Máa Wo Ìwà Rere Táwọn Èèyàn Ní
Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro
Ìgbéraga lè mú kéèyàn kórìíra àwọn ẹlòmíì. Ẹni tó ń gbéra ga máa ń ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Ó máa ń wo ara ẹ̀ pé òun dáa ju àwọn mìí lọ, ó sì gbà pé ẹni tó bá ti yàtọ̀ sóun ò já mọ́ nǹkan kan. Kò sẹ́ni tí kò lè ní ẹ̀mí ìgbéraga. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopædia Britannica sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ẹ̀yà ló máa ń ronú pé ìgbé ayé wọn, oúnjẹ, aṣọ, ìwà àti ìṣe, ohun tí wọ́n gbà gbọ́, ohun tí wọ́n kà sí pàtàkì àtàwọn nǹkan míì tó jẹ́ tiwọn dáa ju ti àwọn ẹ̀yà yòókù lọ.” Báwo lá ṣe lè yẹra fún èrò tí kò dáa yìí?
Ìlànà Bíbélì
“Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.”—FÍLÍPÌ 2:3.
Kí la rí kọ́? Ká bàa lè yẹra fún ìgbéraga, ó pọn dandan ká kọ́ bá a ṣe lè ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀. Ìrẹ̀lẹ̀ máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹlòmíì sàn jù wá lọ láwọn ọ̀nà kan. Kò sí ẹ̀yà kan tó ní gbogbo ìwà tó dáa tán.
Wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Stefan. Orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti ń ṣe ìjọba orí-ò-jorí ló dàgbà sí, àmọ́ ó borí ẹ̀tanú tó ní sáwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè ti kì í ṣe ti ìjọba orí-ò-jorí. Ó ní: “Téèyàn bá gbà pé àwọn míì sàn ju òun lọ, ìyẹn lohun pàtàkì táá jẹ́ kó borí ẹ̀tanú àti ìkórìíra. Gbogbo nǹkan kọ́ ni mo mọ̀. Mo lè rí nǹkan kọ́ lọ́dọ̀ gbogbo èèyàn.”
Ohun Tó O Lè Ṣe
Má ṣe ro ara ẹ ju bó ṣe yẹ lọ, kó o sì máa rántí pé ìwọ náà máa ń ṣàṣìṣe. Fi sọ́kàn pé àwọn ẹlòmíì lè ṣe àwọn nǹkan kan lọ́nà tó dáa ju tìẹ lọ. Má sì rò pé àbùkù kan náà ni gbogbo èèyàn tó wá láti ẹ̀yà kan ní.
Dípò kó o máa fojú burúkú wo ẹnì kan tó wá látinú ẹ̀yà kan, bi ara ẹ pé:
Fi sọ́kàn pé àwọn ẹlòmíì lè ṣe àwọn nǹkan kan lọ́nà tó dáa ju tìẹ lọ
‘Ṣé ìwà ẹni náà burú lóòótọ́, àbí ọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan ló kàn yàtọ̀?’
‘Ṣé èmi náà ò ní àléébù tóun náà lè tọ́ka sí?’
‘Àwọn ọ̀nà wo ni ẹni náà gbà sàn jù mí lọ?’
Tó o bá fi òótọ́ inú dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn, wàá borí ìkórìíra tó o ní sí ẹni náà, wàá sì tún rí àwọn nǹkan míì tó máa wù ẹ́ nínú ìwà ẹni náà.