ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 6/8 ojú ìwé 8-10
  • Kíkojú Ìpèníjà Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkojú Ìpèníjà Náà
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Òbí Tí Ń Ní Ipa Rere
  • Ṣíṣàṣeyọrí Nínú Kíkojú Ìpèníjà Náà
  • Tẹ́wọ́ Gba Àwọn Ìpèsè Jèhófà fún Ìwàláàyè
  • Kí Ní Ń Nípa Lórí Ìṣarasíhùwà Rẹ?
    Jí!—1997
  • Ìṣarasíhùwà Tí Ń yí Pa Dà Ń Ṣokùnfà Àwọn Ìbéèrè Tuntun
    Jí!—1997
  • Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó
    Jí!—2013
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 6/8 ojú ìwé 8-10

Kíkojú Ìpèníjà Náà

ÌKỌLÙ òjijì tí ń bá ìwà rere ti ìbálòpọ̀ máa ń bẹ̀rẹ̀ ní kùtùkùtù ìgbésí ayé, bí tẹlifíṣọ̀n, àwọn ìwé, àwọn ìwé ìròyìn, sinimá, àti orin tí ń gbé ìbálòpọ̀ jáde lákànṣe, ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Ìwọ̀nyí ń rọ àwọn èwe láti gba àwọn ọ̀nà àṣà ìbálòpọ̀ àwọn àgbàlagbà lò láìsí pé wọ́n ń dáàbò bo ìwàdéédéé ìmọ̀lára wọn. Àwọn òbí mélòó kan pàápàá ń dá kún pákáǹleke ìbálòpọ̀ náà nípa fífàyègba dídájọ́-àjọròde nígbà ọmọdé. Ipá ojúgbà ẹni ń fún dídájọ́-àjọròde níṣìírí, ọ̀pọ̀ èwe tó sì ní ọ̀rẹ́kùnrin tàbí ọ̀rẹ́bìnrin tó dúró déédéé yára ń pàdánù ìwàlójúfò wọn, wọ́n sì ń lọ́wọ́ sí ìwà ìbálòpọ̀. Luther Baker, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ìdílé, sọ pé: “Ẹ wo bí ó ti wọ́pọ̀ tó . . . pé kí ọ̀dọ́bìnrin ọ̀dọ́langba kan, tí ó rò pé àwọn òbí òun kò fẹ́ràn òun . . . kó wọnú ìgbánimọ́ra oníbàálòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀, ní níní ìgbàgbọ́ òdì pé yóò mú ìfẹ́ àti ìsúnmọ́ra tímọ́tímọ́ wá.”

Àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ ní ìtẹ̀sí lílo àwọn ọdún ìbàlágà wọn bíi sáà àyàsọ́tọ̀ tí ó kẹ́yìn fún ìtẹ́ra-ẹni-lọ́rùn nínú ìgbésí ayé wọn, kàkà kí ó jẹ́ bí ìmúrasílẹ̀ fún gbígbé ìyókù ìgbésí ayé wọn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Baker sọ pé: “Bí ọ̀tun agbára ìbálòpọ̀ wọn ṣe ń ru wọ́n sókè, tí àwọn ojúgbà wọn sì ń mú un dá wọn lójú pé ìgboyà yíyọrí-ọlá ní ti ìbálòpọ̀ ni ọ̀nà láti jẹ́ ọkùnrin, ọ̀pọ̀ èwe di afiniṣèjẹ ìbálòpọ̀” nígbà àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà wọn. Ní nǹkan bí 30 ọdún sẹ́yìn, òpìtàn Arnold Toynbee kédàárò lórí àdàkàdekè tí a ṣe sí àwọn èwe wa, bí ó ṣe gbà gbọ́ pé ìtàn ti fi hàn pé apá kan làákàyè ìṣẹ̀dáǹkan ti Ìwọ̀ Oòrùn ayé òde òní, ti jẹ yọ láti inú ṣíṣeéṣe láti sún ‘ìgbòkègbodò ìbálòpọ̀’ àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà síwájú, kí wọ́n lè pọkàn pọ̀ sórí kíkó ìmọ̀ jọ.

Àwọn Òbí Tí Ń Ní Ipa Rere

Àwọn òbí tí kò gba àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà láyè láti máa dájọ́ àjọròde fún ìnàjú ń fi ojúlówó àníyàn hàn nípa ìlera àti ayọ̀ tí ó yẹ kí àwọn ọmọ wọn ní lọ́jọ́ ọ̀la. Nípa níní ìlànà ìwà rere gíga àti níní ojúlówó ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, wọ́n lè nípa lórí ìgbésí ayé àwọn ọmọ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Journal of Marriage and the Family ṣe wí, ìwádìí tí a ti ṣe lórí àṣà ìbálòpọ̀ àwọn èwe tọ́ka sí i pé, “ipa yìí lè mú kí àwọn ọmọ sún ìgbòkègbodò ìbálòpọ̀ síwájú.”

Àwọn òbí tí ń gbin ìmọ̀lára ìbára-ẹni-wí àti ẹrù iṣẹ́ lílágbára sí ọkàn àyà àwọn ọmọ wọn ń rí ìyọrísí dídára jù lọ. Ìwádìí kan jẹ́rìí sí i pé: “Nígbà tí àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà àti àwọn òbí wọn bá rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà tí ń tẹnu mọ́ àìgbọ́dọ̀máṣe, ṣíṣeéṣe pé kí àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà náà bímọ láìṣègbéyàwó dín kù lọ́nà gbígbàfiyèsí.” Èyí béèrè pé kí òbí máa kópa tí ń fi ìmọ̀lára kíákíá hàn nínú àwọn ìgbòkègbodò àwọn ọmọ—bíbá wọn bójú tó iṣẹ́ àṣetiléwá wọn; mímọ ibi tí wọ́n ń rìn sí àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn; gbígbé góńgó ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ọwọ́ lè tó kalẹ̀; àti ṣíṣàjọpín àwọn ìlànà ti ẹ̀mí. Àwọn ọmọ tí ń ṣe báyìí ní ìfararora tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn òbí bí wọ́n ṣe ń dàgbà yóò nímọ̀lára dídára jù nípa ara wọn, ara yóò sì tù wọ́n nípa àṣà ìbálòpọ̀ wọn.

Ìmọ̀ràn dídára jù lọ fún àwọn òbí àti àwọn ọmọ lápapọ̀ ni ọgbọ́n tí a rí nínú Bíbélì. A pàṣẹ fún àwọn òbí ní Ísírẹ́lì láti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn ní àwọn ìlànà yíyẹ. Jèhófà bi wọ́n léèrè pé: “Orílẹ̀-èdè ńlá wo ni ó sì wà, tí ó ní àwọn ìlànà òdodo àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ bíi gbogbo òfin yìí tí mo ń fi sí iwájú yín lónìí?” “Àwọn ìlànà òdodo” wọ̀nyí ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi kọ́ àwọn ọmọ wọn nínú ipò ìdílé ọlọ́yàyà àti ìsúnmọ́ra tímọ́tímọ́. “Kí ìwọ . . . fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” A rọ àwọn ọmọ pé: “Pa àṣẹ baba rẹ mọ́, má sì ṣe ṣá òfin ìyá rẹ tì.” Irú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ àti ìtọ́ni ọlọ́yàyà àti ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí bẹ́ẹ̀ láti ọ̀dọ̀ bàbá àti ìyá lápapọ̀ ń fi ìṣarasíhùwà wíwàdéédéé nípa ìgbésí ayé àti àṣà ìbálòpọ̀ kọ́ àwọn ọmọ, èyí tí “yóò máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí” èwe kan jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.—Diutarónómì 4:8; 6:7, NW; Òwe 6:20, 22, NW.

Ẹ̀yin èwe, èé ṣe tí ẹ óò fi ba ọjọ́ ọ̀la yín jẹ́ nípa jíjuwọ́sílẹ̀ fún ìmọ̀lára òjijì fún ìbálòpọ̀? Iye ọdún ìgbà ọ̀dọ́langba jẹ́ nǹkan bíi méje. Ó yẹ kí a lò wọ́n láti dàgbà ní ti èrò orí, ní ti ìmọ̀lára, àti ní ti ẹ̀mí àti láti mú ìṣarasíhùwà wíwàdéédéé nípa àṣà ìbálòpọ̀ dàgbà, ní ìmúrasílẹ̀ fún 50 tàbí 60 ọdún ìgbésí ayé tí ó kàn. Ẹ̀yin òbí, ẹ fọwọ́ ìjẹ́pàtàkì mú ẹrù iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún yín, kí ẹ sì dáàbò bo àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ pákáǹleke ọkàn àyà tí àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré àti oyún àìròtẹ́lẹ̀ máa ń fà. (Oníwàásù 11:10) Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ yín rí bí níní ìfẹ́ àti ìgbatẹnirò fún àwọn ẹlòmíràn ṣe ń gbé ìbátan pípẹ́títí kalẹ̀, nínú ìgbésí ayé yín.

Ṣíṣàṣeyọrí Nínú Kíkojú Ìpèníjà Náà

Má ṣe jẹ́ kí ìfarajin-ìbálòpọ̀ ti lọ́wọ́lọ́wọ́ kó ìdàrúdàpọ̀ bá ojú ìwòye rẹ nípa ìgbésí ayé, kí ó sì ba àǹfààní rẹ fún ọjọ́ ọ̀la onítẹ̀ẹ́lọ́rùn àti aláyọ̀ jẹ́. Ṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpẹẹrẹ ipò ìbátan ẹ̀dá ènìyàn tí ó wà nínú Bíbélì. Jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé ìwàláàyè àti ìfẹ́ kún fún ìgbòkègbodò àti ìtumọ̀ títí lọ lẹ́yìn àwọn ọdún ìgbà ọ̀dọ́langba. Nígbà tí a bá ṣàgbéyẹ̀wò kókó yìí dáradára ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin, nígbà náà ni a fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ìsopọ̀ tímọ́tímọ́, pípẹ́títí fún àwọn ẹni méjì tí ó nífẹ̀ẹ́ ara wọn.

Bí o ti ń ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn àwọn tọkọtaya inú Bíbélì bíi Jékọ́bù àti Réṣẹ́ẹ̀lì, Bóásì àti Rúùtù, àti ọmọdékùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà àti omidan Ṣúlámáítì náà, ìwọ yóò rí àmì ìfàmọ́ra ìbálòpọ̀ nínú ipò ìbátan wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, bí o ti ń fara balẹ̀ ka Jẹ́nẹ́sísì orí 28 àti 29, ìwé Rúùtù, àti Orin Sọ́lómọ́nì, ìwọ yóò rí i pé àwọn ohun pàtàkì míràn wà tí ó mú kí irú ipò ìbátan bẹ́ẹ̀ lárinrin.a

Tẹ́wọ́ Gba Àwọn Ìpèsè Jèhófà fún Ìwàláàyè

Jèhófà, Ẹlẹ́dàá ìran ènìyàn, lóye àṣà ìbálòpọ̀ ẹ̀dá ènìyàn àti àwọn ìsúnniṣe tí ó rọ̀ mọ́ ọn. Tìfẹ́tìfẹ́, ó ti dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, kò dá “apilẹ̀ àbùdá ìṣekúṣe” mọ́ wa, ṣùgbọ́n, ó fún wa ní agbára láti kápá ìmọ̀lára wa ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ inú Ọlọ́run jẹ́, . . . pé kí ẹ takété sí àgbèrè; pé kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun ìlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá, kì í ṣe nínú ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo irúfẹ́ èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì pẹ̀lú tí kò mọ Ọlọ́run ní; pé kí ẹni kankan má ṣe lọ títí dé àyè ṣíṣe ìpalára fún àti rírakaka lé àwọn ẹ̀tọ́ arákùnrin rẹ̀ nínú ọ̀ràn yí.”—Tẹsalóníkà Kíní 4:3-6.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò àgbáyé ń fi èyí hàn. Wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà gíga tí Ọlọ́run ní fún àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Wọ́n ń wo àwọn àgbà ọkùnrin gẹ́gẹ́ bíi bàbá, “àwọn ọ̀dọ́ ọkùnrin gẹ́gẹ́ bí arákùnrin, àwọn àgbà obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìyá, àwọn ọ̀dọ́ obìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.” (Tímótì Kíní 5:1, 2) Ẹ wo irú àyíká gbígbámúṣé tí èyí jẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin láti gbádùn, bí wọ́n ṣe ń dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibi tí agbára wọ́n lè dé, láìsí ìdíwọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ojúgbà wọn tí ń tì wọ́n sí dídájọ́-àjọròde àti ṣíṣègbéyàwó láìtọ́jọ́ tàbí ìdíwọ́ tí àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré ń fà! Ìdílé Kristẹni gbígbéṣẹ́, tí ìjọ Kristẹni ń fún lókun, jẹ́ ibi ààbò kan nínú ayé tí ìbálòpọ̀ ń sín níwín.

Bí àwọn èwe Kristẹni ṣe ń lo àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé wọn, wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ìfarajìn fún ìbálòpọ̀, wọ́n sì ń rí ayọ̀ nínú fífiyèsí ìṣítí tí a fúnni nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pé: “Máa yọ̀, ọ̀dọ́kùnrin, ní ìgbà èwe rẹ, sì jẹ́ kí ọkàn àyà rẹ ṣe ọ́ ní ire ní àwọn ọjọ́ ìgbà ọ̀dọ́kùnrin rẹ, kí o sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà ọkàn àyà rẹ àti nínú àwọn ohun tí ojú rẹ bá rí. Ṣùgbọ́n mọ̀ pé ní tìtorí gbogbo ìwọ̀nyí ni Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe mú ọ wá sínú ìdájọ́. Nítorí náà, mú pákáǹleke kúrò ní ọkàn àyà rẹ, kí o sì taari ìyọnu àjálù kúrò ní ẹran ara rẹ; nítorí pé asán ni ìgbà èwe àti ìgbà ọ̀ṣìngín nínú ìgbésí ayé.”—Oníwàásù 11:9, 10, NW.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ojú ìwé 247 nínú ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

Má ṣe jẹ́ kí fífarajin-ìbálòpọ̀ ba àǹfààní rẹ fún ọjọ́ ọ̀la onítẹ̀ẹ́lọ́rùn àti aláyọ̀ jẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ṣíṣeéṣe pé kí àwọn èwe tí ń ṣe àwọn ìgbòkègbodò ìdílé máa wá ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí oníbàálòpọ̀ kiri kò tó nǹkan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́