“Àdúrà Mi Gbà”
Ohun tí obìnrin kan tó ní ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́sàn-án kan sọ nìyẹn nígbà tí wọ́n mú ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà jáde ní àpéjọ àgbègbè kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní Ireland. Ó sọ tìyanu tìyanu pé: “Omijé sì bẹ̀rẹ̀ sí dà lójú mi! Ìbùkún tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gbáà ló jẹ́ nítorí pé lọ́sẹ̀ to kọjá yìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn nítorí pé mi ò mọ ìwé tó yẹ kí n fi máa kọ́ ọmọ mi lẹ́kọ̀ọ́.”
Obìnrin yìí ṣàlàyé pé: “Mo ti gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ láti mọ bí mo ṣe máa kọ́ ọmọ mi láwọn òtítọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ lọ́nà tó máa rọrùn tá á sì fà á lọ́kàn mọ́ra ṣùgbọ́n mi ò mọ ibi tí mà á ti bẹ̀rẹ̀. Àmọ́, àdúrà mi gbà nígbà tí ọwọ́ mi tẹ ìwé tó ní àwọn àwòrán rírẹwà yìí.”
Ìyá ọlọ́mọ márùn-ún kan ní ìpínlẹ̀ California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà náà kọ̀wé tó jọ bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́. Ó ní: “Nígbà tá à ń padà sí ilé ìtura tá a dé sí láti àpéjọ náà, mo rí i pé àwọn ọmọ mi mẹ́ta tó kéré jù ti ń ka ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, wọ́n ń wo àwòrán inú ẹ̀, wọ́n sì ń jíròrò àwọn ohun tó wọ̀ wọ́n lọ́kàn lára àwọn ohun tó wà níbẹ̀.”
Ó sọ pé: “Bí mo ṣe láyọ̀ tó nígbà tí mo gba ìwé yìí, tó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà, kọjá sísọ, àfi bí ìgbà téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó tàbí ìrìbọmi tàbí ìgbà táǹfààní kan látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá àgbáyé bá ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ èèyàn lọ́wọ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń wò ó pé omijé ayọ̀ tó ń jáde lojú wa ń sọ ohun tá ò lè fẹnu sọ fún Jèhófà, Bàbá wa onífẹ̀ẹ́.”
Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà nírú èrò yẹn lẹ́yìn tó o bá ti ṣàyẹ̀wò ìwé rèǹtè rente, olójú ewé 256, aláwòrán rírẹwà, tó fẹ̀ tó ìwé ìròyìn yìí. O lè rí ẹ̀dà kan gbà nípa kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́ mo fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.