ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ibo Là Ń Lọ Tá A Bá Kú?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
    • ORÍ KẸFÀ

      Ibo Là Ń Lọ Tá A Bá Kú?

      1-3. Àwọn ìbéèrè wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè nípa ikú, ìdáhùn wo sì ni àwọn ẹ̀sìn máa ń fún wọn?

      BÍBÉLÌ sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí “ikú ò ní sí mọ́.” (Ìfihàn 21:4) Ní Orí 5, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ìràpadà máa mú kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́ àwọn èèyàn ṣì ń kú lónìí. (Oníwàásù 9:5) Torí náà, a lè máa ronú pé, kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó kú?

      2 A sábà máa ń béèrè irú ìbéèrè yìí nígbà tí ẹnì kan tá a fẹ́ràn bá kú. A lè máa béèrè pé: Ibo ni ẹni náà lọ? Ṣé ó ń rí wa? Ṣé ó lè ràn wá lọ́wọ́? Ṣé a tún lè pa dà rí i?

      3 Onírúurú ìdáhùn ni àwọn ẹ̀sìn máa ń fún àwọn tó bá béèrè irú àwọn ìbéèrè yẹn. Àwọn kan sọ pé tó o bá jẹ́ èèyàn dáadáa, wàá lọ sí ọ̀run rere, àmọ́ tó o bá jẹ́ èèyàn burúkú, wàá jóná nínú ọ̀run àpáàdì. Àwọn míì tún sọ pé téèyàn bá kú, ẹni náà máa di ẹni ẹ̀mí, á sì máa gbé pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀ tó ti kú. Àwọn kan sì sọ pé lẹ́yìn téèyàn bá kú, tó sì ti gba ìdájọ́, wọ́n á tún ẹni náà bí sáyé bí èèyàn tàbí bí ẹranko.

      4. Kí ni àwọn ẹ̀sìn máa ń kọ́ni nípa ikú?

      4 Ohun tó yàtọ̀ síra ni àwọn ẹ̀sìn ń kọ́ àwọn èèyàn nípa ikú. Àmọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé èrò kan náà ni gbogbo wọn fi ń kọ́ni. Wọ́n sọ pé tí èèyàn bá kú, ohun kan lára ẹ̀ ṣì máa ń wà láàyè nìṣó. Ṣé òótọ́ ni?

      IBO LÀ Ń LỌ TÁ A BÁ KÚ?

      5, 6. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá kú?

      5 Jèhófà mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá kú, ó sì ti jẹ́ ká mọ̀ pé téèyàn bá kú, ẹni yẹn ò sí mọ́ nìyẹn. Ikú ni òdìkejì ìyè. Torí náà tẹ́nì kan bá kú, onítọ̀hún ò mọ nǹkan kan mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lọ gbé níbòmíì.a Tá a bá kú, a ò lè ríran, a ò lè gbọ́ràn, a ò sì lè ronú mọ́.

      6 Ọba Sólómọ́nì sọ pé “àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.” Àwọn òkú kò lè nífẹ̀ẹ́ ohunkóhun, wọn ò sì lè kórìíra ohunkóhun. “Kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú.” (Ka Oníwàásù 9:5, 6, 10.) Bákan náà, Sáàmù 146:4 jẹ́ ká mọ̀ pé tẹ́nì kan bá kú, “èrò inú rẹ̀” ti pa rẹ́ nìyẹn.

      OHUN TÍ JÉSÙ SỌ NÍPA IKÚ

      Tọkọtaya kan jókòó sínú ọgbà kan, wọ́n ń wo òdòdó

      Jèhófà dá àwa èèyàn láti máa gbé ayé títí láé

      7. Kí ni Jésù sọ nípa ikú?

      7 Nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtàtà kú, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti sùn.” Àmọ́, ohun tí Jésù ń sọ kọ́ ni pé Lásárù ń sinmi. Nígbà tó yá, Jésù wá sọ pé: “Lásárù ti kú.” (Jòhánù 11:11-14) Ìyẹn fi hàn pé Jésù fi ikú wé oorun. Kò sọ pé Lásárù wà lọ́run tàbí pé ó wà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀ tó ti kú. Kò sì sọ pé Lásárù ń jìyà nínú ọ̀run àpáàdì tàbí pé wọ́n máa tún un bí sáyé bí èèyàn tàbí bí ẹranko. Ńṣe ló dà bíi pé Lásárù ń sun oorun àsùnwọra. Àwọn ẹsẹ Bíbélì míì fi ikú wé oorun. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n pa Sítéfánù, Bíbélì sọ pé “ó sùn nínú ikú.” (Ìṣe 7:60) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni kan ti “sùn nínú ikú.”​—1 Kọ́ríńtì 15:6.

      8. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run kò dá àwa èèyàn pé ká máa kú?

      8 Ṣé Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà láti gbé ayé fún ìgbà díẹ̀, kí wọ́n sì kú? Rárá o! Jèhófà dá wọn kí wọ́n lè wà láàyè títí láé nínú ìlera pípé. Nígbà tí Jèhófà dá àwa ẹ̀dá èèyàn, ó fi ìfẹ́ láti wà láàyè títí láé sí wa lọ́kàn. (Oníwàásù 3:11) Àwọn òbí kì í fẹ́ káwọn ọmọ wọn dàgbà, kí wọ́n darúgbó, kí wọ́n sì kú lójú ẹ̀mí wọn, bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ wa ṣe rí lára Jèhófà. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run dá wa láti wà láàyè títí láé, kí wá nìdí tá a fi ń kú?

      KÍ NÌDÍ TÁ A FI Ń KÚ?

      9. Kí nìdí tí òfin tí Jèhófà fún Ádámù àti Éfà fi bọ́gbọ́n mu?

      9 Nígbà tí Ádámù wà nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà sọ fún un pé: “O lè jẹ èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà yìí ní àjẹtẹ́rùn. Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, torí ó dájú pé ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ lo máa kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:9, 16, 17) Òfin yẹn yé wọn dáadáa, kò sì nira rárá àti pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa fún Ádámù àti Éfà. Tí wọ́n bá ṣègbọràn sí Jèhófà, wọ́n á fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ rẹ̀. Á tún fi hàn pé wọ́n mọrírì àwọn ohun rere tí Jèhófà ṣe fún wọn.

      10, 11. (a) Báwo ni Sátánì ṣe tan Ádámù àti Éfà jẹ? (b) Kí nìdí tí Ádámù àti Éfà kò fi ní àwíjàre fún ohun tí wọ́n ṣe?

      10 Ó ṣeni láàánú pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Sátánì sọ fún Éfà pé: “Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso gbogbo igi inú ọgbà?” Éfà wá dáhùn pé: “A lè jẹ lára àwọn èso igi inú ọgbà. Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún wa nípa èso igi tó wà láàárín ọgbà pé: ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, kódà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án; kí ẹ má bàa kú.’”​—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-3.

      11 Lẹ́yìn náà Sátánì sọ pé: “Ó dájú pé ẹ ò ní kú. Torí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ tí ẹ bá jẹ ẹ́ ni ojú yín máa là, ẹ máa dà bí Ọlọ́run, ẹ sì máa mọ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:4-6) Sátánì fẹ́ kí Éfà ronú pé ó lè pinnu ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa fúnra rẹ̀. Àmọ́, ó tún parọ́ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí Éfà bá ṣàìgbọràn. Sátánì sọ pé Éfà ò ní kú, torí náà Éfà jẹ lára èso náà, lẹ́yìn náà ó fún ọkọ rẹ̀ jẹ. Ádámù àti Éfà mọ̀ pé Jèhófà ti sọ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ èso náà. Bí wọ́n ṣe jẹ èso yẹn fi hàn pé wọ́n yàn láti ṣàìgbọràn sí àṣẹ tó yéni dáadáa tó sì mọ́gbọ́n dání yẹn. Ó tún fi hàn pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún Baba wọn ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wọn. Kò sí àwíjàre fún ohun tí wọ́n ṣe yẹn.

      12. Kí nìdí tó fi dùn wá pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà?

      12 Ó dùn wá gan-an pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ kò bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wọn! Wo bó ṣe máa rí lára ẹ tó o bá ṣiṣẹ́ kára láti tọ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ẹ dàgbà, àmọ́ tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ẹ, tí wọn ò sì ṣe ohun tó o ní kí wọ́n ṣe. Ṣé kò ní kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ?

      Nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù

      Inú erùpẹ̀ ni Ádámù ti wá, ó sì pa dà sí erùpẹ̀

      13. Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Jèhófà sọ pé “ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀”?

      13 Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, wọ́n pàdánù àǹfààní láti wà láàyè títí láé. Jèhófà wá sọ fún Ádámù pé: “Erùpẹ̀ ni ọ́, ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.” (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:19.) Ìyẹn túmọ̀ sí pé Ádámù á pa dà di erùpẹ̀, bí ẹni pé kò wà láàyè rí. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Lẹ́yìn tí Ádámù ti dẹ́ṣẹ̀, ó kú, kò sì sí mọ́.

      14. Kí nìdí tá a fi ń kú?

      14 Ká ní Ádámù àti Éfà ṣègbọràn sí Ọlọ́run ni, wọ́n ṣì máa wà láàyè títí dòní. Àmọ́ nígbà tí wọ́n ṣàìgbọràn, wọ́n dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì kú. Ńṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ dà bí àrùn burúkú tá a jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa, ìdí nìyẹn tá a fi ń kú. (Róòmù 5:12) Àmọ́, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún àwa èèyàn kọ́ nìyẹn. Ọlọ́run kò fìgbà kankan fẹ́ kí àwa èèyàn máa kú, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe ikú ní “ọ̀tá.”​—1 Kọ́ríńtì 15:26.

      ÒTÍTỌ́ SỌ WÁ DI ÒMÌNIRA

      15. Báwo ni òtítọ́ nípa ikú ṣe sọ wá di òmìnira?

      15 Òtítọ́ nípa ikú sọ wá di òmìnira lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké. Bíbélì kọ́ wa pé àwọn tó ti kú kì í jẹ ìrora, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sí nínú ìbànújẹ́. A ò lè bá wọn sọ̀rọ̀, àwọn náà ò sì lè bá wa sọ̀rọ̀. A ò lè ràn wọ́n lọ́wọ́, àwọn náà ò lè ràn wá lọ́wọ́. Wọn ò lè ṣe wá ní jàǹbá, torí náà kò yẹ ká máa bẹ̀rù wọn. Àmọ́, ńṣe ni ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ń kọ́ni pé àwọn tó ti kú wà láàyè, wọ́n sì ń gbé níbòmíì. Wọ́n tún sọ pé a lè ran àwọn òkú lọ́wọ́ tá a bá ń fún àwọn àlùfáà lówó tàbí àwọn tí wọ́n ń pè ní ẹni mímọ́. Ṣùgbọ́n, tá a bá mọ òtítọ́ nípa ikú, wọn ò ní máa fi irú àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ tàn wá jẹ.

      16. Irọ́ wo ni ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn fi ń kọ́ni nípa àwọn tó ti kú?

      16 Sátánì ń lo ẹ̀sìn èké láti jẹ́ ká rò pé àwọn òkú ṣì wà láàyè. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀sìn kan ń kọ́ni pé tí èèyàn bá kú, ohun kan nínú ẹni yẹn ṣì máa ń wà láàyè nìṣó níbòmíì. Ṣé ohun tí ẹ̀sìn tìẹ kọ́ ẹ nìyẹn, àbí òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì ló fi ń kọ́ ẹ? Sátánì máa ń lo irọ́ láti fa àwọn èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà.

      17. Kí nìdí tí ẹ̀kọ́ náà pé àwọn èèyàn máa jóná nínú ọ̀run àpáàdì fi tàbùkù sí Jèhófà?

      17 Ohun tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ń kọ́ni bani lẹ́rù. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ń kọ́ni pé àwọn èèyàn burúkú máa jóná títí láé nínú ọ̀run àpáàdì. Irọ́ nìyẹn, ó sì tàbùkù sí Jèhófà. Ìdí ni pé Jèhófà ò lè gbà kí irú ìyà bẹ́ẹ̀ jẹ èèyàn láé! (Ka 1 Jòhánù 4:8.) Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá rí ẹnì kan tó ń ti ọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọ iná láti fìyà jẹ ẹ́? Ó dájú pé ìkà lo máa pe irú ẹni bẹ́ẹ̀, o ò sì ní fẹ́ sún mọ́ ọn. Irú ẹni tí Sátánì fẹ́ ká gbà pé Jèhófà jẹ́ nìyẹn!

      18. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù àwọn tó ti kú?

      18 Àwọn ẹ̀sìn kan ń kọ́ni pé tí èèyàn bá kú, ó máa pa ara dà di ẹni ẹ̀mí. Ohun tí irú àwọn ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ ń dọ́gbọ́n kọ́ni ni pé a gbọ́dọ̀ máa bọlá fún àwọn ẹni tó ti kú tàbí ká máa bẹ̀rù wọn, torí pé wọ́n ti di alágbára tó lè ranni lọ́wọ́ tàbí ọ̀tá tó lè ṣe wá ní jàǹbá. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti gba irọ́ yìí. Wọ́n ń bẹ̀rù àwọn tó ti kú, torí náà wọ́n ń jọ́sìn àwọn òkú dípò Jèhófà. Àmọ́, máa rántí pé ẹni tó ti kú ò mọ nǹkan kan mọ́, kò sì yẹ ká máa bẹ̀rù wọn. Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa. Òun ni Ọlọ́run tòótọ́, òun nìkan ṣoṣo ló yẹ ká máa jọ́sìn.​—Ìfihàn 4:11.

      19. Àǹfààní wo là ń rí bá a ṣe mọ òtítọ́ nípa ikú?

      19 Tá a bá mọ òtítọ́ nípa ikú, a máa bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ń kọ́ni. Òtítọ́ yìí á jẹ́ ká lóye àwọn ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe nípa ìgbésí ayé wa àti ọjọ́ ọ̀la wa.

      20. Kí la máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú orí tó kàn?

      20 Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tó ń jẹ́ Jóòbù béèrè pé: “Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè wà láàyè?” (Jóòbù 14:14) Ṣé ẹni tó ti kú lè tún pa dà wà láàyè? Ìdáhùn tí Ọlọ́run fún wa nínú Bíbélì máa mú inú wa dùn gan-an. A máa rí i nínú orí tó kàn.

      a Àwọn kan máa ń sọ pé tí ẹnì kan bá kú, ọkàn rẹ̀ tàbí ẹ̀mí rẹ̀ ṣì máa ń wà láàyè nìṣó. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo Àlàyé Ìparí Ìwé 17 àti 18.

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      ÒTÍTỌ́ 1: TÍ ÈÈYÀN BÁ KÚ, Ẹ̀MÍ RẸ̀ TI DÓPIN NÌYẸN

      “Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.”​—Oníwàásù 9:5

      Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá kú?

      • Sáàmù 146:3, 4; Oníwàásù 9:6, 10

        Tẹ́nì kan bá ti kú, kò lè ríran, kò lè gbọ́ràn, kò sì lè ronú mọ́.

      • Jòhánù 11:11-14

        Jésù fi ikú wé oorun.

      ÒTÍTỌ́ 2: JÈHÓFÀ Ò FẸ́ KÍ ÀWỌN ÈÈYÀN MÁA KÚ

      “O ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, torí ó dájú pé ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ lo máa kú.”​—Jẹ́nẹ́sísì 2:17

      Kí nìdí tá a fi ń kú?

      • Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6

        Sátánì parọ́ fún Éfà pé kò sí nǹkan kan tó máa ṣẹlẹ̀ sí i tó bá ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run. Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, wọ́n dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì kú lẹ́yìn náà.

      • Jẹ́nẹ́sísì 3:19

        Lẹ́yìn tí Ádámù kú, kò sí mọ́.

      • Róòmù 5:12

        Ẹ̀ṣẹ̀ dà bí àrùn burúkú tá a jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa, ìdí nìyẹn tá a fi ń kú.

      • 1 Kọ́ríńtì 15:26

        Bíbélì pe ikú ní ọ̀tá wa.

      ÒTÍTỌ́ 3: ÒTÍTỌ́ NÍPA IKÚ SỌ WÁ DI ÒMÌNIRA

      “Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè wà láàyè? Màá dúró .  . . títí ìtura mi fi máa dé.”​—Jóòbù 14:14

      Báwo ni òtítọ́ tá a mọ̀ nípa ikú ṣe sọ wá di òmìnira lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké?

      • 1 Jòhánù 4:8

        Ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì ń tàbùkù sí Jèhófà. Kò lè fi irú ìyà bẹ́ẹ̀ jẹ èèyàn láé.

      • Ìfihàn 4:11

        Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bẹ̀rù àwọn tó ti kú, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń jọ́sìn àwọn òkú dípò Jèhófà. Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, òun nìkan ṣoṣo ló sì yẹ ká máa jọ́sìn.

  • Àjíǹde Máa Wà!
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
    • ORÍ KEJE

      Àjíǹde Máa Wà!

      1-3. Kí ló sọ gbogbo wa di èrò ẹ̀wọ̀n, báwo sì ni Jèhófà ṣe máa tú wa sílẹ̀?

      KÁ SỌ pé wọ́n jù ẹ́ sẹ́wọ̀n gbére nítorí ọ̀ràn tí o kò mọ ohunkóhun nípa ẹ̀, kò sì sí ìrètí pé wọ́n máa tú ẹ sílẹ̀. O ti gbà pé kò sọ́nà àbáyọ kankan mọ́. Àmọ́, o wá gbọ́ pé ẹnì kan wà tó ní agbára láti tú ẹ sílẹ̀, ẹni náà sì ṣèlérí pé òun á ràn ẹ́ lọ́wọ́! Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ?

      2 Ikú ti sọ gbogbo wa di èrò ẹ̀wọ̀n. A ò rí ọgbọ́n kankan dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀nà àbáyọ fún wa. Àmọ́ Jèhófà ní agbára láti gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú. Ó sì ti ṣèlérí pé “ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn ni a ó sọ di asán.”​—1 Kọ́ríńtì 15:26.

      3 Fojú inú wo bí ara ṣe máa tù ẹ́ tó, tó o bá mọ̀ pé àwa èèyàn ò ní máa kú mọ́. Àmọ́ kì í ṣe pé Jèhófà máa mú ikú kúrò nìkan ni, ó tún máa jí àwọn tó ti kú dìde. Ronú nípa ohun tí ìyẹn máa túmọ̀ sí. Jèhófà ṣèlérí pé “àwọn tí ikú ti pa” máa tún pa dà wà láàyè. (Àìsáyà 26:19) Ohun tí Bíbélì pè ní àjíǹde nìyẹn.

      TÍ ẸNI TÁ A FẸ́RÀN BÁ KÚ

      4. (a) Kí ló lè tù wá nínú tí mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ wa bá kú? (b) Àwọn wo ló wà lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Jésù?

      4 Nígbà tí mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ wa bá kú, ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn wa máa ń pọ̀ gan-an. Ayé á wá sú wa, torí kò sí ohun tá a lè ṣe tẹ́ni náà á fi pa dà wà láàyè. Àmọ́ Bíbélì fún wa ní ìtùnú gidi. (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.) Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé ó ń wu Jèhófà àti Jésù gan-an láti jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó sábà máa ń lọ sọ́dọ̀ Lásárù àtàwọn arábìnrin rẹ̀ Màtá àti Màríà. Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Jésù ni àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Bíbélì sọ pé: “Jésù fẹ́ràn Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù.” Àmọ́, lọ́jọ́ kan, Lásárù kú.​—Jòhánù 11:3-5.

      5, 6. (a) Kí ni Jésù ṣe nígbà tó rí i pé àwọn ẹbí Lásárù àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀? (b) Kí nìdí tó fi tuni nínú láti mọ̀ pé ó máa ń dun Jésù téèyàn bá kú?

      5 Jésù lọ tu Màtá àti Màríà nínú. Nígbà tí Màtá gbọ́ pé Jésù ń bọ̀, ó lọ sẹ́yìn odi ìlú láti lọ pàdé ẹ̀. Inú ẹ̀ dùn láti rí Jésù, àmọ́ ó sọ fún un pé: “Ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú.” Màtá rò pé Jésù ti pẹ́ jù. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù rí Màríà tó ń sunkún. Bí Jésù ṣe rí i tí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò, ó dùn ún, ó sì sunkún. (Jòhánù 11:21, 33, 35) Ó máa ń dun Jésù gan-an tí èèyàn wa bá kú.

      6 Ìtùnú ló jẹ́ fún wa bá a ṣe mọ̀ pé ó máa ń dun Jésù náà tí èèyàn wa bá kú. Jésù sì fi ìyẹn jọ Baba rẹ̀. (Jòhánù 14:9) Jèhófà ní agbára láti mú ikú kúrò títí láé, ohun tó sì máa ṣe láìpẹ́ nìyẹn.

      “LÁSÁRÙ, JÁDE WÁ!”

      7, 8. Kí nìdí tí Màtá kò fi fẹ́ kí wọ́n gbé òkúta náà kúrò ní ibojì Lásárù, àmọ́ kí ni Jésù ṣe?

      7 Nígbà tí Jésù dé ibi tí wọ́n tẹ́ òkú Lásárù sí, wọ́n ti fi òkúta ńlá kan dí ẹnu ọ̀nà ibẹ̀. Jésù sọ pé: “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Àmọ́, Màtá ò fẹ́ kí wọ́n gbé e kúrò. Ìdí sì ni pé ọjọ́ mẹ́rin ni òkú Lásárù ti wà nínú ibojì. (Jòhánù 11:39) Màtá ò sì mọ ohun tí Jésù máa tó ṣe láti ran arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́.

      Nígbà tí Jésù jí Lásárù dìde, inú àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Lásárù dùn

      Wo bí inú ẹbí àti ọ̀rẹ́ Lásárù ṣe máa dùn tó nígbà tí Jésù jí i dìde!​—Jòhánù 11:38-44

      8 Jésù sọ fún Lásárù pé: “Jáde wá!” Ohun tí Màtá àti Màríà rí lẹ́yìn náà jẹ́ ìyàlẹ́nu gbáà fún wọn. “Ọkùnrin tó ti kú náà jáde wá, tòun ti aṣọ tí wọ́n fi dì í tọwọ́tẹsẹ̀ àti aṣọ tí wọ́n fi di ojú rẹ̀.” (Jòhánù 11:43, 44) Lásárù ti jí dìde! Òun àtàwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tún pa dà ríra. Wọ́n fọwọ́ kàn án, wọ́n dì mọ́ ọn, wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀. Iṣẹ́ ìyanu gbáà ni èyí jẹ́! Jésù ti jí Lásárù dìde.

      “ỌMỌBÌNRIN, MO SỌ FÚN Ọ, ‘DÌDE!’”

      9, 10. (a) Ta ló fún Jésù ní agbára láti jí àwọn èèyàn dìde? (b) Kí nìdí tí àwọn àkọsílẹ̀ nípa àjíǹde fi wúlò fún wa?

      9 Ṣé agbára Jésù ló fi jí àwọn èèyàn dìde? Rárá o. Jésù gbàdúrà sí Jèhófà kó tó jí Lásárù dìde, Jèhófà sì fún un lágbára. (Ka Jòhánù 11:41, 42.) Kì í ṣe Lásárù nìkan ni Jésù jí dìde. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa ọmọbìnrin ọlọ́dún méjìlá (12) kan tó ń ṣàìsàn tó le gan-an. Jáírù bàbá rẹ̀ ń wá bí ara ọmọ rẹ̀ ṣe máa yá lójú méjèèjì, ló bá bẹ Jésù pé kó wò ó sàn. Òun nìkan sì ni ọmọ tó bí. Bó ṣe ń bá Jésù sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn ọkùnrin kan wá sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin rẹ ti kú! Kí ló dé tí o ṣì ń yọ Olùkọ́ lẹ́nu?” Àmọ́ Jésù sọ fún Jáírù pé: “Má bẹ̀rù, ṣáà ti ní ìgbàgbọ́, ara ọmọ náà sì máa yá.” Ni Jésù bá tẹ̀ lé Jáírù lọ sí ilé rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ ilé náà, Jésù rí àwọn èèyàn tó ń sunkún. Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ má sunkún mọ́, torí kò kú, ó ń sùn ni.” Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Jésù ń sọ má yé àwọn òbí ọmọ náà. Jésù wá sọ pé kí gbogbo wọn jáde síta, ó wá mú bàbá àti ìyá ọmọ náà lọ sínú yàrá tí wọ́n tẹ́ ọmọ náà sí. Jésù wá di ọwọ́ ọmọ náà mú, ó sì sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin, mo sọ fún ọ, ‘dìde!’” Wo bí inú àwọn òbí rẹ̀ ṣe máa dùn tó nígbà tó dìde tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn! Jésù jí ọmọbìnrin wọn dìde. (Máàkù 5:22-24, 35-42; Lúùkù 8:49-56) Láti ọjọ́ yẹn lọ, bí wọ́n ṣe ń rí ọmọdébìnrin wọn ni wọ́n á máa rántí ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn nípasẹ̀ Jésù.a

      10 Òótọ́ ni pé àwọn tí Jésù jí dìde tún pa dà kú. Àmọ́ ohun tá a kà nípa àwọn èèyàn yìí fún wa ní ìrètí tó dájú. Ó wu Jèhófà láti jí àwọn èèyàn dìde, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀.

      OHUN TÁ A RÍ KỌ́ NÍNÚ ÀKỌSÍLẸ̀ NÍPA ÀJÍǸDE

      Àwọn èèyàn ń wo Pétérù, bó ṣe ń jí Dọ́káàsì dìde

      Àpọ́sítélì Pétérù jí Kristẹni obìnrin kan tó ń jẹ́ Dọ́káàsì dìde.​—Ìṣe 9:36-42

      Opó kan ń gbá ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́ra, lẹ́yìn tí Èlíjà jí ọmọ náà dìde

      Èlíjà jí ọmọkùnrin opó kan dìde.​—1 Àwọn Ọba 17:17-24

      11. Kí ni Oníwàásù 9:5 kọ́ wa nípa Lásárù?

      11 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.” Lásárù náà ò mọ nǹkan kan nígbà tó kú. (Oníwàásù 9:5) Bí Jésù ṣe sọ, ńṣe ló dà bíi pé Lásárù ń sùn. (Jòhánù 11:11) Nígbà tí Lásárù wà nínú sàréè, kò mọ “nǹkan kan rárá.”

      12. Báwo la ṣe mọ̀ pé Lásárù jíǹde lóòótọ́?

      12 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù jí Lásárù dìde. Àwọn ọ̀tá Jésù náà mọ̀ pé ó ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí. Bí Lásárù ṣe pa dà wà láàyè jẹ́ ẹ̀rí pé àjíǹde náà ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. (Jòhánù 11:47) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló lọ kí Lásárù, èyí sì jẹ́ kí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló rán Jésù lóòótọ́. Inú àwọn ọ̀tá Jésù ò dùn sí èyí, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń wá bí wọ́n ṣe máa pa Jésù àti Lásárù.​—Jòhánù 11:53; 12:9-11.

      13. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde?

      13 Jésù sọ pé “gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí” ló máa jíǹde. (Jòhánù 5:28) Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìrántí Jèhófà ló máa pa dà wà láàyè. Àmọ́ kí Jèhófà tó lè jí ẹnì kan dìde, ó gbọ́dọ̀ rántí gbogbo nǹkan nípa ẹni náà. Àmọ́, ṣé Jèhófà lè rántí gbogbo nǹkan nípa àwọn tó máa jí dìde? Rò ó wò ná, àìmọye ìràwọ̀ ló wà lójú ọ̀run. Bíbélì sọ pé Jèhófà mọ orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìràwọ̀ yìí. (Ka Àìsáyà 40:26.) Tó bá lè rántí orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìràwọ̀, ó dájú pé ó máa rọrùn fún un láti rántí gbogbo nǹkan nípa àwọn tó máa jí dìde. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jèhófà ló dá ohun gbogbo, torí náà a mọ̀ pé ó ní agbára láti jí àwọn tó ti kú dìde.

      14, 15. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Jóòbù sọ nípa àjíǹde?

      14 Jóòbù tó jẹ́ ọkùnrin olóòótọ́ gbà pé Ọlọ́run lè jí àwọn òkú dìde. Ó béèrè pé: “Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè wà láàyè?” Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Jèhófà pé: “O máa pè, màá sì dá ọ lóhùn. Ó máa wù ọ́ gan-an láti rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” Ó dá Jóòbù lójú pé Jèhófà ń dúró de àsìkò tó máa jí àwọn òkú dìde.​—Jóòbù 14:​13-15.

      15 Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe rí lára ẹ? O lè máa ronú pé, ‘Ṣé àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ mi tó ti kú ṣì máa jíǹde?’ Ìtùnú ló jẹ́ fún wa bá a ṣe mọ̀ pé ó wu Jèhófà gan-an láti jí àwọn tó ti kú dìde. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn tó máa jíǹde àti ibi tí wọ́n á máa gbé.

      WỌ́N ‘MÁA GBỌ́ OHÙN RẸ̀, WỌ́N Á SÌ JÁDE WÁ’

      16. Irú ìgbésí ayé wo ni àwọn tó bá jíǹde máa gbádùn?

      16 Orí ilẹ̀ ayé ni àwọn tó kú nígbà àtijọ́ jíǹde sí, tí wọ́n sì tún rí ẹbí àti ọ̀rẹ́ wọn pa dà. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ ó tún máa dáa jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn tó máa jíǹde máa ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé, wọn ò sì ní kú mọ́. Wọ́n á sì máa gbé inú ayé kan tó yàtọ̀ gan-an sí èyí tí à ń gbé lónìí. Kò ní sí ogun, ìwà ọ̀daràn àti àìsàn mọ́.

      17. Àwọn wo ló máa jíǹde?

      17 Àwọn wo ló máa jíǹde? Jésù sọ pé ‘gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀, wọ́n á sì jáde wá.’ (Jòhánù 5:28, 29) Bákan náà, Ìfihàn 20:13 sọ pé: “Òkun yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú rẹ̀, ikú àti Isà Òkú yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú wọn.” Ìyẹn fi hàn pé àìmọye èèyàn ló máa jíǹde. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwọn “olódodo àti àwọn aláìṣòdodo” ló máa jíǹde. (Ka Ìṣe 24:15.) Kí ni èyí túmọ̀ sí?

      Nínú Párádísè, àwọn tó jíǹde máa pa dà rí àwọn èèyàn wọn

      Nínú Párádísè, àwọn tó ti kú máa jíǹde, wọ́n á sì pa dà rí àwọn èèyàn wọn

      18. Àwọn wo ni “olódodo” tó máa jíǹde?

      18 Lára “àwọn olódodo” tó máa jíǹde ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n gbé ayé kí Jésù tó wá sáyé. Àwọn bíi Nóà, Ábúráhámù, Sérà, Mósè, Rúùtù àti Ẹ́sítà wà lára àwọn tó máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé níbí. O lè kà nípa díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin àti obìnrin yìí nínú Hébérù orí 11. Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó bá kú lóde òní ńkọ́? Àwọn náà wà lára àwọn “olódodo,” torí náà Ọlọ́run máa jí wọn dìde.

      19. Àwọn wo ni “aláìṣòdodo”? Àǹfààní wo ni Jèhófà máa fún wọn?

      19 Àwọn kan wà tí wọn kò ní àǹfààní láti mọ Jèhófà títí wọ́n fi kú, àwọn ni “àwọn aláìṣòdodo” tó máa jíǹde. Bí wọ́n tiẹ̀ ti kú, Jèhófà ò gbàgbé wọn. Ó máa jí wọn dìde, wọ́n á ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ kí wọ́n sì máa sìn ín.

      20. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó ti kú ló máa jíǹde?

      20 Ṣé ìyẹn túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó ti kú ló máa jíǹde? Rárá o. Jésù sọ pé àwọn kan ò ní jíǹde. (Lúùkù 12:5) Ta ló máa pinnu bóyá ẹnì kan máa jíǹde àbí kò ní jíǹde? Jèhófà ni adájọ́ tó ga jù lọ, àmọ́ ó ti fún Jésù ní ọlá àṣẹ láti jẹ́ “onídàájọ́ alààyè àti òkú.” (Ìṣe 10:42) Torí náà, tó bá dá ẹnikẹ́ni lẹ́jọ́ pé ó jẹ́ ẹni burúkú tí kò ṣe tán láti yí pa dà, kò ní jí irú ẹni bẹ́ẹ̀ dìde.​—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 19.

      ÀJÍǸDE SÍ Ọ̀RUN

      21, 22. (a) Kí ni àjíǹde sí ọ̀run túmọ̀ sí? (b) Ta ló kọ́kọ́ jíǹde sí ọ̀run?

      21 Bíbélì tún sọ pé àwọn èèyàn kan máa gbé ní ọ̀run. Tí Ọlọ́run bá jí ẹnì kan dìde sí ọ̀run, kò ní jíǹde bí èèyàn ẹlẹ́ran ara. Ọ̀run ló máa jíǹde sí bí ẹni ẹ̀mí.

      22 Jésù ni ẹni àkọ́kọ́ tó jíǹde sí ọ̀run. (Jòhánù 3:13) Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta tí wọ́n pa Jésù, Jèhófà jí i dìde. (Sáàmù 16:10; Ìṣe 13:34, 35) Àmọ́, Jésù kò jí dìde pẹ̀lú ara èèyàn. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù, ó ní: “Wọ́n pa á nínú ẹran ara, àmọ́ a sọ ọ́ di ààyè nínú ẹ̀mí.” (1 Pétérù 3:18) Ọlọ́run jí Jésù dìde ní ẹni ẹ̀mí alágbára! (1 Kọ́ríńtì 15:3-6) Àmọ́ Bíbélì sọ pé Jésù nìkan kọ́ ló máa jíǹde sí ọ̀run.

      23, 24. Àwọn wo ni Jésù pè ní “agbo kékeré,” mélòó sì ni wọ́n?

      23 Nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù kú, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Mò ń lọ kí n lè pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín.” (Jòhánù 14:2) Èyí túmọ̀ sí pé díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa jíǹde tí wọ́n á sì máa gbé pẹ̀lú rẹ̀ lọ́run. Mélòó ni wọ́n? Jésù pè wọ́n ní “agbo kékeré,” tó túmọ̀ sí pé wọ́n kéré níye. (Lúùkù 12:32) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ iye tí wọ́n jẹ́ gangan nínú ìran tí Ọlọ́run fi hàn án, tí Jésù ‘dúró lórí Òkè Síónì [ti ọ̀run], tí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) sì wà pẹ̀lú rẹ̀.’​—Ìfihàn 14:1.

      24 Ìgbà wo ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) yìí máa jí dìde? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé èyí máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Kristi bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní ọ̀run. (1 Kọ́ríńtì 15:23) Àkókò yẹn la wà báyìí, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ló sì ti jí dìde sí ọ̀run. Tí èyíkéyìí lára wọn bá sì kú lónìí, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló máa jíǹde sí ọ̀run. Àmọ́ lọ́jọ́ iwájú, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn ló máa jíǹde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

      25. Kí la máa kọ́ nínú orí tó kàn?

      25 Láìpẹ́, Jèhófà máa gba gbogbo èèyàn lọ́wọ́ ikú, kò sì ní sí ikú mọ́ títí láé! (Ka Àìsáyà 25:8.) Àmọ́ kí ni àwọn tó ń lọ sọ́run á máa ṣe níbẹ̀? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba kan. A máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìjọba yẹn ní orí tó kàn.

      a Nínú àwọn àkọsílẹ̀ míì, Bíbélì sọ nípa àjíǹde ọmọdé àti àgbà, ọkùnrin àti obìnrin àti tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àjèjì. O lè kà nípa wọn nínú 1 Àwọn Ọba 17:17-24; 2 Àwọn Ọba 4:32-37; 13:20, 21; Mátíù 28:5-7; Lúùkù 7:11-17; 8:40-56; Ìṣe 9:36-42; 20:7-12.

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      ÒTÍTỌ́ 1: JÈHÓFÀ MÁA MÚ IKÚ KÚRÒ

      “Ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn ni a ó sọ di asán.”​—1 Kọ́ríńtì 15:26

      Tí ẹnì kan bá kú, báwo ni Bíbélì ṣe ń fún wa ní ìtùnú gidi?

      • 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4

        Tí èèyàn wa tàbí ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ wa bá kú, ó máa ń ṣe wá bíi pé a ò ní olùrànlọ́wọ́. Bíbélì fún wa ní ìtùnú gidi.

      • Àìsáyà 25:8; 26:19

        Jèhófà ní agbára láti mú ikú kúrò títí láé. Kódà, ó máa jí àwọn tó ti kú dìde.

      ÒTÍTỌ́ 2: Ó DÁJÚ PÉ ÀWỌN ÒKÚ MÁA JÍǸDE

      “Ọmọbìnrin, mo sọ fún ọ, ‘dìde!’”​—Máàkù 5:41

      Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé àjíǹde máa ṣẹlẹ̀?

      • Jòhánù 11:1-44

        Jésù jí Lásárù dìde.

      • Máàkù 5:22-24, 35-42

        Jésù jí ọmọbìnrin kan dìde.

      • Jòhánù 11:41, 42

        Jésù lo agbára tí Jèhófà fún un láti jí àwọn òkú dìde.

      • Jòhánù 12:9-11

        Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù jí àwọn òkú dìde. Àwọn ọ̀tá Jésù pàápàá mọ̀ pé ó lè ṣe bẹ́ẹ̀.

      ÒTÍTỌ́ 3: JÈHÓFÀ MÁA JÍ ÀÌMỌYE ÈÈYÀN DÌDE

      “O máa pè, màá sì dá ọ lóhùn. Ó máa wù ọ́ gan-an láti rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”​—Jóòbù 14:13-15

      Àwọn wo ló máa jíǹde?

      • Jòhánù 5:28, 29

        Gbogbo àwọn tó wà nínú ìrántí Jèhófà máa jíǹde.

      • Ìṣe 24:15

        Àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo máa jí dìde.

      • Àìsáyà 40:26

        Tí Jèhófà bá lè rántí orúkọ ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan, ó dájú pé ó máa rọrùn fún un láti rántí gbogbo nǹkan nípa àwọn tó máa jí dìde.

      ÒTÍTỌ́ 4: ÀWỌN KAN MÁA JÍǸDE SÍ Ọ̀RUN

      “Mò ń lọ kí n lè pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín.”​—Jòhánù 14:2

      Àwọn wo ló máa jíǹde sí ọ̀run?

      • 1 Pétérù 3:18

        Jésù ló kọ́kọ́ jíǹde sí ọ̀run.

      • Lúùkù 12:32

        Jésù sọ pé díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ló máa jíǹde sí ọ̀run.

      • Ìfihàn 14:1

        Jèhófà ti yan ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) èèyàn láti lọ sí ọ̀run.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́