Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ìwà Ìkà sí Àwọn Ẹranko Dára?
NÍBI ìṣeré orílẹ̀-èdè kan ní Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà, gbogbo èrò dajú bo àwọn adìyẹ méjì, ọ̀kan pupa, èkejì funfun. Àwùjọ náà pariwo gèè nígbà tí adìyẹ pupa, tí a di abẹfẹ́lẹ́ tó mú gidigidi kan mọ́ lẹ́sẹ̀, fi abẹfẹ́lẹ́ náà ya adìyẹ funfun náà. Olùdarí eré kan kó àwọn adìyẹ méjèèjì. Ara adìyẹ funfun náà ti rọ jọwọlọ, ó ti kú, ẹ̀jẹ̀ sì ń ro tó tó lára rẹ̀. Ìjà adìyẹ náà ti parí.
Ní ìhà gúúsù Philippines, wọ́n dojú akọ ẹṣin méjì kọ ara wọn. Àwọn òǹwòran ń wo ìran ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ náà, bí àwọn ẹṣin náà ṣe ń gé ara wọn jẹ ní etí, ọrùn, imú, àti àwọn ẹ̀yà ara mìíràn. Bí ó tilẹ̀ ṣeé ṣe kí àwọn méjèèjì kúrò lójú ìjà náà láàyè, ó kéré tán, ọ̀kan nínú wọn yóò daláàbọ̀ ara tàbí kí ó fọ́jú tàbí kí ó fara pa lọ́nà tí yóò mú kí ó kú níkẹyìn.
Àwọn ajá méjì ń bá ara wọn jà ní Rọ́ṣíà. Ní wàràǹṣeṣà, wọ́n ti yọ ara wọn lójú, wọ́n sì gé ara wọn létí sọ nù, wọ́n wá ń tiro lọ lẹ́yìn tí wọ́n ti dá ara wọn lẹ́sẹ̀, ẹ̀jẹ̀ sì ń ṣàn lójú ọgbẹ́ ara wọn.
Nítorí pé àwọn ènìyàn ń fẹ́ dá ara wọn lára yá, tó sì jẹ́ pé, tẹ́tẹ́ títa ni ó ń sún wọn sí i, wọ́n ti ń mú kí àwọn ẹranko máa bá ara wọn jà láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá. Láfikún sí i, bíbá màlúù jà, dídọdẹ kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àti ìjà aláǹtakùn tún wà níbẹ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lú, a ń fìyà jẹ ọ̀pọ̀ ẹranko nídìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Síwájú sí i, àìlóǹkà ẹranko ni àwọn tó ni wọ́n kì í tọ́jú, bóyá nítorí èèṣì tàbí àmọ̀ọ́mọ̀ṣe.
Ní àwọn ilẹ̀ kan, wọ́n ṣe àwọn òfin lórí bí àwọn ènìyàn ṣe gbọ́dọ̀ máa hùwà sí ẹranko, wọ́n sì fòfin de híhùwà ìkà sí ẹranko. Ní 1641, Ibùdó Massachusetts Bay ṣe “Àkójọ Òfin Òmìnira” tí ó sọ pé: “Ẹnì kankan kò gbọdọ̀ hù Ìwà Ipá tàbí Ìwà Ìkà sí Ẹranko kankan tí a bá ń sìn fún ìlò ènìyàn.” Láti ìgbà náà wá, ọ̀pọ̀ òfin la ti ṣe, tí a sì ti dá ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ sílẹ̀ láti ta ko ìwà ìkà sí àwọn ẹranko.
Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tí ń ṣagbátẹrù àwọn eré ìdárayá tí a mẹ́nu bà lókè kò ka ara wọn sí ẹni tí ń gbé ìwà ìkà sí àwọn ẹranko lárugẹ. Àwọn kan sọ pé àwọ́n fẹ́ràn àwọn ẹranko tí wọ́n ń fìyà jẹ tàbí tí wọ́n ń pa lọ́nà oníkà náà. Àwọn tí wọ́n fẹ́ràn ìjà adìyẹ sọ pé, àwọn adìyẹ àwọn ń pẹ́ láyé ju bó ti yẹ fún àwọn adìyẹ tí a ń pa jẹ lọ—àwáwí gbáà lèyí jẹ́!
Èé Ṣe Tí Ìwà Ìkà Kò fi Dára?
Ọlọ́run yọ̀ǹda fún wa láti jàǹfààní lára àwọn ẹranko. Àwọn ìlànà inú Bíbélì gbà wá láyè láti pa àwọn ẹranko nítorí oúnjẹ àti aṣọ tàbí láti dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ ewu. (Jẹ́nẹ́sísì 3:21; 9:3; Ẹ́kísódù 21:28) Síbẹ̀síbẹ̀, ìwàláàyè ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ lo ipò ọba tí a wà lórí àwọn ẹranko lọ́nà oníwọ̀ntúnwọ̀nsì tó ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún ìwàláàyè. Bíbélì dẹ́bi fún ọkùnrin kan tí ń jẹ́ Nímírọ́dù, tó ṣe kedere pé, ó wulẹ̀ ń pa àwọn ẹranko, bóyá tí ó pa ènìyàn pàápàá, láti fi dá ara rẹ̀ lára yá.—Jẹ́nẹ́sísì 10:9.
Jésù sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń dàníyàn nípa àwọn ẹranko nígbà tí ó wí pé: “Ológoṣẹ́ márùn-ún ni a ń tà ní ẹyọ owó méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:6) Nígbà tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sì ń yí ìpinnu rẹ̀ padà lórí ìparun tó fẹ́ mú bá ìlú kan tó kún fún àwọn olubi tó ronú pìwà dà, ó wí pé: “Ní tèmi, kò ha sì yẹ kí n káàánú fún Nínéfè ìlú ńlá títóbi nì, inú èyí tí àwọn ènìyàn tí ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà wà . . . , yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹran agbéléjẹ̀?” (Jónà 4:11) Dájúdájú, kò ka àwọn ẹranko sí ohun àlòsọnù lásán, tí a lè fi ṣòfò bí a bá ṣe fẹ́.
Nígbà tí Ọlọ́run ń fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lófin, ó kọ́ wọn bó ṣe yẹ láti ṣètọ́jú àwọn ẹranko. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n máa dá ẹranko tí ń ṣáko lọ padà fún ẹni tó ni ín, kí wọ́n sì máa ṣèrànwọ́ fún ẹranko tó bá wà nípò ìnira. (Ẹ́kísódù 23:4, 5) Bí ti àwọn ènìyàn, àwọn ẹranko tún gbọ́dọ̀ jàǹfààní ìsinmi Sábáàtì. (Ẹ́kísódù 23:12) Àwọn òfin wà lórí bí a ṣe gbọ́dọ̀ hùwà sí àwọn ẹranko tí a fi ń ṣiṣẹ́ lóko. (Diutarónómì 22:10; 25:4) Ó ṣe kedere pé, ó yẹ kí a máa tọ́jú àwọn ẹranko, kí a sì máa dáàbò bò wọ́n, kì í ṣe pé kí a máa kó wọn nífà.
Òwe 12:10 sọ èrò Ọlọ́run ní kedere pé: “Olódodo ń bójú tó ọkàn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìkà ni àánú àwọn ẹni burúkú.” Ìwé àlàyé lórí Bíbélì kan túmọ̀ ẹsẹ yìí sí: “Inúure olódodo ń kan àwọn ẹranko tí kì í sọ̀rọ̀ pàápàá, àmọ́ ẹni burúkú níkà, kódà nígbà tó bá ń rò pé òun ń ṣe pẹ̀lẹ́ pàápàá.”—Believer’s Bible Commentary, láti ọwọ́ William MacDonald.
Olódodo ń fi inúure hàn sí àwọn ẹranko, ó sì ń fẹ́ mọ àìní wọn. Ẹni burúkú lè sọ pé òún fẹ́ràn àwọn ẹranko, ṣùgbọ́n “àánú” rẹ̀, níbi tó ti hàn jù, jẹ́ ìkà gidi. Ìwà rẹ̀ táṣìírí èrò onímọtara-ẹni-nìkan tó ní. Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ òtítọ́ tó ní ti àwọn tí ń torí kí wọ́n lè jèrè owó mú kí àwọn ẹranko máa bá ara wọn jà!
Ìtura fún Àwọn Ẹranko
Lóòótọ́, ète tí Ọlọ́run ní nípìlẹ̀ ni pé, kí ènìyàn “máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ète yẹn kò fàyè sílẹ̀ fún ìwà ìkà sí àwọn ẹranko. Ìwà ìkà tí a ń hù sí àwọn ẹranko kò ní máa bá a lọ títí ayé. Ó dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò dáwọ́ gbogbo ìjìyà tí kò tọ́ dúró. Àmọ́, báwo ni?
Ó ṣèlérí pé òun yóò mú àwọn ènìyàn burúkú àti ìkà kúrò. (Òwe 2:22) Nípa ti àwọn ẹranko, Hóséà 2:18 kà pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì dá májẹ̀mú fún wọn ní ọjọ́ yẹn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹranko inú pápá àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti ohun tí ń rákò lórí ilẹ̀, . . . èmi yóò sì mú kí wọ́n dùbúlẹ̀ ní ààbò.” Ẹ wo bí yóò ti dára tó láti wà láàyè ní àkókò yẹn, tí aráyé oníwàtítọ́ àti àwọn ẹranko pẹ̀lú yóò gbádùn ipò alálàáfíà!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
“Bíbá Màlúù Jà Lábúlé Kan,” láti ọwọ́ Francisco Goya