ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • dg apá 1 ojú ìwé 2-3
  • Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ìbéèrè Kẹta: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Jẹ́ Kí Ìyà Máa Jẹ Mí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ayé Kan Ti O Bọ́ Lọwọ Ijiya
    Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
Àwọn Míì
Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
dg apá 1 ojú ìwé 2-3

Apa 1

Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?

1, 2. Ibeere wo ni awọn eniyan ń beere nipa Ọlọrun, eesitiṣe?

NI AKOKO kan ninu igbesi-aye rẹ, iwọ ti lè beere pe: ‘Bi Ọlọrun kan ti o bikita nipa wa niti gidi bá wà, eeṣe ti oun fi fayegba ijiya pupọ tobẹẹ?’ Gbogbo wa ni o ti niriri ijiya tabi ki a mọ ẹnikan ti ó ti ṣe bẹẹ.

2 Niti tootọ, jakejado inu itan awọn eniyan ti jiya irora ati ẹdun ọkan lati ọwọ ogun, iwa ìkà, iwa ọdaran, aiṣedajọ ododo, òṣì, aisan, ati iku awọn ololufẹ ẹni. Ni ọrundun 20 tiwa nikan, ogun ti pa eyi ti o ju 100 million eniyan lọ. Araadọta ọkẹ lọna ọgọrọọrun awọn miiran ni a ti palara tabi ni wọn ti padanu ibugbe ati awọn dukia. Ọpọlọpọ awọn ohun buburu jai ni wọn ti ṣẹlẹ ni ìgbà tiwa, ti wọn ti yọrisi irora ńláǹlà, ọpọlọpọ omije, ati imọlara ainireti niha ọdọ ọ̀kẹ́ aimọye eniyan.

3, 4. Bawo ni ọpọ ṣe ní imọlara nipa fifi ti Ọlọrun fayegba ijiya?

3 Awọn kan kun fun ikoro ọkan wọn si lero pe bi Ọlọrun kan bá wà, oun kò bikita nipa wa niti gidi. Tabi ki wọn tilẹ ni imọlara pe Ọlọrun kò sí. Fun apẹẹrẹ, ọkunrin kan ti o jiya lọwọ inunibini ti ẹ̀yà kan si ikeji eyi ti o ṣokunfa iku awọn ọ̀rẹ́ ati idile ninu Ogun Agbaye I beere pe: “Nibo ni Ọlọrun wa nigba ti a nilo rẹ̀?” Omiran, ti o la ipakupa awọn araadọta ọkẹ lati ọwọ awọn Nazi nigba Ogun Agbaye II já, ni ijiya naa kó ẹ̀dùn bá tobẹẹ gẹẹ ti o fi wi pe: “Bi iwọ bá lè pọ́n ọkan-aya mi lá, yoo jẹ́ majele fun ọ.”

4 Nipa bayii, ọpọ ni kò lè loye idi ti Ọlọrun rere kan yoo fi gba awọn ohun buburu laaye lati ṣẹlẹ. Wọn gbe ibeere dide nipa boya oun bikita nipa wa niti gidi tabi boya oun tilẹ wà rara. Pupọ ninu wọn sì ro pe ijiya yoo maa figba gbogbo baa lọ lati jẹ́ apakan ìgbesi-ayé araye.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2, 3]

Ayé titun kan ti o bọ́ lọwọ ijiya ha sunmọle bi?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́