ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bíbélì Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Nínú Ìgbéyàwó Rẹ
    Ilé Ìṣọ́—2003 | September 15
    • Bíbélì Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́ Nínú Ìgbéyàwó Rẹ

      ÌGBÉYÀWÓ—ọ̀rọ̀ àgbọ́dunnú lọ̀rọ̀ yìí jẹ́ létí àwọn kan. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ gbáà ló jẹ́ létí àwọn ẹlòmíràn. Obìnrin kan sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ pé: “Ńṣe ló máa ń ṣe mí bí ẹni pé èmi àti ọkọ mi ti kọ ara wa sílẹ̀. Gbogbo ìgbà ló máa ń dà bí ẹni pé ó ti pa mí tì, tí mi ò sì ní alábàárò.”

      Kí ló fà á tí ẹni méjì tó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn á máa nífẹ̀ẹ́ ara àwọn, pé àwọn á sì tún máa ṣìkẹ́ ara wọn wá di ẹni tí kò fẹ́ràn ara wọn mọ́? Ìdí kan ni pé àwọn kan kò mọ ohun tí ìgbéyàwó túmọ̀ sí. Ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ akọ̀ròyìn lórí ọ̀ràn ìṣègùn sọ pé: “A kàn ń ṣe ìgbéyàwó ni, a ò gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kankan.”

      Yunifásítì Rutgers nílùú New Jersey, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe onígbọ̀wọ́ ìwádìí kan tí Àjọ Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Ètò Ìgbéyàwó ṣe. Ìwádìí náà fi hàn pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló mọ ohun tí ìgbéyàwó túmọ̀ sí. Olùdarí ìwádìí náà sọ pé “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò lákòókò ìwádìí náà ló jẹ́ àwọn tí ìgbéyàwó àwọn òbí wọn kò láyọ̀ tàbí àwọn tí òbí wọn ti kọ ara wọn sílẹ̀. Wọ́n mọ ohun tí ìgbéyàwó tí kò láyọ̀ túmọ̀ sí àmọ́ wọn kò mọ bí ìgbéyàwó tó lárinrin ṣe máa ń rí. Kìkì àlàyé táwọn kan lè ṣe nípa ìgbéyàwó alárinrin ni pé ‘ó jẹ́ òdìkejì ìgbéyàwó àwọn òbí mi.’”

      Ǹjẹ́ ìṣòro tó ń yọjú láàárín àwọn lọ́kọláya yọ àwọn Kristẹni sílẹ̀ ni? Rárá o. Kódà, àwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní nílò ìmọ̀ràn tó ṣe sàn-án pé kí wọ́n “dẹ́kun wíwá ìtúsílẹ̀” nínú ìgbéyàwó wọn. (1 Kọ́ríńtì 7:27) Kò sí ni kí ìgbéyàwó láàárín ẹ̀dá aláìpé méjì máà ní ìṣòro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ ìrànlọ́wọ́ ńbẹ. Ọkọ àti aya lè mú kí ìgbéyàwó wọn sunwọ̀n sí i nípa fífi àwọn ìlànà inú Bíbélì sílò.

      Lóòótọ́, Bíbélì kì í ṣe ìwé kan tó wà fún kìkì ọ̀ràn ìgbéyàwó. Àmọ́ nígbà tó jẹ́ pé Ẹni tó dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀ gan-an ló mí sí kíkọ Bíbélì, a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé àwọn ìlànà inú rẹ̀ á ranni lọ́wọ́. Jèhófà Ọlọ́run gba ẹnu wòlíì Aísáyà sọ̀rọ̀, ó ní: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”—Aísáyà 48:17, 18.

      Ṣé ìfẹ́ tó ń jo lala láàárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ nígbà kan rí ti bẹ̀rẹ̀ sí dín kù? Ǹjẹ́ o máa ń rò pé o ti há sínú ìgbéyàwó tí kò tí sí ìfẹ́? Obìnrin kan tó ti wà nílé ọkọ fún odindi ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n sọ pé: “Bí àárín ọkọ àti ìyàwó kò bá gún, ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń kó báni kò ṣe é fẹnu sọ. Ìṣòro ni ṣáá lójoojúmọ́, ìṣòro náà kì í sì í tán.” Àmọ́ dípò tí wàá fi gba kámú pé kò sóhun tó o lè ṣe sí ìgbéyàwó rẹ tí kò rí bó o ṣe fẹ́ kó rí, o ò ṣe kúkú wá ọgbọ́n dá sí i? Àpilẹ̀kọ tó kàn á jẹ́ káwọn tọkọtaya rí bí àwọn ìlànà inú Bíbélì ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìgbéyàwó wọn ní ọ̀nà kan pàtó. Ọ̀nà náà ni àdéhùn tí wọ́n jọ ṣe.

  • Bó O Ṣe Lè Mú Kí Ìdè Ìgbéyàwó Rẹ Lágbára Sí I
    Ilé Ìṣọ́—2003 | September 15
    • Bó O Ṣe Lè Mú Kí Ìdè Ìgbéyàwó Rẹ Lágbára Sí I

      FOJÚ inú wo ilé kan tó ń fẹ́ àtúnṣe nítorí pé a ti pa á tì. Ọ̀dà ara rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣí, òrùlé rẹ̀ ti ń jò, igbó sì ti kún dí ilé náà. Òjò ti pa á, oòrùn náà ti pa á, àwọn èèyàn kò sì bójú tó ilé náà mọ́. Ṣé ká wá wo ilé náà dànù ni? Èyí lè má pọn dandan. Bí ìpìlẹ̀ rẹ̀ bá ṣì dúró dáadáa, tí ilé náà kò sì tíì di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, a jẹ́ pé a ṣì lè tún un ṣe.

      Ṣé ipò tí ilé tá a fi ṣàpèjúwe yìí wà jọ ipò tí ìgbéyàwó rẹ wà? Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, ó ṣeé ṣe kí àwọn ìṣòro tó dà bí ìjì ti nípa lórí ìgbéyàwó rẹ. Ẹ lè ti pa ara yín tì dé ìwọ̀n àyè kan. Ọ̀ràn yín lè dà bíi ti Sandy. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó ti wà nílé ọkọ, ó sọ pé: “A kò bá ara wa mu rárá, a kàn fẹ́ ara wa ni. Kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.”

      Kódà bí ìgbéyàwó rẹ bá ti rí bí èyí tá a ń sọ yìí, má ṣe kù gìrì sọ pé kí ẹ tú u ká. Ìgbéyàwó rẹ ṣì lè ní àtúnṣe. Àtúnṣe yìí sinmi lórí irú ọwọ́ tí ẹ̀yin méjèèjì bá fi mú àdéhùn ìgbéyàwó yín. Bí ẹ̀yin méjèèjì bá fi ọwọ́ gidi mú àdéhùn ìgbéyàwó yín, èyí kò ní jẹ́ kó túká lákòókò ìṣòro. Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi ọwọ́ gidi mú àdéhùn ìgbéyàwó rẹ?

      Àdéhùn Ìgbéyàwó Ń Mú Iṣẹ́ Lọ́wọ́

      Ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó túmọ̀ sí kéèyàn fi gbogbo ọkàn dúró lórí àdéhùn tó ṣe. Nígbà mìíràn, ẹnì kan lè pinnu láti dúró lórí àdéhùn tó ṣe nípa ohun kan, irú bí àdéhùn nípa iṣẹ́ ajé. Bí àpẹẹrẹ, bí kọ́lékọ́lé kan bá kọwọ́ bọ ìwé àdéhùn láti kọ́ ilé kan, ó di dandan kó mú àdéhùn náà ṣẹ. Ìyẹn ni pé kó kọ́ ilé náà ní àkọ́yanjú. Ó lè máà mọ ẹni tó ni ilé náà sójú, àmọ́ ó di dandan pé kó mú àdéhùn náà ṣẹ.

      Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn ìgbéyàwó kò dà bí iṣẹ́ ìkọ́lé tá a mẹ́nu kàn lókè yìí, àdéhùn inú rẹ̀ mú iṣẹ́ lọ́wọ́. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọ́run àti èèyàn pé èkùrọ́ ni alábàákú ẹ̀wà, pé ẹ kò ní fi ara yín sílẹ̀ láé. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó dá [ọkùnrin àti obìnrin] láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀.’” Jésù tún fi kún un pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:4-6) Bí ìṣòro bá dé, ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ gbọ́dọ̀ dúró gbọn-in lórí àdéhùn tẹ́ ẹ jọ ṣe.a Ìyàwó kan sọ pé: “Ìgbà tá a jáwọ́ nínú sísọ pé àfi tá a bá kọ ara wa sílẹ̀ la tó bẹ̀rẹ̀ sí rí ojútùú sáwọn ìṣòro wa.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́