ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • dg apá 2 ojú ìwé 3-4
  • Ayé Kan Ti O Bọ́ Lọwọ Ijiya

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayé Kan Ti O Bọ́ Lọwọ Ijiya
  • Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
    Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin Láìpẹ́!
    Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin Láìpẹ́!
  • Àǹfààní Wà Nínú Kéèyàn Fara Da Ìjìyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
dg apá 2 ojú ìwé 3-4

Apa 2

Ayé Kan Ti O Bọ́ Lọwọ Ijiya

1, 2. Oju-iwoye ti o yatọ wo ni ọpọlọpọ ni?

BIOTIWUKIORI, araadọta ọkẹ eniyan jakejado aye ni oju-iwoye ti o yatọ patapata si eyi. Wọn rí ọjọ ọla agbayanu kan fun iran eniyan niwaju. Wọn sọ pe nihin yii gan an lori ilẹ̀-ayé laipẹ aye kan ti o bọ́ patapata lọwọ iwa buburu ati ijiya yoo wà. O da wọn loju pe awọn ohun ti o buru ni a o palẹ rẹ̀ mọ kuro laipẹ ti ayé titun patapata gbaa kan yoo si di eyi ti a fi idi rẹ̀ mulẹ. Wọn tilẹ sọ pe ìpìlẹ̀ ayé titun yii ni a ti ń fi lélẹ̀ lọwọlọwọ bayii!

2 Awọn eniyan wọnyi gbagbọ pe ayé titun naa yoo bọ lọwọ ogun, iwa ìkà, iwa ọdaran, aiṣedajọ ododo, ati òṣì. Yoo jẹ ayé kan laisi aisan, irora, omije, ati iku paapaa. Ni ìgbà naa awọn eniyan yoo dagba dé ijẹpipe wọn yoo si gbe titi lae ninu ayọ ninu paradise ilẹ̀-ayé kan. Họwu, awọn wọnni ti wọn ti ku ni a o tilẹ tun ji dide ti wọn yoo si ni anfaani lati walaaye titi lae!

3, 4. Eeṣe ti iru awọn eniyan bẹẹ fi ni idaniloju nipa oju-iwoye wọn?

3 Oju-iwoye yii nipa ọjọ ọla ha wulẹ jẹ àlá kan lasan, ohun ti a wulẹ fọkanfẹ bi? Bẹẹkọ, rara. A gbe e kari igbagbọ ti o fẹsẹmulẹ pe Paradise ti ń bọ lọna yii daju. (Heberu 11:⁠1) Eeṣe ti o fi dá wọn loju tobẹẹ? Nitori pe olodumare Ẹlẹdaa agbaye ni o ṣeleri rẹ̀.

4 Nipa ti awọn ileri Ọlọrun, Bibeli wi pe: “Kò si ohun kan ti o tase ninu ohun rere gbogbo ti OLUWA [“Jehofa,” NW] Ọlọrun yin ti sọ niti yin; gbogbo rẹ̀ ni o ṣẹ fun yin, kò si si ohun ti o tase ninu rẹ̀.” “Ọlọrun ki iṣe eniyan ti yoo fi ṣeke . . . a ma a wi, ki o má si ṣe e bi? Tabi a maa sọ̀rọ̀ ki o má mu un ṣẹ?” “Oluwa [“Jehofa,” NW] awọn ọmọ-ogun ti bura, wi pe, Lootọ gẹgẹ bi mo ti gbèrò, bẹẹni yoo ri, ati gẹge bi mo ti pinnu, bẹẹni yoo si duro.”​—⁠Joṣua 23:14; Numeri 23:⁠19; Isaiah 14:⁠24.

5. Awọn ibeere wo ni o ń fẹ idahun?

5 Bi o ti wu ki o ri, bi o bá jẹ ete Ọlọrun ni lati gbe paradise ilẹ̀-ayé kan ti o bọ lọwọ ijiya kalẹ, eeṣe ti oun fi fayegba awọn ohun buburu lati maa ṣẹlẹ lakọọkọ ná? Eeṣe ti oun fi duro fun ẹgbẹrun ọdun mẹfa titi di isinsinyi lati ṣatunṣe ohun ti o ṣaitọ? Gbogbo awọn ọrundun ijiya wọnyẹn ha lè tọkasi pe Ọlọrun kò bikita nipa wa niti gidi, tabi koda pe oun kò si rara bi?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́