ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ó Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • ORÍ KẸẸ̀Ẹ́DÓGÚN

      Ó Gbèjà Àwọn Èèyàn Ọlọ́run

      1-3. (a) Kí nìdí tí ẹ̀rù fi lè máa ba Ẹ́sítérì nígbà tó fẹ́ lọ rí ọkọ rẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nípa Ẹ́sítérì?

      Ẹ́SÍTÉRÌ gbìyànjú láti ṣọkàn akin bó ṣe ń sún mọ́ àgbàlá tó wà nínú ààfin Ṣúṣánì. Àmọ́ kò rọrùn. Gbogbo ohun tó wà nínú ààfin náà ni wọ́n ṣe lọ́nà táá mú kéèyàn máa kọ hà. Wọ́n gbẹ́ àwọn màlúù abìyẹ́, àwọn tafàtafà àtàwọn kìnnìún aláwọ̀ mèremère tí wọ́n fi bíríkì dídán ṣe sí ara ògiri. Àwọn òpó aláràbarà tí wọ́n fi òkúta ṣe àtàwọn ère gàgàrà wà níbẹ̀. Kódà, ibi tí ààfin náà wà tún kàmàmà. Ó wà lórí àwọn ibi gíga tó wà nítòsí àwọn Òkè Ságírọ́sì tí yìnyín bò, ó sì dojú kọ odò Choaspes tí omi inú rẹ̀ mọ́ gaara. Gbogbo iṣẹ́ ọnà yìí máa ń jẹ́ kí àlejò kọ̀ọ̀kan tó bá wá sí ààfin mọ bí agbára ọkùnrin tí Ẹ́sítérì ń lọ bá yìí ṣe pọ̀ tó, ìyẹn ọba tó pe ara rẹ̀ ní “ọba ńlá.” Òun náà sì tún ni ọkọ rẹ̀.

      2 Ọkọ rẹ̀ kẹ̀! Ahasuwérúsì yìí yàtọ̀ pátápátá sí irú ọkùnrin tí ọmọbìnrin Júù èyíkéyìí tó jẹ́ olùfọkànsìn máa fẹ́ fi ṣe ọkọ!a Kò dà bíi Ábúráhámù, tó fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún un pé kó fetí sí Sárà, aya rẹ̀. (Jẹ́n. 21:12) Tí ọba yìí bá tiẹ̀ mọ̀ nípa Jèhófà, Ọlọ́run Ẹ́sítérì, tàbí Òfin rẹ̀, ohun tó mọ̀ kò tó nǹkan kan. Àmọ́, Ahasuwérúsì mọ òfin ilẹ̀ Páṣíà dáadáa, títí kan èyí tó ka ohun tí Ẹ́sítérì fẹ́ lọ ṣe yìí léèwọ̀. Kí ni òfin náà? Ohun tí òfin yẹn sọ ni pé kí wọ́n pa ẹnikẹ́ni tó bá tọ ọba Páṣíà wá láìjẹ́ pé ọba tí kọ́kọ́ sọ fún un pé kó wá. Ní ti Ẹ́sítérì, ọba kọ́ ló ní kó wá, àmọ́ ó ti gbéra báyìí, ó sì ti ń gba ọ̀dọ̀ ọba lọ. Bó ṣe ń sún mọ́ àgbàlá inú lọ́hùn-ún, níbi tí ọba ti máa rí i látorí ìtẹ́, ó lè ti máa rò pé wọ́n máa pa òun.—Ka Ẹ́sítérì 4:11; 5:1.

      3 Kí nìdí tí Ẹ́sítérì fi fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu lọ́nà yẹn? Kí la sì lè rí kọ́ látinú ìgbàgbọ́ obìnrin àtàtà yìí? Lákọ̀ọ́kọ́ náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Ẹ́sítérì ṣe dé ipò ayaba ilẹ̀ Páṣíà, èyí tó jẹ́ ipò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

      Ìgbà Kékeré Ẹ́sítérì

      4. Kí la mọ̀ nípa ìgbà kékeré Ẹ́sítérì? Kí ló fà á tó fi wá ń gbé lọ́dọ̀ Módékáì tó jẹ́ ìbátan rẹ̀?

      4 Ọmọ òrukàn ni Ẹ́sítérì. A ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa àwọn òbí tó sọ ọ́ ní Hádásà, ìyẹn ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “igi mátílì,” ìyẹn igi kékeré tó ní òdòdó funfun tó fani mọ́ra. Nígbà tí àwọn òbí Ẹ́sítérì kú, ọ̀kan lára àwọn ìbátan rẹ̀, ìyẹn ọkùnrin onínúure kan tó ń jẹ́ Módékáì, ló bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú rẹ̀. Èèyàn òbí Ẹ́sítérì ni Módékáì, àmọ́ ó ju Ẹ́sítérì lọ dáadáa. Ó ní kí Ẹ́sítérì wá máa gbé lọ́dọ̀ òun, ó sì mú un bí ọmọ tirẹ̀.—Ẹ́sít. 2:5-7, 15.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 126]

      Inú Módékáì á máa dùn bí Ẹ́sítérì tó dà bí ọmọ fún un ṣe ń tọ́jú rẹ̀

      5, 6. (a) Báwo ni Módékáì ṣe tọ́ Ẹ́sítérì dàgbà? (b) Báwo ni nǹkan ṣe rí fún Ẹ́sítérì àti Módékáì ní Ṣúṣánì?

      5 Módékáì àti Ẹ́sítérì wà lára àwọn Júù tó wà ní ìgbèkùn. Ṣúṣánì tó jẹ́ olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Páṣíà ni wọ́n ń gbé, ó sì ṣeé ṣe kí àwọn ará ibẹ̀ máa ṣe ẹ̀tanú sí wọn nítorí ẹ̀sìn wọn àti Òfin tí wọ́n ń tẹ̀ lé torí pé wọ́n jẹ́ Júù. Àmọ́ ó dájú pé Ẹ́sítérì túbọ̀ sún mọ́ Módékáì. Ìdí ni pé ìbátan rẹ̀ yìí ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú tó ti gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìṣòro lọ́pọ̀ ìgbà nígbà àtijọ́, tó sì tún máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Léf. 26:44, 45) Ó ṣe kedere pé Ẹ́sítérì àti Módékáì fẹ́ràn ara wọn, wọ́n sì ń fi inú kan bá ara wọn lò.

      6 Àfàìmọ̀ ni kò fi ní jẹ́ pé Módékáì wà lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba ní Ṣúṣánì. Òun àtàwọn ìránṣẹ́ ọba míì máa ń jókòó sí ẹnu ibodè tó wọ ààfin déédéé. (Ẹ́sít. 2:19, 21; 3:3) A kò fi bẹ́ẹ̀ mọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ẹ́sítérì ń dàgbà, àmọ́ ó dájú pé ó tọ́jú Módékáì tó kù ní baba fún un dáadáa, ó sì ń ṣètọ́jú ilé. Ó jọ pé apá ibi tí àwọn tálákà ń gbé, ní òdìkejì odò tó ṣàn gba ààfin kọjá, ni ilé wọn wà. Ó ṣeé ṣe kó fẹ́ràn láti máa lọ sí ọjà tó wà ní Ṣúṣánì, níbi tí àwọn alágbẹ̀dẹ tó ń fi góòlù àti fàdákà ṣe ohun ọ̀ṣọ́ àti àwọn oníṣòwò pàtẹ ọjà wọn sí. Kò sí ohun tó máa mú kí Ẹ́sítérì ronú pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí òun á ní ànító àti àníṣẹ́kù àwọn ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye yẹn. Kò mọ bí ìyípadà tó ń bọ̀ wá dé bá ìgbésí ayé rẹ̀ á ṣe pọ̀ tó.

      Ó “Lẹ́wà ní Ìrísí”

      7. Kí nìdí tí ọba fi yọ Fáṣítì kúrò nípò ayaba? Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

      7 Lọ́jọ́ kan, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í rojọ́ kiri nípa ọ̀rọ̀ kan tó ń jà ràn-ìn ní ààfin ọba ní Ṣúṣánì. Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ahasuwérúsì Ọba se àsè ńlá kan tó sì fi oúnjẹ àti ọtí wáìnì rẹpẹtẹ kó àwọn ìjòyè rẹ̀ lẹ́nu jọ, ó ránṣẹ́ pe Fáṣítì ayaba rẹ̀ tó rẹwà. Fáṣítì náà wà níbi tó ti ń ṣe àríyá pẹ̀lú àwọn obìnrin, àmọ́ ó kọ̀ láti jẹ́ ìpè ọba. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ti ọba lójú gan-an, ó sì mú inú bí i. Torí náà, ó ní kí àwọn agbani-nímọ̀ràn òun sọ ìyà tí wọ́n rò pé ó tọ́ kí òun fi jẹ Fáṣítì. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn? Ńṣe ni ọba yọ ọ́ kúrò ní ipò ayaba. Àwọn ìránṣẹ́ ọba wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri ilẹ̀ náà láti wá àwọn wúńdíá tó rẹwà, kí ọba lè yan èyí tó máa jẹ́ ayaba tuntun lára wọn.—Ẹ́sít. 1:1–2:4.

      8. (a) Bí Ẹ́sítérì ṣe ń dàgbà, kí ló lè mú kí Módékáì máà ṣàníyàn nípa rẹ̀? (b) Báwo lo ṣe rò pé a lè fi òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ nípa ẹwà ojú sílò? (Tún wo Òwe 31:30.)

      8 Ó ṣeé ṣe kí orí Módékáì máa wú ní gbogbo ìgbà tó bá ṣáà ti ń rí Ẹ́sítérì. Àmọ́ lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún lè máa ṣàníyàn ní báyìí tí ọmọ èèyàn rẹ̀ kékeré ọjọ́sí yìí ti wá dàgbà di òrékelẹ́wà tí kò lẹ́gbẹ́. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọ̀dọ́bìnrin náà sì rẹwà ní wíwò, ó sì lẹ́wà ní ìrísí.” (Ẹ́sít. 2:7) Bíbélì ò bẹnu àtẹ́ lu ẹwà ojú, àmọ́ ó sọ pé ó yẹ kéèyàn ní ọgbọ́n àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè mú kéèyàn jọra ẹ lójú, kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, tàbí kéèyàn máa hu àwọn ìwà míì tí kò dára. (Ka Òwe 11:22.) Ṣé ìwọ náà gbà pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn? Àmọ́, irú èèyàn wo ni ẹwà máa sọ Ẹ́sítérì dà, ṣé ó máa wúlò fún un ni àbí ó máa ṣàkóbá fún un? Ọjọ́ iwájú ló máa sọ.

      9. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ọba rí Ẹ́sítérì? Kí nìdí tó fi máa ṣòro fún Ẹ́sítérì láti fi Módékáì sílẹ̀? (b) Kí nìdí tí Módékáì fi gbà pé kí Ẹ́sítérì fẹ́ ẹni tí kì í ṣe Júù, tó tún jẹ́ abọ̀rìṣà? (Tún wo àpótí.)

      9 Àwọn ìránṣẹ́ ọba rí Ẹ́sítérì pé ó jẹ́ arẹwà, wọ́n sì kó o mọ́ àwọn arẹwà yòókù tí wọ́n rí. Bó ṣe di pé wọ́n mú un kúrò lọ́dọ̀ Módékáì nìyẹn, tí wọ́n sì mú un lọ sí ààfin ńlá tó wà ní òdìkejì odò. (Ẹ́sít. 2:8) Ó dájú pé ó máa ṣòro fún àwọn méjèèjì láti ya ara wọn, torí pé ńṣe ni wọ́n dà bíi bàbá àti ọmọ. Kò ní wu Módékáì pé kí Ẹ́sítérì tó dà bí ọmọ fún un yìí fẹ́ aláìgbàgbọ́, kódà kó jẹ́ ọba, àmọ́ ọ̀rọ̀ náà kọjá agbára rẹ̀.b Ó dájú pé gbogbo ìmọ̀ràn tí Módékáì fún Ẹ́sítérì ló máa fetí sí dáadáa kó tó di pé wọ́n mú un lọ. Bí wọ́n ṣe ń mú un lọ sí ààfin tó wà ní Ṣúṣánì, oríṣiríṣi ìbéèrè lá máa jà gùdù lọ́kàn rẹ̀. Báwo ni nǹkan á ṣe rí fún un tó bá débẹ̀?

      Ó Rí ‘Ojú Rere Gbogbo Àwọn Tó Ń Rí I’

      10, 11. (a) Kí ló lè yára ṣẹlẹ̀ sí Ẹ́sítérì ní àyíká tuntun tó bá ara rẹ̀ yìí? (b) Báwo ni Módékáì ṣe fi hàn pé ọ̀ràn Ẹ́sítérì jẹ òun lógún?

      10 Ẹ́sítérì bá ara rẹ̀ ní ibi tí kò dé rí, tó sì tún yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ó wà láàárín “àwọn ọ̀dọ́bìnrin púpọ̀” tí wọ́n ṣà jọ jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Páṣíà. Àṣà, èdè àti ìwà wọn máa yàtọ̀ síra gan-an ni. Wọ́n fi àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà sábẹ́ àbójútó ìránṣẹ́ ọba kan tó ń jẹ́ Hégáì, kí wọ́n lè fún gbogbo wọn ní ìtọ́jú ẹwà fún odindi ọdún kan gbáko. Èyí gba pé kí wọ́n máa fi àwọn òróró tó ń ta sánsán wọ́ra fún wọn. (Ẹ́sít. 2:8, 12) Ibi tí àwọn ọ̀dọ́bìnrin yìí wà àti irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé níbẹ̀ lè mú kí ọ̀rọ̀ ìrísí ara yára gbà wọ́n lọ́kàn. Ó lè mú kí wọ́n máa bára wọn díje kí wọ́n sì jọra wọn lójú. Kí nìyẹn mú kí Ẹ́sítérì ṣe?

      11 Kò sí ẹni tí ọ̀rọ̀ Ẹ́sítérì máa jẹ́ lógún tó Módékáì. Bíbélì sọ pé ojoojúmọ́ ló máa ń lọ sí itòsí ilé àwọn obìnrin. Ó máa ń sún mọ́ ibẹ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, kó lè mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún Ẹ́sítérì. (Ẹ́sítérì 2:11) Bí àwọn ìránṣẹ́ tó gba ti Módékáì ní agboolé ọba ṣe ń fún un ní ìsọfúnni díẹ̀díẹ̀ nípa Ẹ́sítérì, ńṣe ni orí rẹ̀ á máa wú. Kí nìdí?

      12, 13. (a) Báwo ni àwọn tó sún mọ́ Ẹ́sítérì ṣe ń ṣe sí i? (b) Kí nìdí tí inú Módékáì á fi dùn nígbà tó gbọ́ pé Ẹ́sítérì ò tíì jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé Júù ni òun?

      12 Inú Hégáì dùn sí Ẹ́sítérì débi pé ó ṣe ojú rere tó pọ̀ gan-an sí i, ó fún un ní ìránṣẹ́bìnrin méje àti ibi tó dára jù lọ nínú ilé àwọn obìnrin. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Ní gbogbo àkókò yìí, Ẹ́sítérì ń bá a lọ ní jíjèrè ojú rere ní ojú gbogbo àwọn tí ó bá rí i.” (Ẹ́sít. 2:9, 15) Ṣé torí ẹwà nìkan ni gbogbo èèyàn ṣe fẹ́ràn Ẹ́sítérì tó bẹ́ẹ̀? Rárá o, ohun míì wà tó mú kí wọ́n fẹ́ràn Ẹ́sítérì.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 128, 129]

      Ẹ́sítérì mọ̀ pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ọgbọ́n ṣe pàtàkì gan-an ju ẹwà ara lọ

      13 Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Ẹ́sítérì kò tíì sọ nípa àwọn ènìyàn rẹ̀ tàbí nípa àwọn ìbátan rẹ̀, nítorí Módékáì fúnra rẹ̀ ti gbé àṣẹ kalẹ̀ fún un pé kí ó má sọ.” (Ẹ́sít. 2:10) Módékáì ti sọ fún ọmọbìnrin náà pé kò gbọ́dọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Júù ni òun. Ó ní láti jẹ́ pé Módékáì ti rí i pé àwọn tó ń ṣe ẹ̀tanú sáwọn èèyàn òun wà lára àwọn èèyàn ọba Páṣíà. Torí náà, ńṣe ni inú Módékáì á máa dùn pé bí Ẹ́sítérì ò tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ òun mọ́, ó ṣì jẹ́ ọlọgbọ́n àti onígbọràn.

      14. Báwo ní àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí ṣe lè ṣe bíi ti Ẹ́sítérì?

      14 Àwọn ọ̀dọ́ òde ìwòyí náà lè mú inú àwọn òbí àti àwọn alágbàtọ́ wọn dùn. Ó lè ṣẹlẹ̀ pé wọn ò sí níbi tí ojú àwọn òbí wọn ti lè tó wọn. Irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ sì lè máa gbé ní àárín àwọn tí kò láròjinlẹ̀, àwọn oníṣekúṣe, tàbí àwọn oníjàgídíjàgan. Síbẹ̀, wọ́n lè ṣàì kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ kí wọ́n sì máa ṣe ohun tí wọ́n mọ̀ pé ó tọ́. Tí wọ́n bá ṣe bíi ti Ẹ́sítérì, wọ́n á mú ọkàn Baba wọn ọ̀run yọ̀.—Ka Òwe 27:11.

      15, 16. (a) Kí ló mú kí ọba nífẹ̀ẹ́ Ẹ́sítérì? (b) Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún Ẹ́sítérì láti máa ṣe bí ayaba?

      15 Nígbà tó kan Ẹ́sítérì láti lọ rí ọba, wọ́n yọ̀ǹda fún un láti mú ohunkóhun tó bá rí pé ó máa wúlò fún òun, bóyá láti túbọ̀ gbé ẹwà rẹ̀ yọ. Àmọ́ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Ẹ́sítérì ò jẹ́ kó béèrè kọjá ohun tí Hégáì ní kó lò. (Ẹ́sít. 2:15) Kí nìdí? Ó ṣeé ṣe kó ti kíyè sí i pé òun ò lè torí ẹwà nìkan rí ojú rere ọba àti pé ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ló máa ṣe pàtàkì jù lọ ní ààfin tí òun wà yẹn. Ṣé èrò Ẹ́sítérì tọ̀nà?

      16 Bíbélì sọ pé: “Ọba sì wá nífẹ̀ẹ́ Ẹ́sítérì ju gbogbo àwọn obìnrin yòókù lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì jèrè ojú rere àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ púpọ̀ sí i níwájú rẹ̀ ju gbogbo àwọn wúńdíá yòókù. Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi ìwérí ayaba sí i ní orí, ó sì fi í ṣe ayaba dípò Fáṣítì.” (Ẹ́sít. 2:17) Bí Ẹ́sítérì ṣe di ìyàwó ọba tó lágbára jù lọ láyé ìgbà yẹn nìyẹn o! Gẹ́gẹ́ bí ayaba tuntun, ó máa ṣòro fún ọmọbìnrin Júù tó níwà ìrẹ̀lẹ̀ yìí láti máa ṣe bí ayaba. Ǹjẹ́ Ẹ́sítérì jẹ́ kí ipò tuntun yìí kó sí òun lórí, kó sì wá máa gbéra ga? Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀!

      17. (a) Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe ń bá a nìṣó láti máa ṣègbọràn sí bàbá tó gbà á tọ́? (b) Kí nìdí tí àpẹẹrẹ Ẹ́sítérì fi ṣe pàtàkì fún wa lóde òní?

      17 Ẹ́sítérì ń bá a nìṣó láti máa ṣègbọràn sí Módékáì tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀. Kò sọ fún ẹnikẹ́ni pé Júù lòun. Yàtọ̀ síyẹn, Módékáì sọ fún Ẹ́sítérì pé àwọn kan ń pète pèrò láti pa Ahasuwérúsì Ọba. Ẹ́sítérì ò kọ̀ sí Módékáì lẹ́nu, ó fi ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ náà tó ọba létí. Ọwọ́ ba àwọn tó ń pète láti pa ọba, ìmọ̀ wọn sì dòfo. (Ẹ́sít. 2:20-23) Bákan náà, Ẹ́sítérì ṣì ń bá a nìṣó láti máa lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó ń hùwà ìrẹ̀lẹ̀, ó sì jẹ́ onígbọràn. Lóde òní táwọn èèyàn ò ka jíjẹ́ onígbọràn sí nǹkan pàtàkì mọ́, tí àìgbọràn àti ìṣọ̀tẹ̀ sì gbayé kan, ó ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ẹ́sítérì. Àwọn èèyàn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ ka jíjẹ́ onígbọràn sí ohun iyebíye gẹ́gẹ́ bí Ẹ́sítérì ti ṣe.

      Àdánwò Ló Jẹ́ fún Ìgbàgbọ́ Ẹ́sítérì

      18. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Módékáì fi kọ̀ láti tẹrí ba fún Hámánì? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Lóde òní, báwo ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ní ìgbàgbọ́ ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Módékáì?

      18 Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Hámánì di ẹni ńlá láàfin Ahasuwérúsì. Ọba yan Hámánì sí ipò tó ga jù lọ ní ilẹ̀ ọba náà, ó fi í ṣe olórí agbani-nímọ̀ràn àti igbá kejì rẹ̀. Ọba tiẹ̀ tún pàṣẹ pé gbogbo ẹni tó bá rí olóyè yìí gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún un. (Ẹ́sít. 3:1-4) Ó ṣòro fún Módékáì láti pa àṣẹ yẹn mọ́. Ó mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí ọba, àmọ́ kì í ṣe débi tí òun á fi ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Òótọ́ kan ni pé ọmọ Ágágì ni Hámánì. Ìyẹn fi hàn pé àtọmọdọ́mọ Ágágì, ìyẹn ọba Ámálékì tí Sámúẹ́lì wòlíì Ọlọ́run pa, ni ọ̀gbẹ́ni yìí. (1 Sám. 15:33) Àwọn ọmọ Ámálékì yìí burú débi pé wọ́n sọ ara wọn di ọ̀tá Jèhófà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Torí náà, ẹni tí ìparun tọ́ sí lójú Ọlọ́run ni gbogbo àwọn ọmọ Ámálékì.c (Diu. 25:19) Báwo wá ni Júù kan tó jẹ́ adúróṣinṣin á ṣe máa tẹrí ba fún Hámánì tó jẹ́ ará Ámálékì? Módékáì ò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Ó kọ̀ láti tẹrí ba fún un. Títí dòní, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ní ìgbàgbọ́ ti fi ẹ̀mí ara wọn jin ikú torí kí wọ́n lè tẹ̀ lé ìlànà inú Bíbélì tó sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.

      19. Kí ni Hámánì fẹ́ ṣe? Báwo ló ṣe yí ọba lérò pa dà?

      19 Inú bí Hámánì gan-an. Àmọ́ kò wù ú kó jẹ́ pé Módékáì nìkan ló máa wá ọ̀nà láti pa. Ńṣe ló fẹ́ pa gbogbo àwọn èèyàn Módékáì run! Kí Hámánì bàa lè yí ọba lérò pa dà, ó sọ̀rọ̀ àwọn Júù láìdáa. Kò dárúkọ wọn fún ọba, àmọ́ ó jẹ́ kí ọba rí wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Ó pè wọ́n ní àwọn èèyàn “tí a tú ká, tí a sì yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn ènìyàn.” Èyí tó tún wá burú jù níbẹ̀ ni bó ṣe sọ pé wọn kò pa àwọn àṣẹ ọba mọ́, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ paraku. Ó sọ pé òun máa san owó púpọ̀ jaburata sínú ibi ìṣúra ọba, kí wọ́n lè ná an láti fi pa gbogbo àwọn Júù tó wà ní ilẹ̀ ọba náà run.d Ahasuwérúsì fún Hámánì ní òrùka àmì àṣẹ rẹ̀ pé kó fi lu àṣẹ èyíkéyìí tó bá ní lọ́kàn láti pa ní òǹtẹ̀.—Ẹ́sít. 3:5-10.

      20, 21. (a) Nígbà tí Módékáì àti gbogbo àwọn Júù tó wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Páṣíà gbọ́ ìkéde tí Hámánì ṣe, báwo ló ṣe rí lára wọn? (b) Kí ni Módékáì bẹ Ẹ́sítérì pé kó ṣe?

      20 Kò pẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ fi bẹ̀rẹ̀ sí í gun ẹṣin sáré lọ sí ibi gbogbo ní ilẹ̀ ọba gbígbòòrò náà, tí wọ́n sì ń jíṣẹ́ tó já sí ìdájọ́ ikú fáwọn Júù. Ẹ fojú inú wo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe máa rí lára àṣẹ́kù àwọn Júù tó kúrò ní ìgbèkùn ní Bábílónì nígbà tí wọ́n gbọ́ ní iyànníyàn Jerúsálẹ́mù, níbi tí wọ́n ti ń sapá láti ṣàtúnkọ́ ìlú tí kò tíì ní ògiri tó lè dáàbò bò ó. Nígbà tí Módékáì gbọ́ ìròyìn tó ń bani lẹ́rù yìí, ó ṣeé ṣe kó ronú nípa àwọn àṣẹ́kù yìí àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó wà ní Ṣúṣánì. Torí pé inú rẹ̀ bà jẹ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ, ó ku eérú sórí, ó sì ń sunkún kíkankíkan ní àárín ìlú náà. Àmọ́ ní ti Hámánì, ó jókòó ti ọba, wọ́n jọ ń mutí, kò bìkítà rárá nípa ìbànújẹ́ tó dá sílẹ̀ láàárín àwọn Júù tó pọ̀ rẹpẹtẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn tó wà ní Ṣúṣánì.—Ka Ẹ́sítérì 3:12–4:1.

      21 Módékáì mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ kí ló lè ṣe sí i? Ẹ́sítérì gbọ́ nípa bí Módékáì ṣe ń banú jẹ́, ó sì fi aṣọ ránṣẹ́ sí i, àmọ́ ìyẹn ò tu Módékáì nínú. Ó lè ti máa ṣe kàyéfì tipẹ́ nípa ìdí tí Jèhófà, Ọlọ́run rẹ̀, fi yọ̀ǹda pé kí wọ́n mú Ẹ́sítérì ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n, kí wọ́n sì sọ ọ́ di ayaba fún alákòóso tó jẹ́ abọ̀rìṣà. Ó wá jọ pé ìdí náà ti ń ṣe kedere bọ̀ báyìí. Módékáì ránṣẹ́ sí Ẹ́sítérì ayaba pé kó lọ bẹ ọba, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ gbèjà “àwọn ènìyàn rẹ̀.”—Ẹ́sít. 4:4-8.

      22. Kí nìdí tí ẹ̀rù fi ba Ẹ́sítérì láti lọ bá ọba tó jẹ́ ọkọ rẹ̀ sọ̀rọ̀? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

      22 Àyà Ẹ́sítérì ti ní láti já nígbà tó gbọ́ nǹkan tí Módékáì ní kó ṣe. Àdánwò ńlá lèyí jẹ́ fún ìgbàgbọ́ Ẹ́sítérì. Bó ṣe dá Módékáì lóhùn láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ fi hàn pé ẹ̀rù bà á. Ó rán Módékáì létí òfin ọba pé téèyàn bá tọ ọba Páṣíà lọ láìjẹ́ pé ọba ké sí i, ńṣe ni wọ́n máa pa á. Àyàfi bí ọba bá na ọ̀pá aládé wúrà rẹ̀ sí ẹni náà ni ikú fi máa yẹ̀ lórí rẹ̀. Ṣé ó wá yẹ kí Ẹ́sítérì ronú pé ọba máa fi àánú hàn sí òun lọ́nà yẹn, àgàgà tó bá rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Fáṣítì nígbà tó kọ̀ láti jẹ́ ìpè ọba nígbà tí ọba pàṣẹ pé kó wá? Ẹ́sítérì sọ fún Módékáì pé ọba kò tíì pe òun láti ọgbọ̀n ọjọ́ sẹ́yìn! Níwọ̀n bó ti pẹ́ díẹ̀ tí ọba ti pa Ẹ́sítérì tì, ìdí púpọ̀ wà fún un láti máa ṣiyè méjì pé bóyá ọba tí èrò rẹ̀ lè yí pa dà nígbàkigbà yìí kò gba tòun mọ́.e—Ẹ́sít. 4:9-11.

      23. (a) Kí ni Módékáì sọ kó lè fún ìgbàgbọ́ Ẹ́sítérì lókun? (b) Kí nìdí tí Módékáì fi yẹ lẹ́ni tá a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

      23 Módékáì dá Ẹ́sítérì lóhùn láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ láti fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun. Ó sọ fún un pé bí kò bá ṣe ohun tó yẹ, àwọn Júù á rí ìgbàlà láti ibòmíì. Àmọ́, báwo ni Ẹ́sítérì ṣe lè rò pé inúnibíni náà máa yọ òun sílẹ̀ tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í le ju bó ṣe wà yẹn lọ? Lọ́nà yìí, Módékáì fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà pé kò ní jẹ́ kí wọ́n pa àwọn èèyàn rẹ̀ run, kò sì ní jẹ́ kí àwọn ìlérí rẹ̀ kùnà. (Jóṣ. 23:14) Módékáì tún wá bi Ẹ́sítérì pé: “Ta sì ni ó mọ̀ bóyá nítorí irú àkókò yìí ni ìwọ fi dé ipò ọlá ayaba?” (Ẹ́sít. 4:12-14) Ǹjẹ́ kò wá yẹ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Módékáì? Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pátápátá. Ṣé àwa náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá?—Òwe 3:5, 6.

      Ìgbàgbọ́ Tó Borí Ìbẹ̀rù Ikú

      24. Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà?

      24 Ní báyìí, ọ̀rọ̀ ti dójú ẹ̀ fún Ẹ́sítérì. Ó ní kí Módékáì sọ fún àwọn Júù pé kí wọ́n bá òun gbààwẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, ó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí ó bá ṣe pé èmi yóò ṣègbé, èmi yóò ṣègbé.” (Ẹ́sít. 4:15-17) Títí di òní, gbogbo àwọn tó ń gbọ́ gbólóhùn yìí ló gbà pé Ẹ́sítérì fi ìgbàgbọ́ àti ìgboyà hàn. Ó dájú pé ó ti ní láti gbàdúrà kíkankíkan láàárín ọjọ́ mẹ́ta yẹn ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àmọ́ níkẹyìn, àkókò tó láti lọ rí ọba. Ó wọ èyí tó dára jù lọ nínú àwọn aṣọ oyè rẹ̀, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí ìrísí rẹ̀ lè wu ọba. Lẹ́yìn náà, ó lọ sọ́dọ̀ ọba.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 132, 133]

      Ẹ́sítérì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kó lè dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run

      25. Sọ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ bí Ẹ́sítérì ṣe yọ sí ibi tí ọkọ rẹ̀ wà.

      25 Bá a ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ orí yìí, Ẹ́sítérì forí lé ibi tí ọba ń gúnwà sí nínú ààfin. Ẹ wo bí oríṣiríṣi èrò á ṣe kún inú ọkàn rẹ̀ tó, táá sì máa gbàdúrà kíkankíkan bó ṣe ń lọ. Ó wọ inú àgbàlá tó wà nínú ààfin, ó sì dúró síbi tó ti lè rí Ahasuwérúsì lórí ìtẹ́ rẹ̀. Bóyá ńṣe ló ń gbìyànjú láti wo bí ojú ọba ṣe rí láàárín irun orí rẹ̀ tó máa ń wé wálẹ̀ àti irùngbọ̀n rẹ̀ tó máa ń gún régé bí wọ́n bá dì í tán, kó lè fi òye mọ ohun tó ń rò. Tó bá sì ní láti dúró kó tó rí ọba, ńṣe ló máa dà bíi pé ó ti pẹ́ jù. Láìpẹ́ láìjìnnà, ọkọ rẹ̀ rí i. Ó dájú pé èyí ya ọba lẹ́nu, àmọ́ ìrísí ojú rẹ̀ fi hàn pé ó yọ́nú sí Ẹ́sítérì. Ó na ọ̀pá aládé wúrà rẹ̀ sí i!—Ẹ́sít. 5:1, 2.

      26. Kí nìdí tí àwa Kristẹni tòótọ́ fi nílò ìgboyà bíi ti Ẹ́sítérì? Kí ló fi hàn pé Ẹ́sítérì ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣe?

      26 Ọba ti ṣe tán báyìí láti fetí sí ohun tí Ẹ́sítérì fẹ́ sọ. Ẹ́sítérì ti múra tán láti ṣojú fún Ọlọ́run rẹ̀ kó sì gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀. Láti ìgbà yẹn wá títí di òní, ọ̀nà tó gbà lo ìgbàgbọ́ jẹ́ àpẹẹrẹ tó gbámúṣé fún gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Lóde òní, àwa Kristẹni tòótọ́ mọyì irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀. Jésù sọ pé ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ làwọn èèyàn máa fi mọ àwọn tó jẹ́ ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn òun. (Ka Jòhánù 13:34, 35.) Ó sábà máa ń gba pé ká ní ìgboyà bíi ti Ẹ́sítérì ká tó lè fi irú ìfẹ́ yìí hàn. Àmọ́, lẹ́yìn tí Ẹ́sítérì ti múra tán láti gbèjà àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́jọ́ yẹn, ó ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣe. Báwo ló ṣe máa mú kí ọba gbà pé elétekéte ni Hámánì tó jẹ́ agbani-nímọ̀ràn tí ọba fẹ́ràn jù lọ? Báwo ló ṣe máa mú kí ikú yẹ̀ lórí àwọn èèyàn rẹ̀? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí ní orí tó kàn.

      a Ọ̀pọ̀ ló gbà pé Ahasuwérúsì náà ló ń jẹ́ Sásítà Kìíní, tó ṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Páṣíà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

      b Wo àpótí náà, “Ohun Tí Àwọn Kan Béèrè Nípa Ẹ́sítérì,” ní Orí 16.

      c Ìgbà ayé Hesekáyà Ọba ni wọ́n ti pa “àṣẹ́kù” àwọn ọmọ Ámálékì, torí náà, ó ṣeé ṣe kí Hámánì wà lára àwọn tó gbẹ̀yìn pátápátá lára wọn.—1 Kíró. 4:43.

      d Hámánì sọ pé òun á fún ọba ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] tálẹ́ńtì fàdákà. Lóde òní, iye yẹn tó ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù dọ́là. Tó bá jẹ́ pé Ahasuwérúsì yìí ni Sásítà Kìíní, owó tí Hámánì sọ yìí ti ní láti wọ̀ ọ́ lójú. Ìdí ni pé Sásítà nílò owó rẹpẹtẹ tó máa ná sórí ogun tó ti wà lọ́kàn rẹ̀ tipẹ́ láti bá ilẹ̀ Gíríìsì jà, síbẹ̀ kò rọ́wọ́ mú nínú ogun náà.

      e Sásítà Kìíní jẹ́ onínúfùfù, ìgbàkigbà ni èrò rẹ̀ sì lè yí pa dà. A rí àpẹẹrẹ èyí nínú ìtàn tí òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tó ń jẹ́ Herodotus kọ nípa ogun tí Sásítà bá ilẹ̀ Gíríìsì jà. Sásítà pàṣẹ pé kí wọ́n to ọkọ ojú omi sí ẹgbẹ́ ara wọn láti fi ṣe afárá sórí odò Hellespont. Nígbà tí ìjì ba afárá náà jẹ́, Sásítà pàṣẹ pé kí wọ́n bẹ́ orí àwọn ẹnjiníà tó ṣe afárá náà. Ó tiẹ̀ tún ní kí àwọn ìránṣẹ́ òun máa kó ẹgba bo odò Hellespont kí wọ́n sì máa ṣépè lé e lórí bíi ká sọ pé wọ́n ń fìyà jẹ omi odò náà. Lákòókò yìí kan náà, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wá bẹ Sásítà pé kó máà jẹ́ kí wọ́n mú ọmọ òun wọṣẹ́ ológun. Àmọ́, ńṣe ni Sásítà ní kí wọ́n gé ọmọ náà sí méjì, kí wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí gbangba kó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn míì.

      OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ . . .

      • Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti onígboyà?

      • Báwo ni Módékáì ṣe mú kí Ẹ́sítérì ṣe ohun tó fi ìgbàgbọ́ hàn?

      • Kí ni Ẹ́sítérì ṣe tó fi hàn pé ó ní ìgboyà?

      • Àwọn ọ̀nà wo ni wàá fẹ́ gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Ẹ́sítérì?

  • Ó Lo Ọgbọ́n àti Ìgboyà, Kò sì Mọ Tara Rẹ̀ Nìkan
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
    • ORÍ KẸRÌNDÍNLÓGÚN

      Ó Lo Ọgbọ́n àti Ìgboyà, Kò sì Mọ Tara Rẹ̀ Nìkan

      1-3. (a) Báwo ló ṣe rí lára Ẹ́sítérì nígbà tó ń lọ sí ibi tí ọba gúnwà sí? (b) Kí ni ọba ṣe nígbà tó rí Ẹ́sítérì?

      Ẹ́SÍTÉRÌ rọra ń lọ sí ibi ti ọba gúnwà sí, bẹ́ẹ̀ ni àyà rẹ̀ ń lù kìkì. Ṣé o lè fojú inú wo bí gbogbo nǹkan á ṣe ṣàdédé pa rọ́rọ́ ní ààfin aláyélúwà ti Ilẹ̀ Ọba Páṣíà tó wà ní Ṣúṣánì? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀ ni Ẹ́sítérì ń gbé ẹsẹ̀, síbẹ̀ kẹ́kẹ́ pa débi pé ó ń gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì tún ń gbọ́ bí aṣọ oyè tó wọ̀ ṣe rọra ń rún wúrúwúrú. Òótọ́ ni pé ẹwà ààfin náà kọyọyọ. Àwọn òpó tí wọ́n fi iṣẹ́ ọnà dárà sí wà níbẹ̀. Bákàn náà sì ni àwọn igi kédárì tí wọ́n kó wá láti iyànníyàn ìlú Lẹ́bánónì. Wọ́n gbẹ́ àwọn igi yìí lọ́nà tó fa kíki, wọ́n sì fi wọ́n bo àjà inú ààfin náà. Àmọ́, Ẹ́sítérì ò rí gbogbo ìyẹn rò. Ẹni tó gúnwà sorí ìtẹ́ náà ló tẹjú mọ́, nítorí ọwọ́ ọba yìí ni ẹ̀mí rẹ̀ wà.

      2 Ọba náà tẹjú mọ́ Ẹ́sítérì tó ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì na ọ̀pá aládé wúrà rẹ̀ sí i. Èyí lè má dà bí nǹkan bàbàrà, àmọ́ ńṣe ló túmọ̀ sí pé ikú yẹ̀ lórí Ẹ́sítérì. Òfin ilẹ̀ Páṣíà ni Ẹ́sítérì ṣẹ́ sí bó ṣe wọlé wá láìjẹ́ pé ọba ké sí i, ṣùgbọ́n ọ̀pá tí ọba nà sí i túmọ̀ sí pé ọba ti forí jì í. Nígbà tí Ẹ́sítérì dé iwájú ìtẹ́ Ahasuwérúsì, ó na ọwọ́ rẹ̀ ó sì fi kan orí ọ̀pá náà láti fi hàn pé òun mọrírì bí ọba ṣe ṣàánú òun.—Ẹ́sít. 5:1, 2.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 136, 137]

      Ẹ́sítérì fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn, ó mọrírì àánú tí ọba fi hàn sí i

      3 Kò sí ẹni tó rí Ahasuwérúsì Ọba tí kò ní mọ̀ pé ó ní ọrọ̀ àti agbára tó kàmàmà. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé owó tó ń parí aṣọ ìgúnwà àwọn ọba ilẹ̀ Páṣíà ayé ìgbà yẹn máa ń tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ dọ́là. Síbẹ̀, Ẹ́sítérì rí i lójú ọba pé ó ṣì yọ́nú sí òun; ọba fi hàn lọ́nà yìí pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ọba wá bi í pé: “Kí ni ìwọ ń fẹ́, Ẹ́sítérì Ayaba, kí sì ni ìbéèrè rẹ? Títí dé ìdajì ipò ọba—àní kí a fi fún ọ!”—Ẹ́sít. 5:3.

      4. Àwọn ìṣòro wo ní Ẹ́sítérì ṣì ń bọ̀ wá dojú kọ?

      4 Ẹ́sítérì ti lo ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tó kọyọyọ ní ti pé ó wá sọ́dọ̀ ọba kó lè gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ Hámánì tó ti pète láti pa gbogbo wọn run. Ní báyìí, ó ti dé ọ̀dọ̀ ọba ó sì rí ojú rere rẹ̀, àmọ́ àwọn ìṣòro kan wà tó ṣì ń bọ̀ wá dojú kọ. Ó ṣì ní láti mú kí ọba tó jọra rẹ̀ lójú yìí gbà pé olubi ẹ̀dá ni agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ tó fọkàn tán jù lọ, pé ó ti dọ́gbọ́n tan ọba láti dájọ́ ikú fún gbogbo àwọn èèyàn òun. Báwo ló ṣe máa mú kí ọba gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú bó ṣe lo ìgbàgbọ́?

      Ó Fi Ọgbọ́n Yan “Ìgbà Sísọ̀rọ̀”

      5, 6. (a) Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe fi ìlànà tó wà nínú Oníwàásù 3:1, 7 sílò? (b) Báwo ni ọ̀nà tí Ẹ́sítérì gbà bá ọkọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ ṣe fi ọgbọ́n hàn?

      5 Ṣé ó yẹ kí Ẹ́sítérì sọ gbogbo ìṣòro náà fún ọba lójú gbogbo àwọn tó wà láàfin? Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè dójú ti ọba, kó sì jẹ́ kí Hámánì agbani-nímọ̀ràn ọba ráyè ro ẹjọ́ tó máa gbè é. Kí wá ni Ẹ́sítérì ṣe? Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, Ọlọ́run mí sí ọlọgbọ́n ọba náà, Sólómọ́nì láti kọ̀wé pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.” (Oníw. 3:1, 7) Ó dájú pé Módékáì, ọkùnrin adúróṣinṣin tó dà bíi bàbá fún Ẹ́sítérì á ti fi gbogbo irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kọ́ ọmọbìnrin náà bó ṣe ń tọ́ ọ títí tó fi dàgbà. Dájúdájú, Ẹ́sítérì mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn fara balẹ̀ yan “ìgbà sísọ̀rọ̀.”

      6 Ẹ́sítérì fèsì pé: “Bí ó bá dára ní ojú ọba, kí ọba àti Hámánì wá lónìí síbi àkànṣe àsè tí mo ti sè fún un.” (Ẹ́sít. 5:4) Ọba sọ pé àwọn máa wá, ó sì ránṣẹ́ pe Hámánì. Ǹjẹ́ ò kíyè sí bí Ẹ́sítérì ṣe fi ọgbọ́n sọ̀rọ̀? Ó bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀, ibi tó tọ́ àti ìgbà tó dára jù lọ ló sì yàn láti sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún un.—Ka Òwe 10:19.

      7, 8. Kí ló ṣẹlẹ̀ níbi àsè àkọ́kọ́ tí Ẹ́sítérì sè fún ọba? Síbẹ̀, kí nìdí tó fi sún ọ̀rọ̀ tó fẹ́ bá ọba sọ síwájú?

      7 Kò sí àní-àní pé Ẹ́sítérì fara balẹ̀ se àsè náà, ó sì rí i dájú pé gbogbo nǹkan tí ọkọ òun fẹ́ràn ni òun pèsè. Ọtí wáìnì tó jíire tó máa mú inú ọba dùn tún wà níbi àsè náà. (Sm. 104:15) Ahasuwérúsì gbádùn ara rẹ̀ dọ́ba, ló bá tún bi Ẹ́sítérì léèrè pé kí ló ń fẹ́. Ṣé àkókò ti tó wàyí fún Ẹ́sítérì láti tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀?

      8 Ẹ́sítérì kò rò bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló bẹ ọba pé kí òun àti Hámánì tún wá síbi àkànṣe àsè míì tí òun máa sè lọ́jọ́ kejì. (Ẹ́sít. 5:7, 8) Kí nìdí tí Ẹ́sítérì ò fi tíì sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀? Rántí pé gbogbo èèyàn Ẹ́sítérì pátá ni òfin tí ọba fọwọ́ sí sọ pé kí wọ́n pa. Látàrí èyí, Ẹ́sítérì gbọ́dọ̀ rí i pé ìgbà tó dára jù lọ lòun sọ ọ̀rọ̀ náà. Ó wá ṣe sùúrù, kó lè ní àǹfààní láti tún fi han ọkọ rẹ̀ pé òun bọ̀wọ̀ fún un gan-an ni.

      9. Báwo ni sùúrù ti ṣe pàtàkì tó? Báwo làwa náà ṣe lè jẹ́ onísùúrù bíi ti Ẹ́sítérì?

      9 Sùúrù ṣeyebíye, ó sì ṣọ̀wọ́n gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkàn Ẹ́sítérì ò balẹ̀, tó sì fẹ́ láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún ọba, ó ṣe sùúrù títí di ìgbà tó yẹ kó sọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Ẹ́sítérì torí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wa là ń rí àwọn nǹkan tó nílò àtúnṣe. Tá a bá fẹ́ kí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ bá wá bójú tó ìṣòro kan, ó lè gba pé ká ní sùúrù bíi ti Ẹ́sítérì. Ìwé Òwe 25:15 sọ pé: “Sùúrù ni a fi ń rọ aláṣẹ lọ́kàn, ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ egungun.” Tá a bá ṣe sùúrù di ìgbà tó yẹ, tá a sì sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, bíi ti Ẹ́sítérì, àwa náà lè borí àtakò tó le bí egungun. Ǹjẹ́ Ẹ́sítérì ń rí ìbùkún Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ gbà bó ṣe ń lo sùúrù àti ọgbọ́n?

      Sùúrù Ẹ́sítérì Mú Kó Rí Ìdájọ́ Òdodo Gbà

      10, 11. Kí nìdí tí ojú Hámánì fi yí pa dà lẹ́yìn tó kúrò níbi àkànṣe àsè àkọ́kọ́ yẹn? Kí ni ìyàwó àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbà á nímọ̀ràn pé kó ṣe?

      10 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ ní àsìkò tí Ẹ́sítérì fi ń ṣe sùúrù. Nígbà tí Hámánì kúrò níbi àkànṣe àsè àkọ́kọ́ yẹn, inú rẹ̀ dùn gan-an pé òun ni ọba àti ayaba yẹ́ sí tó bẹ́ẹ̀. Àmọ́ bí Hámánì ṣe ń gba ẹnubodè ààfin jáde ló rí Módékáì, ìyẹn Júù tó ṣì kọ̀ láti júbà rẹ̀. Bá a ṣe rí i ní orí kẹẹ̀ẹ́dógún, kì í ṣe ìwà ọ̀yájú ló mú kí Módékáì kọ̀ láti júbà Hámánì. Ẹ̀rí ọkàn Módékáì àti àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run ni kò jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ńṣe ni Hámánì “kún fún ìhónú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”—Ẹ́sít. 5:9.

      11 Hámánì rojọ́ fún aya rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé Módékáì ṣe àfojúdi sí òun. Torí náà, wọ́n sọ fún un pé kó ṣe òpó igi kan tó ga ju mítà méjìlélógún tàbí òpó iná méjì lọ. Lẹ́yìn náà, kó wá lọ gba àṣẹ lọ́dọ̀ ọba pé kí wọ́n gbé Módékáì kọ́ sórí rẹ̀. Ìmọ̀ràn wọn dára lójú Hámánì, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sì ní kí wọ́n lọ ṣètò òpó náà.—Ẹ́sít. 5:12-14.

      12. Kí nìdí tí ọba fi ní kí wọ́n ka ìwé àkọsílẹ̀ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọba òun sí òun létí? Kí ni ọba tipa báyìí mọ̀?

      12 Ó ṣẹlẹ̀ pé ohun kan tó ṣàjèjì ṣẹlẹ̀ sí ọba ní òru mọ́jú. Bíbélì sọ pé: “Oorun dá lójú ọba.” Torí náà, ó ní kí wọ́n ka àkọsílẹ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọba òun sí òun létí. Ara ohun tí wọ́n kà sí Ahasuwérúsì létí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tó pète láti pa á. Ọba rántí ìṣẹ̀lẹ̀ náà; ọwọ́ tẹ àwọn tó fẹ́ pa ọba wọ́n sì pa wọ́n. Àmọ́ kí ni wọ́n ṣe fún Módékáì tó tú àṣírí ète tí wọ́n pa náà? Ṣàdédé ló sọ sí ọba lọ́kàn pé kó béèrè ohun tí wọ́n ṣe fún Módékáì. Nígbà tó sì béèrè, wọ́n sọ fún un pé wọn ò tíì ṣe nǹkan kan fún un.—Ka Ẹ́sítérì 6:1-3.

      13, 14. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í dojú rú fún Hámánì? (b) Kí ni àwọn ọ̀rẹ́ Hámánì àti ìyàwó rẹ̀ sọ fún un?

      13 Ìdáhùn náà ká ọba lára gan-an, ó wá béèrè òṣìṣẹ́ ààfin tó wà nítòsí tó lè ran òun lọ́wọ́ láti wá nǹkan ṣe sí àṣìṣe yẹn. Àfi bó ṣe jẹ́ pé Hámánì ló wà láàfin lásìkò náà. Ó jọ pé ńṣe ló jí wá ní kùtùkùtù. Ó ṣáà ń wù ú pé kó wá gbàṣẹ láti pa Módékáì. Àmọ́ kí Hámánì tó béèrè ohun tó fẹ́, ọba ní kó sọ ọ̀nà tó dára jù lọ tóun lè gbà dá ọkùnrin kan tó rí ojú rere ọba lọ́lá. Hámánì rò pé òun ni ọba ní lọ́kàn, ló bá yáa dámọ̀ràn àwọn nǹkan ńláńlá. Ó ní kí wọ́n fi aṣọ ọ̀ṣọ́ ọba wọ ọkùnrin náà, kí wọ́n gbé e gun orí ẹṣin ọba, kí wọ́n sì jẹ́ kí ọ̀kan lára àwọn ìjòyè pàtàkì mú un yí ká ìlú Ṣúṣánì, kó sì máa yìn ín bó ṣe ń lọ. Wo bó ṣe máa rẹ Hámánì wá nígbà tó gbọ́ pé Módékáì ni ọkùnrin tí ọba fẹ́ dá lọ́lá! Ta sì ni ọba yàn pé kó máa kókìkí Módékáì? Hámánì gan-an ni!—Ẹ́sít. 6:4-10.

      14 Agbára káká ni Hámánì fi ṣe iṣẹ́ tó kà sí ìwọ̀sí ńlá yìí kó tó sá lọ sílé pẹ̀lú ìbànújẹ́ lọ́kàn rẹ̀. Aya rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé ńṣe ni nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn fi hàn pé ibi tí wàhálà tó ń bá Módékáì, tó jẹ́ Júù, fà máa já sí ò ní dáa.—Ẹ́sít. 6:12, 13.

      15. (a) Báwo ni sùúrù Ẹ́sítérì ṣe já sí ibi tó dáa? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká ní “ẹ̀mí ìdúródeni”?

      15 Torí pé Ẹ́sítérì ṣe sùúrù, tó dúró fún ọjọ́ kan sí i kó tó bá ọba sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, àyè ṣí sílẹ̀ fún Hámánì láti fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ara rẹ̀. Àfàìmọ̀ ni ò sì ní jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ló mú kí oorun dá lójú ọba mọ́jú ọjọ́ náà. (Òwe 21:1) Abájọ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi gbà wá níyànjú pé ká ní “ẹ̀mí ìdúródeni”! (Ka Míkà 7:7.) Tá ò bá sì kánjú ju Ọlọ́run lọ, a lè wá rí i pé ọ̀nà tó máa gbà yanjú ìṣòro wa máa ta yọ ọgbọ́n yòówù tí àwa fúnra wa bá fẹ́ dá sí i.

      Ó Fi Ìgboyà Sọ̀rọ̀

      16, 17. (a) Àkókò wo ni “ìgbà sísọ̀rọ̀” dé fún Ẹ́sítérì? (b) Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe yàtọ̀ sí Fáṣítì tó jẹ́ ayaba tẹ́lẹ̀?

      16 Ẹ́sítérì ò jẹ́ tán ọba ní sùúrù, torí náà ó gbọ́dọ̀ sọ tẹnu rẹ̀ níbi àkànṣe àsè kejì. Àmọ́, lọ́nà wo? Ọba fúnra rẹ̀ ló fún un láǹfààní láti sọ̀rọ̀, torí ó tún bi Ẹ́sítérì pé kó sọ ohun tó fẹ́ béèrè lọ́wọ́ òun. (Ẹ́sít. 7:2) “Ìgbà sísọ̀rọ̀” tó wàyí fún Ẹ́sítérì.

      17 Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ńṣe ni Ẹ́sítérì kọ́kọ́ fọkàn gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Ọlọ́run kó tó wá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí mo bá ti rí ojú rere ní ojú rẹ, ọba, bí ó bá sì dára ní ojú ọba, jẹ́ kí a fi ọkàn mi fún mi nípa ohun tí mo tọrọ àti àwọn ènìyàn mi nípa ìbéèrè mi.” (Ẹ́sít. 7:3) Wà á rí i nínú ọ̀rọ̀ tí Ẹ́sítérì sọ pé ó ṣe tán láti fara mọ́ ohun tí ọba bá pinnu pé ó dára. Ẹ ò rí i pé gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ni Ẹ́sítérì fi yàtọ̀ sí Fáṣítì tó jẹ́ aya ọba tẹ́lẹ̀, ẹni tó dìídì dójú ti ọkọ rẹ̀! (Ẹ́sít. 1:10-12) Bákan náà, Ẹ́sítérì ò ṣe lámèyítọ́ ọba pé ìwà òmùgọ̀ ló hù torí bó ṣe fọkàn tán Hámánì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló bẹ ọba pé kó gba òun torí ẹ̀mí òun wà nínú ewu.

      18. Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba?

      18 Ẹ̀bẹ̀ yìí ta ọba kìjí, ó sì yà á lẹ́nu gidigidi. Ta ní lórí láyà láti gba ẹ̀mí ayaba òun? Ẹ́sítérì wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “A ti tà wá, èmi àti àwọn ènìyàn mi, láti pa wá rẹ́ ráúráú, láti pa wá àti láti run wá. Wàyí o, ká ní a tà wá láti di ẹrúkùnrin lásán-làsàn àti ìránṣẹ́bìnrin lásán-làsàn ni, èmi ì bá dákẹ́. Ṣùgbọ́n wàhálà náà kò bá a mu nígbà tí yóò jẹ́ sí ìpalára ọba.” (Ẹ́sít. 7:4) Kíyè sí i pé Ẹ́sítérì sọ bí ìṣòro náà ṣe jẹ́ gan-an láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, síbẹ̀ ó fi kún un pé, òun ì bá dákẹ́ ká ní ẹrú lásán ni wọ́n fẹ́ fi àwọn ṣe. Ṣùgbọ́n ìpalára tó máa ṣe fún ọba tí wọ́n bá pa odindi ẹ̀yà kan run kọjá ohun tí òun lè mú mọ́ra.

      19. Kí la lè rí kọ́ lára Ẹ́sítérì nípa béèyàn ṣe lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń yíni lọ́kàn pa dà?

      19 A rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ lára Ẹ́sítérì nípa béèyàn ṣe lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń yíni lọ́kàn pa dà. Tó o bá fẹ́ mú ìṣòro kan tó burú jáì wá sí etígbọ̀ọ́ èèyàn rẹ kan tàbí ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ, ó máa gba pé kó o lo sùúrù, kó o fi ọ̀wọ̀ hàn, kó o sì sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an.—Òwe 16:21, 23.

      20, 21. (a) Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe tú Hámánì fó? Kí ni ọba wá ṣe? (b) Kí ni Hámánì ṣe lẹ́yìn tí Ẹ́sítérì fi hàn pé amòòkùnṣìkà ni?

      20 Ahasuwérúsì béèrè pé: “Ta ni ẹni yìí, ibo gan-an sì ni ẹni náà wà, tí ó ki ara rẹ̀ láyà láti ṣe bẹ́ẹ̀?” Fojú inú wo bí Ẹ́sítérì ṣe nàka sí Hámánì, tó sì sọ pé: “Ọkùnrin náà, elénìní àti ọ̀tá náà, ni Hámánì búburú yìí.” Ṣàǹgbá fọ́! Ìdí Hámánì domi. Wo bí ojú ọba tí inú rẹ̀ tètè máa ń ru yìí ṣe máa ranko nígbà tó wá rí i pé agbani-nímọ̀ràn tí òun fọkàn tán ti tan òun láti fọwọ́ sí ìwé àṣẹ tó máa yọrí sí ikú aya òun àtàtà! Ọba yára jáde lọ sínú ọgbà ààfin kí ìbínú rẹ̀ lè rọlẹ̀ díẹ̀.—Ẹ́sít. 7:5-7.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 140, 141]

      Ẹ́sítérì fi ìgboyà tú àṣírí ìwà ibi Hámánì

      21 Ní báyìí tí àṣírí ti tú pé amòòkùnṣìkà ni Hámánì, ó wólẹ̀ sẹ́bàá ẹsẹ Ẹ́sítérì ó sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i. Nígbà tí ọba pa dà wọlé tó sì rí Hámánì lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú Ẹ́sítérì tó ń bẹ̀bẹ̀, inú bí i, ó sì fi ẹ̀sùn kan Hámánì pé ó fẹ́ fi ipá bá ayaba lò pọ̀ nínú ilé òun. Bí Hámánì ṣe gba ìdájọ́ ikú rẹ̀ nìyẹn o! Ni wọ́n bá daṣọ bò ó lójú wọ́n sì mú un lọ. Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ààfin wá sọ fún ọba pé Hámánì tiẹ̀ ti ri òpó igi gàgàrà kan sílé rẹ̀ tó fẹ́ gbé Módékáì kọ́. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ọba pàṣẹ pé Hámánì gan-an ni kí wọ́n lọ gbé kọ́ sórí òpó náà.—Ẹ́sít. 7:8-10.

      22. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Ẹ́sítérì tí kò ní jẹ́ ká sọ̀rètí nù, ká gbà pé kò sẹ́ni tó ṣeé gbára lé, tàbí kí ìgbàgbọ́ wa yingin?

      22 Nínú ayé aláìṣòdodo tá à ń gbé yìí, ó rọrùn láti ronú pé kò síbi tá a ti lè rí ìdájọ́ òdodo. Ṣé irú èrò yẹn ti wá sí ẹ lọ́kàn rí? Ẹ́sítérì ò fìgbà kan sọ̀rètí nù, kò gbà pé kò sẹ́ni tó ṣeé gbára lé, ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò sì yingin. Nígbà tí àkókò tó, ó fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa ohun tó tọ́, ó sì fi ìyókù lé Jèhófà lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí àwa náà máa ṣe bíi ti Ẹ́sítérì! Jèhófà tó ran Ẹ́sítérì lọ́wọ́ ò tíì yí pa dà. Ó ṣì lè mú kí àwọn aṣebi àti àwọn alárèékérekè fi ọwọ́ ara wọn ṣe ara wọn bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Hámánì.—Ka Sáàmù 7:11-16.

      Ó Fínnúfíndọ̀ Lo Ara Rẹ̀ fún Jèhófà Àtàwọn Èèyàn Rẹ̀

      23. (a) Báwo ni ọba ṣe dá Módékáì àti Ẹ́sítérì lọ́lá? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nípa Bẹ́ńjámínì ṣe ní ìmúṣẹ? (Wo àpótí náà, “Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Tó Ní Ìmúṣẹ.”)

      23 Níkẹyìn, ọba wá mọ̀ pé yàtọ̀ sí bí Módékáì ṣe jẹ́ olóòótọ́ èèyàn tó tú àṣírí àwọn tó fẹ́ pa òun, òun náà tún ni alágbàtọ́ Ẹ́sítérì. Ahasuwérúsì wá fi Módékáì sí ipò igbá kejì ọba tí Hámánì wà tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọba fún Ẹ́sítérì ní ilé Hámánì títí kan gbogbo dúkìá rẹpẹtẹ tó ní, Ẹ́sítérì sì fi gbogbo rẹ̀ sí ìkáwọ́ Módékáì.—Ẹ́sít. 8:1, 2.

      24, 25. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣírí Hámánì tó pète ibi ti tú, kí ló fà á tí Ẹ́sítérì ò fi káwọ́ gbera kó máa wòran? (b) Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe tún fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu?

      24 Ní báyìí tí ikú ti yẹ̀ lórí Ẹ́sítérì àti Módékáì, ṣó wá yẹ kí Ẹ́sítérì káwọ́ gbera kó máa wòran? Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé tara rẹ̀ nìkan ló mọ̀. Ní gbogbo ìgbà yẹn, wọ́n ṣì ń fi òfin tí Hámánì ṣe pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù run ránṣẹ́ sí gbogbo àgbègbè ilẹ̀ ọba náà. Hámánì sì ti ṣẹ́ kèké tàbí Púrì, tó jẹ́ oríṣi ọ̀nà ìbẹ́mìílò kan, láti fi mọ àkókò tó dára jù lọ tí wọ́n máa pa àwọn Júù nípa ìkà. (Ẹ́sít. 9:24-26) Òótọ́ ni pé ó ṣì máa tó oṣù mélòó kan sí i, àmọ́ ọjọ́ náà túbọ̀ ń yára sún mọ́lé. Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ lè rí nǹkan ṣe sí àjálù náà?

      25 Ẹ́sítérì tún fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu, ó lọ sọ́dọ̀ ọba lẹ́ẹ̀kan sí i láìjẹ́ pé ọba ní kó wá. Lọ́tẹ̀ yìí, ńṣe ló ń sunkún nítorí àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ọkọ rẹ̀ pé kó wọ́gi lé òfin líle koko yẹn. Ṣùgbọ́n òfin tí wọ́n bá ti ṣe ní orúkọ ọba Páṣíà kò ṣeé wọ́gi lé. (Dán. 6:12, 15) Torí náà, ọba fún Ẹ́sítérì àti Módékáì láṣẹ pé kí wọ́n ṣe òfin míì. Èyí mú kí wọ́n pa dà kéde fún àwọn èèyàn pé ọba ti fún àwọn Júù láṣẹ láti gbèjà ara wọn. Látàrí èyí, àwọn ẹlẹ́ṣin sáré mú ìròyìn ayọ̀ yìí tọ àwọn Júù tó wà jákèjádò ilẹ̀ ọba náà lọ. Ó wá ṣe kedere sí àwọn Júù báyìí pé àwọn ti rí ọ̀nà àbáyọ. (Ẹ́sít. 8:3-16) Ẹ sì wo bí àwọn Júù jákèjádò ilẹ̀ ọba tó gbòòrò náà á ṣe máa kó ohun ìjà jọ tí wọ́n á sì máa gbára dì! Ká ní kì í ṣe ti òfin tuntun yẹn ni, wọn ò ní lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, pàtàkì ibẹ̀ ni pé, ǹjẹ́ “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” máa wà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀?—1 Sám. 17:45.

      [Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 143]

      Ẹ́sítérì àti Módékáì fi àwọn ìkéde ránṣẹ́ sí àwọn Júù tó ń gbé ní Ilẹ̀ Ọba Páṣíà

      26, 27. (a) Báwo ni àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn tó látàrí bó ṣe tì wọ́n lẹ́yìn? (b) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ló ṣẹ nígbà tí wọ́n pa àwọn ọmọkùnrin Hámánì?

      26 Nígbà tí ọjọ́ tí wọ́n dá pé, àwọn Júù ti múra tán láti gbèjà ara wọn. Kódà ọ̀pọ̀ nínú àwọn olóyè láàfin ọba Páṣíà ti wà lẹ́yìn wọn báyìí, torí òkìkí ti kàn káàkiri pé Módékáì tó jẹ́ Júù ti di igbá kejì ọba. Jèhófà mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣẹ́gun lọ́nà tó kàmàmà. Ó dájú pé ó jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ pa àwọn ọ̀tá wọn run yán-ányán-án, kó má bàa di pé wọ́n á pa dà wá gbẹ̀san.a—Ẹ́sít. 9:1-6.

      27 Bákan náà, ẹ̀mí Módékáì máa wà nínú ewu tó bá ń ṣàkóso ilé Hámánì nígbà tí àwọn ọmọkùnrin mẹ́wàá tí Hámánì bí ṣì wà láàyè. Nítorí èyí, wọ́n pa àwọn ọmọ Hámánì pẹ̀lú. (Ẹ́sít. 9:7-10) Ọlọ́run ti sọ tipẹ́tipẹ́ pé wọ́n máa pa àwọn ará Ámálékì tó jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn rẹ̀ run pátápátá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ló wá mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì náà ṣẹ. (Diu. 25:17-19) Ó sì ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ Hámánì yìí jẹ́ ara àwọn tó gbẹ́yìn pátápátá nínú ẹ̀yà Ámálékì tí Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa pa run.

      28, 29. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi fọwọ́ sí i pé kí Ẹ́sítérì àti àwọn èèyàn rẹ̀ jagun? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìbùkún ni àpẹẹrẹ tí Ẹ́sítérì fi lélẹ̀ jẹ́ fún wa lónìí?

      28 Iṣẹ́ bàǹtàbanta ló já lé Ẹ́sítérì léjìká látàrí bó ṣe bá wọn lọ́wọ́ sí òfin tó ní í ṣe pẹ̀lú ogun jíjà àti pípani. Ó kúrò ni kèrémí. Àmọ́, ó wu Jèhófà pé kó dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ pa wọ́n run. Ìdí sì ni pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò ti wá. Ipasẹ̀ Mèsáyà yìí nìkan ṣoṣo ni aráyé fi máa rí ìgbàlà. (Jẹ́n. 22:18) Ó dùn mọ́ àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní pé nígbà tí Jésù tó jẹ́ Mèsáyà wá sáyé, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jagun nípa tara mọ́.—Mát. 26:52.

      29 Àmọ́ ṣá o, àwa Kristẹni ṣì ń ja irú ogun kan. Torí pé Sátánì túbọ̀ ń wá gbogbo ọ̀nà tó lè fi ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run jẹ́, à ń lọ́wọ́ nínú ogun tẹ̀mí. (Ka 2 Kọ́ríńtì 10:3, 4.) Ìbùkún ńlá ni àpẹẹrẹ tí Ẹ́sítérì fi lélẹ̀ jẹ́ fún wa! Bíi ti Ẹ́sítérì, ẹ jẹ́ kí àwa náà ní ìgbàgbọ́, ká máa fi ọgbọ́n àti sùúrù sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń yíni lérò pa dà, ká jẹ́ onígboyà, ká sì múra tán láti fi ẹ̀mí ara wa wewu ká lè gbèjà àwọn èèyàn Ọlọ́run.

      Ohun Tí Àwọn Kan Béèrè Nípa Ẹ́sítérì

      Kí nìdí tí Módékáì fi gbà kí Ẹ́sítérì fẹ́ ẹni tí kì í ṣe Júù, tó tún jẹ́ abọ̀rìṣà?

      Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ajìfà ni Módékáì. Wọ́n ní torí kó lè wà ní ipò iyì ló ṣe gbà kí Ẹ́sítérì fẹ́ ọba. Kò sí ẹ̀rí tó ti ohun tí wọ́n sọ yìí lẹ́yìn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Júù adúróṣinṣin ni Módékáì, kò ní fẹ́ kí irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ wáyé. (Diu. 7:3) Ó wà nínú ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù ìgbà yẹn pé Módékáì ò fẹ́ kí wọ́n fẹ́ra. Àmọ́, ó jọ pé kò fi bẹ́ẹ̀ sí ohun tí Módékáì tàbí Ẹ́sítérì lè ṣe sí ọ̀rọ̀ náà torí pé àjèjì lásán ni wọ́n. Ọba apàṣẹwàá táwọn èèyàn kà sí ẹni àkúnlẹ̀bọ ló sì ń ṣàkóso lé wọn lórí. Nígbà tó yá, ó wá hàn gbangba pé ńṣe ni Jèhófà lo ìgbéyàwó Ẹ́sítérì láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀.—Ẹ́sít. 4:14.

      Kí nìdí tí kò fi sí orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, nínú ìwé Ẹ́sítérì?

      Ẹ̀rí fi hàn pé Módékáì ni Ọlọ́run mí sí láti kọ ìwé Ẹ́sítérì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kọ́kọ́ tọ́jú ìwé náà pẹ̀lú àwọn àkọsílẹ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọba Páṣíà kó tó wá di pé wọ́n mú un lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ká ní wọ́n lo orúkọ Jèhófà nínú ìwé náà, àwọn tó ń bọ àwọn òrìṣà ilẹ̀ Páṣíà lè lọ dáná sun ún. Ṣùgbọ́n, ó hàn gbangba pé Jèhófà lọ́wọ́ sí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn náà. Ó dùn mọ́ni láti mọ̀ pé orúkọ Ọlọ́run wà nínú ìwé Ẹ́sítérì tí wọ́n fi èdè Hébérù àtijọ́ kọ. Ó kàn jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ to àwọn lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ náà lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Wọ́n máa ń fi àwọn lẹ́tà náà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mẹ́rin tó wà nínú gbólóhùn kan tàbí kí wọ́n fi wọ́n parí àwọn ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn náà. Lọ́nà yìí, tá a bá wo àpapọ̀ àwọn lẹ́tà náà láti ìbẹ̀rẹ̀ tàbí láti ìparí gbólóhùn náà, ó máa dúró fún orúkọ Ọlọ́run.—Ẹ́sít. 1:20, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

      Ṣé ọ̀rọ̀ inú ìwé Ẹ́sítérì bá ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn mu?

      Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ sọ pé ọ̀rọ̀ inú ìwé Ẹ́sítérì kò bá ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn mu. Ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ẹni tó kọ ìwé náà mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ọba àti ìdílé ọba ilẹ̀ Páṣíà, ó sì mọ bí àwọn ará Páṣíà ṣe ń kọ́lé àti àṣà wọn. Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn ò tíì rí ìwé ìtàn kankan tí wọ́n kọ nígbà yẹn lọ́hùn-ún tó sọ̀rọ̀ nípa Ẹ́sítérì Ayaba, àmọ́ kò lè jẹ́ Ẹ́sítérì nìkan ni ará ilé ọba tí wọ́n yọ orúkọ rẹ̀ kúrò nínú àkọsílẹ̀ gbogbo gbòò. Pabanbarì rẹ̀ wá ni pé àwọn ìwé ìtàn sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Mardukâ, ìyẹn Módékáì lédè Páṣíà, pé ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ní ààfin tó wà ní Ṣúṣánì nígbà tí àwọn nǹkan tó wà nínú ìwé Ẹ́sítérì ṣẹlẹ̀.

      Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Tó Ní Ìmúṣẹ

      Bí Ẹ́sítérì àti Módékáì ṣe jà fún àwọn èèyàn Ọlọ́run yẹn mú àsọtẹ́lẹ̀ àtijọ́ kan tó wà nínú Bíbélì ṣẹ. Ní èyí tó ju ẹgbẹ̀fà [1,200] ọdún ṣáájú, Jèhófà mí sí baba ńlá náà Jékọ́bù láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Bẹ́ńjámínì yóò máa fani ya bí ìkookò. Ní òwúrọ̀, òun yóò jẹ ẹran tí a mú, àti ní ìrọ̀lẹ́, òun yóò pín ohun ìfiṣèjẹ.” (Jẹ́n. 49:27) Ní “òwúrọ̀” tàbí ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn àwọn ọba tó jẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ìlà ìdílé Bẹ́ńjámínì ni Sọ́ọ̀lù Ọba àtàwọn alágbára míì tó jagun fún àwọn èèyàn Jèhófà ti wá. Ní “ìrọ̀lẹ́” tàbí nígbà tí ọba jíjẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì ti dópin, Ẹ́sítérì àti Módékáì táwọn náà wá látinú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, bá àwọn ọ̀tá Jèhófà jà wọ́n sì ṣẹ́gun. Bákan náà, a tún lè sọ pé wọ́n pín ohun ìfiṣèjẹ ní ti pé gbogbo dúkìá Hámánì di tiwọn.

      a Ọba gba àwọn Júù láyè láti máa bá ìjà náà lọ lọ́jọ́ kejì kí wọ́n lè rẹ́yìn àwọn ọ̀tá wọn. (Ẹ́sít. 9:12-14) Àwọn Júù ṣì máa ń ṣe ìrántí ìṣẹ́gun yẹn lọ́dọọdún. Ó máa ń jẹ́ ní oṣù Ádárì, èyí tó sábà máa ń bọ́ sí ìparí oṣù February àti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù March lóde òní. Wọ́n ń pe ayẹyẹ náà ní Púrímù, ìyẹn orúkọ kèké tí Hámánì ṣẹ́ nígbà tó pète láti pá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run.

      OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ . . .

      • Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe lo ọgbọ́n láti yan “ìgbà sísọ̀rọ̀”?

      • Àwọn ìbùkún wo ni sùúrù Ẹ́sítérì yọrí sí?

      • Báwo ni Ẹ́sítérì ṣe lo ìgboyà tí kò sì mọ tara rẹ̀ nìkan nínú bó ṣe gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀?

      • Àwọn ọ̀nà wo lo ti pinnu pé wàá gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Ẹ́sítérì?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́