ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g16 No. 1 ojú ìwé 9
  • Kí Ló Máa Ń Fa Wàhálà Nínú Ilé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Máa Ń Fa Wàhálà Nínú Ilé?
  • Jí!—2016
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jékọ́bù àti Ísọ̀ Parí Ìjà Wọn
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ẹ Wa Alaafia Ki Ẹ Si Maa Lepa rẹ̀”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Bí Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ilé
    Jí!—2016
  • Àwọn Ìbejì Tí Wọn Ò Jọra
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Jí!—2016
g16 No. 1 ojú ìwé 9
Àwọn ọmọ kan ń gbọ́ bí àwọn òbí wọn ṣe ń jiyàn

Kí Ló Máa Ń Fa Wàhálà Nínú Ilé?

OBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Saraha lórílẹ̀-èdè Gánà tí òun àti Jacob ti ṣègbéyàwó fún ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé: “A sábà máa ń bá ara wa fa ọ̀rọ̀ owó.” Sarah ṣàlàyé pé: “Inú máa ń bí mi torí pé iṣẹ́ kékeré kọ́ ni mò ń ṣe láti bójú tó ìdílé wa, àmọ́ Jacob kì í bá mi sọ nǹkan kan nípa bá a ṣe fẹ́ náwó. Nígbà míì, a kò ní bá ara wa sọ̀rọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀.”

Jacob ọkọ rẹ̀ sọ pé: “Òótọ́ ni pé àwọn ìgbà míì wà tá a máa ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí ara wa. Àìgbọ́ra-ẹni-yé ló sábà máa ń fà á àti pé a kì í bá ara wa sọ̀rọ̀ tó nítumọ̀. Nígbà míì sì rèé, wàhálà máa ń ṣẹlẹ̀ torí pé a máa ń gba ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan sódì.”

Nathan ní Íńdíà tó ṣègbéyàwó lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan tí bàbá ìyàwó rẹ̀ jágbe mọ́ ìyá ìyàwó rẹ̀. Ó ní: “Ọ̀rọ̀ náà bí ìyá ìyàwó mi nínú, ó sì bínú jáde nílé. Nígbà tí mo bi bàbá ìyàwó mi pé kí ló dé tó fi pariwo bẹ́yẹn, ńṣe ló sọ pé mò ń rí òun fín. Kí n tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, bàbá yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo mọ́ gbogbo wa.”

Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti rí i pé ọ̀rọ̀ tí kò yẹ lè bọ́ sódì lára ẹnì kejì, kó sì dá wàhálà sílẹ̀ nínú ilé. Ọ̀rọ̀ tí ẹ fi ohùn tútù bẹ̀rẹ̀ lè di èyí tí ẹ máa bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo mọ́ ara yín. Kò sẹ́ni tí kì í ṣi ọ̀rọ̀ sọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, èyí sì lè mú kí ẹnì kejì ṣi ọ̀rọ̀ náà lóye. Láìka èyí sí, ẹ lè gbádùn àlàáfíà àti ìṣọ̀kan nínú ìdílé yín.

Kí lo lè ṣe nígbà tí awuyewuye bá ṣẹlẹ̀? Àwọn nǹkan wo lẹ lè ṣe kí ìdílé tún lè pa dà wà ní àlàáfíà? Kí sì lẹ lè ṣe tí àlàáfíà fi máa jọba nínú ilé? Jọ̀wọ́ ka àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

a A ti yí àwọn orúkọ kan nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́