ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Híhá Sínú Ìgbéyàwó Aláìnífẹ̀ẹ́
    Jí!—2001 | January 8
    • Híhá Sínú Ìgbéyàwó Aláìnífẹ̀ẹ́

      “Nínú ayé kan tí ìkọ̀sílẹ̀ ti pọ̀ jaburata yìí, àfèèṣì ni kò fi ní jẹ́ pé ohun tó máa gbẹ̀yìn púpọ̀ àwọn ìgbéyàwó tí kò láyọ̀ nìyẹn. Ó sì tún ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó tún di aláìláyọ̀.”—ẸGBẸ́ TÓ Ń ṢÈWÁDÌÍ NÍPA Ọ̀RÀN ÌDÍLÉ NÍ AMẸ́RÍKÀ.

      ÀWỌN alákìíyèsí ti sọ pé inú ìgbéyàwó ni púpọ̀ nínú ayọ̀ téèyàn ń ní láyé àti wàhálà téèyàn ń kó sí láyé ti ń wá. Lóòótọ́, nínú ìgbésí ayé, ìwọ̀nba ni ohun tó lè fúnni ní ayọ̀ púpọ̀ jọjọ—tàbí kí ó kó làásìgbò báni lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ìgbéyàwó. Bí àpótí tó wà nínu àpilẹ̀kọ yìí ti fi hàn, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ni ìdààmú tó pọ̀ ju agbára wọn lọ ń bá.

      Ṣùgbọ́n apá kan ìṣòro náà ni àkọsílẹ̀ nípa àwọn ìkọ̀sílẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ fi hàn. Bí ìgbéyàwó kan péré bá forí ṣánpọ́n, àìmọye àwọn mìíràn ni kò tíì forí ṣánpọ́n ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé wàhálà kò tán rí nínú ìgbéyàwó náà. Obìnrin kan tó ti lé ní ọgbọ̀n ọdún tó ti wọnú ìdè ìgbéyàwó sọ láṣìírí pé: “Ìdílé aláyọ̀ ni ìdílé wa tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ọdún méjìlá tó kọjá kò rọgbọ fún wa rárá. Ọkọ mi kò tiẹ̀ fẹ́ mọ nǹkan kan nípa mi mọ́. Kí n sọ tòótọ́, òun ni ọ̀tá mi tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bà mí lọ́kàn jẹ́ jù lọ.” Bákan náà, ọkọ kan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó ti gbéyàwó kédàárò pé: “Ìyàwó mi ti sọ fún mi pé òun kò nífẹ̀ẹ́ mi mọ́. Ó sọ pé, ó tẹ́ òun lọ́rùn ká kàn jọ máa gbélé, kí olúkúlùkù sì máa ṣe tiẹ̀.”

      Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn kan tí wọ́n ní irú ìṣòro lílekoko yẹn máa ń kọ ara wọn sílẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì wà tí wọn kì í ronú nípa kíkọ ara wọn sílẹ̀. Èé ṣe? Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀mọ̀wé Karen Kayser ti sọ, àwọn ìdí tó ń fà á ni ọmọ tí wọ́n ti bí, orúkọ burúkú tó lè fà fún wọn láwùjọ, ìṣúnná owó, àwọn ọ̀rẹ́, àwọn ẹbí, àti ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn lè mú kí tọkọtaya kan ṣì wà papọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní sí ìfẹ́ láàárín wọn. Ó sọ pé: “Nítorí pé ó lè má ṣeé ṣe fún àwọn tọkọtaya yìí láti kọ ara wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, wọ́n á kúkú yàn láti máa gbé papọ̀ ṣùgbọ́n wọ́n á ti kọ ara wọn sílẹ̀ nínú ọkàn wọn.”

      Ṣé ọ̀ranyàn ni kí tọkọtaya tí àárín wọn kò gún régé mọ́ máa gbé pọ̀ láìsí ìtẹ́lọ́rùn ni? Ṣé ọ̀nà kan ṣoṣo táa lè fi yẹra fún ìkọ̀sílẹ̀ ni ká wà nínú ìdè ìgbéyàwó àmọ́ ká máà nífẹ̀ẹ́ ara ẹni? Ìrírí fi hàn pé a lè yọ ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó nínú làásìgbò tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀—a lè yọ wọ́n nínú àìfararọ tí ìkọ̀sílẹ̀ ń fà àti nínú ẹ̀dùn ọkàn tí àìnífẹ̀ẹ́ ara ẹni ń fà.

  • Èé Ṣe Tí Ìfẹ́ Fi Ń Pòórá?
    Jí!—2001 | January 8
    • Èé Ṣe Tí Ìfẹ́ Fi Ń Pòórá?

      “Ó jọ pé ó rọrùn gan-an láti bẹ̀rẹ̀ nínífẹ̀ẹ́ ẹnì kan ju mímú kí ìfẹ́ yẹn máa bá a nìṣó.”—Ọ̀MỌ̀WÉ KAREN KAYSER.

      PÍPỌ̀ tí àwọn ìgbéyàwó tí kò ti sí ìfẹ́ ń pọ̀ sí i kò fi bẹ́ẹ̀ yani lẹ́nu. Oríṣi àjọṣe kan tó díjú gbáà ni ìgbéyàwó jẹ́ láàárín àwọn èèyàn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ń kó wọnú rẹ̀ láìsí ìmúrasílẹ̀ tí ó tó. Dókítà Dean S. Edell sọ pé: “Wọ́n máa ń fẹ́ ká fi hàn kedere pé a tóótun dáadáa táa bá fẹ́ gba ìwé àṣẹ ìwakọ̀, ṣùgbọ́n táa bá fẹ́ gba ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó, tìrọ̀rùntìrọ̀rùn la fi máa ń buwọ́ lùwé.”

      Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ń ṣe dáadáa, tí wọ́n sì jẹ́ aláyọ̀ lóòótọ́, nǹkan kò rọgbọ fún àwọn kan. Ó lè jẹ́ pé àwọn tọkọtaya kan tàbí ẹnì kan nínú àwọn méjèèjì wọnú ìgbéyàwó pẹ̀lú ìrètí pé nǹkan á dára ṣùgbọ́n tí wọn kò mọ àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe tí ìbágbépọ̀ wọn yóò fi tọ́jọ́. Ọ̀mọ̀wé Harry Reis sọ pé: “Nígbà tí àwọn èèyàn bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rìn mọ́ ara wọn, ọkàn wọ́n máa ń balẹ̀ nípa ara wọn gan-an.” Wọ́n máa ń rò pé ẹnì kejì àwọn “nìkan ni èrò rẹ̀ bá tàwọn mu ní gbogbo ayé. Èrò yẹn máa ń ṣá nígbà míì, tó bá sì rí bẹ́ẹ̀, ó lè ṣàkóbá fún ìgbéyàwó náà.”

      A dúpẹ́ pé ọ̀rọ̀ kò burú tó bẹ́ẹ̀ yẹn nínú ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun tó ti mú kí ìfẹ́ pòórá nínú àwọn ọ̀ràn kan.

      Ìjákulẹ̀—“Ohun Tí Mo Retí Kọ́ Yìí”

      Rose sọ pé: “Nígbà tí mo fẹ́ Jim, mo rò pé èkùrọ́ lalábàákú ẹ̀wà—pé a óò máa fara rora, a óò máa ṣera wa ní jẹ̀lẹ́ńkẹ́, a óò sì máa gba ti ara wa rò ni.” Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tó fi di pé ẹni tí Rose gba tiẹ̀ gan-an tẹ́lẹ̀ kò dára lójú rẹ̀ mọ́. Ó sọ pé: “Ó wá já mi kulẹ̀ pátápátá.”

      Ọ̀pọ̀ sinimá, ìwé, àti àwọn orin tó wọ́pọ̀ kì í sọ òótọ́ nípa ìfẹ́. Nígbà tí ọkùnrin àti obìnrin kan bá ń fẹ́ ara wọn sọ́nà, wọ́n lè máa rò pé àlá àwọn ti ṣẹ; ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mélòó kan tí wọ́n bá ti ṣègbéyàwó, wọ́n máa ń sọ pé àlá lásán làwọ́n ń lá nígbà yẹn! Bí ohun téèyàn kà nínú ìwé ìtàn nípa ìfẹ́ kò bá ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó ẹni, ìgbéyàwó tó tòrò lè dà bí èyí tó forí ṣánpọ́n.

      Lóòótọ́, kò burú láti fojú sọ́nà fún àwọn ohun kan nínú ìgbéyàwó. Fún àpẹẹrẹ, ohun tó bójú mu ni láti retí pé kí ẹni tí a fẹ́ nífẹ̀ẹ́ ẹni, kó fúnni láfiyèsí, kó sì tini lẹ́yìn. Ṣùgbọ́n àwọn ohun tí a retí wọ̀nyí tiẹ̀ lè má ṣẹlẹ̀. Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ ìyàwó kan ní Íńdíà, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Meena, sọ pé: “Díẹ̀ ló kù kó rí lára mi bíi pé mi ò tíì relé ọkọ. Mo nìkan wà, mo di ẹni ìpatì.”

      Àìbáramu—“Kò Sóhun Táa Fi Bára Mu”

      Obìnrin kan sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tí èmi àti ọkọ mi fohùn ṣọ̀kan lé lórí. Kó sọ́jọ́ kan tó kọjá rí tí mi ò kábàámọ̀ gidigidi pé mo fẹ́ ẹ. A ò tiẹ̀ bára wa mu rárá ni.”

  • Ǹjẹ́ Ìrètí Ńbẹ?
    Jí!—2001 | January 8
    • Ǹjẹ́ Ìrètí Ńbẹ?

      “Ìṣòro kan tó máa ń wà nínú àwọn ìgbéyàwó tó ní wàhálà nínú ni èrò tí wọ́n máa ń ní pé nǹkan kò lè dára. Irú èrò bẹ́ẹ̀ sì máa ń dojú àtúnṣe délẹ̀ ni nítorí pé kò ní jẹ́ kí ẹ lè ní ẹ̀mí láti gbìyànjú ohunkóhun tó lè mú nǹkan dára.”—Ọ̀MỌ̀WÉ AARON T. BECK.

      KÁ SỌ pé o ń jẹ̀rora, o wá tọ dókítà lọ láti mọ ohun tó ń ṣe ọ́. Ọkàn rẹ ò balẹ̀—kò sì sọ́gbọ́n kó máà rí bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, ìlera rẹ—kódà ẹ̀mí rẹ pàápàá lè wà nínú ewu. Ṣùgbọ́n ká ní lẹ́yìn àyẹ̀wò náà, dókítà wá sọ fún ọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ń ṣe ẹ́ kò ṣeé fọwọ́ yẹpẹrẹ mú, ṣùgbọ́n ó ṣeé wò sàn. Dókítà tilẹ̀ sọ fún ọ pé bí o bá ṣọ́ bóo ṣe ń jẹun, tóo sì ń ṣeré ìmárale níwọ̀n tó yẹ, ara rẹ yóò yá pátápátá. Ó dájú pé ọkàn rẹ yóò balẹ̀ gan-an, tayọ̀tayọ̀ ni wàá si fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò!

      Fi ìṣẹ̀lẹ̀ àfinúrò yìí wéra pẹ̀lú ohun tí a ń jíròrò rẹ̀. O ha ń ní ìrora ọkàn nínú ìgbéyàwó rẹ bí? Lóòótọ́, kò sí ìgbéyàwó tí ìṣòro àti aáwọ̀ kì í bá fínra. Nítorí náà, bí àárín yín kò bá gún régé láwọn àkókò kan, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé kò sí ìfẹ́ nínú ìgbéyàwó yín. Ṣùgbọ́n bí ohun tó ń fa ìrora ọkàn náà kò bá tán, tó ń bá a lọ fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, oṣù, tàbí ọdún pàápàá ńkọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ̀rù bà ọ́ lóòótọ́, nítorí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ yìí kì í ṣe ọ̀ràn kékeré. Láìṣe àní-àní, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó rẹ lè fẹ́rẹ̀ẹ́ nípa lórí gbogbo apá ìgbésí ayé rẹ—àti ti àwọn ọmọ rẹ. Fún àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé tí ìgbéyàwó ò bá fara rọ, ìyẹn lè fa àwọn ìṣòro bí ìsoríkọ́, àìjáfáfá lẹ́nu iṣẹ́, àti kí àwọn ọmọ máa fìdí rẹmi nílé ìwé. Ṣùgbọ́n kò tán síbẹ̀ o. Àwọn Kristẹni mọ̀ pé àjọṣe tó wà láàárín àwọn àti ẹni táwọn fẹ́ lè nípa lórí àjọṣe àwọn pẹ̀lú Ọlọ́run.—1 Pétérù 3:7.

      Ti pé ìṣòro wà láàárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ kò túmọ̀ sí pé ọ̀ràn yín ti burú kọjá àtúnṣe. Mímọ òkodoro òtítọ́ náà nípa ìgbéyàwó—pé ìṣòro yóò máa wà—lè ran tọkọtaya kan lọ́wọ́ láti wo àwọn ìṣòro wọn láwòjinlẹ̀ kí wọ́n sì gbìyànjú láti wá ojútùú sí i. Ọkọ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Isaac sọ pé: “Mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé kì í ṣe ohun tójú ò rí rí kí tọkọtaya ní gbọ́nmi-si-omi-o-to nínú ìgbéyàwó wọn. Mo rò pé a níṣòro àrà ọ̀tọ̀ kan ni!”

      Kódà bí ìgbéyàwó rẹ bá ti burú débi pé kò sí ìfẹ́ láàárín yín mọ́, ẹ ṣì lè ṣe é kí ó má forí ṣánpọ́n. Òótọ́ ni pé àwọn ìrora ọkàn tí àjọṣe tí kò gún régé ń fà lè dunni gan-an, ní pàtàkì tí àwọn ìṣòro náà bá ti ń ṣẹlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ṣùgbọ́n a ṣì lè fọkàn sí pé nǹkan á dára. Gbígbégbèésẹ̀ jẹ́ kókó pàtàkì kan nínú rẹ̀. Kódà, àwọn èèyàn méjì tí wọ́n ní ìṣòro tó le gan-an nínú ìgbéyàwó wọn ṣì lè ṣàtúnṣe tó bá jẹ wọ́n lógún.a

  • Ó Ṣeé Ṣe Kí Ìgbéyàwó Yín Má Forí Ṣánpọ́n O!
    Jí!—2001 | January 8
    • Ó Ṣeé Ṣe Kí Ìgbéyàwó Yín Má Forí Ṣánpọ́n O!

      Àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́, tó lè ṣàǹfààní fún tọkọtaya kún inú Bíbélì rẹpẹtẹ. Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ àgbọ́-ṣe-hàà, nítorí pé Ẹni tó mí sí Bíbélì náà ló tún dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀.

      BÍ Ọ̀RÀN ìgbéyàwó ṣe rí gẹ́lẹ́ ni Bíbélì ṣe sọ ọ́. Ó sọ pé ọkọ àti aya yóò ní “ìpọ́njú” tàbí gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ New English Bible ṣe sọ ọ́, wọn yóò ní “ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn.” (1 Kọ́ríńtì 7:28) Síbẹ̀, Bíbélì tún sọ pé ìgbéyàwó lè mú ayọ̀ wá, àní ayọ̀ púpọ̀ jọjọ, ó sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. (Òwe 5:18, 19) Àwọn èrò méjèèjì wọ̀nyí kò tako ara wọn rárá. Ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ fi hàn pé láìka àwọn ìṣòro tó le koko sí, àárín tọkọtaya kan ṣì lè dán mọ́rán, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn dáadáa.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́