ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/07 ojú ìwé 3-4
  • Bí Ìwàkiwà Ṣe Gbayé Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ìwàkiwà Ṣe Gbayé Kan
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibi Tí Ìwà Rere Jó Rẹ̀yìn Dé Kárí Ayé
  • Kí Ló Burú Nínú Jíjíwèé Wò?
    Jí!—2003
  • Kí Ní Ń Nípa Lórí Ìṣarasíhùwà Rẹ?
    Jí!—1997
  • Àwọn Ohun Arùfé-Ìṣekúṣe-Sókè—Ṣé Nǹkan Ṣeréṣeré Lásán ni Wọ́n?
    Jí!—2002
  • Ìpalára Tí Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Ń Ṣe
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 4/07 ojú ìwé 3-4

Bí Ìwàkiwà Ṣe Gbayé Kan

Ọ̀GBẸ́NI David Callahan tó kọ̀wé The Cheating Culture, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí, sọ pé: “Ibi gbogbo ni wọ́n ti ń rẹ́ni jẹ.” Lára irú ìrẹ́nijẹ tó mẹ́nu kàn pé ó ń wáyé ní Amẹ́ríkà ni “káwọn ọmọ ilé ìwé girama àtàwọn míì tó wà ní kọ́lẹ́ẹ̀jì máa jíwèé wò,” káwọn èèyàn máa “ṣe ẹ̀dà” orin àti eré sinimá “láìgbàṣẹ,” “jíjalè lẹ́nu iṣẹ́,” “fífi èrú wá owó nídìí ọ̀ràn ìlera” àti lílo àwọn oògùn tó ń mú kí iṣan le bí wọ́n bá fẹ́ ṣeré ìdárayá. Ibi tó wá parí ọ̀rọ̀ náà sí ni pé: “Béèyàn bá wá pa gbogbo onírúurú ìwà táwọn èèyàn ń hù pọ̀, èyí tí kò bójú mu àtèyí tí kò bófin mu, èèyàn á rí i pé ìwàkiwà táwọn èèyàn ń hù ti wá lékenkà.”

Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé nígbà tí ìjì líle tí wọ́n pè ní Hurricane Katrina jà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lóṣù kẹjọ ọdún 2005, “àwọn èèyàn hùwà jìbìtì, wọ́n ṣèrú, ìjọba náà sì ṣowó ìlú báṣubàṣu lọ́nà tó tíì pabanbarì jù lọ lóde ìwòyí.” Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tiẹ̀ ròyìn pé: “Béèyàn bá wo ibi tí wọ́n fi ọ̀dájú ṣèrú dé, ibi tí wọ́n fi ògbójú ṣowó ìlú báṣubàṣu dé àti bí wọ́n ṣe ná iná àpà tó, èèyàn á lanu, itọ́ á sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máa já bọ́.”

Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ṣì wà tó fi hàn pé àwọn èèyàn ń fi àìmọtara-ẹni-nìkan hùwà rere sáwọn ẹlòmíì. (Ìṣe 27:3; 28:2) Àmọ́, ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ni pé: “Oore kí nìyẹn fẹ́ ṣe fún mi? Kí ni màá rí gbà ńbẹ̀?” Ó dà bíi pé ohun tó gbayé kan báyìí ni pé káwọn èèyàn ṣáà kọ́kọ́ máa gbọ́ tara wọn.

Látijọ́, ọ̀kan lára ohun tí wọ́n sọ pó fà á tí ọ̀làjú ò fi ran àwọn orílẹ̀-èdè bí Ilẹ̀ Ọba Róòmù lọ́wọ́ ni ìwà ìṣekúṣe tó bògìrì, tó sì kún fún ìmọtara-ẹni-nìkan. Àbí, ó wa lè jẹ́ pé pẹ̀lú àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí késekése la wulẹ̀ ń rí kó jẹ́ pé kàsàkàsà ṣì ń bọ̀ lọ́nà? Ó wa lè jẹ́ pé “pípọ̀ sí i ìwà àìlófin,” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pó máa sàmì sí ìparí gbogbo ètò nǹkan ìsinsìnyí ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ jákèjádò ayé náà nìyẹn?—Mátíù 24:3-8, 12-14; 2 Tímótì 3:1-5.

Ibi Tí Ìwà Rere Jó Rẹ̀yìn Dé Kárí Ayé

Nígbà tí ìwé ìròyìn Africa News ti June 22, 2006, ń ṣàlàyé nípa “àpérò kan tó dá lórí ìṣekúṣe àti wíwo àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe,” èyí tó máa ń wáyé láwọn ilé jẹ́gẹjẹ̀gẹ tí wọ́n kọ́ sapá ibì kan báyìí lórílẹ̀-èdè Uganda, ó sọ pé “pípa táwọn òbí pa àwọn ọmọ wọn tì ló mú kí iṣẹ́ aṣẹ́wó àti lílo oògùn olóró pọ̀ sí i ládùúgbò náà.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ọlọ́pàá tó wà nídìí àbójútó àwọn ọmọ àti ìdílé, ìyẹn Child and Family Protection Unit, ní Àgọ́ Ọlọ́pàá tó wà nílùú Kawempe, Ọ̀gbẹ́ni Dhabangi Salongo, sọ pé iye àwọn ọmọdé tí wọ́n ń bá ṣèṣekúṣe àti ìjà tó ń wáyé lábẹ́ ọ̀ọ̀dẹ̀ ti pọ̀ sí i gan-an.”

Ṣe ló dà bí ọ̀rọ̀ tí dókítà kan lórílẹ̀-èdè Íńdíà sọ pé “àṣà àjogúnbá tó ń fìwà rere kọ́ni ti ń kásẹ̀ nílẹ̀ láwùjọ.” Obìnrin kan tó jẹ́ olùdarí fíìmù lórílẹ̀-èdè náà sọ pé “àmì míì tó tún fi hàn pé orílẹ̀-èdè Íńdíà ti ń rì wọnú ìwà ìṣekúṣe irú èyí tó wọ́pọ̀ nílẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ni bí pípa tí wọ́n ń pa lílo oògùn olóró pọ̀ mọ́ ìṣekúṣe ṣe ń pọ̀ sí i.”

Hu Peicheng, akọ̀wé àgbà fún àjọ kan tó ń rí sí ọ̀rọ̀ lákọlábo, tí wọ́n ń pè ní China Sexology Association nílùú Beijing sọ pé: “Tẹ́lẹ̀ láwùjọ, a mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó dára àti ohun tó burú. Ní báyìí, ohun tó wù wá là ń ṣe.” Ohun tí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn China Today sọ nípa ọ̀rọ̀ náà nìyí: “Àwọn èèyàn tó wà láwùjọ ò tiẹ̀ wá fi bẹ́ẹ̀ fojú tí kò dáa wo kẹ́ni tó bá ti ṣègbéyàwó máa lójú síta mọ́.”

Ìwé ìròyìn kan nílẹ̀ England, ìyẹn Yorkshire Post, tiẹ̀ sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé: “Ó dà bíi pé ṣe ni olúkúlùkù ń bọ́ṣọ kúrò lára tí wọ́n sì ń fi ìbálòpọ̀ polówó ọjà. Bó bá jẹ́ pé ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn ni, gbogbo èèyàn pátá ló máa kẹ̀yìn sírú àṣà bẹ́ẹ̀. Lóde tòní, ibi yòówù kéèyàn yíjú sí, ṣe ni òpòòrò àwòrán nípa ìbálòpọ̀ ń rọ́ wá ní ọlọ́kan-ò-jọ̀kan, a ò sì ríbi yẹ ọ̀rọ̀ àwòrán oníhòòhò sí nítorí pé . . . ó ti dohun táwọn èèyàn ń fẹ́ láwùjọ.” Ìwé ìròyìn náà tún fi kún un pé: “Ìwé tàbí eré tó wà fún kìkì àwọn ọmọ tọ́jọ́ orí wọn bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ ọdún méjìdínlógún tẹ́lẹ̀ ti dèyí tí gbogbo ìdílé ń kà tàbí tí wọ́n ń wò báyìí. Àti pé gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń gbógun ti wíwo àwòràn oníhòòhò ṣe sọ, torí àwọn ọmọdé ni wọ́n ṣe máa ń gbé irú àwọn àwòrán bẹ́ẹ̀ jáde.”

Ìwé ìròyìn The New York Times Magazine sọ pé: “[Àwọn kan tí wọn ò tíì pé ọmọ ogún ọdún] máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ nípa [bí wọ́n ṣe ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì], láì fìkan pe méjì bí ìgbà téèyàn ń sọ̀rọ̀ irú oúnjẹ tó maá jẹ lọ́sàn-án.” Ìwé ìròyìn Tweens News, “tó máa ń tọ́ àwọn òbí tí àwọn ọmọ wọn wà láàárín ọdún mẹ́jọ sí méjìlá sọ́nà” sọ nípa “ọ̀dọ́mọbìnrin kékeré kan tó fi lẹ́tà wọ́gọwọ̀gọ kọ ọ̀rọ̀ tí ń bani lọ́kàn jẹ́ yìí pé: ‘Màmá mi ń yọ mi lẹ́nu pé kí n máa lọ bá àwọn ọmọdékùnrin jáde kí n sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn. Mi ò ju ọmọ ọdún méjìlá lọ, . . . ẹ gbà mí o!’”

Ìgbà mà ti yí padà o! Ìwé ìròyìn Toronto Star ti orílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé lẹ́nu bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, “báwọn èèyàn bá gbọ́ pé ọkùnrin ń bá ọkùnrin lò pọ̀, obìnrin sì ń bá obìnrin lò pọ̀ ní gbangba, ohun ẹ̀gbin gbáà ni wọ́n máa kà á sí.” Àmọ́, Barbara Freemen, tó jẹ́ olùkọ́ni ní ìtàn nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí láwùjọ nílé ẹ̀kọ́ gíga Carleton University, nílùú Ottawa, ṣàkíyèsí pé: “Ohun táwọn èèyàn ń sọ báyìí ni pé, ‘Ohun tó bá wù àwọn làwọn lè ṣe nínú kọ́lọ́fín yàrá àwọn. Wọ́n láwọn ò fẹ́ káwọn ẹlòmíì máa yọjúràn.’”

Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé láti nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, ìwà rere ti yára jó rẹ̀yìn lọ́pọ̀ ibi jákèjádò ayé. Kí ló fà á tí ìfàsẹ́yìn fi yára bá ìwà rere lọ́nà yìí? Báwo sì lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ? Ibò sì làwọn ìyípadà náà ń dorí ayé kọ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́