Wọ́n Lè Tu Àwọn Tí Ọ̀fọ̀ Ṣẹ̀ Nínú
Obìnrin kan láti ìpínlẹ̀ Jalisco, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Mẹ́síkò. Ó béèrè pé: “Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú ṣọwọ́ sí mi. N kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà o, àmọ́ mo fara mọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan tẹ́ ẹ gbà gbọ́.”
Obìnrin tó kọ lẹ́tà náà ṣàlàyé ohun tó mú kó sọ pé òun fẹ́ àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, ó sọ pé: “Mò ń fẹ́ àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà nítorí mo rò pé wọ́n á wúlò fún àwọn kan tí wọ́n wá ń ra òdòdó ní ṣọ́ọ̀bù wa, ìyẹn àwọn tó máa ń bá wa ra òdòdó ẹ̀yẹ tí wọ́n máa ń gbé sórí sàréè. Nígbà míì, wọ́n lè jẹ́ ìyàwó, àwọn ọmọ, tàbí ọkọ ẹni tó kú náà. Mo lérò pé àwọn ìwé pẹlẹbẹ wọ̀nyẹn á ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an ni.”
Ìwọ tàbí ẹnì kan tó o mọ̀ sì lè rí ìtùnú nípa kíka ìwé pẹlẹbẹ olójú-ewé 32 yìí o. Ó dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Báwo ni mo ṣe lè gbé pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn mi? Báwo ni àwọn ẹlòmíràn ṣe lè ṣèrànwọ́? Kí ni ìrètí táwọn òkú ní?
Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé yìí, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́ mo fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.