ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g17 No. 6 ojú ìwé 12-13
  • Alhazen

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Alhazen
  • Jí!—2017
  • Ìsọ̀rí
  • Ó FẸ́ ṢE ÌSÉDÒ SÓRÍ ODÒ NÁÍLÌ
  • Ó ṢE ÌWÉ NÍPA ÌMỌ́LẸ̀
  • Ó ṢE CAMERA OBSCURA
  • ÌJÌNLẸ̀ ÌWÁDÌÍ NÍNÚ SÁYẸ́ǸSÌ
Jí!—2017
g17 No. 6 ojú ìwé 12-13

ÌTÀN ÀTIJỌ́

Alhazen

Alhazen

ǸJẸ́ o ti gbọ́ nípa Abū ‘Alī al-Ḥasan ibn al-Haytham rí? Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń pè é ní Alhazen, ìyẹn orúkọ àbísọ rẹ̀ lédè Lárúbáwá. Yálà o mọ̀ ọ́n àbí o kò mọ̀ ọ́n, ohun kan ni pé ò ń jàǹfààní lára àwọn iṣẹ́ tí ọkùnrin yìí ti ṣe. Àwọn kan sọ pé ọ̀gbẹ́ni yìí jẹ́ “òléwájú àti ọ̀kan lára àwọn èèyàn pàtàkì nínú ìtàn sáyẹ́ǹsì.”

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ

  • Nítorí àwọn ìwádìí rẹ̀ tó jinlẹ̀ àti ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ribiribi tó ṣe, àwọn kan gbà pé Alhazen ni “ojúlówó onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àkọ́kọ́ láyé.”

  • Òun ló ṣàwárí àwọn ìlànà tó pilẹ̀ fọ́tò yíyà lóde òní.

  • Lára àwọn ìwádìí ìjìnlẹ̀ to ṣe nípa gíláàsì ló jẹ́ kí àwọn onímọ̀ lè ṣe gíláàsì ojú, títí kan ẹ̀rọ microscope tí wọ́n fi ń wo àwọn ohun tíntìntín àti ẹ̀rọ telescope tí wọ́n fi ń wo àwọn nǹkan tó wà lọ́nà jíjìn.

Ìlú Basra tó wà lórílẹ̀-èdè Iraq lóde òní ní wọ́n bí Alhazen sí. Nǹkan bí ọdún 965 Sànmàní Kristẹni ni wọ́n bí i. Ìṣirò, ìṣègùn, orin, ewì, ẹ̀kọ́ físíìsì, kẹ́mísírì, ẹ̀kọ́ nipa ojú ọ̀run àti ẹ̀kọ́ nípa ìmọ́lẹ̀ wà lára àwọn nǹkan tó ṣe. Àmọ́ iṣẹ́ wo gangan la fẹ́ yìn ín fún?

Ó FẸ́ ṢE ÌSÉDÒ SÓRÍ ODÒ NÁÍLÌ

Ìtàn àtijọ́ kan sọ nípa Alhazen pé ó gbèrò láti ṣe ìsédò sórí Odò Náílì. Ìyẹn jẹ́ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún kí wọ́n tó wá ṣe iṣẹ́ náà gangan ní ìlú Aswân lọ́dún 1902.

Bí ìtàn yẹn ṣe sọ, Alhazen gbèrò pé tí òun bá lè ṣe ìsédò sórí odò Náílì, ìṣòro omíyalé àti ọ̀dá á dópin nílẹ̀ Íjíbítì. Nígbà tí Caliph al-Hakim tó jẹ́ alákòóso ìlú Cairo ìgbà yẹn gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ náà, ó pe Alhazen wá sí Íjíbítì pé kó wá ṣe ìsédò náà. Àmọ́ nígbà tí Alhazen máa fojú kan odò yẹn, ó rí i pé iṣẹ́ náà ju agbára òun lọ. Ẹ̀rù bà á pé ọba lè fìyà jẹ òun, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í díbọ́n bí ẹni pé orí òun ti yí. Torí náà, wọ́n lọ tọ́jú ẹ̀ síbì kan. Ohun tó ṣe yẹn ni kò jẹ́ kí wọ́n pa á. Lẹ́yìn ọdún mọ́kànlá, ọba yẹn kú lọ́dún 1021. Níbi tó wà yẹn, ó ráyè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan.

Ó ṢE ÌWÉ NÍPA ÌMỌ́LẸ̀

Nígbà tí wọ́n máa fi tú u sílẹ̀, Alhazen ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kọ ìwé méje tán lórí ẹ̀kọ́ físíìsì, ó pe ìwé náà ní Book of Optics, àwọn onímọ̀ sọ pé ìwé náà jẹ́ “ọ̀kan lára ìwé tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ẹ̀kọ́ físíìsì.” Inú ìwé yìí ló ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwádìí tó ṣe nípa ìmọ́lẹ̀, títí kan àlàyé nípa bí ìmọ́lẹ̀ ṣe máa tàn tí á sì pín sí oríṣiríṣi àwọ̀, bó ṣe ń tàn lára gíláàsì, àti bí ìmọ́lẹ̀ ṣe máa ń tàn láti ara nǹkan kan dé ara nǹkan míì. Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa bí ojú wa ṣe máa ń ríran, gbogbo ẹ̀yà ojú àti bó ṣe ń ṣiṣẹ́.

Nígbà tó máa fi di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹtàlá, wọ́n ti túmọ̀ àwọn ìwádìí tí Alhazen ṣe láti èdè Lárúbáwá sí èdè Latin, látìgbà yẹn lọ, ńṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù sábà máa ń tọ́ka sí àwọn ìwádìí àti iṣẹ́ rẹ̀ nínú ìwé àti ọ̀rọ̀ wọn láti fi hàn pé ọ̀gá ni. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ìwádìí Alhazen àti àkọsílẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ nípa gíláàsì àti ìmọ́lẹ̀ di ìpìlẹ̀ ohun ti àwọn èèyàn ilẹ̀ Yúróòpù ń wò ṣe gíláàsì ojú, àti awò tí wọ́n fi ń wo ohun tíntìntín àtèyí tí wọ́n fi ń wo ojú ọ̀run.

Ó ṢE CAMERA OBSCURA

Alhazen ló pilẹ̀ ìlànà tí àwọn onífọ́tò ń lò nígbà tó ṣe ohun kan tá a lè pè ní camera obscura àkọ́kọ́ nínú ìtàn. Ohun tó ṣe yìí dà bí “yàrá tó ṣókùnkùn” tó ní ihò tóóró kan tí ìmọ́lẹ̀ ń gbà wọlé, àwòrán ohun tó wà ní ìta á dà bí èyí tó dorí kodò lára ògiri inú yàrá lọ́hùn-ún.

Camera obscura

Alhazen ló ṣe ohun tá a lè pè ní camera obscura àkọ́kọ́ nínú ìtàn

Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi camera obscura ṣe fọ́tò jáde. Bó ṣe di pé àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í lo kámẹ́rà nìyẹn o. Àbẹ́ ò rí nǹkan! Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ìlànà tí camera obscura ń bá ṣiṣẹ́ tó fi lè gbé fọ́tò jáde náà ni gbogbo kámẹ́rà òde òní ń lò, títí kan ojú wa pàápàá.a

ÌJÌNLẸ̀ ÌWÁDÌÍ NÍNÚ SÁYẸ́ǸSÌ

Ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ Alhazen tó ta yọ jù lọ ni ìwádìí tó fẹ̀sọ̀ ṣe ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nípa àwọn nǹkan. Àwọn ọ̀nà tó ń gbà ṣe ìwádìí rẹ̀ ta yọ nígbà ayé rẹ̀ torí pé òun ni ẹni àkọ́kọ́ tó gbìyànjú láti dán ohun tó ń ṣe ìwádìí lé lórí wò. Kì í bẹ̀rù láti béèrè ìbéèrè lórí àwọn òfin àti ìlànà sáyẹ́ǹsì tó bá rújú, pàápàá tí kò bá rí ẹ̀rí tó dájú pé òótọ́ ni àwọn òfin àti ìlànà náà.

Ìyẹn ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní fi máa ń sọ pé: “Fi ẹ̀rí ohun tó ò ń sọ múlẹ̀ ká rí i!” Ìyẹn gan-an ni ohun tí Alhazen ṣe, ìdí nìyẹn tí àwọn kan fi gbà pé “ọ̀gá ló jẹ́ nínú kéèyàn máa wádìí jinlẹ̀ nínú sáyẹ́ǹsì.” Tá a bá wo gbogbo akitiyan rẹ̀ yìí, àá rí i pé ó yẹ ká dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ ọ̀gbẹ́ni náà.

a Ìfiwéra tí wọ́n ṣe nípa ojú àti camera obscura yìí kò fi bẹ́ẹ̀ yé àwọn èèyàn nígbà yẹn ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti Yúróòpù, àfìgbà tí ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Johannes Kepler ṣàlàyé rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹtàdínlógún.

“Ó Kọ́ Wa Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Sáyẹ́ǹsì”

Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Jim Al-Khalili pọ́n Alhazen lé gan-an nígbà tó sọ pé “kì í ṣe pé Alhazen ṣe àwárí àwọn ohun ńlá nìkan ni. . . Ó kọ́ wa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáyẹ́ǹsì.” Ìwé rẹ̀ tó kọ, ìyẹn Book of Optics jẹ́ “ojúlówó ìwé sáyẹ́ǹsì,” ó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa àwọn ìwádìí tó ṣe, àwọn ohun tó fi ṣe ìwádìí náà, títí kan gbogbo ìṣirò tó ṣe àti àbájáde ìwádìí rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́