Mímọ Àwọn Ìṣòro Líle Koko Tí Kì Í Jẹ́ Kéèyàn Rí Oorun Sùn
NÍGBÀ míì, àwọn àmì téèyàn ń rí lè fi hàn pé èèyàn ní ìṣòro tó le koko tí kì í jẹ́ kéèyàn rí oorun sùn. Àwọn ìṣòro lílégbá kan, títí kan àárẹ̀ ọkàn, ló máa ń fa ìṣòro àìróorunsùntó tó le gan-an, èyí tó máa ń wà bẹ́ẹ̀ fún ohun tó lé lóṣù. Ìṣòro àìróorunsùntó tó le gan-an tún lè jẹ́ àmì pé àìsàn ńlá kan fẹ́ ṣeni.
Ìṣòro Síséèémí Lójú Oorun
Mario máa ń tòògbé gan-an lójú mọmọ. Tó bá ń wakọ̀ ìdílé wọn lọ, ìyàwó rẹ̀ ní láti máa ṣọ́ ọ lójú méjèèjì nítorí ìgbàkigbà loorun lè gbé e lọ fún àkókò díẹ̀, èyí tóun fúnra rẹ̀ kì í fi bẹ́ẹ̀ rántí. Ó máa ń han-anrun gan-an látìgbàdégbà lóru, ìgbà míì sì rèé, ó lè ta jí wùyà lójú oorun tí yóò sì máa mi hẹlẹhẹlẹ.a
Ìṣòro síséèémí lójú oorun tí Mario ní jẹ́ irú èyí tó wọ́pọ̀. Èémí lè sé fún nǹkan bí ìṣẹ́jú àáyá mẹ́wàá sí ìṣẹ́jú méjì tàbí mẹ́ta. Ńṣe lẹni tó ní ìṣòro yìí sábà máa ń yí kiri, tí yóò máa mí gúlegúle àmọ́ lẹ́yìn náà yóò tún sùn lọ, ni yóò bá tún séèémí lọ tí èyí sì máa ń ṣẹlẹ̀ fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìgbà lóru. Ọ̀nà mẹ́ta ni ìṣòro síséèémí lójú oorun pín sí.
Ìṣòro síséèémí lójú oorun nítorí àìṣedéédéé kan nínú ọpọlọ máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí apá kan nínú ọpọlọ tó ń darí mímí kò bá sọ fún ara láti mí déédéé. Ìṣòro síséèémí lójú oorun nítorí ọ̀fun tó dí ni èkejì, tí apá òkè ibi tí èémí máa ń gbà kọjá lẹ́yìn ọ̀nà ọ̀fun máa ń dí pátápátá tí kò sì ní ṣeé ṣe fún afẹ́fẹ́ láti ráyè kọjá. Ìṣòro síséèémí lójú oorun tí àìṣedéédéé kan nínú ọpọlọ àti ọ̀nà ọ̀fun tó dí ń fà ni ẹ̀kẹta, tó túmọ̀ sí pé wọ́n máa ń ṣẹlẹ̀ pa pọ̀, èyí ló sì wọ́pọ̀ jù lọ. Tẹ́ni tó ní èyíkéyìí nínú àwọn ìṣòro síséèémí lójú oorun yìí bá jí, ó lè má yàtọ̀ sẹ́ni tí kò sùn lóru rárá, tí èyí á sì máa ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ lálaalẹ́!
Àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé ìgbésí ayé tó léwu làwọn tó ní ìṣòro síséèémí lójú oorun ń gbé, nítorí oorun lè gbé wọn lọ lẹ́nu iṣẹ́ tàbí níbi tí wọ́n ti ń wakọ̀ lọ. Ìwọ̀n ìfúnpá wọn lè máa ga, kí ọkàn wọn tóbi ju bó ṣe yẹ lọ, wọ́n sì lè tètè ní àrùn rọpárọsẹ̀ tàbí kí ọkàn wọn máa dáwọ́ iṣẹ́ dúró. Dókítà William Dement ti Yunifásítì Stanford fojú bù ú pé ẹgbẹ̀rún méjìdínlógójì [38,000] àwọn ará Amẹ́ríkà ló ń kú lọ́dọọdún látàrí àwọn ìṣòro tó jẹ mọ́ ọkàn, èyí tó jẹ́ àbájáde ìṣòro síséèémí lójú oorun.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin tó sanra gan-an tí wọ́n ti lé lógójì ọdún ni ìṣòro síséèémí lójú oorun sábà máa ń ṣe, kò sí ọjọ́ orí tí kò lè ṣeni, kódà ó ń ṣe àwọn ọmọ kékeré pàápàá. Oríṣiríṣi ìtọ́jú ló wà fún un, ó sì dára gan-an pé kí àwọn ìtọ́jú wọ̀nyí wáyé lábẹ́ àbójútó dókítà tó mọ̀ nípa oorun dáadáa. Ìtọ́jú tí kò la iṣẹ́ abẹ lọ tó gbéṣẹ́ jù lọ fún àìsàn yìí ni lílo ẹ̀rọ kan tó máa ń rọra fẹ́ afẹ́fẹ́ sínú ihò imú àti ẹnu. Ẹni tó ní ìṣòro náà á máa lo ohun kan tó ń bá ẹ̀rọ ṣiṣẹ́ láti bo imú rẹ̀ lóru, tí ohun kan tó ń díwọ̀n afẹ́fẹ́ (tí dókítà á ti yí sí ìwọ̀n tó yẹ) yóò sì máa fẹ́ kìkì ìwọ̀n afẹ́fẹ́ tẹ́ni náà nílò láti má séèémí lójú oorun. Bí èyí kò bá yanjú ìṣòro náà, àwọn iṣẹ́ abẹ bíi mélòó kan wà tí wọ́n lè ṣe, títí kan lílo àkànṣe ẹ̀rọ tó ń lo ìtànṣán láti mú àpọ̀jù ìṣù ẹran tó wà lọ́nà ọ̀fun kúrò.
Ìṣòro Kí Oorun Máa Ṣàdéédéé Gbéni Lọ
Ìṣòro oorun mìíràn tó tún ń fẹ́ àmójútó ni kí oorun máa ṣàdéédéé gbéni lọ, ìyẹn ìṣòro kan nínú ọpọlọ tó máa ń mú kéèyàn máa sùn ṣáá bí ẹtà lójú mọmọ. Bí àpẹẹrẹ, ńṣe ni Buck máa ń tòògbé ṣáá. Kódà, ó máa ń sùn lọ nígbà tí ìpàdé pàtàkì bá ń lọ lọ́wọ́. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ̀ dání débi pé tó bá tún ti ṣèèṣì sùn lọ, ariwo táwọn kọ́kọ́rọ́ náà máa pa nígbà tí wọ́n bá jábọ́ sílẹ̀ á lè jí i. Ẹ̀yìn èyí ló tún ní ìṣòro kan tó ń jẹ́ cataplexy, èyí tí kì í jẹ́ kí orúnkún rẹ̀ lágbára tí yóò sì ṣubú lulẹ̀ nígbàkigbà tí ara rẹ̀ bá yá gágá. Lẹ́yìn ìyẹn ló di pé kí gbogbo ara rẹ̀ máa rọ jọwọrọ láìlè gbápá-gbẹ́sẹ̀ kí oorun tó gbé e lọ tàbí tó bá ń jí bọ̀, yóò sì tún máa ṣèrànrán kó tó gbàgbé sùn lọ.
Nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́wàá sí ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ìṣòro kí oorun máa ṣàdéédéé gbéni lọ sábà máa ń bẹ̀rẹ̀. Nígbà míì, àwọn tó ń ṣe á máa ṣe bí ẹni ń ṣarán, tí yóò dà bíi pé wọ́n ń hùwà bó ṣe yẹ àmọ́ tí wọn ò ní rántí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò ti kọjá lọ. Ibi tí àìsàn yìí burú sí ni pé ó lè máa ṣe ẹnì kan fún ọ̀pọ̀ ọdún láìmọ̀, tí wọ́n á sì máa fi ojú ọ̀lẹ èèyàn wo ẹni náà tàbí kí wọ́n kà á sí dìndìnrìn tàbí àdàmọ̀dì èèyàn. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, wọ́n ní kò ṣeé wò sàn, àmọ́ lílo oògùn àti yíyí ọ̀nà téèyàn ń gbà gbé ìgbésí ayé padà lè dènà àwọn ìṣòro tó máa ń jẹ yọ, èyí sì máa ń mú onírúurú àṣeyọrí wá.b
Àwọn Ìṣòro Mìíràn Tí Kì Í Jẹ́ Kéèyàn Rí Oorun Sùn
Apá àti ẹsẹ̀ làwọn ìṣòro méjì míì tó máa ń ṣeni pa pọ̀ nígbà míì máa ń dìídì bá jà, èyí sì lè yọrí sí àìróorunsùntó tó le gan-an. Ọ̀kan lára rẹ̀ ni kéèyàn máa japá jasẹ̀ lójú oorun, èyí tó jẹ́ pé èèyàn á máa ju ẹsẹ̀, àti nígbà míì apá, lójú oorun. Gbé ọ̀ràn ti Michael yẹ̀ wò. Àwọn àyẹ̀wò fi hàn pé báwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ ṣe máa ń jù lọ jù bọ̀ máa ń mú kó ta jí ní àádọ́ta dín nírínwó [350] ìgbà lóròòru!
Ìṣòro mìíràn tó tún yàtọ̀ ni kí ẹsẹ̀ máa rinni wìnnìwìnnì,c èyí tó máa ń mú kí àwọn nǹkan kan nínú àwọn iṣan inú ẹsẹ̀ àti orúnkún máa rinni wìnnìwìnnì, táá sì mú kí ẹni náà fẹ́ dìde máa rìn, tí kò sì ní lè rí oorun sùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìkìí ṣe eré ìmárale tàbí kí ẹ̀jẹ̀ má ṣàn dáadáa nínú ara ni wọ́n sọ pé ó ń fà á, ó jọ pé mímu àwọn nǹkan tó ní èròjà kaféènì ló ń fa tàwọn kan. Wọ́n tún sọ pé mímu ọtí líle náà ń dá kún un nígbà míì.
Bruxism tún jẹ́ irú ìṣòro oorun mìíràn tó máa ń mú kéèyàn máa jeyín tàbí kó máa wayín pọ̀ tó bá ń sùn lóru. Tó bá ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo, ó lè mú kí eyín máa yìnrìn kó sì tún máa fa ìrora nínú erìgì, tí èyí kò sì ní jẹ́ kéèyàn lè sùn rárá. Ìtọ́jú rẹ̀ lè jẹ́ ṣíṣe iṣẹ́ abẹ ẹnu tàbí lílo ohun èlò kan láti fi dáàbò bo eyín ní alẹ́, èyí sinmi lórí bí ìṣòro náà bá ṣe le sí.
Ìwọ̀nba díẹ̀ tá a gbé yẹ̀ wò yìí lára ọ̀pọ̀ ìṣòro tó máa ń ṣèdíwọ́ fún oorun sísùn fi hàn pé ó léwu láti ṣàìkà wọ́n sí. Ìtọ́jú wọn lè rọrùn tàbí kó le gan-an, àmọ́ ó sábà máa ń ṣe pàtàkì pé kéèyàn gba ìtọ́jú. Bí ìwọ tàbí èèyàn rẹ kan bá ní ìṣòro àìróorunsùntó tó le gan-an tàbí tóò ń rí àwọn àmì èyíkéyìí tó fi hàn pé o ní ìṣòro oorun líle koko, á dára kó o tètè lọ rí dókítà fún ìtọ́jú. Kódà, bí ìtọ́jú ò bá tiẹ̀ mú àwọn ìṣòro náà kúrò pátápátá, ó lè dín àwọn ewu tó ṣeé ṣe kó jẹ yọ kù gan-an kó sì mú kó túbọ̀ rọrùn fún gbogbo àwọn tí ọ̀ràn kàn láti lè fara dà á. Lọ́jọ́ iwájú, nígbà táwọn ìlérí Bíbélì bá nímùúṣẹ, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” Gbogbo àìsàn pátá ni yóò di ohun àwátì nígbà tí Ọlọ́run bá sọ “ohun gbogbo di tuntun.”—Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:3-5.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kéèyàn máa han-anrun kó sì máa séèémí látìgbàdégbà yàtọ̀ sí bí ọ̀pọ̀ ṣe máa ń han-anrun lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ń sùn o, èyí tó jẹ́ pé ìṣòro ibẹ̀ kò ju pé àwọn tó wà nínú yàrá pẹ̀lú ẹni náà kò ní lè sùn.
b Fún àlàyé síwájú sí i lórí ìṣòro kí oorun máa ṣàdéédéé gbéni lọ, wo Jí! April 8, 1991, ojú ìwé 19 sí 21.
c Wo Jí! December 8, 2000, fún àlàyé síwájú sí i lórí ìṣòro yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìtọ́jú ìṣòro oorun gbọ́dọ̀ wáyé lábẹ́ àbójútó dókítà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Híhan-anrun lè jẹ́ àmì pé ẹnì kan ní ìṣòro síséèémí lójú oorun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ọ̀lẹ ni wọ́n sábà máa ń ka àwọn tó bá ní ìṣòro kí oorun máa ṣàdéédéé gbéni lọ sí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àwọn ohun èlò tó máa ń jẹ́ kí afẹ́fẹ́ ráyè kọjá dáadáa lọ́nà ọ̀fun lè dín ìṣòro síséèémí lójú oorun kù