Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ní Ìbẹ̀rẹ̀?
▪ Ìdáhùn tí Bíbélì fún wa ni pé Ọlọ́run kò ní ìbẹ̀rẹ̀. Kò sí ìgbà kankan rí tí Ọlọ́run kò sí. A ò lè tìtorí pé kò ṣeé ṣe fún wa láti mọ ìbẹ̀rẹ̀ Ọlọ́run, ká wá pa ọ̀ràn náà tì.
Ṣé ó ṣeé ṣe pé ká lóye gbogbo ọ̀nà Ọlọ́run? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!” (Róòmù 11:33) A kò lè lóye gbogbo bí ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run ti pọ̀ tó àní bí ọmọ jòjòló kan kò ṣe lè mọ gbogbo nǹkan tí òbí rẹ̀ ń ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí ń sọ nípa bí ọgbọ́n àti àánú Ọlọ́run ṣe jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ohun kan wà nípa Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn ohun tó ń ṣe tó jinlẹ̀ gan-an tí làákàyè wa kò lè gbé. Wíwà tí Ọlọ́run wà láìní ìbẹ̀rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn nǹkan náà. Síbẹ̀, a ṣì lè fọkàn tán ohun tí Bíbélì kọ́ni nípa Ọlọ́run. Jésù Kristi sọ fún wa nípa Ìwé Mímọ́ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”—Jòhánù 17:17.
Mósè sọ nínú àdúrà rẹ̀ sí Jèhófà pé: “O ti fìgbà gbogbo wà, ìwọ yóò sì máa wà nígbà gbogbo.” (Sáàmù 90:2, Bíbélì The Holy Bible, New Century Version) Ní ibi yìí, Mósè ṣàlàyé wíwà Ọlọ́run ní oríṣi ọ̀nà méjì. Ọ̀kan ni pé Ọlọ́run á máa wà títí lọ. Jèhófà ni “Ẹni tí ó wà láàyè títí láé àti láéláé.” (Ìṣípayá 4:10) Nítorí náà, Ọlọ́run wà títí ayérayé. Èkejì ni pé Ọlọ́run ti wà láti ayérayé. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, kò sí ẹni tó dá Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ti wà láti ayérayé.
Àwọn ohun téèyàn kò lè fojú rí máa ń ṣòro fún èyí tó pọ̀ jù lára wa láti lóye. Síbẹ̀, nígbà míì a máa ń bá irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ pàdé lọ́pọ̀ ìgbà, irú bíi lílo òǹkà láti fi ṣe ìṣirò. Ó dájú pé tá a bá bẹ̀rẹ̀ òǹkà ní ení, èjì, ẹ̀ta títí lọ, kò lópin, irú bíi pé kéèyàn fẹ́ ka iyanrìn etí òkun tó jẹ́ àìlópin. Bákan náà lọ̀rọ̀ ṣe rí tó bá kan iye ọdún tí Ẹlẹ́dàá wa ti wà, àìlópin ni.
Ó bá a mu nígbà náà pé Ọlọ́run nìkan ló ń jẹ́ orúkọ aláìlẹ́gbẹ́ náà, “Ọba ayérayé.” (1 Tímótì 1:17) Ní ti Jésù Kristi àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run àtàwọn èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, gbogbo wọn pátá ló ní ìbẹ̀rẹ̀ nítorí pé a dá wọn ni. (Kólósè 1:15, 16) Àmọ́, tí Ọlọ́run kò rí bẹ́ẹ̀. Téèyàn bá ń sọ pé Ọlọ́run ní láti ní ìbẹ̀rẹ̀ kan, pé ẹnì kan ló dá Ẹlẹ́dàá, ńṣe lèèyàn á kàn máa béèrè ìbéèrè tí kò ní lójútùú, tó sì jẹ́ àwámáàrídìí. Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà nìkan ló wà “láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 90:2) Ká sọ ọ́ lọ́nà míì, Jèhófà wà ní “gbogbo ayérayé tí ó ti kọjá.”—Júúdà 25.
Àmọ́ ṣá o, ká fi í sọ́kàn pé wíwà Ọlọ́run láti ayérayé dé ayérayé kì í ṣe òtítọ́ kan tí kò ṣeni láǹfààní. Tá a bá gbé àdúrà Mósè yẹn yẹ̀ wò dáadáa, a máa rí i pé wíwà Ọlọ́run láti ayérayé dé ayérayé mú un dá wa lójú pé a lè rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà. Láìdà bí ìwàláàyè wa ìsinsìnyí tí kì í pẹ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ “ibùgbé gidi fún wa ní ìran dé ìran.” Gẹ́gẹ́ bíi Bàbá onífẹ̀ẹ́, Jèhófà wà fún wa nígbà tó ti kọjá, nísinsìnyí àti títí láé. Ǹjẹ́ kí òtítọ́ àgbàyanu yẹn máa tù ọ́ nínú!—Sáàmù 90:1.