ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 6/8 ojú ìwé 4-7
  • Kí Ní Ń Nípa Lórí Ìṣarasíhùwà Rẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ní Ń Nípa Lórí Ìṣarasíhùwà Rẹ?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Arùfẹ́ Ìṣekúṣe Sókè Ń Fi Ìbálòpọ̀ Hàn Lọ́nà Òdì
  • Àwọn Ohun Ìnàjú Ń Lo Ìbálòpọ̀
  • Ipa Iṣẹ́ Tí Ń Yí Pa Dà Yí Ìṣarasíhùwà Sódì
  • Ẹ̀kọ́ Nípa Ìbálòpọ̀ Nílé Ẹ̀kọ́
  • Kí Ni Ìfẹ́, Kí sì Ni Ìfarajìn?
  • Ìṣarasíhùwà Tí Ń yí Pa Dà Ń Ṣokùnfà Àwọn Ìbéèrè Tuntun
    Jí!—1997
  • Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó
    Jí!—2013
  • Kíkojú Ìpèníjà Náà
    Jí!—1997
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìbálòpọ̀?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 6/8 ojú ìwé 4-7

Kí Ní Ń Nípa Lórí Ìṣarasíhùwà Rẹ?

NÍ NǸKAN bí 2,700 ọdún sẹ́yìn ni òǹkọ̀wé onímìísí kan ṣàkọsílẹ̀ òwe amúnironú náà pé: “Sí arìndìn, bíbá a lọ ní híhu ìwà àìníjàánu dà bí ìdárayá.” (Òwe 10:23, NW) Òtítọ́ inú ọ̀rọ̀ yí ti ṣe kedere ní pàtàkì láti ìgbà ìyípadà nínú àṣà ìbálòpọ̀. Kí ìpayà àrùn AIDS tó dé, ìṣarasíhùwà tó gbòde ni pé ìbálòpọ̀ jẹ́ ‘ìdárayá fún ẹni tí ń ṣe é,’ a sì gbọ́dọ̀ tẹ́ ìfẹ́ ọkàn fún ìbálòpọ̀ lọ́rùn ‘láìka ohun yòó wù tí ó lè jẹ́ àbájáde rẹ̀ sí.’ Ìṣarasíhùwà yí ha ti yí pa dà bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ ní gidi.

Ìfarajin-ìbálòpọ̀ ní òde òní ṣì ń mú “ìfàmọ́ra onífàájì àṣejù,” ‘àwọn akóbìnrinjọ àti akọ́kọjọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́,’ àti “àwọn afiniṣèjẹ ìbálòpọ̀,” tí ń jiyàn pé ọ̀ràn ara ẹni ni ìwà rere, àti pé ìbálòpọ̀ fàlàlà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ alájọṣe bójú mu, jáde. (Wo àpótí náà, “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Ní Ti Ìbálòpọ̀,” ní ojú ìwé 6.) Wọ́n sọ pé, bíbá ẹnikẹ́ni tó bá wuni lò pọ̀ ‘kò pa ẹnikẹ́ni lára’ níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ láàárín àwọn àgbàlagbà tí wọ́n fohùn ṣọ̀kan. Ní 1964, Ira Reiss, onímọ̀ ìbágbépọ̀-ẹ̀dá ní Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Iowa, pe èyí ní “ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ onífẹ̀ẹ́ni.”

Ó jọ pé, bíṣọ́ọ̀bù ìjọ Áńgílíkà ti Edinburgh, Scotland, lérò kan náà, nítorí tí ó wí pé a dá ẹ̀dá ènìyàn láti máa ní ọ̀pọ̀ olùfẹ́. Nínú ọ̀rọ̀ kan tí ó sọ lórí ìbálòpọ̀ àti ìsìn Kristẹni, ó sọ pé: “Nígbà tí Ọlọ́run dá wa, ó mọ̀ pé òun ti fún wa ní ìfẹ́ ọkàn fún ìbálòpọ̀ láti jáde lọ, kí a sì tẹ́ ìfẹ́ wa fún ìbálòpọ̀ lọ́rùn. Ó ti fún wa ní apilẹ̀ àbùdá ìṣekúṣe. Mo rò pé kì yóò tọ̀nà pé kí ṣọ́ọ̀ṣì dá àwọn ènìyàn tí ó ti tẹ̀ lé ìsúnṣe àdánidá wọn lẹ́bi.”

Irú èrò bẹ́ẹ̀ ha gbé ìlera lárugẹ bí? Kí ni ìbálòpọ̀ fàlàlà ń náni? Ǹjẹ́ ìbálòpọ̀ onígbàdíẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ́ àwọn alájọṣe kan ń mú ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ wá bí?

Àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré tí ń jà káyé àti òkodoro òtítọ́ náà pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ń lóyún láìṣègbéyàwó, pàápàá láàárín àwọn ọ̀dọ́langba, ń jẹ́rìí sí ìjákulẹ̀ irú ọgbọ́n èrò orí bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Newsweek ṣe sọ, ní United States nìkan, iye àwọn ọ̀dọ́langba tí a fojú bù pé àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré ń pọ́n lójú lọ́dọọdún jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ta. Síwájú sí i, ọ̀pọ̀ lára “àwọn àgbàlagbà tí wọ́n fohùn ṣọ̀kan” wọ̀nyí ni ó jọ pé wọn kò ní “ìfẹ́ni àdánidá” tàbí ìmọ̀lára àìgbọ́dọ̀máṣe kankan fún ọmọ tí wọn kò ì bí tí ó sábà máa ń yọrí sí, wọ́n sì yára máa ń wá ọ̀nà láti ṣẹ́ oyún náà. (Tímótì Kejì 3:3) Èyí ń ná ọmọ tí wọn kò ì bí náà ní ìwàláàyè rẹ̀, bí wọ́n ti ń yà á nípa kúrò lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀ lọ́nà òǹrorò. Ó lè yọrí sí ìsoríkọ́ gidigidi àti ẹ̀bi fún ìyá náà, èyí tí ó sì lè máa dà á láàmú jálẹ̀ gbogbo ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀.

Lágbedeméjì àwọn ọdún 1990 ní ilẹ̀ Britain nìkan ṣoṣo, iye owó tí ìyọrísí ìyípadà nínú àṣà ìbálòpọ̀ ń náni lọ́dọọdún jẹ́ 20 bílíọ̀nù dọ́là, bí Dókítà Patrick Dixon ṣe ṣírò rẹ̀. Nínú ìwé rẹ̀, The Rising Price of Love, Dókítà Dixon ṣe ìṣirò dé orí iye yìí nípa ṣíṣe àkọsílẹ̀ iye tí a ń ná láti ṣètọ́jú àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré, títí kan àrùn AIDS; iye tí ìkọ̀sílẹ̀ ń náni; iye tí jíjẹ́ òbí anìkàntọ́mọ ń ná ẹgbẹ́ àwùjọ; àti iye tí ìtọ́jú ìdílé àti ọmọ ń náni. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail, ìwé agbéròyìnjáde ojoojúmọ́ kan ní Kánádà, ṣe ròyìn rẹ̀, Dókítà Dixon parí ọ̀rọ̀ sí pé: “Ìyípadà èyíkéyìí nínú ìbálòpọ̀, tí ó ṣèlérí òmìnira fún wa ti mú ọ̀pọ̀ ènìyàn lẹ́rú, nínú ayé kan tí ìdàrúdàpọ̀ ìbálòpọ̀, ọ̀ràn ìbànújẹ́, ìnìkanwà, ìrora ti ìmọ̀lára, ìwà ipá àti ìṣekúṣe ti bà jẹ́.”

Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí ìfarajin-ìbálòpọ̀, yíyan ìbálòpọ̀ onígbàdíẹ̀ láàyò, àti ìrinkinkin mọ́ ìbálòpọ̀ fàlàlà aláìníjihìn fi ń bá a lọ? Lójú irú ìyọrísí búburú bẹ́ẹ̀ láàárín ẹ̀wádún mẹ́ta tó kọjá yìí, kí ní ń tanná ran ìfarajìn apanirun yìí?

Ohun Arùfẹ́ Ìṣekúṣe Sókè Ń Fi Ìbálòpọ̀ Hàn Lọ́nà Òdì

A ti tọ́ka sí ohun arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè gẹ́gẹ́ bí kókó kan tí ń tanná ran ìfarajin-ìbálòpọ̀. Asọ̀bálòpọ̀-dibárakú kan, tí ó fúnra rẹ̀ jẹ́wọ́, kọ̀wé nínú ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star pé: “Mo ṣíwọ́ mímu sìgá lọ́dún márùn-ún sẹ́yìn, mo ṣíwọ́ mímu ọtí líle lọ́dún méjì sẹ́yìn, ṣùgbọ́n kò tí ì sí ohun tí ó ṣòro fún mi láti ṣíwọ́ nínú ìgbésí ayé mi tó ìsọ̀bálòpọ̀-dibárakú àti ohun arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè.”

Ó tún dá a lójú pé àwọn ọ̀dọ́langba tí ń fi ara wọn fún fífi àwọn ohun arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè bọ́ ọkàn wọn déédéé ń ní ojú ìwòye onídàrúdàpọ̀ nípa àṣà ìbálòpọ̀. Wọ́n ń gbé ìgbésí ayé ìfọkànyàwòrán ìbálòpọ̀, ojúlówó ìbálòpọ̀ ń dojú rú mọ́ wọn lọ́wọ́, ó sì ń ṣòro fún wọn. Èyí máa ń yọrí sí ìyara-ẹni-sọ́tọ̀ àti àwọn ìṣòro mìíràn, tí ọ̀kan lára àwọn ìṣòro pàtàkì rẹ̀ sì jẹ́ ti níní ìdè ìfẹ́ wíwàpẹ́títí.

Àwọn Ohun Ìnàjú Ń Lo Ìbálòpọ̀

Àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé oníṣekúṣe tí ó kan ọ̀pọ̀ alájọṣe, bóyá lọ́nà òfin tàbí lọ́nà tí kò lọ́wọ́ òfin nínú, ni àwọn ohun ìnàjú ń fi dáṣà, tí wọ́n sì ń fi hàn ní gbangba. Àfihàn ìbálòpọ̀ lọ́nà àìnífẹ̀ẹ́ àti ìrẹ̀nípòwálẹ̀ lójú gọgọwú ẹ̀rọ ń tanná ran ìfarajin-ìbálòpọ̀, ó sì ń fún ìran yìí ní ojú ìwòye onídàrúdàpọ̀ nípa ìbálòpọ̀ ẹ̀dá ènìyàn. Lọ́nà èké, àwọn ilé iṣẹ́ tí ń gbé eré ìnàjú jáde sábà máa ń fi ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó hàn bí ohun tí ó bá ìsúnmọ́ra onífẹ̀ẹ́ dọ́gba. Ó jọ pé àwọn olólùfẹ́ eré ìnàjú, tí wọ́n ti sọ àwọn òṣèré ìnàjú dòrìṣà, kò lè dá fìyàtọ̀ sáàárín ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìfẹ́, sáàárín àjọṣe oréfèé ti ìbálòpọ̀ onígbàdíẹ̀ àti ìfarajìn onígbàpípẹ́, tàbí láàárín ìfọkànyàwòrán àti ìjóòótọ́-gidi.

Bákan náà, nígbà púpọ̀ ni àwọn ìpolówó ọjà ti lo ìbálòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìtajà. Ẹnì kan tí ó jẹ́ olùṣètọ́jú ọ̀ràn ìbálòpọ̀ láìlo egbòogi sọ pé, ó ti wá di “ohun kan tí kò gba ànímọ́ tàbí ìmọ̀lára ẹ̀dá ènìyàn, tí ète rẹ̀ jẹ́ láti fa àfiyèsí mọ́ ohun àṣejáde kan.” Àwọn olùpolówó ti lo ìbálòpọ̀, wọ́n sì ti so ìhùwà ìbálòpọ̀ mọ́ ìgbésí ayé àfọkànfẹ́, síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìwé àtìgbàdégbà náà, Family Relations, ṣe sọ ọ́, èyí jẹ́ “ìdàrúdàpọ̀” míràn ní ti “ojú ìwòye nípa ìbálòpọ̀” láàárín ọ̀rúndún ogún.

Ipa Iṣẹ́ Tí Ń Yí Pa Dà Yí Ìṣarasíhùwà Sódì

Àyíká àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tí ń yí pa dà, àti kíkó tí a kó egbòogi málòóyún sórí àtẹ ní 1960 yí àṣà ìbálòpọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ obìnrin pa dà. Egbòogi náà fún àwọn obìnrin ní èròǹgbà àparò-kan-ò-ga-jùkan-lọ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin, ní ti ìbálòpọ̀, òmìnira ìbálòpọ̀ tàbí àìgbáraléni fún ìbálòpọ̀ irú èyí tí wọn kò ní rí. Bíi ti àwọn ọkùnrin, wọ́n lè fi ìbálòpọ̀ onígbàdíẹ̀ dánra wò wàyí, láìsí ìbẹ̀rù pé àwọn lè lóyún àìròtẹ́lẹ̀. Bí wọ́n ti ń yọ̀ nínú ìdáǹdè ìbálòpọ̀ wọn, àti akọ àti abo bákan náà ń yẹ ipa iṣẹ́ àdánidá ti ìdílé àti ìbálòpọ̀ sílẹ̀ dé àyè kíkú àkúrun gan-an.

Òǹkọ̀wé Bíbélì kan ní ọ̀rúndún kìíní sọ nípa irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ pé: “Wọ́n ní àwọn ojú tí ó kún fún panṣágà tí kò sì lè yọwọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ . . . Wọ́n ní ọkàn àyà tí a fi ojúkòkòrò kọ́. . . . Ní pípa ipa ọ̀nà títọ́ tì, a ti ṣì wọ́n lọ́nà.”—Pétérù Kejì 2:14, 15.

Ẹ̀kọ́ Nípa Ìbálòpọ̀ Nílé Ẹ̀kọ́

Ìwádìí kan tí United States ṣe láàárín 10,000 àwọn ọmọbìnrin tí kò lọ́kọ rí, tí ọjọ́ orí wọ́n wà ní ti ilé ẹ̀kọ́ gíga fi hàn pé, “ìmọ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ nípa ìbálòpọ̀ ṣe tọ́ka rẹ̀ àti ìmọ̀ tí wọ́n sọ pé àwọn ní nípa ọ̀nà málòóyún,” kò ní ipa lórí ìwọ̀n ìlóyún láàárín àwọn ọ̀dọ́langba tí ko ṣègbéyàwó. Síbẹ̀síbẹ̀, ìhùwàpadà àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan sí àjàkálẹ̀ náà ni pípín kọ́ńdọ̀mù ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àríyànjiyàn gbígbóná janjan ń lọ lórí àṣà náà.

Akẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún 17 kan nílé ẹ̀kọ́ gíga tí ìwé ìròyìn Calgary Herald fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ pé: “Òtítọ́ ni pé, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀dọ́langba nílé ẹ̀kọ́ gíga ń ní ìbálòpọ̀ . . . , kódà, àwọn ọmọ ọdún 12 pàápàá.”

Kí Ni Ìfẹ́, Kí sì Ni Ìfarajìn?

Ìfẹ́, ìgbẹ́kẹ̀lé, àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tí a ṣìkẹ́ kì í ṣe àbájáde tí ń wá láìṣiṣẹ́fún-un láti inú ìfàmọ́ra ojú ẹsẹ̀ fún ìbálòpọ̀ tàbí títẹ́ ìmọ̀lára òjijì fún ìbálòpọ̀ lọ́rùn. Ìbálòpọ̀ nìkan ṣoṣo kò lè mú ojúlówó ìfẹ́ wá. Ìfẹ́ àti ìsúnmọ́ra ń wá láti inú ọkàn àyà àwọn ẹni méjì tí ń bìkítà, tí wọ́n sì fara jin gbígbé ipò ìbátan aláìyípadà kan kalẹ̀.

Ìbálòpọ̀ onígbàdíẹ̀ máa ń fini sílẹ̀ níkẹyìn nínú ipò àìláàbò, ìdáwà, àti bóyá, tí a sì ti kó àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré bí àrùn AIDS. Àwọn alágbàwí ìbálòpọ̀ fàlàlà ni a lè fi àwọn ọ̀rọ̀ inú Pétérù Kejì 2:19 ṣàpéjúwe dáradára pé: “Nígbà tí wọ́n ń ṣèlérí òmìnira fún wọn, àwọn fúnra wọ́n wà gẹ́gẹ́ bí ẹrú ìdíbàjẹ́. Nítorí ẹni yòó wù tí ẹlòmíràn ṣẹ́pá rẹ̀ ni ẹni yìí sọ di ẹrú.”

Ìgbìmọ̀ àìgbọdọ̀máṣe láàárín àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn, tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ England gbé kalẹ̀, gbé ìròyìn iṣẹ́ rẹ̀ jáde ní June 1995, tí ó ní àkọlé pé, “Ohun Kan Láti Ṣayẹyẹ Rẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star ṣe sọ, ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ìmọ̀ràn inú Bíbélì náà, ìgbìmọ̀ ọ̀hún rọ ṣọ́ọ̀ṣì náà láti “pa àpólà ọ̀rọ̀ náà, ‘gbígbé nínú ẹ̀ṣẹ̀’ rẹ́, kí ó sì ṣíwọ́ ìṣarasíhùwà ìdánilẹ́bi rẹ̀ sí àwọn tí ń gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó.” Ìròyìn náà dámọ̀ràn pé, “ó yẹ kí àwọn ìjọ máa fàyè gba àwọn alájọgbé-láìṣègbéyàwó, kí wọ́n máa tẹ́tí sí wọn, kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ wọn, . . . kí gbogbo wọn lè ṣàwárí bí Ọlọ́run ṣe wà nínú ìgbésí ayé wọn.”

Kí ni Jésù ì bá ti pe irú àwọn aṣáájú ìsìn bẹ́ẹ̀? Láìsíyèméjì, “afọ́jú afinimọ̀nà” ni. Àwọn tó sì ń tọ irú àwọn afinimọ̀nà bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ńkọ́? Ó ronú pé: “Bí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, àwọn méjèèjì yóò já sínú kòtò.” Ó lè dá ọ lójú pé Jésù sọ ní kedere pé, “panṣágà” àti “àgbèrè” wà lára “àwọn ohun tí ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.”—Mátíù 15:14, 18-20.

Lójú gbogbo onírúurú kókó abájọ tí ń ṣe ìdàrúdàpọ̀ ìbálòpọ̀ tí ó sì ń lò ó wọ̀nyí, báwo ni ẹnì kan, ní pàtàkì, àwọn èwe, ṣe lè jàjàbọ́ lọ́wọ́ ìfarajin-ìbálòpọ̀? Kí ni àṣírí ìbáṣepọ̀ onígbàpípẹ́, tí ó jẹ́ aláyọ̀? Àpilẹ̀kọ tí ó kàn yóò pa àfiyèsí pọ̀ sórí ohun tí àwọn òbí lè ṣe láti ran àwọn èwe lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún ọjọ́ iwájú.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

Ní United States nìkan, àwọn ọ̀dọ́langba tí a fojú bù pé àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré ń pọ́n lójú lọ́dọọdún jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ta

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Ní Ti Ìbálòpọ̀

Ìfàmọ́ra onífàájì aṣejù: Wọ́n ti sọ ara wọn di ẹrú ìbálòpọ̀, nítorí náà wọ́n ń ní ìbálòpọ̀ fúngbà díẹ̀ láti ìgbà dé ìgbà, bí ìrunisókè ìfẹ́ onígbòónára náà bá ti lọ sílẹ̀. Dókítà Michael Liebowitz, láti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn Ọpọlọ ti Ìpínlẹ̀ New York, ló ṣẹ̀dá orúkọ yìí fún un.

Àwọn akóbìnrinjọ àti akọ́kọjọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́: Àwọn onímọ̀ ìbágbépọ̀-ẹ̀dá ló ṣàpèjúwe àwọn ènìyàn tí ń ṣe ìgbéyàwó, ìkọ̀sílẹ̀, àti ìtúnṣègbéyàwó lábẹ́ òfin léraléra lọ́nà yí.

Àwọn afiniṣèjẹ ìbálòpọ̀: Luther Baker, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ìdílé, tí a sì jẹ́rìí sí gẹ́gẹ́ bí olùṣètọ́jú ọ̀ràn ìbálòpọ̀ láìlo egbòogi, sọ pé, àwọn wọ̀nyí máa ń fẹ́ láti ṣàṣehàn ìgboyà yíyọrí ọlá wọn ní ti ìbálòpọ̀ nípa níní ọ̀pọ̀ ẹni tí wọ́n ń bá lò pọ̀. Ní báyìí, a tún ti ń lo ọ̀rọ̀ náà fún àwọn afìbálòpọ̀-fìtínà-ọmọdé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ohun arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè máa ń di bárakú, ó sì ń yọrí sí ojú ìwòye ìdàrúdàpọ̀ nípa àṣà ìbálòpọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́