ORÍ KẸWÀÁ
Ohun Tó Yẹ Kó o Ṣe Kó o Lè Ní Ìdílé Tó Ń múnú Ọlọ́run Dùn
1. Kí ló mú káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lápapọ̀ ní ìdílé aláyọ̀?
ÀWỌN èèyàn mọ̀ dáadáa pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìdílé aláyọ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Bryan Wilson tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Oxford University kọ̀wé pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fúnni ní onírúurú ìmọ̀ràn tó múná dóko . . . lórí àjọgbé tọkọtaya, lórí irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù, béèyàn ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ, àti lórí àwọn ọ̀ràn pàtàkì mìíràn. [Wọ́n] lè ranni lọ́wọ́ gan-an nípa fífúnni ní ojúlówó ìmọ̀ràn. Ìwé Mímọ́ ni wọ́n máa ń gbé ìmọ̀ràn wọn kà wọ́n sì máa ń jẹ́ kéèyàn rí i pé ìmọ̀ràn náà jẹ́ ara àwọn ohun tó yẹ kéèyàn máa tẹ̀ lé.” Kò sí àní-àní pé ìwọ alára ti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa béèyàn ṣe lè ní ìdílé aláyọ̀.
2. (a) Kí lo kíyè sí nípa àwọn ìdílé nínú ayé lónìí? (b) Inú àwọn ìwé wo nínú Bíbélì la ti fẹ́ wo ìtọ́sọ́nà nípa bí ìdílé ṣe lè jẹ́ aláyọ̀?
2 Bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé, ìdílé ni Sátánì ń gbógun tì jù. Ìyẹn ló fà á tí ọ̀pọ̀ ò fi ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ìdílé mọ́, bó ṣe rí nígbà ayé Míkà. Míkà kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú alábàákẹ́gbẹ́. . . . Ṣọ́ líla ẹnu rẹ lọ́dọ̀ obìnrin tí ń dùbúlẹ̀ ní oókan àyà rẹ. Nítorí ọmọkùnrin ń tẹ́ńbẹ́lú baba; ọmọbìnrin ń dìde sí ìyá rẹ̀; aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀; àwọn ọ̀tá ènìyàn ni àwọn ènìyàn agbo ilé rẹ̀.” (Míkà 7:5, 6) Ètò ìdílé ti jó àjórẹ̀yìn láyé òde òní, àmọ́ ìwọ ń sapá gan-an kí èèràn yẹn má bàa ràn ọ́. Ìyẹn ló mú kí ìdílé rẹ máa dára sí i, tó sì túbọ̀ ń tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Ó ṣeé ṣe kó o ti fi àwọn ẹsẹ Bíbélì bíi Diutarónómì 6:5-9; Éfésù 5:22–6:4; àti Kólósè 3:18-21 sílò. Àmọ́, ṣé o ti rò ó rí pé ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà jẹ́ ibi téèyàn ti lè rí ìmọ̀ràn nípa bí ìdílé ṣe lè jẹ́ aláyọ̀? Ní orí yìí, a óò gbé díẹ̀ yẹ̀ wò nínú irú àwọn ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ tó wà nínú àwọn ìwé náà. Ṣùgbọ́n má fi mọ sí wíwulẹ̀ gbé àwọn kókó tá a máa rí nínú àwọn ìmọ̀ràn náà yẹ̀ wò o. Látinú àwọn ìmọ̀ràn tí a óò gbé yẹ̀ wò, gbìyànjú láti mọ ọ̀nà pàtàkì tó o lè gbà rí àwọn ẹ̀kọ́ mìíràn kọ́ nínú àwọn ìwé méjìlá náà. Ní ìparí orí yìí, wàá rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wàá lò láti fi rí irú àwọn ẹ̀kọ́ mìíràn bẹ́ẹ̀ kọ́.
“ÒUN KÓRÌÍRA ÌKỌ̀SÍLẸ̀”
3, 4. (a) Lóde òní, ọ̀nà wo lọ̀pọ̀ tọkọtaya máa ń gbà yanjú ìṣòro wọn? (b) Ohun búburú wo ló ń wáyé láàárín àwọn tọkọtaya nígbà ayé Málákì?
3 Ìhà kan tó bọ́gbọ́n mu pé ká kọ́kọ́ gbé yẹ̀ wò ni àjọgbé tọkọtaya. Àìpẹ́ yìí làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í wo ìkọ̀sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tó rọrùn láti fòpin sí ìṣòro àárín tọkọtaya. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìkọ̀sílẹ̀ kì í ṣe ohun tó rọrùn láti gbà; ní nǹkan bí igba ọdún sẹ́yìn, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Ìgbìmọ̀ Aṣòfin gbọ́dọ̀ pinnu kí tọkọtaya tó lè kọra wọn sílẹ̀. Bí wọn kò ṣe fi ojú tó dára wo ìkọ̀sílẹ̀ nígbà yẹn kì í sábà jẹ́ kí ìdílé tú ká. Àmọ́ nǹkan ti yí padà lóde òní. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ńṣe làwọn tọkọtaya tó ń kọra wọn sílẹ̀ kàn ń pọ̀ sí i ṣáá ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì . . . Ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìkọ̀sílẹ̀ ti yí padà gan-an, . . . ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló ń fàyè gbà á báyìí.” Ìkọ̀sílẹ̀ ti di méjì eépìnnì láwùjọ, kódà, ó ti dà bẹ́ẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè bíi Kòríà tó jẹ́ pé, títí di nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ojú tí kò dára ni wọ́n fi ń wo ìkọ̀sílẹ̀. Lóde òní, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè làwọn èèyàn ti rò pé ìkọ̀sílẹ̀ jẹ́ ohun kan tó máa mú káwọn tọkọtaya bọ́ nínú ìṣòro tó wà láàárín wọn.
4 Nígbà ayé Málákì, ìyẹn ní ọ̀rúndún kárùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìkọ̀sílẹ̀ wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn Júù. Ni Málákì bá sọ fún wọn pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti jẹ́rìí láàárín ìwọ àti aya ìgbà èwe rẹ, ẹni tí ìwọ alára ti ṣe àdàkàdekè sí.” Nítorí àdàkàdekè táwọn ọkọ wọn ṣe sí wọn, omijé àwọn aya kún orí pẹpẹ Jèhófà, “pẹ̀lú ẹkún sísun àti ìmí ẹ̀dùn.” Àwọn àlùfáà oníwà ìbàjẹ́ sì fàyè gba irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀!—Málákì 2:13, 14.
5. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìkọ̀sílẹ̀? (b) Kí nìdí tí híhu ìwà àdàkàdekè sí aya tàbí ọkọ ẹni kì í fi í ṣe ọ̀ràn kékeré?
5 Ojú wo ni Jèhófà fi wo ohun búburú tó ń wáyé láàárín àwọn tọkọtaya nígbà ayé Málákì? Málákì kọ̀wé pé: “‘Òun kórìíra ìkọ̀sílẹ̀,’ ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí.” Ó tún tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà “kò yí padà.” (Málákì 2:16; 3:6) Ṣé o ti wá rí kókó náà báyìí? Látìgbà ìwáṣẹ̀ ni Ọlọ́run ti fi hàn pé òun lòdì sí ìkọ̀sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18, 24) Bákan náà ló kórìíra rẹ̀ nígbà ayé Málákì. Lóde òní náà sì rèé, ó ṣì kórìíra rẹ̀. Àwọn kan lè pinnu láti fòpin sí àjọgbé àwọn àtẹni tí wọ́n bá ṣègbéyàwó, kìkì nítorí pé onítọ̀hún ò tẹ́ wọn lọ́rùn. Àmọ́ bó ti wù kí ọkàn wọn jẹ́ aládàkàdekè tó, Jèhófà yóò wò ó fínnífínní láti mọ ohun tó wà ńbẹ̀. (Jeremáyà 17:9, 10) Irú ọgbọ́n tó wù kẹ́nì kan fi ṣe ìkọ̀sílẹ̀, Jèhófà mọ ẹ̀tàn tàbí ìpètepèrò ìwà ìkà tó mú kẹ́ni náà ṣe bẹ́ẹ̀. Dájúdájú, “ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.”—Hébérù 4:13.
6. (a) Tó o bá ń fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ìkọ̀sílẹ̀ wò ó, báwo ni ìyẹn á ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́? (b) Kí ni kókó pàtàkì tó wà nínú ìṣílétí Jésù nípa ìkọ̀sílẹ̀?
6 Ó ṣeé ṣe kí àjọgbé ìwọ àtẹni tó o bá ṣègbéyàwó má wà ní ipò tí ìkọ̀sílẹ̀ fi lè wáyé, síbẹ̀, ó dára kó o fi ojú tí Jèhófà fi ń wo ìkọ̀sílẹ̀ sọ́kàn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé aláìpé ni gbogbo wa, ìṣòro àti èdèkòyédè lè wáyé láàárín tọkọtaya. Àmọ́, ǹjẹ́ wàá rò pé ìkọ̀sílẹ̀ ni ọ̀nà àbáyọ tó rọrùn láti yanjú ìṣòro tẹ́ ẹ ní? Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe awuyewuye tó gbóná girigiri, ṣé o ò ní sọ pé àbí kẹ́ ẹ tiẹ̀ kọ ara yín sílẹ̀ ni? Àwọn kan ti ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àjọgbé tọkọtaya fi hàn pé ó yẹ káwọn tọkọtaya túbọ̀ sapá kí àjọgbé wọn má forí ṣánpọ́n. Òótọ́ ni pé Jésù sọ pé ohun kan ṣoṣo tó lè mú kí tọkọtaya kọ ara wọn sílẹ̀ lọ́nà tó bófin mu ni àgbèrè, ìyẹn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe aya ẹni tàbí ọkọ ẹni. Àmọ́, kí ni kókó pàtàkì tó wà nínú ìṣílétí Jésù? Ó sọ fáwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù gbé ìlànà Jèhófà tí kì í yí padà lárugẹ, ìyẹn ìlànà tí Málákì mẹ́nu kàn ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́ta [450] ọdún ṣáájú kí Jésù tó wá sórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 19:3-9.
Ǹjẹ́ wàá rò pé ìkọ̀sílẹ̀ ni ọ̀nà àbáyọ tí ìṣòro bá wà láàárín ìwọ àti ọkọ rẹ tàbí aya rẹ?
7. Níbàámu pẹ̀lú ìṣílétí tó wà nínú ìwé Málákì, báwo lo ṣe lè mú kí ìdè ìṣọ̀kan tó wà láàárín ìwọ àti ọkọ rẹ tàbí aya rẹ lágbára?
7 Nítorí náà, báwo làwọn tọkọtaya ò ṣe ní jẹ́ kí ìdè ìṣọ̀kan wọn já? Málákì sọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Kí ẹ sì ṣọ́ ara yín ní ti ẹ̀mí yín, kí ẹ má sì ṣe àdàkàdekè.” (Málákì 2:16) Ìyẹn túmọ̀ sí pé ká máa ṣọ́ra kí ẹ̀mí tó ń sún wa ṣe nǹkan má bàa díbàjẹ́. Tá a bá ń ‘ṣọ́ ẹ̀mí wa,’ a ò ní fàyè gba ìdẹwò láti fiyè sí ẹni tí kì í ṣe aya wa tàbí ọkọ wa lọ́nà tí kò yẹ. (Mátíù 5:28) Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ó máa ń dùn mọ́ wa nínú lọ́hùn-ún tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ń pọ́n wa tàbí tó bá ń fi hàn nínú ìṣe rẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa? Tó bá ń dùn mọ́ wa, ohun tí ìyẹn ń fi hàn ni pé a ò fọwọ́ pàtàkì mú ṣíṣọ́ ẹ̀mí wa mọ́. Nítorí náà, ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tó wà nínú àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ náà tó máa mú kí ìdè ìṣọ̀kan tó wà láàárín tọkọtaya lágbára ni pé, kí wọ́n máa ṣọ́ ‘ẹ̀mí wọn,’ ìyẹn ẹ̀mí tó ń sún wọn ṣe nǹkan.
Kí ni gbígbà tí Hóséà gba Gómérì padà kọ́ wa nípa Jèhófà?
8, 9. Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí àkọsílẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Hóséà àti Gómérì wà nínú Bíbélì?
8 Ó dájú pé o ti pinnu pé o ò ní jẹ́ kí mìmì kan mi àjọgbé ìwọ àtẹni tó o bá ṣègbéyàwó. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, máa rántí pé, o ò lè bọ́ pátápátá lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tó máa ń wáyé láàárín tọkọtaya. Ọ̀nà wo ló dára jù lọ tó o lè gbà bójú tó ìṣòro tó bá yọjú, pàápàá, àwọn ìṣòro tó o bá rò pé ọkọ rẹ tàbí aya rẹ ló fà á? Rántí ohun tí Orí Kejì àti Orí Kẹrin ìwé yìí sọ nípa Hóséà. Gómérì aya rẹ̀ di “àgbèrè aya,” ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ‘lépa àwọn olùfẹ́ rẹ̀ onígbòónára.’ Nígbà tó yá, àwọn tó ń tẹ̀ lé kiri wọ̀nyẹn já a jù sílẹ̀, ló bá di akúùṣẹ́ àti ẹrú. Hóséà fi iye kan rà á padà, Jèhófà si sọ pé kó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kí nìdí? Ó jẹ́ láti ṣàpèjúwe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín Jèhófà àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà yẹn. Jèhófà jẹ́ “ọkọ olówó orí” àwọn èèyàn rẹ̀, bí aya ni wọ́n jẹ́ sí i.—Hóséà 1:2-9; 2:5-7; 3:1-5; Jeremáyà 3:14; Aísáyà 62:4, 5.
9 Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò yẹn làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń ṣe ohun tó ń dun Jèhófà nípa títẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn. (Ẹ́kísódù 32:7-10; Àwọn Onídàájọ́ 8:33; 10:6; Sáàmù 78:40, 41; Aísáyà 63:10) Ti ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá àríwá ló burú jù, màlúù làwọn ń jọ́sìn ní tiwọn. (1 Àwọn Ọba 12:28-30) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó jẹ́ Ọkọ Olówó Orí wọn, àwọn olólùfẹ́ wọn tí wọ́n jẹ́ olóṣèlú ni wọ́n gbójú lé. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ń tẹ̀ lé Ásíríà bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà tó ń wá bó ṣe máa gùn lójú méjèèjì. (Hóséà 8:9) Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tí ọkọ rẹ tàbí aya rẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀?
10, 11. Báwo lo ṣe lè fara wé Jèhófà tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ tó sì dà bíi pé ọkọ rẹ tàbí aya rẹ ló jẹ̀bi?
10 Nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Hóséà, ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún méje ọdún tí Jèhófà ti bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà fẹ́ láti dárí jì wọ́n, kìkì bí wọ́n bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Hóséà ti bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣáájú ọdún 803 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nípa bẹ́ẹ̀, ọgọ́ta ọdún sí i ni Jèhófà fi fara dà á fún Ísírẹ́lì, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì ọdún sí i ló sì fi fara dà á fún Júdà! Nípa fífi ìdílé Hóséà ṣe àpèjúwe, Jèhófà ṣì ń pe àwọn èèyàn rẹ̀ tó bá dá májẹ̀mú pé kí wọ́n ronú pìwà dà. Ìdí tó bófin mu wà tó fi lè fòpin sí ìgbéyàwó tó bá Ísírẹ́lì ṣe, síbẹ̀, ó ṣì ń rán àwọn wòlíì láti ran aya rẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ lọ́wọ́ kó lè padà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrànlọ́wọ́ ọ̀hún ná òun alára ní nǹkan.—Hóséà 14:1, 2; Ámósì 2:11.
11 Tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀, tó sì dà bíi pé ọkọ rẹ tàbí aya rẹ ló jẹ̀bi, ǹjẹ́ wàá ṣe bíi ti Jèhófà? Ǹjẹ́ wàá kọ́kọ́ ṣe ohun tó máa mú kí àárín yín tún dáa bíi ti tẹ́lẹ̀? (Kólósè 3:12, 13) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni èyí ń béèrè. O ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dára ni Jèhófà fi lélẹ̀ nínú ọ̀nà tó gbà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò! (Sáàmù 18:35; 113:5-8) Ọlọ́run ‘bá ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀,’ kódà ó bẹ̀ wọ́n. Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa tá a jẹ́ ẹ̀dá èèyàn aláìpé ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ̀; ṣé kò yẹ ká bá ọkàn ọkọ wa tàbí aya wa sọ̀rọ̀, ká gbìyànjú láti yanjú ìṣòro tó wà láàárín wa ká sì gbójú fo àṣìṣe rẹ̀ dá? Bí ìsapá Jèhófà ṣe ní àbájáde rere kọ́ wa ní nǹkan kan. Àṣẹ́kù àwọn èèyàn náà jẹ́ ìpè Jèhófà nígbà tí wọ́n wà ní ìgbèkùn Bábílónì, nígbà tó sì yá, wọ́n padà sí ilẹ̀ wọn, wọ́n sì pe Jèhófà ní “ọkọ Mi.”—Hóséà 2:14-16.a
Fara wé Jèhófà nípa kíkọ́kọ́ dá ọ̀rọ̀ bí ẹ óò ṣe yanjú ìṣòro tó wà láàárín yín sílẹ̀
12. Tó o bá ronú lórí bí Jèhófà ṣe ṣe ọ̀ràn aya rẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ sí, ọ̀nà wo ni ìyẹn lè gbà ṣe àjọṣe ìwọ àtẹni tó o bá ṣègbéyàwó láǹfààní?
12 Tí ìṣòro ńlá bá wáyé, ìsapá àtọkànwá tó o bá ṣe láti mú kí àárín yín tún padà gún régé lè so èso rere. Àní Ọlọ́run múra tán láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, ìyẹn àgbèrè tẹ̀mí, ji aya rẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìṣòro tó sì wà láàárín àwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ni ò tíì le tó bẹ́ẹ̀. Ibi tí ọ̀pọ̀ ìṣòro ti máa ń bẹ̀rẹ̀ ni ká sọ ọ̀rọ̀ tó lè dunni tàbí ọ̀rọ̀ tó le jù. Nítorí náà, tí ọ̀rọ̀ tí ń gúnni bí idà tí aya rẹ tàbí ọkọ rẹ sọ bá dùn ọ́, rántí ohun tí Hóséà àti Jèhófà fúnra rẹ̀ fara dà. (Òwe 12:18) Ǹjẹ́ ìyẹn ò lè mú kó o dárí jì í?
13. Kí la lè rí kọ́ nínú bí Jèhófà ṣe béèrè pé káwọn èèyàn rẹ̀ ronú pìwà dà?
13 Ìhà míì tún wà nínú ìtàn yìí tí a óò gbé yẹ̀ wò. Ǹjẹ́ Ọlọ́run ṣe tán láti mú kí àjọṣe tó wà láàárín òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ padà bọ̀ sípò nígbà tí wọ́n ṣì ń ṣàgbèrè? Ohun tí Ọlọ́run sọ fún Hóséà nípa orílẹ̀-èdè onípanṣágà yẹn ni pé: ‘Kí ó mú àgbèrè rẹ̀ kúrò níwájú ara rẹ̀ àti ìwà panṣágà rẹ̀ kúrò láàárín ọmú rẹ̀.’ (Hóséà 2:2) Àwọn èèyàn náà ní láti ronú pìwà dà kí wọ́n sì ‘so èso tó yẹ ìrònúpìwàdà.’ (Mátíù 3:8) Lórí kókó yìí, má ṣe gbájú mọ́ àṣìṣe aya rẹ tàbí ọkọ rẹ, àṣìṣe tìrẹ ni kó o máa wá bí wàá ṣe ṣàtúnṣe rẹ̀. Tó o bá ti ṣẹ ọkọ rẹ tàbí aya rẹ, o ò ṣe wá bí àárín yín á ṣe tún gún régé, kó o bẹ̀ ẹ́ tọkàntọkàn kó o sì yí ìwà rẹ padà? Ó lè dárí jì ọ́.
“OKÙN ÌFẸ́” LÓ Ń MÚNI BÁNI WÍ
14, 15. (a) Pẹ̀lú ohun tí Málákì 4:1 sọ, kí nìdí tó fi yẹ kẹ́ ẹ fi ọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe yín láti máa kọ́ àwọn ọmọ yín? (b) Báwo lẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà?
14 A tún lè rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ sí i nípa ìdílé nínú àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò bó ṣe wà nínú àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ méjìlá náà. Àwọn ìwé wọ̀nyẹn fi bẹ́ ẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ hàn. Dájúdájú, títọ́ ọmọ ò rọrùn lóde ìwòyí. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe yìí. Ìwé Málákì sọ fún wa pé: “‘Ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò sì jẹ [àwọn ènìyàn] run dájúdájú,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘tó bẹ́ẹ̀ tí kì yóò fi fi yálà gbòǹgbò tàbí ẹ̀tun sílẹ̀ fún wọn.’” (Málákì 4:1) Lọ́jọ́ ìjíhìn yẹn, Jèhófà yóò fòdodo ṣèdájọ́ àwọn ọmọdé (ìyẹn àwọn ẹ̀tun, tàbí lédè mìíràn, àwọn ẹ̀ka), níbàámu pẹ̀lú ìdájọ́ tó ṣe fún àwọn òbí wọn, (ìyẹn àwọn gbòǹgbò), tí àwọn ọmọ náà wà níkàáwọ́ wọn. (Aísáyà 37:31) Ọ̀nà táwọn òbí gbà ń gbé ìgbé ayé wọn lè pinnu bóyá ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ wọn á dára tàbí kò ní dára. (Hóséà 13:16) Bí ẹ̀yin òbí, tẹ́ ẹ jẹ́ (gbòǹgbò) kò bá ṣe ìfẹ́ Jèhófà, kí ló ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ (ìyẹn àwọn ẹ̀tun, tàbí ẹ̀ka) yín ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà? (Sefanáyà 1:14-18; Éfésù 6:4; Fílípì 2:12) Àmọ́, tẹ́ ẹ bá ń sapá láti rí ojú rere Jèhófà, ìyẹn lè ṣe àwọn ọmọ yín láǹfààní.—1 Kọ́ríńtì 7:14.
15 Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì sọ nípa ìdí téèyàn fi ní láti ké pe orúkọ Jèhófà, ó kọ̀wé pé: “Báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀?” (Róòmù 10:14-17; Jóẹ́lì 2:32) Ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ni Pọ́ọ̀lù ń sọ, àmọ́ ẹ lè fi ìlànà tó wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò nínú kíkọ́ àwọn ọmọ yín. Báwo làwọn ọmọ yín ṣe lè nígbàgbọ́ nínú Jèhófà bí wọn kò bá gbọ́ nípa rẹ̀? Ǹjẹ́ ẹ máa ń fi àkókó tó tó sílẹ̀ lójoojúmọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ yín nípa bí Jèhófà ṣe dára tó, kẹ́ ẹ sì máa tipa bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀? Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ dẹni tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń jẹ lọ́kàn tí wọ́n bá ń gbọ́ nípa Jèhófà lójoojúmọ́ nínú ilé.—Diutarónómì 6:7-9.
16. Níbàámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Míkà 6:3-5, báwo lo ṣe lè fara wé Jèhófà nígbà tó o bá ń bá àwọn ọmọ rẹ wí?
16 Nígbà táwọn ọmọ wà ní kékeré, ó lè má ṣòro láti mú wọn lọ sí ìpàdé ìjọ. Àmọ́ bí wọ́n bá ṣe ń dàgbà, àwọn náà á bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tara wọn. Báwo lo ṣe lè ṣe ọ̀ràn àwọn ọmọ rẹ sí tó bá jẹ́ pé wọ́n máa ń fẹ́ hùwà bí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? O lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ méjìlá náà, kó o kíyè sí bí Jèhófà ṣe bá Ísírẹ́lì àti Júdà lò. (Sekaráyà 7:11, 12) Bí àpẹẹrẹ, bó o bá ṣe ń ka Míkà 6:3-5, kíyè sí irú ohùn tí Jèhófà fi bá wọn sọ̀rọ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe nǹkan tí kò dára; síbẹ̀ Jèhófà ṣì pè wọ́n ní “ènìyàn mi.” Ó bẹ̀ wọ́n pé: “Ìwọ ènìyàn mi, jọ̀wọ́, rántí.” Dípò kó fi ìbínú bá wọn wí, ńṣe ló gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ dé inú ọkàn wọn. Ǹjẹ́ o lè fara wé Jèhófà, kódà nígbà tó o bá ń bá àwọn ọmọ rẹ wí? Irú ìwàkiwà tó wù kí wọ́n hù, bá wọn lò gẹ́gẹ́ bí ara ìdílé rẹ, má ṣe sọ̀rọ̀ àbùkù sí wọn. Kàkà kó o bẹnu àtẹ́ lù wọ́n, ńṣe ni kó o pàrọwà fún wọn. Bi wọ́n ní ìbéèrè kó o lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ wọ̀ wọ́n lọ́kàn kí wọ́n lè sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn.—Òwe 20:5.
17, 18. (a) Kí ló yẹ kó mú ọ bá àwọn ọmọ rẹ wí? (b) Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí “okùn ìfẹ́” tó wà láàárín ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ le dan-indan-in, kó má ṣe já?
17 Kí nìdí tó o fi máa ń bá àwọn ọmọ rẹ wí? Àwọn òbí kan máa ń bá àwọn ọmọ wọn wí kí wọ́n má bàa ba orúkọ ìdílé jẹ́. Jèhófà sọ ìdí tó fi ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí, ó ní: “Mo kọ́ Éfúráímù ní ìrìn, ní gbígbé wọn sí apá mi . . . Mo ń bá a nìṣó láti fi àwọn ìjàrá ará ayé fà wọ́n, pẹ̀lú àwọn okùn ìfẹ́.” (Hóséà 11:3, 4) Nínú àpẹẹrẹ yìí, Hóséà fi àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àti Ísírẹ́lì wé àjọṣe tó wà láàárín bàbá àti ọmọ. Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo òbí kan tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́, tó mú okùn dání tó sì fi ń ṣamọ̀nà ọmọ tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tíì ranlẹ̀, tó ń ràn án lọ́wọ́ láti rìn? Okùn náà ni kò ní jẹ́ kí ọmọ náà ṣubú tó bá kọsẹ̀, yóò sì ṣamọ̀nà rẹ̀ tó bá forí lé ibi tí kò yẹ kó gbà.—Jeremáyà 31:1-3.
Ǹjẹ́ ìwọ òbí ń fara wé Jèhófà nínú bó o ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ rẹ?
18 Ǹjẹ́ wàá fara wé Ọlọ́run, kó o ní irú ìfẹ́ tó ní sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Léraléra ni wọ́n ń kọ ẹ̀yìn sí i, àmọ́ kò tètè fi okùn ìfẹ́ náà sílẹ̀. Ó dà bíi pé àwọn ọmọ máa ń rìn gbéregbère nígbà míì tàbí kí àwọn ohun tí ò tó nǹkan kọ́ wọn lẹ́sẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ gbìyànjú láti mú kí okùn ìfẹ́ tó wà láàárín ìwọ àtàwọn ọmọ náà le dan-indan-in, kó má ṣe já. Fi sọ́kàn pé Jèhófà kò jẹ́ kí inúure mú òun gbójú fo ìwàkiwà àwọn èèyàn òun. Ó ṣe ohun tó yẹ kó ṣe, ó fìfẹ́ bá wọn wí, ó sì fàyè sílẹ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò fún wọn. Tó o bá kíyè sí i pé ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin rẹ ti ń fi òtítọ́ sílẹ̀, má ṣe fi mímọ̀ ṣaláìmọ̀ o. Ńṣe ni kó o sapá láti tọ́ ọ sọ́nà, bíi pé ò ń fi okùn ṣamọ̀nà rẹ̀, kó o ràn án lọ́wọ́ ní àkókò ìṣòro yẹn. Ṣe sùúrù fún ọmọ oníwàhálà náà. Máa fi àkókò sílẹ̀ láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, ó ṣe pàtàkì gan-an!
19. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o sọ̀rètí nù nípa ọmọ rẹ?
19 Hóséà rí i tẹ́lẹ̀ pé àṣẹ́kù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò gba ìbáwí, ó ní: “Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò padà wá, wọn yóò sì wá Jèhófà Ọlọ́run wọn dájúdájú, [wọn] yóò sì wá Dáfídì ọba wọn; dájúdájú, wọn yóò sì fi ìgbọ̀npẹ̀pẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jèhófà àti sínú oore rẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́.” (Hóséà 3:5) Dájúdájú, ìbáwí Jèhófà ṣe àṣẹ́kù àwọn èèyàn rẹ̀ láǹfààní. Ní ẹ̀mí pé bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rí fáwọn ọmọ rẹ náà. Gbìyànjú láti máa rí ibi tí wọ́n dára sí. Fi sùúrù bá wọn sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n má ṣàìrọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì. Bí ọmọ aláìgbọràn kan ò bá tiẹ̀ yà sí nǹkan tó ò ń bá a sọ nísinsìnyí, ta ló mọ̀ bóyá á ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí orí rẹ̀ bá wálé?
MÁ ṢE KÓ ẸGBẸ́KẸ́GBẸ́!
20. Ìbéèrè wo nípa ẹgbẹ́ kíkó làwọn ọ̀dọ́ lè rí ìdáhùn sí nínú ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà?
20 Kí lẹ̀yin ọ̀dọ́ lè rí kọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táwọn òbí yín máa ń lò jù nígbà tí wọ́n bá ń bá yín sọ̀rọ̀ ni 1 Kọ́ríńtì 15:33, nípa bó ṣe yẹ kẹ́ ẹ yẹra fún ẹgbẹ́ búburú. Àwọn kan lára yín lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣé bẹ́ẹ̀ náà ni bíbá àwọn tí kì í jọ́sìn Jèhófà ṣọ̀rẹ́ burú tó ni?’ Ó dára, wàá rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn nínú àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí.
21-23. (a) Kí làwọn ọ̀dọ́ lè rí kọ́ nínú ohun tí àwọn ọmọ Édómù ṣe? (b) Àwọn wo gan-an lò ń bá ṣọ̀rẹ́?
21 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìwé méjìlá náà wà fún, ìwé Ọbadáyà sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ Édómù, tí Jèhófà pè ní arákùnrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.b (Diutarónómì 2:4) Ìwé Ọbadáyà ṣe ohun kan tí àwọn tó kù lára àwọn ìwé méjìlá náà kò ṣe, ó lo ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ náà, ìwọ, fún àwọn ọmọ Édómù nígbà tó ń bá wọn sọ̀rọ̀. Wàyí o, ronú nípa àwọn ọmọ Édómù. Ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni lohun tá à ń wí yìí ṣẹlẹ̀, nígbà táwọn ará Bábílónì sàga ti Jerúsálẹ́mù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbejì ni baba ńlá àwọn ọmọ Édómù àti baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí í ṣe Jékọ́bù, o jẹ́ mọ̀ pé ńṣe làwọn ọmọ Édómù ṣètìlẹ́yìn fáwọn ará Bábílónì nígbà tí wọ́n sàga ti Jerúsálẹ́mù! Wọ́n ń ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Tú u sí borokoto! Tú u sí borokoto”! (Sáàmù 137:7; Ọbadáyà 10, 12) Wọ́n pète pèrò láti gba ilẹ̀ Júdà. Kódà wọ́n bá àwọn ará Bábílónì jẹun, ohun tí ìyẹn sì máa ń fi hàn ní apá Ìwọ̀ Oòrùn ayé láyé ọjọ́un ni pé, ìhà méjèèjì ti bá ara wọn dá májẹ̀mú.
22 Wo nǹkan tí Ọbadáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọmọ Édómù. Ó ní: “Àní gbogbo àwọn ènìyàn [ìyẹn àwọn ará Bábílónì] tí ó wà nínú májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ ti tàn ọ́ jẹ. Àwọn ènìyàn tí ó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ ti borí rẹ. Àwọn tí ń bá ọ jẹun yóò fi àwọ̀n sábẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò ní ìfòyemọ̀.” (Ọbadáyà 7) Kí lohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an sáwọn ọmọ Édómù tí wọ́n ta Jékọ́bù arákùnrin wọn nù, tí wọ́n wá di ọ̀rẹ́ àwọn ará Bábílónì? Ńṣe làwọn ará Bábílónì lábẹ́ àṣẹ Nábónídọ́sì pa wọ́n run lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Málákì, Ọlọ́run ti sọ àwọn òkè Édómù dahoro, ó sì ti sọ ogún wọn di ti akátá.—Málákì 1:3.
23 Wàyí o, wá ronú nípa àwọn tí kì í jọ́sìn Jèhófà tó o pè ní ọ̀rẹ́ rẹ. Ṣé o ò tíì kíyè sí i ni, pé ‘àwọn ọmọkùnrin [tàbí àwọn ọmọbìnrin] tí wọ́n bá ara wọn dá májẹ̀mú,’ tàbí lédè mìíràn, tí wọ́n ń bára wọn ṣọ̀rẹ́, sábà máa ń tan ara wọn jẹ tí wọ́n sì máa ń “fi àwọ̀n sábẹ́” àwọn tí wọ́n pè ní ọ̀rẹ́ wọn? Nígbà tó bá sì wá hàn fáyé rí pé ẹ̀tàn lásán ni wọ́n ń bá ọ̀rẹ́ wọn ṣe, kí ni wọ́n máa ń sọ? Wọ́n lè sọ pé ọ̀dẹ̀ lọ̀rẹ́ àwọn táwọn tàn jẹ, pé kò gbọ́n tó láti mọ̀ téèyàn bá ń tàn án jẹ. Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn láàárín àwọn ará Bábílónì àtàwọn ọmọ Édómù ọ̀rẹ́ wọn! Ǹjẹ́ o rò pé irú “àwọn ọ̀rẹ́” bẹ́ẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí ìṣòro bá dé? (Ọbadáyà 13-16) Ó dáa, wá ronú nípa Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn èèyàn rẹ̀ òde òní. Jèhófà ṣe tán láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbàkigbà. Yóò fún ọ lágbára kó o lè la ìṣòro tó o bá ní já. Bẹ́ẹ̀ sì làwọn èèyàn rẹ̀ jẹ́ ‘alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ tó máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà,’ wọ́n dà bí arákùnrin tí a “bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.
Ṣé àwọn tó o pè ní ọ̀rẹ́ rẹ kì í “fi àwọ̀n sábẹ́ rẹ”?
MỌYÌ ÀJỌṢE TÓ ṢE PÀTÀKÌ JU GBOGBO ÀJỌṢE LỌ
24, 25. Kí ló yẹ kó gba ipò iwájú nígbèésí ayé wa?
24 Dájúdájú, àjọṣe tó wà nínú ìdílé ṣe pàtàkì gan-an ó sì yẹ kéèyàn jẹ́ kó lágbára. A lè rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ nípa àjọṣe tó wà nínú ìdílé nínú ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà. O ò ṣe ka àwọn ìwé náà kó o sì gbìyànjú láti fi àwọn ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú wọn sílò? Ìyẹn á jẹ́ kó o rí ẹ̀kọ́ tó pọ̀ sí i kọ́ nípa bó o ṣe lè jẹ́ kí àjọṣe tó wà nínú ìdílé rẹ dára sí i. Àmọ́, ǹjẹ́ níní ìdílé aláyọ̀ ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ sí àwọn olùjọsìn Ọlọ́run lónìí?
25 Inú wa dùn pé Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà tó ń bọ̀, pé: “Ẹ kó àwọn ènìyàn náà jọpọ̀. Ẹ sọ ìjọ di mímọ́. . . . Kí ọkọ ìyàwó jáde kúrò ní inú yàrá rẹ̀ inú lọ́hùn-ún, àti ìyàwó kúrò ní inú ìyẹ̀wù ìgbà ìgbéyàwó rẹ̀.” (Jóẹ́lì 2:15, 16) Gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé gbọ́dọ̀ máa kóra jọ fún ìjọsìn Jèhófà. Kódà èyí kan àwọn tọkọtaya ọ̀ṣìngín tó jẹ́ pé wọ́n máa ń ní ìpínyà ọkàn pàápàá! Ohunkóhun ò gbọ́dọ̀ gbapò iwájú lọ́wọ́ ìkórajọpọ̀ wa láti jọ́sìn Ọlọ́run. Pẹ̀lú bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń yára sún mọ́lé yìí, ohun tó yẹ kó gba ipò iwájú nínú ìgbésí ayé wa ni bí a óò ṣe máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ní ìsọ̀rí tó gbẹ̀yìn nínú ìwé yìí, a óò ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tó yẹ ká máa fayọ̀ ṣe lónìí.
a Tí ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni bá ṣe panṣágà, ọkọ rẹ̀ tàbí aya rẹ̀ ni yóò pinnu bóyá òun á dárí jì í tàbí òun ò ní dárí jì í.—Mátíù 19:9.
b Ìwé mìíràn tí kì í ṣe pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló wà fún ni ìwé Náhúmù, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ dá lórí àwọn ará Nínéfè.