ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lff ẹ̀kọ́ 20
  • Bá A Ṣe Ṣètò Ìjọ Kristẹni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Ṣètò Ìjọ Kristẹni
  • Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
  • KÓKÓ PÀTÀKÌ
  • ṢÈWÁDÌÍ
  • Báwo Ni Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Ran Ìjọ Lọ́wọ́?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
  • “Ẹ Ní Ẹ̀mí Ìkanisí Fún Àwọn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára Láàárín Yín”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • “Pe Àwọn Alàgbà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • “Ẹ Máa Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Ọlọ́run Tí Ń bẹ Lábẹ́ Àbójútó Yín”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
lff ẹ̀kọ́ 20
Ẹ̀kọ́ 20. Ní ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, arákùnrin kan béèrè ìbéèrè, àwọn ará lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà nawọ́ láti dáhùn.

Ẹ̀KỌ́ 20

Bá A Ṣe Ṣètò Ìjọ Kristẹni

Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé

Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó máa ń ṣe nǹkan létòlétò. (1 Kọ́ríńtì 14:33) Torí náà, ó yẹ káwọn èèyàn rẹ̀ wà létòlétò. Báwo la ṣe ṣètò ìjọ Kristẹni? Kí la lè ṣe tí nǹkan á fi máa lọ létòlétò nínú ìjọ?

1. Ta ni olórí ìjọ Kristẹni?

‘Kristi ni orí ìjọ.’ (Éfésù 5:23) Láti ọ̀run ni Kristi ti ń darí ìjọ àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé. Jésù yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tó jẹ́ àwùjọ àwọn alàgbà tí wọ́n ti ń sin Jèhófà bọ̀ tipẹ́, tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì yé wọn dáadáa. A tún mọ̀ wọ́n sí Ìgbìmọ̀ Olùdarí. (Ka Mátíù 24:45-47.) Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tí wọ́n wà ní Jerúsálẹ́mù ló máa ń tọ́ àwọn Kristẹni sọ́nà. Bákan náà lóde òní, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló máa ń tọ́ àwọn ìjọ wa sọ́nà kárí ayé. (Ìṣe 15:2) Àmọ́, àwọn ọkùnrin yìí kì í ṣe olórí ẹ̀sìn wa o. Àṣẹ Jèhófà tó wà nínú Bíbélì ni wọ́n ń tẹ̀ lé, wọ́n sì ń jẹ́ kí Jésù máa darí àwọn.

2. Kí ni iṣẹ́ àwọn alàgbà?

Àwọn alàgbà ni àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tí wọ́n ti ń sin Ọlọ́run bọ̀ tipẹ́. Wọ́n máa ń fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn Jèhófà, wọ́n máa ń bójú tó wọn, wọ́n máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń fún wọn níṣìírí. Wọn kì í gbowó nítorí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ṣiṣẹ́ ‘tinútinú níwájú Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí èrè tí kò tọ́, àmọ́ wọ́n ń fi ìtara ṣe é látọkàn wá.’ (1 Pétérù 5:1, 2) Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló máa ń ran àwọn alàgbà lọ́wọ́, tó bá yá, àwọn náà lè kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń yan àwọn alàgbà kan láti di alábòójútó àyíká. Àwọn alábòójútó àyíká yìí máa ń bẹ àwọn ìjọ wò kí wọ́n lè tọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin sọ́nà, kí wọ́n sì fún wọn lókun. Wọ́n tún máa ń yan àwọn arákùnrin tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ láti di alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.​—1 Tímótì 3:1-10, 12; Títù 1:5-9.

3. Kí ni ojúṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan?

Gbogbo wa nínú ìjọ máa ń “yin orúkọ Jèhófà.” Ọ̀nà tá à ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a máa ń dáhùn ìbéèrè nípàdé, a sì máa ń fi iṣẹ́ ìwàásù dánra wò, a máa ń gbọ́ àsọyé, a máa ń kọrin, a sì máa ń wàásù fáwọn èèyàn bí agbára kálukú wa bá ṣe mọ.​—Ka Sáàmù 148:12, 13.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa irú aṣáájú tí Jésù jẹ́, bí àwọn alàgbà ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, àti bá a ṣe lè máa ṣègbọràn sí Jésù ká sì máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn alàgbà.

4. Aṣáájú tó lójú àánú ni Jésù

Jésù ń fìfẹ́ pè wá pé ká sún mọ́ òun. Ka Mátíù 11:28-30, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Irú aṣáájú wo ni Jésù? Kí ló sọ pé òun máa ṣe fún wa?

Báwo làwọn alàgbà ṣe ń tẹ̀ lé apẹẹrẹ Jésù? Wo FÍDÍÒ yìí.

FÍDÍÒ: Àwọn Alàgbà Dìde Ìrànwọ́ Nígbà Ìmìtìtì Ilẹ̀ Ní Nepal (4:56)

Bíbélì jẹ́ káwọn alàgbà mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ wọn.

Ka Àìsáyà 32:2 àti 1 Pétérù 5:1-3, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Báwo ló ṣe rí lára ẹ bó o ṣe mọ̀ pé àwọn alàgbà máa ń mára tu àwọn èèyàn bíi ti Jésù?

  • Àwọn ọ̀nà míì wo làwọn alàgbà máa ń gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

5. Ìwà àwọn alàgbà bá ohun tí wọ́n ń kọ́ni mu

Ojú wo ni Jésù fẹ́ káwọn alàgbà máa fi wo iṣẹ́ wọn? Wo FÍDÍÒ yìí.

FÍDÍÒ: Ẹ̀yin Alàgbà, Ẹ Máa Múpò Iwájú! (7:39)

Jésù fi ìlànà lélẹ̀ fáwọn alábòójútó nínú ìjọ. Ka Mátíù 23:8-12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ìlànà wo ló wà nínú Bíbélì tó yẹ káwọn alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni máa tẹ̀ lé? Ṣé o rò pé àwọn olórí ẹ̀sìn ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì yìí?

A. Àwòrán: Alàgbà kan ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. 1. Ó kọ́kọ́ gbàdúrà kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. 2. Ó ń kọ́ ọmọbìnrin rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyàwó rẹ̀ náà sì ń lóhùn sí i. B. Alàgbà yẹn àti ìyàwó rẹ̀ lọ wo arábìnrin kan nínú ìjọ wọn tó wà nílé ìwòsàn. D. Alàgbà yẹn lọ wàásù fún ọkùnrin kan nílé. E. Àwòrán: 1. Alàgbà yẹn ń sọ àsọyé nípàdé ìjọ. 2. Ó ń nu ilẹ̀ nípàdé.
  1. A. Àwọn alàgbà máa ń mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà lágbára, wọ́n sì ń ran ìdílé wọn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀

  2. B. Àwọn alàgbà máa ń bójú tó gbogbo àwọn ará ìjọ

  3. D. Àwọn alàgbà máa ń wàásù déédéé

  4. E. Àwọn alàgbà máa ń kọ́ni nínú ìjọ. Wọ́n tún máa ń ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó àtàwọn iṣẹ́ míì

6. Máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn alàgbà

Bíbélì sọ ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn alàgbà. Ka Hébérù 13:17, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé o rò pé ohun tí Bíbélì sọ bọ́gbọ́n mu pé ká máa ṣègbọràn sáwọn alábòójútó nínú ìjọ, ká sì máa tẹrí ba fún wọn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Ka Lúùkù 16:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn alàgbà kódà nínú àwọn ohun tá a rò pé kò tó nǹkan?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò pọn dandan kí n dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan kí n tó lè sin Ọlọ́run”

  • Àǹfààní wo lo rò pé ẹnì kan máa rí tó bá ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ láti jọ́sìn Ọlọ́run?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Jésù ni orí ìjọ. À ń fayọ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn alàgbà tí Jésù ń darí, torí pé wọ́n máa ń mára tù wá, ìwà wọn sì bá ohun tí wọ́n ń kọ́ni mu.

Kí lo rí kọ́?

  • Ta ni orí ìjọ?

  • Báwo làwọn alàgbà ṣe ń ran ìjọ lọ́wọ́?

  • Kí ni ojúṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Wo fídíò yìí kó o lè rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí àtàwọn alàgbà tó kù fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ àwa Kristẹni òde òní.

A Fún Àwọn Ará Wa Lókun Nígbà Tí Wọ́n Fòfin De Iṣẹ́ Wa (4:22)

Wo fídíò yìí kó o lè mọ iṣẹ́ táwọn alábòójútó àyíká ń ṣe.

Ìgbésí Ayé Alábòójútó Àyíká Tó Lọ Sìn ní Ìgbèríko Kan (4:51)

Ka àpilẹ̀kọ yìí, kó o lè mọ ipa táwọn obìnrin ń kó nínú ìjọ.

“Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Àwọn Obìnrin Tó Jẹ́ Òjíṣẹ́ Ọlọ́run?” (Ilé Ìṣọ́, September 1, 2012)

Ka ìwé yìí kó o lè mọ bí àwọn alàgbà ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láti fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ níṣìírí.

“Àwọn Alàgbà Jẹ́ ‘Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Fún Ìdùnnú Wa’” (Ilé Ìṣọ́, January 15, 2013)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́