“Ohun Tá A Ti Ń Wá Gan-an Nìyí!”
Igbe ayọ̀ tí ìyá kan ké lórílẹ̀-èdè Ítálì nìyẹn ní gbàrà tọ́wọ́ ẹ̀ tẹ ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Ó sọ pé: “Ṣe ni mo mẹ́kún sun nítorí pé mi ò lè mú un mọ́ra mọ́. Ó tún wá fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọbìnrin rẹ̀ kún un pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì mọ̀wé kà, àwọn àwòrán tó wà nínú ìwé náà máa ń jẹ́ kó rántí àwọn kókó pàtàkì. Ó máa ń fọkàn sí ohun tó wà níbẹ̀ torí pé wọ́n kọ ọ́ bí ìgbà tí ìjíròrò ń wáyé láàárín ìwé náà àti ẹni tó ń kà á, á wá dà bíi pé ẹni tó ń kàwé náà ń lóhùn sí ìjíròrò náà. Ẹ̀bùn wo ló tún dáa tóyẹn tá a lè rí gbà.”
Baálé ilé kan lórílẹ̀-èdè Ítálì ṣàlàyé pé òun àti ìyàwó òun ti ń bi ara àwọn báwọn ṣe máa ṣàlàyé ọ̀ràn ìbálòpọ̀ fọ́mọ àwọn ọkùnrin. Wọ́n wá sọ pé: “Nígbà tí ìwé tuntun yìí jáde, ṣe ló dà bíi pé Ọlọ́run ti mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro wa. Lẹ́yìn tá a ti yẹ ìwé yìí wò, àwa méjèèjì jọ sọ ọ́ láàárín ara wa pé ìwé tuntun náà á ran ọmọ wa ọkùnrin lọ́wọ́ gan-an, á jẹ́ kó máa ronú jinlẹ̀.”
Láti orílẹ̀-èdè Japan, ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe nígbà tó wà lọ́mọdé mọrírì ìwé náà gan-an, ó sì kọ̀wé pé: “Ńṣe ni omijé ń jábọ́ pòròpòrò lójú mi, mi ò sì yé dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Ìwé náà ò fìkan pe méjì, òótọ́ sì ni gbogbo ohun tó sọ nípa ìṣòro táwọn ọmọdé lè ní láwọn àkókò búburú tá à ń gbé yìí. Àwọn ìbéèrè tó wà nínú ìwé náà máa ń jẹ́ káwọn ọmọdé sọ tinú wọn. Orí 32 nínú ìwé náà tún ti lọ wà jù, nítorí pé ó máa dáàbò bo àwọn ọmọdé lọ́wọ́ àwọn àgbàlagbà tó bá fẹ́ bayé wọn jẹ́! Ayé mi ì bá máà rí bó ṣe rí yìí ká ní ọwọ́ mi ti tẹ irú ìwé tí kò firọ́ pé òótọ́ tó sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ báyìí ní ogún ọdún sẹ́yìn.”
Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan lára ìwé olójú ewé 256, tó ní àwòrán rírẹwà tó sì fẹ̀ tó ìwé ìròyìn yìí, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.