APÁ 3
Yíyan Ọ̀rẹ́
Báwo ni níní ọ̀rẹ́ ṣe ṣe pàtàkì tó lójú ẹ?
□ Kò ṣe pàtàkì
□ Ó ṣe pàtàkì díẹ̀
□ Ó ṣe pàtàkì gan-an
Ṣó máa ń rọrùn fún ẹ láti báwọn èèyàn ṣọ̀rẹ́?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ṣó o ní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ànímọ́ wo ló máa wù ẹ́ jù lọ pé kí ọ̀rẹ́ rẹ ní?
Bíbélì sọ pé “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Irú alábàákẹ́gbẹ́ tó yẹ ẹ́ nìyẹn! Àmọ́, ọ̀tọ̀ ni wíwá ẹni bá ṣọ̀rẹ́, ọ̀tọ̀ tún ni kírú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ tọ́jọ́. Báwo wa lo ṣe lè rí ọ̀rẹ́ àtàtà tẹ́ ẹ jọ máa bára yín ṣọ̀rẹ́ pẹ́? Gbé ìmọ̀ràn tó wà ní Orí 9 sí 12 nínú ìwé yìí yẹ̀ wò.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 84, 85]