“Ohun Èlò Àtàtà Tó Ṣeé Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́!”
Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lórílẹ̀-èdè Panama ló sọ̀rọ̀ yìí nínú lẹ́tà tó kọ sí wa nípa ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ìwé olójú ewé igba ó lé mẹ́rìnlélógún [224] tó ní àwòrán mèremère yìí là ń lò níbi gbogbo láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Ó tún sọ nínú ìwé tó kọ ránṣẹ́ náà pé: “Ìwé náà mọ níwọ̀n, wọ́n gbé ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ, àlàyé inú ẹ̀ sì ń tẹ́ni lọ́rùn. Béèyàn bá sì tún wo ọ̀nà àkọ̀tun tí wọ́n ń gbà tọ́ka sáwọn kókó ẹ̀kọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà nínú ìwé náà àti àfikún inú rẹ̀, ńṣe lá máa wu onítọ̀hún láti wádìí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni síwájú àti síwájú sí i.”
Obìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tóun náà kọ̀wé ránṣẹ́ láti ìpínlẹ̀ Missouri, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Èdè tó rọrùn tí wọ́n fi kọ̀wé náà wù mí gan-an. Òun ni ìwé tí màá kọ́kọ́ rí tí wọ́n to kókó inú ẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ, lọ́nà tó tíì bọ́gbọ́n mu jù lọ.” Gbàrà tọ́wọ́ obìnrin yìí tẹ ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, ó mú un tọ obìnrin kan lọ. Obìnrin náà ti ń fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́lẹ̀, àmọ́ kò tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
Obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí sọ bí ọ̀hún ṣe rí. Ó ní: “Kò tíì ka àkòrí kìíní jálẹ̀ tó ti ké sí mi lórí fóònù tó sì sọ fún mi bóun ṣe ń gbádùn ìwé náà tó.” Kódà, ó sọ pé òun rò pé torí òun ni wọ́n ṣe kọ̀wé náà, àti pé òun fẹ́ láti padà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Obìnrin Ẹlẹ́rìí tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ tún sọ pé òun kíyè sí i pé lẹ́yìn táwọn ti ka orí mẹ́wàá àkọ́kọ́ parí, ńṣe ni ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ ń mú kí ayọ̀ ẹ̀ túbọ̀ máa pọ̀ sí i.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì pé ọdún méjì tá a tẹ ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, àròpọ̀ ẹ̀dà tá a ti tẹ̀ báyìí lé ní àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àádọ́ta ní èdè tó ju àádọ́jọ lọ [150]. Bó o bá fẹ́ gba ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.