KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ AYÉ YÌÍ TI BÀ JẸ́ KỌJÁ ÀTÚNṢE?
Ohun Tí Àwọn Èèyàn Ń Sọ
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ni ẹ̀rù máa ń bà nítorí àwọn ìròyìn burúkú tí wọ́n ń gbọ́ lójoojúmọ́, ṣé bó ṣe máa ń rí lára tìẹ náà nìyẹn? Lọ́dún 2014, Barack Obama tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà kan sọ pé, torí pé àwọn nǹkan burúkú ni ìròyìn ń gbé jáde, ńṣe ni àwọn èèyàn rò pé “ayé yìí ń sáré tete lọ sí ìparun, kò sì sí ohun tí ẹnikẹ́ni lè ṣe sí i.”
Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó sọ àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ ṣe láti yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń bá aráyé fínra. Ó tiẹ̀ pe ìgbésẹ̀ tí àwọn ìjọba kan ń gbé ní “ìròyìn ayọ̀,” ó sì sọ pé: “Ọkàn òun balẹ̀, ìrètí òun sì dájú.” Lédè míì, ohun tó ń sọ ni pé gbogbo ìsapá tí àwọn èèyàn tó lọ́kàn rere ń ṣe lè mú kí aráyé bọ́ lọ́wọ́ àjálù tó ń bọ̀.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní irú èrò yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni àwọn kan gbẹ́kẹ̀ lé, èrò wọn ni pé ìtẹ̀síwájú tó ń lọ nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ ló máa yanjú àwọn ìṣòro tí aráyé ní. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan tiẹ̀ fi gbogbo ẹnu sọ pé tó bá máa fi di ọdún 2030, “ìmọ̀ ẹ̀rọ á ti tẹ̀síwájú lọ́nà tó gadabú, tó bá sì máa fi di ọdún 2045, ìtẹ̀síwájú náà á tún ti bùáyà ju ti ọdún 2030 lọ.” Ó tún sọ pé: “Lóòótọ́, àwọn ìṣòro aráyé kò tíì pọ̀ tó báyìí rí, àmọ́ àwọn ohun tá a lè ṣe láti yanjú wọn pọ̀ lọ súà. Torí náà, a lè sọ pé à ń gbìyànjú.”
Báwo tiẹ̀ ni ayé yìí ṣe bà jẹ́ tó gan-an? Ṣé òótọ́ ni pé àjálù ńlá kan ń bọ̀ tó máa pa gbogbo ayé run? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olóṣèlú kan àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń sọ fún àwọn èèyàn pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa, síbẹ̀, ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn kò balẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú. Kí nìdí?
Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn ìṣòro míì tó le koko tí aráyé ń kojú. Àmọ́, tó o bá kàn ń ronú ṣáá nípa àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní tàbí tó ò ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ àwọn olóṣèlú àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, ìyẹn ò ní kó o mọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí gangan. Bá a ṣe sọ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ọ̀pọ̀ ti rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè nípa ipò tí ayé yìí wà àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ibo la ti lè rí àwọn ìdáhùn náà?
ÀWỌN OHUN ÌJÀ RUNLÉ-RÙNNÀ. Ìparapọ̀ orílẹ̀-èdè àtàwọn àjọ míì ti gbìyànjú gan-an láti dín àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà kù, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn já sí. Ohun tó sì fà á ni pé, ńṣe làwọn aṣíwájú kan tí wọ́n ya ọlọ̀tẹ̀ kọ̀ láti gbárùkù ti òfin tó máa mú kí wọ́n dín àwọn ohun ìjà kù. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ní àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà kò da àwọn ohun ìjà wọn nù, ńṣe ni wọ́n tún ń ṣe àwọn bọ́ǹbù tuntun míì tó túbọ̀ lágbára sí i. Àwọn orílẹ̀-èdè tí kò tiẹ̀ ní àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà tẹ́lẹ̀ ti wá ní àwọn ohun ìjà tí wọ́n lè fi pa ọ̀pọ̀ èèyàn run.
Bí àwọn ohun ìjà yìí ṣe gbalẹ̀gbòde ti wá mú kí ayé yìí di ibi eléwu, kódà ní àkókò tó tiẹ̀ dà bíi pé àlàáfíà wà. Ìwé ìròyìn Bulletin of the Atomic Scientist sọ pé: “Ó ń kó ìdààmú ọkàn báni láti mọ̀ pé wọ́n ti fi kọ̀ǹpútà ṣe àwọn ohun ìjà kan tó lè máa pa àwon èèyàn lọ ràì láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni ló ń darí wọn.”
ÀÌSÀN Ń HAN ÀWỌN ÈÈYÀN LÉÈMỌ̀. Pẹ̀lú gbogbo bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì ṣe ń sapá tó ká lè ní ìlera tó dáa, àwa èèyàn ò yéé ṣàìsàn. Ojoojúmọ́ làwọn nǹkan tó ń fa àìsan ń pọ̀ sí i, àwọn nǹkan bí ẹ̀jẹ̀ ríru, ìlòkulò oògùn, sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ àtàwọn ohun tó ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́. Èyí sì ti fa oríṣiríṣi àìsàn tó ń ṣekú pa ọ̀pọ̀ èèyàn bí àrùn jẹjẹrẹ, àìsàn ọkàn àti ìtọ̀ ṣúgà. Àìsàn ọpọlọ àtàwọn àìsàn míì sì ti sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di aláìlera. Láwọn ọdún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá yìí, àwọn àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí míì tún jẹ yọ, bí àìsàn Ebola àti Zika. Kókó ibẹ̀ ni pé agbára ẹ̀dá èèyàn ò ká àìsàn, ó dà bíi pé àwa èèyàn ò ní yéé máa ṣàìsàn!
ÀWỌN ÈÈYÀN Ń BA AYÉ JẸ́. Ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́. Àìmọye èèyàn ló ń kú lọ́dọọdún torí àwọn gáàsì gbẹ̀mígbẹ̀mí táwọn kan ń tú sínú afẹ́fẹ́.
Àwọn èèyàn àtàwọn ilé iṣẹ́ ìjọba kan máa ń da oríṣiríṣi ìdọ̀tí sínú òkun bí omi ìdọ̀tí, oògùn, àwọn nǹkan oko, ike àtàwọn nǹkan míì. Ìwé Encyclopedia of Marine Science ṣàlàyé pé “ewu ni àwọn ìdọ̀tí tí wọ́n ń dà sínú òkun jẹ́ fún àwọn ohun ẹlẹ́mìí tó wà nínú òkun àtàwọn tó bá jẹ wọ́n.”
Bẹ́ẹ̀ sì rèé, omi gidi ṣọ̀wọ́n. Òǹṣèwé onímọ̀ sáyẹ́ńsì ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ésì tó ń jẹ́ Robin McKie sọ pé: “Gbogbo ayé pátá ni wàhálà ọ̀rọ̀ omi yìí máa kàn.” Àwọn olóṣèlú pàápàá gbà pé àwa èèyàn la fi ọwọ́ ara wa fa ìṣòro àìtó omi, èyí sì lè gbẹ̀mí àwọn èèyàn.
ÌJÁBÁ Ń ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN ÈÈYÀN. Ìmìtìtì ilẹ̀, ìjì líle àti ìjì àjàyípo ti fa àkúnya omi, ó sì ń ba ilẹ̀ àtàwọn nǹkan míì jẹ́. Àwọn nǹkan yìí ti ṣe ìpalára fún ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà tó peléke jù ti ìgbàkigbà rí lọ. Nínú ìwádìí kan tí àjọ National Aeronautics and Space Administration ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe tí wọ́n sì tẹ̀ jáde, wọ́n sọ pé “ìjì líle, àwọn ìjì tó ń móoru gan-an àti omíyalé tó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sírú ẹ̀ rí máa tó ṣẹlẹ̀.” Ṣé àwọn ìjábá yìí ló máa pa ìran ẹ̀dá èèyàn run?
Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn ìṣòro mí ì tó le koko tí aráyé ń kojú. Àmọ́, tó o bá kàn ń ronú ṣáá nípa àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní tàbí tó ò ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ àwọn olóṣèlú àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, ìyẹn ò ní kó o mọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí gangan. Bá a ṣe sọ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ọ̀pọ̀ ti rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè nípa ipò tí ayé yìí wà àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ibo la ti lè rí àwọn ìdáhùn náà?