ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/11 ojú ìwé 25
  • “O Ò Jẹ́ Kó Sú Ẹ”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “O Ò Jẹ́ Kó Sú Ẹ”
  • Jí!—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀yin Tẹ́ Ẹ Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ṣègbéyàwó, Ẹ Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ìdí Táwọn Ìlànà Fi Ń Yí Padà
    Jí!—2003
  • Ìdààmú Àwọn Dókítà
    Jí!—2005
  • Báwo Ni Ara Rẹ Ṣe Lè Dá Ṣáṣá?
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 1/11 ojú ìwé 25

“O Ò Jẹ́ Kó Sú Ẹ”

● Camila ní àwọn ìṣòro tó ní í ṣe pẹ̀lú àìtó ẹ̀jẹ̀, iṣan ìfura àti ìdàgbàsókè ara. Ìyẹn ló fà á tó fi jẹ́ pé, nígbà tó fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́jọ, kò ga ju ẹsẹ̀ bàtà méjì àti ààbọ̀ lọ. Àwọn òbí Camila tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pinnu láti mú un lọ síbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìlera, tí wọ́n ṣe ní gbọ̀ngàn ìwòran kan tó wà ní abúlé wọn lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà. Apá iwájú ni Camila àti Marisa, ìyá rẹ̀ jókòó sí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] èèyàn ló sì wà níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà.

Nígbà tí dókítà kan ń sọ̀rọ̀ níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà, ó nawọ́ sí Camila, ó sì fi ṣe àpẹẹrẹ ẹni tó ní ìlera tó dáa. Torí pé dókítà náà kò mọ ọjọ́ orí Camila àtàwọn àìsàn tó ń ṣe é, ó bi ìyá rẹ̀ pé: “Kí ni ọjọ́ orí ọmọ yìí?”

Marisa tó jẹ́ ìyá Camila, dáhùn pé: “Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni.”

Dókítà náà sọ pé: “Ọmọ oṣù mẹ́jọ, àbí?”

Ìyá Camila tún dáhùn pé: “Rárá o, ọmọ ọdún mẹ́jọ ni.”

Kàyéfì lọ̀rọ̀ yìí jẹ́ fún dókítà náà, ló bá ní kí ìyá Camila àti ọmọ rẹ̀ máa bọ̀ lórí pèpéle láti wá dáhùn àwọn ìbéèrè kan. Lẹ́yìn tí ìyá Camila ti ṣàlàyé àwọn àyẹ̀wò tí àwọn dókítà ti ṣe lórí ọ̀rọ̀ Camila àti oríṣiríṣi ìtọ́jú tó ti gbà, dókítà náà sọ pé: “Àwọn abiyamọ kan wà tí wọ́n máa ń sunkún torí pé òtútù lásánlàsàn ń mú ọmọ wọn. Àmọ́ lẹ́yìn ọdún méje tí ọmọ rẹ ti ń gba ìtọ́jú lóríṣiríṣi, tó o sì ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe fún un, o ò jẹ́ kó sú ẹ. Ọgbọ́n wo lò ń dá sí i?”

Nígbà tí ìyá Camila máa fèsì ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣàlàyé fún gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ nípa ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn bí Ọlọ́run ṣe máa mú gbogbo àìsàn àti ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn, tó fi mọ́ ikú kúrò nínú ayé tuntun òdodo. (Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:3, 4) Ìyá Camila tún ṣàlàyé bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń jàǹfààní ẹgbẹ́ ará kárí ayé àti bí ìfẹ́ tí wọ́n ní láàárín ara wọn ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa fara da àdánwò àtàwọn ìṣòro míì tó tún ń jẹ yọ nígbèésí ayé.—Jòhánù 13:35.

Nígbà tí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà parí, obìnrin kan wá bá ìyá Camila, ó sì sọ̀ fún un pé kó ṣàlàyé síwájú sí i fún òun nípa àwọn nǹkan tó sọ lẹ́ẹ̀kan yẹn. Torí pé obìnrin náà fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn tó dìídì fẹ́ lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì àtàwọn nǹkan àgbàyanu tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún ìran èèyàn lọ́jọ́ iwájú nìyẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Camila ọmọ ọdún mẹ́jọ rèé pẹ̀lú Marisa ìyá rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́