ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g18 No. 1 ojú ìwé 12-13
  • Ìgbésí Ayé Tó Nítumọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbésí Ayé Tó Nítumọ̀
  • Jí!—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹlẹ́dàá Lè Mú Kí Ayé Rẹ Nítumọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ṣé Ayé àti Ọ̀run Ní Ìbẹ̀rẹ̀?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Báwo Ni Àgbáálá Ayé àti Ìwàláàyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀?
    Jí!—2002
  • Ta Ni Ó Lè Sọ Fun Wa?
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
Àwọn Míì
Jí!—2018
g18 No. 1 ojú ìwé 12-13
Ọkùnrin kan ń ronú nípa ìdí tó fi wà láyé

OHUN TÓ Ń FÚNNI LÁYỌ̀

Ìgbé Ayé Tó Nítumọ̀

Ọ̀PỌ̀ Ọ̀NÀ NI ÀWA ÈÈYÀN GBÀ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀​—A MÁA Ń KỌ̀WÉ, A MÁA Ń YÀWÒRÁN, A MÁA Ń ṢẸ̀DÁ NǸKAN, A SÌ MÁA Ń RONÚ NÍPA ÀWỌN ÌBÉÈRÈ PÀTÀKÌ NÍPA ÌGBÉSÍ AYÉ BÍI: Kí nìdí tí àgbàyé yìí fi wà? Ibo ni àwa èèyàn ti ṣẹ̀ wá? Kí nìdí tá a fi wà láyé? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la?

Àwọn kan kì í fẹ́ béèrè irú àwọn ìbéèrè yìí, wọ́n gbà pé ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí kọjá òye wa. Àwọn kan sọ pé àwọn ìbéèrè yẹn ò bọ́gbọ́n mu rárá, torí wọ́n gbà pé ńṣe ni gbogbo nǹkan ṣàdédé wà. Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìtàn àtàwọn ohun alààyè kan tó ń jẹ́ William Provine sọ pé: “Kò sí Ọlọ́run kan níbì kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sídìí pàtàkì kan tá a fi wà láyé.” Ó tún sọ pé: “Mi ò gbà pé ìlànà pàtó kan wà tó yẹ káwa èèyàn máa tẹ̀ lé, ìgbésí ayé ò sì já mọ́ nǹkan kan.”

Àwọn kan ò fara mọ́ ohun tí ọ̀jọ̀gbọ́n yìí sọ rárá. Wọ́n gbà pé ńṣe ni àwọn nǹkan tó wà láyé àti lójú ọ̀run wà létòlétò àti pé àwọn ìlànà pàtó kan ló ń darí wọn. Enu máa ń yà wọ́n tí wọ́n bá ń wo àwọn ohun àrà tó wà láyé, àwọn ohun àrà yìí sì làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ máa ń wò láti fi ṣe àwọn nǹkan. Àwọn nǹkan àgbàyanu tí wọ́n ń rí lójoojúmọ́ tún ń jẹ́ kí wọ́n rí i pé ọlọ́gbọ́n àti olóye kan ló ṣe àwọn iṣẹ́ àrà náà, kì í ṣe pé wọ́n ṣàdédé wà.

Àwọn tó ti fìgbà kan rí gbà pé ohun gbogbo tó wà láyé ṣàdédé wà ti wá tún èrò wọn pa báyìí. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì yìí.

ALEXEI MARNOV TÓ JẸ́ ONÍṢẸ́ ABẸ ỌPỌLỌ sọ pé: “Ní ilé ẹ̀kọ́ tí mo lọ, wọ́n kọ́ wa pé kò sí Ọlọ́run àti pé ńṣe ni gbogbo nǹkan tó wà láyé ṣàdédé wà. Tí ẹnì kan bá sì sọ pé òun gbà pé Ọlọ́run wà, ńṣe ni wọ́n máa ń kà á sí ẹni tí kò dákan mọ̀.” Àmọ́ lọ́dún 1990, ó bẹ̀rẹ̀ sí í yí èrò rẹ̀ pa dà.

Dókítà yìí sọ pé: “Mo máa ń fẹ́ láti mọ ìdí tó bọ́gbọ́n mu tí àwọn nǹkan fi rí bí wọ́n ṣe rí, títí kan ọpọlọ èèyàn. Àwọn onímọ̀ gbà pé ọpọlọ èèyàn ló jẹ́ ohun àrà jù lọ láyé yìí. Àmọ́, ṣé gbogbo nǹkan tí ọpọlọ wà fún kò ju pé kéèyàn fi kẹ́kọ̀ọ́, kó fi kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe oríṣiríṣi nǹkan, kí ọpọlọ náà sì wá kú? Mi ò gbà pé èyí bọ́gbọ́n mu rárá. Ìyẹn ló mú kí ń bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì pé: ‘Kí nìdí tá a fi wà láyé?’ Lẹ́yìn tí mo ronú dáadáa lórí ọ̀rọ̀ yìí, mo wá gbà pé Ọlọ́run wà.”

Torí pé Alexei fẹ́ mọ ìdí tá a fi wà láyé, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, ìyàwó ẹ̀ tí òun náà jẹ́ dókítà tí kò sì gbà pé Ọlọ́run wà, bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ohun tó kọ́kọ́ mú kó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé ó fẹ́ fi yé ọkọ rẹ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run wà! Àmọ́ ní báyìí, àwọn méjèèjì ti wá ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọlọ́run, wọ́n sì ti lóye ohun tí Iwé Mímọ́ sọ nípa ìdí tá a fi wà láyé.

HUABI YIN TÓ JẸ́ ONÍMỌ̀ ÌJÌNLẸ̀. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Huabi Yin kẹ́kọ̀ọ́ nípa physics, ó sì fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣe ìwádìí nípa oòrùn.

Ó sọ pé: “Nígbàkigbà táwa onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá ń ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan tó wà láyé àti lójú ọ̀run, a máa ń rí i pé gbogbo wọn wà létòlétò àti pé ó ní ìlànà pàtó tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Mo máa ń ṣe kàyéfì pé: ‘Tá lo fi àwọn ìlànà yìí lélẹ̀?’ ‘Tó bá jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ máa bójú tó iná tá a fi ń se oúnjẹ lásán kó má bàa pọ̀ jù, ta wá lẹni tó ń bojú tó oòrùn tó fi jẹ́ pé kì í ṣiṣẹ́ kọjá àyè?’ Nígbà tó yá, mo wá gbà pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n pátápátá ni ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì, èyí tó sọ pé: ‘Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.’ ”​—Jẹ́nẹ́sísì 1:1.

Òótọ́ ni pé, sáyẹ́ǹsì ti jẹ́ ká rí ìdáhùn sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa bí àwọn nǹkan ṣe ń ṣiṣẹ́, irú bíi: Báwo ni àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ọpọlọ ṣe ń ṣiṣẹ́? Báwo ni oòrùn ṣe ń mú ooru àti ìmọ́lẹ̀ jáde? Àmọ́ Alexei àti Huabi ti wá rí i pé Bíbélì ló dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù, irú bíi: Kí nìdí tí àgbáyé yìí fi wà? Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìlànà ni àwọn nǹkan tó wà láyé àti lójú ọ̀run ń tẹ̀ lé? Kí la wá ṣe láyé?

Bíbélì sọ nípa ayé yìí pé, ‘Ọlọ́run kò wulẹ̀ dá a lásán, ṣùgbọ́n ó ṣẹ̀dá rẹ̀ kí a lè máa gbé inú rẹ̀.’ (Aísáyà 45:18) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí i pé ó ní ìdí pàtàkì tí Ọlọ́run fi dá ayé, àwọn nǹkan tí Ọlọ́run sì máa ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ọjọ́ ọ̀la wa máa dára gan-an.

KÓKÓ PÀTÀKÌ

‘Ọlọ́run kò wulẹ̀ dá ayé lásán, ṣùgbọ́n ó ṣẹ̀dá rẹ̀ kí a lè máa gbé inú rẹ̀.’​—Aísáyà 45:18.

“A gbọ́dọ̀ ní ohun gidi kan tá à ń fi ayé wa ṣe”

Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìwà àti ìrònú ẹ̀dá tó ń jẹ́ William McDougall sọ pé: “Tá a bá fẹ́ kí ara wa yá gágá kí ọpọlọ wa sì jí pépé, a gbọ́dọ̀ ní ohun gidi kan tá à ń fi ayé wa ṣe. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Carol Ryff, tí òun náà jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìwà àti ìrònú ẹ̀dá sọ pé, àwọn tó bá “ní ohun gidi tí wọ́n ń fi ayé wọn ṣe máa ń ní ìlera tó dáa gan-an. Ọpọlọ wọn sábà máa ń jí pépé . . . , wọn kì í sábà ní àrùn ọkàn, ara wọn máa ń tètè yá tí wọ́n bá ní àìsàn rọpárọsẹ̀ . . . ẹ̀mí wọn sì máa ń gùn dé ìwọ̀n àyè kan.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́