ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 2/8 ojú ìwé 13
  • Ilẹ̀ Ayé Wa—Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Sí i Lọ́jọ́ Iwájú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ilẹ̀ Ayé Wa—Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Sí i Lọ́jọ́ Iwájú?
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Pílánẹ́ẹ̀tì Wa Ẹlẹgẹ́—Báwo Ni Ọjọ́ Ọ̀la Yóò Ṣe Rí?
    Jí!—1996
  • Ṣé Àwọn Èèyàn Ò Ní Ba Ayé Yìí Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ta Ló Máa Tún Ayé Yìí Ṣe?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Bíba Ilé Ayé Jẹ́ Máa Dópin!
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 2/8 ojú ìwé 13

Ilẹ̀ Ayé Wa—Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Sí i Lọ́jọ́ Iwájú?

Ìwé ìròyìn Globe and Mail ti ilẹ̀ Kánádà sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún làwọn èèyàn ti máa ń bẹ̀rù ‘àmúwá Ọlọ́run’ irú bí omíyalé àti ọ̀dá, ní báyìí o, ewu tí wọ́n dojú kọ tún wá burú jùyẹn lọ, òun ni ‘àfọwọ́fà’, ìyẹn ìjábá tọ́mọ aráyé ń fọwọ́ ara wọn fà.” Ètò Àbójútó Àyíká ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè (UNEP) tẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn kan jáde tó fi ń rọ àwọn èèyàn láti dáwọ́ àwọn nǹkan tó ń ba àyíká jẹ́ dúró kó tó pẹ́ jù. Klaus Toepfer tó jẹ́ olùdarí àgbà fún àjọ UNEP sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan la ti wá mọ̀ báyìí tó ń jẹ́ ká rí i bí àwọn ohun táà ń ṣe, àtàwọn ohun tá a kọ̀ láti ṣe, ṣe lè nípa lórí àyíká àtàwọn ohun tó ń gbé inú ilẹ̀ ayé wa ẹlẹ́wà yìí tó bá fi máa di ọdún 2032.”

Ìtẹ̀síwájú díẹ̀ ti wáyé nínú dídáàbò bo àyíká látìgbà tí wọ́n ti dá àjọ UNEP sílẹ̀ lọ́dún 1972. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Toronto Star ti sọ, “nílẹ̀ Yúróòpù àti Àríwá Amẹ́ríkà, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ba afẹ́fẹ́ jẹ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ ni omi odò sì ti dára sí i, àwọn ìkálọ́wọ́kò tí wọ́n sì gbé ka títú kẹ́míkà dà sínú afẹ́fẹ́ ti mú kó ṣeé ṣe fún òsóònù (afẹ́fẹ́ ààbò tó yí ilẹ̀ ayé wa ká) láti máa tún ara rẹ̀ ṣe.” Bákan náà, àwọn ètò tí wọ́n ṣe láti bójú tó igbó, bí irú àwọn tí wọ́n ń ṣe ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Kánádà, Finland àti Norway “ti ń rí sí i pé gígé tí wọ́n ń gé gẹdú ní àgéjù yóò di ohun tó dín kù.” Síbẹ̀, àjọ UNEP sọ pé, bí ètò ọrọ̀ ajé bá ń bá a lọ láti máa fẹjú sí i, táwọn ibi tó jẹ́ igbó tẹ́lẹ̀ sì ń di ìgboro, àkóbá kékeré kọ́ lèyí máa ṣe fáwọn ẹranko igbó àti onírúurú ohun alààyè. Ìwé ìròyìn Globe sọ pé: “Nǹkan bí ìlàjì àwọn odò tó wà láyé ló ti dìdàkudà tàbí lomi inú wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ tán. Ọgọ́rin orílẹ̀-èdè, tó jẹ́ pé àwọn ló kó ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo èèyàn tó ń gbé ayé, ni kò ní omi tó tó rárá.”

Toepfer gbà gbọ́ pé “gbígbé ìgbésẹ̀ akíkanjú ṣì lè tún nǹkan ṣe.” Ó fi kún un pé: “A gbọ́dọ̀ gbé ètò kan tó ṣe gúnmọ́ kalẹ̀ . . . ohun kan pàtó tá a fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí . . . àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, káwọn ìjọba kéde rẹ̀ fáwọn aráàlú.” Àmọ́, ìrètí wo la ní báwọn aṣáájú ayé ò bá ṣe tán láti ṣe ohun tó máa ṣe ilẹ̀ ayé láǹfààní?

Jẹ́ kó dá ọ lójú pé ẹnì kan wà tó ti ṣe ‘ìkéde,’ òun sì ni yóò gbé “ìgbésẹ̀ akíkanjú”—ìyẹn ni Jèhófà Ọlọ́run. Kódà, ó ti sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe kedere pé òun máa dá sí ọ̀ràn ilẹ̀ ayé, òun yóò sì “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Síwájú sí i, Ọlọ́run fi dá wa lójú pé ìbáṣepọ̀ àárín àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn yóò tún padà bọ̀ sípò. Àwọn aṣálẹ̀ yóò yọ ìtànná. (Aísáyà 35:1) Oúnjẹ yóò pọ̀ rẹpẹtẹ. Kò ní sí ẹ̀gbin nínú àwọn odò mọ́. (Sáàmù 72:16; 98:8) Ọlọ́run fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo ohun alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátá lòun yóò bù kún.—Sáàmù 96:11, 12.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]

Fọ́tò NASA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́