ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 6/8 ojú ìwé 3
  • Ìṣarasíhùwà Tí Ń yí Pa Dà Ń Ṣokùnfà Àwọn Ìbéèrè Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣarasíhùwà Tí Ń yí Pa Dà Ń Ṣokùnfà Àwọn Ìbéèrè Tuntun
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ní Ń Nípa Lórí Ìṣarasíhùwà Rẹ?
    Jí!—1997
  • Kíkojú Ìpèníjà Náà
    Jí!—1997
  • Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó
    Jí!—2013
  • Gbígbé Ìgbésí Ayé Tó Yàtọ̀ Sí Ti Ẹ̀dá—Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fọwọ́ Sí I?
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 6/8 ojú ìwé 3

Ìṣarasíhùwà Tí Ń yí Pa Dà Ń Ṣokùnfà Àwọn Ìbéèrè Tuntun

“ÌYÍPADÀ NÍNÚ ÀṢÀ ÌBÁLÒPỌ̀,” “ìsọ̀bálòpọ̀-dibárakú,” “ìyípadà nínú ìwà rere.” Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó sọ ìṣarasíhùwà tí ń yí pa dà nípa ìbálòpọ̀ di olókìkí, ní pàtàkì, ní agbedeméjì àwọn ọdún 1960 àti lẹ́yìn náà. Ọ̀pọ̀ ló tẹ́wọ́ gba àṣà náà, “ìbálòpọ̀ fàlàlà,” tí ó jẹ́ àmì ìdánimọ̀ ọ̀nà ìgbésí ayé kan, nínú èyí tí àwọn ènìyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ti kẹ̀yìn sí ìgbéyàwó àti wíwà ní ipò wúńdíá.

Ìkéde ojú ìwòye òǹkọ̀wé Ernest Hemingway pé, “Ohun tí ó jẹ́ ìwà rere ni èyí tí o kò nímọ̀lára ẹ̀bi nípa rẹ̀, ohun tí kò sì jẹ́ ìwà rere ni èyí tí o nímọ̀lára ẹ̀bi nípa rẹ̀,” lè ṣàkópọ̀ kíkúnrẹ́rẹ́ lórí ìhùwàsí àwọn tí èèdì ìlérí òmìnira ìbálòpọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn adùn ìbálòpọ̀ mú. Títẹ́wọ́gba àbá èrò orí yìí dá níní ìbálòpọ̀ onígbàdíẹ̀ pẹ̀lú àwọn alájọṣe mélòó kan, nínú èyí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan, akọ àti abo, ń ṣàwárí àṣà ìbálòpọ̀ tiwọn fúnra wọn, láre. “Ìtẹ́lọ́rùn adùn” ìbálòpọ̀ kò láàlà. Àwọn egbòogi málòóyún, tí wọ́n kó dé láàárín ẹ̀wádún kan náà, kó ipa láti mú kí àfidánrawò ìbálòpọ̀ tí a kò ká lọ́wọ́ kò gbilẹ̀.

Bí ó ti wù kí ó rí, àrùn AIDS àti àwọn àrùn míràn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré wá di ogún tí ọ̀nà ìgbésí ayé oníṣekúṣe yìí fi sílẹ̀. Ìṣarasíhùwà oníbàálòpọ̀ ìran aláìmọ́ ti dojú rú. Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Time gbé àkọlé náà, “Àṣà Ìbálòpọ̀ Láàárín Àwọn Ọdún 1980—Ìyípadà Náà Ti Dópin,” jáde. Wọ́n gbé ìpolongo yìí karí bí àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré, tí ń bá ọ̀pọ̀ àwọn ará America fínra, ṣe gbilẹ̀ tó ní pàtàkì. Títí di báyìí, àròpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn AIDS jákèjádò àgbáyé ti pọ̀ tó iye amúnijígìrì tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 30 mílíọ̀nù!

Ìbẹ̀rù àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré ṣokùnfà ìsúnsíwájú kan nínú ìṣarasíhùwà ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ìbálòpọ̀ onígbàdíẹ̀. Nígbà tí ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn adánilárayá tí ń jẹ́ US kan ní 1992 ń ròyìn ìwádìí kan tí ìjọba ṣe, ó wí pé: “Nǹkan bíi mílíọ̀nù 6.8 àwọn obìnrin tí kò lọ́kọ ti yí ọ̀nà ìhùwà ìbálòpọ̀ wọn pa dà nítorí ìbẹ̀rù àrùn AIDS àti àwọn àrùn míràn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré.” Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ náà ṣe sọ, ìsọfúnni náà ṣe kedere pé: “Ìbálòpọ̀ kì í ṣe ọ̀ràn yẹpẹrẹ. Ó léwu.”

Báwo ni àwọn ẹ̀wádún onírúkèrúdò wọ̀nyí ṣe ti nípa lórí ìṣarasíhùwà àwọn ènìyàn nípa ìbálòpọ̀? A ha ti kẹ́kọ̀ọ́ kankan láti inú ìkáràmásìkí aláìníjàánu, tí ìbálòpọ̀ fàlàlà ní àwọn ẹ̀wádún lọ́ọ́lọ́ọ́ jẹ́ àmì àfihàn rẹ̀, àti láti inú ìjótìítọ́ tí ń múni sorí kọ́ nípa àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré ní àwọn ọdún 1980 bí? Mímú ẹ̀kọ́ nípa ìbálòpọ̀ wọnú àwọn kókó ẹ̀kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ìjọba ha ti ran àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti àwọn ọ̀dọ́bìnrin lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí ní kíkojú àṣà ìbálòpọ̀ wọn bí? Ọ̀nà wo ni ó dára jù lọ láti gbà kojú ìpèníjà tí ìṣarasíhùwà tí ó ti yí pa dà nípa ìbálòpọ̀ lóde òní ń mú wá?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́