẹ́ ẹni 70 ọdún, ń ka Bíbélì nígbà àkọ́kọ́, ó rí èrò fífi ẹranko rúbọ bí èyí tí kò bá òun lára mu. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ Ìwé Mímọ́, ó wá rí i pé àwọn ìrúbọ tí Ọlọ́run pa láṣẹ ní ète kan. Wọ́n ń tọ́ka síwájú sí ìrúbọ Jésù Kristi, tí ó wà fún mímú ohun tí a béèrè fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ lọ́nà òfin. (Hébérù 8:3-5; 10:1-10; Jòhánù Kíní 2:1, 2) Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ púpọ̀, àwọn ẹbọ náà tún ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún àwọn àlùfáà àti lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan fún àwọn olùjọ́sìn. (Léfítíkù 7:11-21; 19:5-8) Ọlọ́run, tí ó ni gbogbo ẹ̀dá alààyè, lè fi ẹ̀tọ́ gbé irú ìṣètò bẹ́ẹ̀ kalẹ̀ fún ète kan. Dájúdájú, gbàrà tí Jésù ti kú, a kò béèrè fún fífi ẹranko rúbọ nínú ìjọsìn mọ́.—Kólósè 2:13-17; Hébérù 10:1-12.

Jíjẹ Ẹranko

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀ràn ti pípa ẹranko jẹ ńkọ́? Òtítọ́ ni pé ewébẹ̀ nìkan ni oúnjẹ ènìyàn látètèkọ́ṣe. Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, Jèhófà wá fi ẹran kún un. Ní nǹkan bí 4,000 ọdún sẹ́yìn—ní ọjọ́ Nóà olódodo—Jèhófà mú kí ìkún omi kan ṣẹlẹ̀ kárí ayé, ó sì fòpin sí ìwà burúkú tó wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà náà. Nóà, ìdílé rẹ̀, àti àwọn ẹ̀dá alààyè tí ó kó sínú áàkì la Ìkún Omi náà já. Lẹ́yìn tí wọ́n jáde kúrò nínú áàkì, fún ìgbà àkọ́kọ́, Jèhófà wí pé: “Gbogbo ẹran tí ń rìn, tí ó wà láàyè, lè jẹ́ oúnjẹ fún yín. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ti ewéko tútù yọ̀yọ̀, mo fi gbogbo rẹ̀ fún yín.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, NW) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lákòókò kan náà, Ọlọ́run ṣe òfin pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó ti ta ẹ̀jẹ̀ tirẹ̀ sílẹ̀, nítorí ní àwòrán Ọlọ́run ni ó ṣe ènìyàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:6, NW) Ní kedere, Ọlọ́run kò fi àwọn ẹranko àti ènìyàn sí ipò kan náà.

Ní gidi, èrò tí Sujata ní nípa àwọn ẹranko jẹ́ látàrí èrò ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àtúnwáyé. Nípa èyí, Bíbélì ṣàlàyé pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn àti ẹranko jẹ́ ọkàn, ọkàn kì í ṣe aláìlèkú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4, 20; Ìṣe 3:23; Ìṣípayá 16:3) Bí ọkàn, àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko ń kú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í sí mọ́. (Oníwàásù 3:19, 20) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ènìyàn ní ìrètí àgbàyanu ti àjínde nínú ayé tuntun Ọlọ́run.b (Lúùkù 23:43; Ìṣe 24:15) Èyí pẹ̀lú ń fi hàn pé àwọn ẹranko kò bá ènìyàn dọ́gba.

“Síbẹ̀, kí ló fa ti yíyí oúnjẹ pa dà?” Sujata fẹ́ láti mọ̀. Ẹ̀rí fi hàn pé ipò ojú ọjọ́ ilẹ̀ ayé ti yí pa dà gidigidi nítorí Ìkún Omi náà. Bíbélì kò sọ bóyá ńṣe ni Jèhófà fi ẹran kún oúnjẹ ènìyàn nítorí pé ó fojú sọ́nà fún àwọn àìní àwọn ìran ọjọ́ iwájú tí yóò gbé àwọn àgbègbè tí ewébẹ̀ yóò ti ṣọ̀wọ́n. Ṣùgbọ́n Sujata lè gbà pé Ẹni tí ó ni ohun alààyè gbogbo ní ẹ̀tọ́ láti yí nǹkan pa dà.

Fífi Ọ̀wọ̀ Hàn fún Ìwàláàyè Ẹranko

Síbẹ̀, Sujata ṣe kàyéfì pé, ‘Ó kéré tán, kò ha yẹ kí a fi ọ̀wọ̀ díẹ̀ hàn fún ìwàláàyè ẹranko bí?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí a fi hàn. Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo sì sọ bí a ṣe lè ṣe èyí fún wa. Òfin rẹ̀ sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 9:4 (NW) pé: “Kìkì ẹran pẹ̀lú ọkàn rẹ̀—ẹ̀jẹ̀ rẹ̀—ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ.” Kí ló fa kíkà tí a ka jíjẹ ẹ̀jẹ̀ léèwọ̀? Bíbélì wí pé: “Nítorí ọkàn [ìwàláàyè] ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀.” (Léfítíkù 17:10, 11, NW) Jèhófà ti fi lélẹ̀ pé: ‘Orí ilẹ̀ ni kí o da ẹ̀jẹ̀ ẹran tí o pa náà jáde sí bí omi.’—Diutarónómì 12:16, 24, NW.

Èyí kò túmọ̀ sí pé àǹfààní jíjẹ ẹran fúnni lómìnira láti sọ títa ẹ̀jẹ̀ ẹranko sílẹ̀ láìnídìí dàṣà nítorí ìmóríyá ṣíṣe ọdẹ tàbí fífi agbára àrà ọ̀tọ̀ tí a ní hàn. Dájúdájú, Nímírọ́dù ṣe èyí. Bíbélì tọ́ka sí i bí “ọdẹ alágbára ńlá ní ìlòdì sí Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 10:9, NW) Kódà lónìí pàápàá, ìmóríyá ṣíṣe ọdẹ àti pípa àwọn ẹranko lè tètè gbèrú nínú àwọn kan. Ṣùgbọ́n irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú ìwà àìka ìwàláàyè ẹranko sí, tí ó ṣòro láti ṣàkóso, Ọlọ́run kò sì fọwọ́ sí i.c

Níní Ìyọ́nú fún Àwọn Ẹranko

Àwọn kan tí wọn kì í jẹ ẹran àyàfi ewébẹ̀ lónìí pẹ̀lú ní àníyàn aláìlábòsí nípa ọ̀nà tí àwọn ilé iṣẹ́ tí ń pèsè ẹran ń gbà bá àwọn ẹranko lò. Ìwé ìléwọ́ náà, The Vegetarian Handbook, sọ pé: “Ìwọ̀nba ọkàn ìfẹ́ kéréje ni òwò iṣẹ́ àgbẹ̀ ní nínú ìsúnniṣe àdánidá àwọn ẹranko.” Ìwé náà sọ pé: “Bí a ti ń sìn wọ́n nínú àyíká híhá gádígádí, tí kò bójú mu, tí kò sì bá ti ẹ̀dá mu, a ti kó àwọn ẹranko òde òní nífà pátápátá lọ́nà tí ó túbọ̀ pọ̀ ju èyí tí ó tí ì ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹranko rí lọ.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé jíjẹ àwọn ẹranko kò lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run, híhùwà sí wọn lọ́nà rírorò lòdì sí ìfẹ́ rẹ̀. Bíbélì sọ nínú Òwé 12:10 (NW) pé: “Olódodo ń bójú tó ọkàn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ̀.” Òfin Mósè sì pàṣẹ ọ̀nà bíbójútó àwọn ẹranko agbéléjẹ̀ lọ́nà bíbẹ́tọ̀ọ́mu.—Ẹ́kísódù 23:4, 5; Diutarónómì 22:10; 25:4.

Kristẹni Kan Ha Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Ẹni Tí Ń Jẹ Ewébẹ̀ Bí?

Gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú ọ̀rọ̀ tí a ń bá bọ̀, ọ̀ràn dídi ẹni tí ń jẹ ewébẹ̀—tàbí bíbá a lọ ní ipò náà—jẹ́ ọ̀ràn ìpinnu àdáṣe jálẹ̀jálẹ̀. Nítorí ìlera, ipò ìṣúnná owó, àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn, tàbí ìyọ́nú sí àwọn ẹranko, ẹnì kan lè yàn láti máa jẹ ewébẹ̀ nìkan. Ṣùgbọ́n ó gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n bí ọ̀kan ṣoṣo lára àwọn ìlànà oúnjẹ. Kò gbọ́dọ̀ ṣe àríwísí àwọn tí wọ́n yàn láti máa jẹ ẹran, lọ́nà kan náà tí ẹnì kan tí ń jẹ ẹran kò fi gbọ́dọ̀ dẹ́bi fún ẹnì kan tí ń jẹ ewébẹ̀ nìkan. Jíjẹ ẹran tàbí ṣíṣàìjẹran kò sọni di ẹni dídára jù. (Róòmù 14:1-17) Bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ ẹni kò gbọ́dọ̀ di lájorí àníyàn ẹni nínú ìgbésí ayé ẹni. Jésù wí pé: “Ènìyàn gbọ́dọ̀ wà láàyè, kì í ṣe nípasẹ̀ búrẹ́dì nìkanṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo gbólóhùn àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.”—Mátíù 4:4.

Nípa ti ìwà òǹrorò sí àwọn ẹranko àti lílo àwọn ohun àlùmọ́nì ilẹ̀ ayé nílòkulò, Jèhófà ti ṣèlérí láti fòpin sí ètò ìgbékalẹ̀ dídíbàjẹ́ tí ó níwọra yìí, kí ó sì fi ayé tuntun tí òun yóò mú wá rọ́pò rẹ̀. (Orin Dáfídì 37:10, 11; Mátíù 6:9, 10; Pétérù Kejì 3:13) Nínú ayé tuntun yẹn, ènìyàn àti ẹranko yóò wà lálàáfíà pẹ̀lú ara wọn títí láé, Jèhófà yóò sì “tẹ́ ìfẹ́ ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.”—Orin Dáfídì 145:16; Aísáyà 65:25.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Jí!, June 22, 1997, ojú ìwé 3 sí 13.

b Wo Ilé Ìsọ́, May 15, 1997, ojú ìwé 3 sí 8, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.

c Wo Ilé Ìṣọ́nà, May 15, 1990, ojú ìwé 30 sí 31.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]

Punch

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́