Báwo Ni Ohun Tí Ọmọ Rẹ Lè Mọ̀ Ṣe Pọ̀ Tó?
Àwọn àgbàlagbà kì í sábà mọ bí ohun tí àwọn ọmọ kékeré lè mọ̀ ṣe pọ̀ tó. Síbẹ̀, àwọn ọmọdé sábà máa ń tètè lóye èdè tuntun ju àwọn òbí wọn lọ. Nígbà tí wọ́n bá fi máa di ọmọ ọdún mẹ́rin, àwọn kan ti máa ń sọ èdè méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lọ́dún tó kọjá, Rhonda, obìnrin kan láti ìlú Auburn, ní ìpínlẹ̀ Washington, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tó ti máa ń ṣiyèméjì nípa bí ohun tí ọmọdé kan lè mọ̀ ṣe pọ̀ tó, kọ̀wé pé: “Ẹ ṣé gan-an tẹ́ ẹ jẹ́ kí n mọ̀ pé èrò mi ò tọ̀nà rárá.”
Rhonda ṣàlàyé pé òun ti kà nípa ìrírí kan nínú ìwé ìròyìn wa kejì, ìyẹn Ilé-Ìṣọ́nà, ìtẹ̀jáde ti August 1, 1988, ó sì sọ pé: “Ní ojú ìwé 13, ìyá ọmọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin ààbọ̀ sọ pé nígbà tí òun ń ka Iwe Itan Bibeli Mi tí òun sì dánu dúró, ńṣe ni ọmọ òun ń ka ìtàn náà lọ láìṣi ọ̀rọ̀ kankan pè. Ó fi kún un pé ọmọ náà ti mọ ìtàn mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àkọ́kọ́ nínú ìwé náà sórí, títí kan orúkọ àwọn àgbègbè àtàwọn èèyàn tó ṣòro láti pè. Mo ní láti jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé mo rò ó nínú ara mi nígbà náà pé ìyẹn ò lè ṣeé ṣe. Àmọ́ o, èrò mi ò tọ̀nà. Báyìí, mo jẹ́ ìyá ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin tóun náà ti mọ púpọ̀ nínú àwọn ìtàn tó wà nínú Iwe Itan Bibeli Mi lámọ̀sórí.”
Kí ni ìwọ náà ń ṣe láti fún ọmọ rẹ níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́? Iwe Itan Bibeli Mi olójú ewé 256 yìí ní ìtàn mẹ́rìndínlọ́gọ́fà tó sọ nípa àwọn èèyàn àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú Bíbélì. O lè rí i gbà nípa kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.