“Rántí Ẹlẹ́dàá Rẹ”
“Máa rántí Ẹlẹ́dàá rẹ nígbà tó o ṣì wà ní ọ̀dọ́! Bó bá di ẹ̀yìnwá ọ̀la, àwọn ìṣòro á wọ̀ ọ́ lọ́rùn wà á sì sọ pé, ‘Mi ò gbádùn ìgbésí ayé mọ́.’”—Oníwàásù 12:1, “Contemporary English Version.”
Ọ̀RỌ̀ tó gbàrònú jinlẹ̀ gan-an ni ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí lókè yìí. Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré ni wàá jẹ́ ọ̀dọ́ mọ. Bó bá wá dẹ̀yìn ọ̀la, wà á máa rántí àwọn ọdún ìbàlágà rẹ sí rere tàbí sí búburú. Èwo lo fẹ́ kó jẹ́ tìẹ ńbẹ̀? Báwo lo ṣe lè mú kó jẹ́ èyí tí wàá máa rántí sí rere?
Bíbélì gbà ọ́ níyànjú nínú ẹsẹ Bíbélì tá a fà yọ lókè yìí pé kó o “rántí Ẹlẹ́dàá rẹ.” Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Nípa pípa àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ ni. Rárá o, èyí ò túmọ̀ sí pé wà á sọ ara ẹ di alákatakítí, kó o sì wá fi gbogbo ìgbádùn du ara ẹ. Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá, rírántí Ẹlẹ́dàá rẹ á mú kó o láyọ̀ gan-an. Báwo ni ìyẹn ṣe lè jẹ́ bẹ́ẹ̀?
Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé ẹnì kan fún ọ ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan àti ìwé àṣẹ ìwakọ̀. O ti dòmìnira nìyẹn láti wakọ̀ ní fàlàlà, ìyẹn sì lè mú kó o láyọ̀ gan-an ni. Ṣáà ronú nípa onírúurú ibi tó o lè wakọ̀ lọ! Àmọ́ ṣá o, òmìnira tó tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ yìí ò ṣaláìní ẹrù iṣẹ́ tó gbàrònú jinlẹ̀. Nígbà tó o bá ń wakọ̀, o gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí àwọn òfin ìrìnnà, àwọn àmì ojú ọ̀nà, àmì tó ń sọ bó o ṣe gbọ́dọ̀ sáré sí àti àwọn àmì ìkìlọ̀ mìíràn. Ǹjẹ́ ẹrù iṣẹ́ tó o ní láti pòfin mọ́ yìí á ṣèpalára fún ayọ̀ tó yẹ kó o ní bó o ṣe ń wakọ̀? Àgbẹdọ̀! Kódà, ńṣe lá á máa dáàbò bò ẹ́. Jàǹbá mọ́tò kì í ṣohun ayọ̀ kẹ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Bákan náà ló rí pẹ̀lú òmìnira tí Ẹlẹ́dàá rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, fún ọ. Bó o bá ti kúrò lọ́mọdé, á jẹ́ kó o yan ọ̀nà tó o máa gbà gbé ìgbésí ayé rẹ. (Diutarónómì 30:19; Òwe 27:11) Àǹfààní ńláǹlà mà nìyẹn o! Ṣùgbọ́n òmìnira yẹn gbé ẹrù iṣẹ́ bàǹtàbanta kà ọ́ lórí. Jèhófà ti la àwọn ‘òfin ìrìnnà,’ ìyẹn àwọn ìlànà tó fẹ́ kó máa darí ìgbésí ayé rẹ, lẹ́sẹẹsẹ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣé àwọn ìlànà yìí ń ba ayọ̀ rẹ jẹ́ ni? Ó tì o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n á dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ àìbalẹ̀ àyà àti ìrora tó ń bá ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fínra lónìí.
Federico, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ọgbọ̀n ọdún, mọ̀ pé kò sírọ́ ńbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin, ó rí i báwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nílé ìwé ṣe ń lọ́wọ́ nínú onírúurú ìgbòkègbodò tí ò yẹ kó bá wọn lọ́wọ́ sí. Ó sọ pé: “Ńṣe ló dà bí ẹni pé wọ́n ń gbádùn ara wọn, ṣùgbọ́n mi ò rò pé wọ́n ní ojúlówó ayọ̀.” Bí Federico bá wá bojú wẹ̀yìn, ńṣe ni inú rẹ̀ máa ń dùn pé ó ní àwọn ìlànà Bíbélì tó ṣe atọ́nà rẹ̀ nígbà ìbàlágà. Ó sọ pé: “Lóòótọ́, àwọn ìṣòro kan bá mi fínra bíi tàwọn ọ̀dọ́ yòókù o. Ṣùgbọ́n, Bíbélì dáàbò bò mí gan-an ni. Ẹnì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni sì sábà máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ràn mí lọ́wọ́. Títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì ti mú kí n láyọ̀ tó pọ̀ ju bí mo ti lè rò lọ!”
Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kó o ní ojúlówó ayọ̀ tí kò lábùlà. Ìyẹn kúrò ní ayọ̀ oréfèé tàbí ayọ̀ ṣákálá kan ṣáá tó gbé ìbànújẹ́ pa mọ́. Bíbélì sọ pé: “Gbádùn ìgbà èwe rẹ. Máa yọ̀ nígbà tó o ṣì wà léwe.” Ṣùgbọ́n ẹsẹ Bíbélì kan náà yìí wá fi ìkìlọ̀ kan kún-un. Ó sọ pé: “Rántí pé Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́ nítorí ohunkóhun tó o bá ṣe.”—Oníwàásù 11:9, Today’s English Version.
Máa rántí Ẹlẹ́dàá rẹ nípa fífọgbọ́n lo òmìnira tó fún ọ. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o lè ní ìdánilójú pé Ẹlẹ́dàá rẹ á máa rántí rẹ yóò sì mú kó o ní ayọ̀ débi tó yẹ kéèyàn ní in dé. Bíbélì sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”—Òwe 10:22.
Nítorí àtiran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti kojú àdánwò ìgbà ìbàlágà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi tẹ ìwé olójú ewé 320 náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, jáde. Títí di bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ti tẹ ẹ̀dà bíi mílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n jáde ní èdè mẹ́tàdínlọ́gọ́rin. O lè rí ẹ̀dà kan gbà nípa kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Kó O Bàa Lè Kẹ́sẹ Járí Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀dọ́langba
Máa wá àkókò láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́
Má ṣe kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́
Máa fọ̀rọ̀ wérọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ
[Credit Line]
Àwòrán ẹ̀yìn ìwé pẹlẹbẹ: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.