ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 2/8 ojú ìwé 31
  • Orúkọ Ọlọ́run Lára Àwọn Ilé Àtayébáyé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Orúkọ Ọlọ́run Lára Àwọn Ilé Àtayébáyé
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Fi Orúkọ Ọlọ́run Ṣe Àwọn Ilé Lọ́ṣọ̀ọ́ ní Czech
    Jí!—1998
  • Ọlọ́run Ní Orúkọ Kan!
    Jí!—2004
  • A4 Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jí!—2004
g04 2/8 ojú ìwé 31

Orúkọ Ọlọ́run Lára Àwọn Ilé Àtayébáyé

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ SLOVENIA

Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti ń kọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àti ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé sí téńté orí àwọn òkè jákèjádò ilẹ̀ Yúróòpù. Wọ́n kọ́ àwọn kan lára àwọn ilé àtayébáyé wọ̀nyí lọ́nà táwọn ará Róòmù ń gbà kọ́lé ní Sànmánì Ìgbà Ọ̀làjú. Irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ sábà máa ń ní ògiri tó nípọn àtàwọn ẹnu ọ̀nà tí òkè wọn tẹ̀ kọrọdọ tó sì ṣe rìbìtì. Ó sì tún lè jẹ́ èyí tí wọ́n kọ́ lọ́nà kíkàmàmà nípa lílo àwọn ọwọ̀n tí wọ́n gbẹ́ àwòrán sí lára tí wọ́n sì ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ jìngbìnnì bíi tàwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé Sànmánì Ìgbà Ọ̀làjú. Ó dùn mọ́ni pé a lè rí lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀ lára àwọn ilé wọ̀nyí.

Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ti Stična, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé Cistercian tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ, tó wà lórílẹ̀-èdè Slovenia. Ọdún 1135 ni wọ́n kọ́ ọ, ní nǹkan bí ogójì ọdún lẹ́yìn tí wọ́n dá ètò àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ti Cistercian sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Faransé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ṣàtúnṣe sí ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé yìí lọ́pọ̀ ìgbà, bí wọ́n ṣe kọ́ ọ bíi tàwọn ará Róòmù yẹn náà ló ṣì wà àmọ́, wọ́n ti wá kó ọ̀ṣọ́ bò ó jìngbìnnì báyìí. Wọ́n fi onírúurú àwòrán àtàwọn ère gbígbẹ́ ṣe inú rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n fi àwọn lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run, tí wọ́n fi omi wúrà kọ gàdàgbà, tí wọ́n sì fi irin fàdákà gbá lẹ́gbẹ̀ẹ́ yíká, ṣe pẹpẹ kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú ilé náà lọ́ṣọ̀ọ́.

Nínú àwọn àkọsílẹ̀ kan tó ti wà láti ọ̀rúndún kẹwàá ni wọ́n ti kọ́kọ́ mẹ́nu kan ìlú Slovenj Gradec. Wọ́n kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kan tó ní ilé ìwòsàn síbẹ̀ lọ́dún 1419, èyí tó ní ọwọ̀n ńlá àti ẹnu ọ̀nà títẹ̀ kọrọdọ. Ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà yàwòrán sára amọ̀ tútù ní ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n lò láti fi yàwòrán àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n látinú Bíbélì sára abala ògiri kan nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà. Ó bẹ̀rẹ̀ látorí àjíǹde Lásárù títí dé ìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì. Lápá ibòmíràn nínú ilé kan náà yìí, wọ́n fi lẹ́tà ìkọ̀wé dúdú kọ orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù sára ibi tí omi góòlù wà.

Ní àgbègbè ìhà àríwá orílẹ̀-èdè náà ni ìlú Radovljica wà. Láwọn ọdún 1400, àwọn ògiri àti kòtò ńlá ló yí ibùdó kékeré náà ká; ilé olódi kan, ṣọ́ọ̀ṣì àti onírúurú àwọn ilé mìíràn sì tún wà níbẹ̀. Lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run wà lára àmì olómi góòlù tó wà lára ọ̀kan nínú àwọn pẹpẹ inú ṣọ́ọ̀ṣì náà.

Ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé àtayébáyé kan wà nítòsí abúlé kékeré kan tó ń jẹ́ Podčetrtek. Wọ́n ti kọ́ ọ síbẹ̀ láti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún. Ẹni tó bá fara balẹ̀ wo inú ilé náà á rí àwòrán kan tí wọ́n fi orúkọ Ọlọ́run ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.

Lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run yìí tún wà lára ọ̀pọ̀ àwọn ilé àtayébáyé mìíràn lórílẹ̀-èdè Slovenia. Nítorí èyí, bí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ṣe ń fójú lóúnjẹ nípa wíwo iṣẹ́ ọnà àtàwòrán ìgbà àtijọ́, wọ́n tún lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ pé orúkọ Ọlọ́run kò ṣàjèjì sáwọn èèyàn ayé ọjọ́un.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Pẹpẹ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ti Stična

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ní ṣọ́ọ̀ṣì Sveti Duh tó wà ní Slovenj Gradec

[Credit Line]

Slovenj Gradec - Cerkev Sv. Duha, Slovenija

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́