ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 2/8 ojú ìwé 19-23
  • Bí Àwọn Kan Ṣe Gbìyànjú Láti Tẹ Orúkọ Ọlọ́run Rì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Àwọn Kan Ṣe Gbìyànjú Láti Tẹ Orúkọ Ọlọ́run Rì
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òfin Kẹta
  • Ìgbìyànjú Síwájú Sí I Láti Fi Orúkọ Náà Pa Mọ́
  • Àṣà Tí Kò Bá Ìfẹ́ Ọlọ́run Mu
  • Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2017
  • Ó Ha Lòdì Láti Máa Pe Orúkọ Ọlọ́run Bí?
    Jí!—1999
  • Orukọ Ọlọrun ati Awọn Atumọ Bibeli
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run àti Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lò Ó
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 2/8 ojú ìwé 19-23

Bí Àwọn Kan Ṣe Gbìyànjú Láti Tẹ Orúkọ Ọlọ́run Rì

HANANIAH Ben Teradion lorúkọ rẹ̀. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Júù ni ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, a sì mọ̀ ọ́n bí ẹní mowó fún pípe ìpàdé ìta gbangba láti lè fi ìwé òfin Sefer Torah kọ́ni, ìyẹn ni àkájọ ìwé tó ní àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì nínú. Òdú tún ni Ben Teradion kì í ṣàìmọ̀ olóko bó bá di pé ká lo orúkọ Ọlọ́run ká sì tún fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Bá a bá sì tún rántí pé àpapọ̀ orúkọ Ọlọ́run tó wà nínú àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì lé ní ẹgbàá ó dín igba [1,800], ọgbọ́n wo ló fẹ́ dá sí i tí ò fi ní fi orúkọ Ọlọ́run gan-an kọ́ni níbi tó ti ń ṣàlàyé ìwé òfin Torah.

Àmọ́ ṣá o, àkókò eléwu ni ìgbà ayé Ben Teradion jẹ́ fáwọn Júù tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn Júù tó jẹ́ òpìtàn ti sọ, olú ọba Róòmù fòfin de ìsìn Júù àti fífi ẹ̀kọ́ ìsìn náà kọ́ni, ẹni tí wọ́n bá sì gbá mú pípa ni wọ́n á pa á. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn ará Róòmù fàṣẹ ọba mú Ben Teradion. Nígbà tí wọ́n mú un yìí, ẹ̀dà ìwé òfin Sefer Torah wà lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà tó ń dá àwọn olùfisùn rẹ̀ lóhùn, ó là á mọ́lẹ̀ fún wọn pé àṣẹ Ọlọ́run lòun ń ṣègbọràn sí bóun ti ń fi Bíbélì kọ́ni. Síbẹ̀, wọ́n dájọ́ ikú fún un.

Lọ́jọ́ tí wọ́n fẹ́ pa Ben Teradion, wọ́n wé àkájọ ìwé Bíbélì tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tí wọ́n mú un mọ́ ọn lára. Lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé e kọ́gi, wọ́n sì dáná sun ún. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica sọ pé “kó bàa lè joró dáadáa, wọ́n ti ìdìpọ̀ òwú bọnú omi wọ́n wá fi lé àyà rẹ̀ kó má bàa tètè kú.” Lára ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni pé wọ́n pa ìyàwó rẹ̀, wọ́n sì tún ta ọmọbìnrin rẹ̀ sílé aṣẹ́wó.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Róòmù ló ṣokùnfà pípa tí wọ́n pa Ben Teradion nípakúpa yìí, ìwé Talmuda sọ pé “wọ́n dáná sun ún nítorí pé ó pe Orúkọ Ọlọ́run ní àpèjá.” Dájúdájú, lójú àwọn Júù, ẹní to bá pe orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an ti forí jálé agbọ́n.

Òfin Kẹta

Ẹ̀rí fi hàn pé, ní ọ̀rúndún kìíní àti ìkejì Sànmánì Tiwa, ìgbàgbọ́ asán nípa lílo orúkọ Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí gbèrú láàárín àwọn Júù. Ìwé Mishnah (tó jẹ́ àkójọ àlàyé táwọn rábì ṣe, èyí tí wọ́n gbé ìwé Talmud kà) sọ pé “ẹni tó bá pe orúkọ Ọlọ́run ní àpèjá bí wọ́n ṣe ń kọ ọ́ sílẹ̀ gan-an” kò ní ní ìpín kankan nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òún ń mú bọ̀.

Níbo ni irú ìkálọ́wọ́kò bẹ́ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀? Àwọn kan sọ pé àwọn Júù ka orúkọ Ọlọ́run sí ohun tó jẹ́ mímọ́ ju ohun téèyàn aláìpé lè máa fẹnu pè lọ. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn èèyàn ń lọ́ tìkọ̀ láti máa kọ orúkọ náà sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ṣe sọ, ohun tó mú kí ẹ̀rù máa bà wọ́n ni pé wọ́n ronú pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ju ohun tí wọ́n kọ orúkọ náà sí sínú ìkólẹ̀sí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, tí ìyẹn á sì yọrí sí sísọ orúkọ Ọlọ́run di aláìmọ́.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica sọ pé “ohun tó fà á tí wọ́n fi yẹra fún pípe orúkọ náà YHWH . . . ni pé wọ́n ṣi Òfin Kẹta lóye.” Ìkẹta nínú Òfin Mẹ́wàá tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kà pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò ní láárí, nítorí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹni tí ó lo orúkọ rẹ̀ lọ́nà tí kò ní láárí.” (Ẹ́kísódù 20:7) Nítorí èyí, wọ́n gbé àṣẹ Ọlọ́run pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣi orúkọ òun lò gbòdì, wọ́n sì sọ lílo orúkọ náà di ohun èèwọ̀.

Dájúdájú, kò sẹ́ni tó ń sọ lọ́jọ́ tòní pé Ọlọ́run á fẹ́ kí wọ́n so ẹni tó bá pe orúkọ rẹ̀ mọ́gi, kí wọ́n sì sun ún níná! Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ asán táwọn Júù ní nípa orúkọ Ọlọ́run ò tíì kásẹ̀ nílẹ̀. Àwọn míì ṣì ń pe lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fórúkọ Ọlọ́run náà ní “Kò-ṣeé-pè.” Àwùjọ àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n máa ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣi orúkọ Ọlọ́run pè kí wọ́n má bàa ṣe ohun tó lòdì sí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, Káà ni wọ́n ń pe Jáà, tàbí Yáà, tó jẹ́ ìkékúrú orúkọ Ọlọ́run. Wọ́n ń pe Halelúyà ní Halelúkà. Àwọn kan ti ẹ̀ yẹra pátápátá fún kíkọ ọ̀rọ̀ náà, “Ọlọ́run” ní kíkún.

Ìgbìyànjú Síwájú Sí I Láti Fi Orúkọ Náà Pa Mọ́

Kì í ṣe ìsìn àwọn Júù nìkan ló yẹra fún lílo orúkọ Ọlọ́run o. Gbé ọ̀ràn Jerome yẹ̀ wò, ẹni tó jẹ́ àlùfáà Kátólíìkì àti akọ̀wé Póòpù Damasus Kìíní. Lọ́dún 405 Sànmánì Tiwa, Jerome parí iṣẹ́ tó ń ṣe lórí títúmọ̀ Bíbélì lódindi sí èdè Látìn, èyí tá a wá mọ̀ sí ìtumọ̀ Latin Vulgate. Jerome ò lo orúkọ Ọlọ́run nínú ìtumọ̀ rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, nípa títẹ̀lé àṣà tó wọ́pọ̀ nígbà tiẹ̀, ó fi àwọn ọ̀rọ̀ náà, “Olúwa” àti “Ọlọ́run” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run. Ìtumọ̀ Latin Vulgate wá di ìtumọ̀ Bíbélì Kátólíìkì àkọ́kọ́ tí wọ́n fàṣẹ sí, orí rẹ̀ ni wọ́n sì gbé ọ̀pọ̀ àwọn ìtumọ̀ tí wọ́n ṣe sí onírúurú èdè mìíràn kà.

Bí àpẹẹrẹ, ìtumọ̀ Bíbélì tí àwọn Kátólíìkì ṣe lọ́dún 1610, tí wọ́n ń pè ní Douay Version, wulẹ̀ jẹ́ ìtumọ̀ Latin Vulgate tí wọ́n tú sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Nígbà náà, kò yani lẹ́nu pé kò sí orúkọ Ọlọ́run nínú ìtumọ̀ Bíbélì yìí rárá. Àmọ́ o, ìtumọ̀ Douay Version kì í wulẹ̀ ṣe ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn kan lásán. Òun ló wá di Bíbélì kan ṣoṣo tí wọ́n fàṣẹ sí fáwọn onísìn Kátólíìkì tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì títí di àwọn ọdún 1940. Bẹ́ẹ̀ ni, fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni Bíbélì yìí ti gbórúkọ Ọlọ́run pa mọ́ fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn.

Tún gbé ìtumọ̀ Bíbélì King James Version yẹ̀ wò. Lọ́dún 1604, Ọba James Kìíní, ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, yanṣẹ́ fún àwùjọ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan pé kí wọ́n túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ní nǹkan bí ọdún méje lẹ́yìn náà, wọ́n mú ìtumọ̀ King James Version, tí wọ́n tún ń pè ní Authorized Version jáde.

Nínú ìtumọ̀ yìí pẹ̀lú, àwọn atúmọ̀ náà yẹra fún lílo orúkọ Ọlọ́run, àyàfi nínú ẹsẹ díẹ̀ péré ni wọ́n ti lò ó. Níbi tó pọ̀ jù lọ, ọ̀rọ̀ náà “OLÚWA” tàbí “ỌLỌ́RUN” ni wọ́n fi rọ́pò lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fórúkọ Ọlọ́run. Ìtumọ̀ Bíbélì yìí wá di èyí tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ń lò. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ World Book Encyclopedia sọ pé “kò tún sí ìtumọ̀ Bíbélì kankan tí wọ́n kà sí lédè Gẹ̀ẹ́sì, fún ohun tó ju igba ọdún lọ lẹ́yìn tí wọ́n tẹ ìtumọ̀ King James Version jáde. Lákòókò yìí, ìtumọ̀ King James Version làwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ń lò jù lọ.”

Àpẹẹrẹ mẹ́ta péré lèyí jẹ́ lára ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì tó yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò tàbí tí kò kà á kún lára àwọn tá a ti tẹ̀ jáde látọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn. Abájọ nígbà náà tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ lára àwọn tó sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni lónìí kì í fẹ́ láti lo orúkọ Ọlọ́run tàbí tí wọn ò tiẹ̀ mọ̀ ọ́n rárá. Òótọ́ ni pé látìgbà náà wá, àwọn atúmọ̀ Bíbélì kan ti lo orúkọ Ọlọ́run nínú ìtumọ̀ Bíbélì wọn. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìtumọ̀ wọ̀nyí ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń tẹ̀ jáde láwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ nípa lórí ojú táwọn èèyàn ní gbogbo gbòò fi ń wo orúkọ Ọlọ́run.

Àṣà Tí Kò Bá Ìfẹ́ Ọlọ́run Mu

Lórí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ẹ̀dá èèyàn ni wọ́n gbé àṣà káwọn èèyàn má máa lo orúkọ Ọlọ́run kà, èyí tó ti wá gbilẹ̀, kì í ṣe lórí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Júù kan tó jẹ́ olùṣèwádìí, Tracey R. Rich, tó tún jẹ́ olùdásílẹ̀ ibi ìkósọfúnni sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ń pè ní Judaism 101 ṣàlàyé pé: “Kò sí ohunkóhun nínú ìwé òfin Torah tó kà á léèwọ̀ fún ẹnikẹ́ni pé kó má ṣe pé Orúkọ Ọlọ́run. Kódà, ohun tá a rí nínú Ìwé Mímọ́ fi hàn pé àwọn èèyàn máa ń pe Orúkọ Ọlọ́run déédéé.” Bẹ́ẹ̀ ni o, láwọn àkókò tá a kọ Bíbélì, àwọn olùjọsìn Ọlọ́run lo orúkọ rẹ̀.

Dájúdájú, mímọ orúkọ Ọlọ́run ká sì máa lò ó túbọ̀ ń mú wa sún mọ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run fọwọ́ sí pé ká máa gbà jọ́sìn òun, bó ti rí láwọn àkókò tá a kọ Bíbélì. Èyí lè jẹ́ ìgbésẹ̀ tá a kọ́kọ́ máa gbé ká tó lè fìdí àjọṣe múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, èyí tó ṣe pàtàkì lọ́pọ̀lọpọ̀ ju wíwulẹ̀ mọ orúkọ rẹ̀. Jèhófà Ọlọ́run ń ké sí wa ní ti gidi pé ká ní irú àjọṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú òun. Òun ló mí sí ìkésíni ọlọ́yàyà náà pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Àmọ́, ‘Báwo lèèyàn tó jẹ́ ẹni kíkú ṣe lè gbádùn irú àjọṣe tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run Olódùmarè?’ Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí ṣàlàyé bó o ṣe lè ní irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé Talmud jẹ́ àkópọ̀ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù ìgbàanì, wọ́n sì kà á sí ọ̀kan lára àwọn ìwé mímọ́ jù lọ àtèyí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó sọ̀rọ̀ nípa ìsìn àwọn Júù.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]

Halelújà!

Kí ló máa ń wá sí ọ lọ́kàn bó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “Halelújà”? Bóyá ó máa ń mú kó o rántí orin tí akọrin kan tó ń jẹ́ Handel kọ tó pè ní “Mèsáyà.” Àgbà orin kan nínú èyí tí wọ́n ti fi Halelújà kọrin lọ́nà kíkàmàmà lèyí jẹ́ láwọn ọdún 1700. Dájúdájú, lọ́nà kan tàbí òmíràn, ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “Halelújà.” Bóyá o tiẹ̀ ń lò ó látìgbàdégbà. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o mọ ohun tó túmọ̀ sí?

Halelújà—Ọ̀nà tí èdè Gẹ̀ẹ́sì gbà ṣe ìyípadà lẹ́tà ọ̀rọ̀ Hébérù náà ha·lelu-Yahʹ, tó túmọ̀ sí “yin Jáà,” tàbí “ẹ yin Jáà.”

Jáà—Ìkékúrú orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, nínú ọ̀rọ̀ ewì. Ó fara hàn ju ìgbà àádọ́ta lọ nínú Bíbélì, èyí sì sábà máa ń jẹ́ gẹ́gẹ́ bí apá kan ọ̀rọ̀ náà, “Halelújà.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]

Ṣé Orúkọ Ọlọ́run Fara Hàn Nínú Orúkọ Rẹ?

Ọ̀pọ̀ orúkọ inú Bíbélì ṣì gbajúmọ̀ lóde òní. Ní ti díẹ̀ lára àwọn orúkọ wọ̀nyí, orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú ìtumọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ní lédè Hébérù. Àpẹẹrẹ díẹ̀ lára irú àwọn orúkọ bẹ́ẹ̀ àti ìtumọ̀ wọn nìyí. Bóyá orúkọ rẹ tiẹ̀ wà lára wọn.

Jòánà—“Jèhófà Ti Jẹ́ Olóore Ọ̀fẹ́”

Jóẹ́lì—“Jèhófà Ni Ọlọ́run”

Jòhánù—“Jèhófà Ti Fi Ojú Rere Hàn”

Jónátánì—“Jèhófà Ti Fifúnni”

Jósẹ́fù—“Ǹjẹ́ Kí Jáà Fi Kún”b

Jóṣúà—“Ti Jèhófà Ni Ìgbàlà”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b “Jáà” ni ìkékúrú orúkọ “Jèhófà.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwọn Ọ̀nà Mìíràn Tí Bíbélì Gbà Pe Ọlọ́run

Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àtàwọn àyọkà látinú wọn lo àwọn ọ̀rọ̀ bí Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá, Baba àti Olúwa fún Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn ibi tí Ìwé Mímọ́ ti pè é ni orúkọ tó ń jẹ́ gan-an pọ̀ ju gbogbo ibi tó ti lo ọ̀rọ̀ mìíràn fún un lọ. Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run fẹ́ ká lo orúkọ òun. Ìwọ ṣáà wo àwọn orúkọ tó wà nísàlẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.c

Jèhófà—ìgbà 6,973

Ọlọ́run—ìgbà 2,605

Olódùmarè—ìgbà 48

Olúwa—ìgbà 40

Olùṣẹ̀dá—ìgbà 25

Ẹlẹ́dàá—ìgbà 7

Baba—ìgbà 7

Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé—ìgbà 3

Olùkọ́ni Atóbilọ́lá—ìgbà 2

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

c Ìye ìgbà tá a fojú díwọ̀n pé wọ́n fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

Ọlọ́run Tó Ń Mú Kí Ohun Gbogbo Ṣeé Ṣe

Ẹnu àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ò kò nípa ohun tí orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, túmọ̀ sí. Àmọ́ ṣá o, lẹ́yìn ìwádìí tó pọ̀ lórí kókó ọ̀rọ̀ náà, ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé orúkọ náà jẹ́ ẹ̀yà ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù náà ha·wahʹ (di), tó túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.”

Nítorí náà, nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun,d ohun tá a túmọ̀ àkọsílẹ̀ inú Ẹ́kísódù 3:14, níbi tí Mósè ti béèrè orúkọ Ọlọ́run sí rèé: “Látàrí èyí, Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: ‘èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́.’ Ó sì fi kún un pé: ‘Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, “èmi yóò jẹ́ ti rán mi sí yín.”’”

Ìtumọ̀ yẹn ṣe wẹ́kú nítorí pé Ọlọ́run ní agbára láti sọ ara rẹ̀ di ohunkóhun tó bá pọn dandan fún un láti jẹ́. Kò sí ohun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó bá fẹ́ ṣe. Kò tíì sígbà kan rí tí ète rẹ̀ àtàwọn ìlérí rẹ̀ kò ní ìmúṣẹ. Lọ́nà títayọ, Ọlọ́run yìí náà tún ni Ẹlẹ́dàá, ẹni tó lágbára tí kò láàlà láti mú kí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀. Òun ló dá ayé òun ọ̀run. Ó sì tún ṣẹ̀dá ẹgbàágbèje ẹ̀dá ẹ̀mí. Ní tòótọ́, òun ni Ọlọ́run tó ń mú kí ohun gbogbo ṣeé ṣe!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

d Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ère gbígbẹ́ tó fi bí wọ́n ṣe pa Hananiah ben Teradion hàn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]

Àwọn Ibi Tí Orúkọ Ọlọ́run Ti Fara Hàn Gbangba Gbàǹgbà

1. Ṣọ́ọ̀ṣì kan nílùú Lomborg lórílẹ̀-èdè Denmark, ọ̀rúndún kẹtàdínlógún

2. Fèrèsé onígíláàsì tó ní iṣẹ́ ọnà lára, nílé ìjọsìn ńlá tó wà nílùú Bern, lórílẹ̀-èdè Switzerland

3. Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ti Sáàmù, tó wà lára àwọn àkọsílẹ̀ Hébérù ìgbà ìjímìjí, lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, nǹkan bí ọdún 30 sí 50 Sànmánì Tiwa

[Credit Line]

Shrine of the Book, Israel Museum, Jerusalem

4. Owó wẹ́wẹ́ orílẹ̀-èdè Sweden, ọdún 1600

[Credit Line]

Kungl. Myntkabinettet, Sveriges Ekonomiska Museum

5. Ìwé àdúrà lédè Jámánì, ọdún 1770

[Credit Line]

Látinú ìwé Die Lust der Heiligen an Jehova. Oder: Gebaet-Buch, 1770

6. Ìkọ̀wé ara òkúta, ìpínlẹ̀ Bavaria, lórílẹ̀-èdè Jámánì

7. Òkúta Móábù, ìlú Paris, lórílẹ̀-èdè France, ọdún 830 Ṣáájú Sànmánì Tiwa

[Credit Line]

Musée du Louvre, Paris

8. Àwòrán ṣọ́ọ̀ṣì olórùlé rìbìtì, ìlú Olten, lórílẹ̀-èdè Switzerland

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́