Bíbá Ọlọ́run Rìn—Pẹ̀lú Ayérayé Lọ́kàn
“Àwa . . . yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—MÍKÀ 4:5.
1. Èé ṣe tí a fi lè pe Jèhófà ní “Ọba ayérayé”?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN kò ní ìbẹ̀rẹ̀. Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, a pè é ní “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” níwọ̀n bí òun ti wà kánrin kése látẹ̀yìnwá. (Dáníẹ́lì 7:9, 13) Jèhófà yóò sì tún máa wà títí ayérayé lọ́jọ́ iwájú. Òun nìkan ṣoṣo ni “Ọba ayérayé.” (Ìṣípayá 10:6; 15:3) Lójú rẹ̀, ẹgbẹ̀rún ọdún sì dà bí “kìkì àná nígbà tí ó bá kọjá, àti bí ìṣọ́ kan ní òru.”—Sáàmù 90:4.
2. (a) Kí ni ète Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn onígbọràn? (b) Kí ni ó yẹ kí a gbé ìrètí àti ìwéwèé wa kà?
2 Níwọ̀n bí Olùfúnni ní ìyè ti jẹ́ ẹni ayérayé, ó lè fún tọkọtaya àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ní ìfojúsọ́nà fún ìwàláàyè tí kò lópin nínú Párádísè. Ṣùgbọ́n, nítorí àìgbọràn, Ádámù pàdánù ẹ̀tọ́ sí ìyè àìnípẹ̀kun, ó mú kí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú kọjá sọ́dọ̀ àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. (Róòmù 5:12) Síbẹ̀, ìṣọ̀tẹ̀ Ádámù kò dènà ohun tí Ọlọ́run pète ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ìfẹ́ Jèhófà ni pé kí àwọn ènìyàn onígbọràn máa wà láàyè títí láé, yóò sì mú ète rẹ̀ ṣẹ láìkùnà. (Aísáyà 55:11) Nígbà náà, ẹ wo bí ó ti bá a mu tó pé kí a gbé ìrètí àti àwọn ìwéwèé wa ka sísin Jèhófà pẹ̀lú ayérayé lọ́kàn. Bí a ti ń fẹ́ láti fi “ọjọ́ Jèhófà” sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí, ó ṣe pàtàkì láti rántí pé góńgó wa ni láti máa bá Ọlọ́run rìn títí ayérayé.—2 Pétérù 3:12.
Jèhófà Ń Gbégbèésẹ̀ Ní Àkókò Tí Ó Ti Yàn Kalẹ̀
3. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ní ‘àkókò tí ó yàn kalẹ̀’ láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ?
3 Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń bá Ọlọ́run rìn, a nífẹ̀ẹ́ gidigidi nínú pé kí ó mú ète rẹ̀ ṣẹ. A mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ Olùpàkókòmọ́ Gíga Jù Lọ, a sì ní ìgbọ́kànlé pé òun kì í kùnà láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ ní àkókò tí òun yàn kalẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, “nígbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkókò dé, Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ jáde.” (Gálátíà 4:4) A sọ fún àpọ́sítélì Jòhánù pé “àkókò tí a yàn kalẹ̀” wà tí a óò mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí òun rí nípa àwọn àmì ṣẹ. (Ìṣípayá 1:1-3) “Àkókò tí a yàn kalẹ̀” wà “láti ṣèdájọ́ àwọn òkú.” (Ìṣípayá 11:18) Ní ohun tí ó ju 1,900 ọdún sẹ́yìn, a mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé Ọlọ́run “ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo.”—Ìṣe 17:31.
4. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ mú òpin dé bá ètò àwọn nǹkan búburú yìí?
4 Jèhófà yóò mú òpin dé bá ètò àwọn nǹkan búburú yìí, nítorí pé a ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀ nínú ayé lónìí. Àwọn ẹni burúkú ti pọ̀ rẹpẹtẹ. (Sáàmù 92:7) Wọ́n ti fi ìwọ̀sí lọ Ọlọ́run nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn, ó sì dùn ún láti rí i pé a ń kẹ́gàn àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ tí a sì ń ṣe inúnibíni sí wọn. (Sekaráyà 2:8) Abájọ tí Jèhófà fi pàṣẹ pé ètò àjọ Sátánì látòkè délẹ̀ ni a óò mú òpin dé bá láìpẹ́! Ọlọ́run ti pinnu ìgbà tí èyí yóò ṣẹlẹ̀ gan-an, àwọn ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sì mú kí ó ṣe kedere pé “àkókò òpin” ni a ń gbé báyìí. (Dáníẹ́lì 12:4) Òun yóò gbégbèésẹ̀ láìpẹ́ fún ìbùkún gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
5. Ojú wo ni Lọ́ọ̀tì àti Hábákúkù fi wo àwọn ipò tí ó yí wọn ká?
5 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́ yán hànhàn láti rí òpin ìwà burúkú. Lọ́ọ̀tì olódodo ni “ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ nínú ìwà àìníjàánu àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà kó wàhálà-ọkàn bá gidigidi.” (2 Pétérù 2:7) Àwọn ipò tí ó yí wòlíì Hábákúkù ká kó ẹ̀dùn ọkàn bá a, ó sì pàrọwà pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́, tí ìwọ kò sì gbọ́? Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá, tí ìwọ kò sì gbà là? Èé ṣe tí ìwọ fi mú kí n rí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, tí ìwọ sì ń wo èkìdá ìdààmú? Èé sì ti ṣe tí ìfiṣèjẹ àti ìwà ipá fi wà ní iwájú mi, èé sì ti ṣe tí aáwọ̀ fi ń ṣẹlẹ̀, èé sì ti ṣe tí gbọ́nmi-si omi-ò-to fi ń bẹ?”—Hábákúkù 1:2, 3.
6. Kí ni Jèhófà fi fèsì àdúrà Hábákúkù, kí ni a sì lè kọ́ nínú èyí?
6 Lápá kan, Jèhófà fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá Hábákúkù lóhùn pé: “Ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, ó sì ń sáré lọ ní mímí hẹlẹhẹlẹ sí òpin, kì yóò sì purọ́. Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.” (Hábákúkù 2:3) Ọlọ́run tipa báyìí sọ ọ́ di mímọ̀ pé òun yóò gbégbèésẹ̀ ní “àkókò tí a yàn kalẹ̀.” Bí ó tilẹ̀ dà bí ẹni pé ó ń falẹ̀, Jèhófà yóò mú ète rẹ̀ ṣẹ—láìkùnà!—2 Pétérù 3:9.
Sísìn Pẹ̀lú Ìtara Tí Kì Í Yẹ̀
7. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kò mọ àkókò náà gan-an tí ọjọ́ Jèhófà yóò dé, báwo ni ó ṣe ń bá ìgbòkègbodò rẹ̀ lọ?
7 Mímọ àkókò náà gan-an tí Jèhófà ti yàn fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ha jẹ́ ohun tí a nílò kí a bàa lè máa fi ìtara bá Ọlọ́run rìn bí? Rárá o, kò rí bẹ́ẹ̀. Gbé àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan yẹ̀ wò. Jésù lọ́kàn-ìfẹ́ gidigidi sí àkókò náà tí ìfẹ́ Ọlọ́run yóò di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí ní ọ̀run. Ní tòótọ́, Kristi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù mọ̀ pé a óò dáhùn àdúrà yìí, kò mọ àkókò náà gan-an tí a ti yàn fún èyí. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì rẹ̀ nípa òpin ètò àwọn nǹkan yìí, ó sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:36) Níwọ̀n bí Jésù Kristi ti jẹ́ òpómúléró nínú mímú àwọn ète Ọlọ́run ṣẹ, ní tààràtà, òun yóò lọ́wọ́ nínú mímú ìdájọ́ ṣẹ lórí àwọn ọ̀tá Baba rẹ̀ ọ̀run. Àmọ́ ṣá o, nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, àní òun pàápàá kò mọ ìgbà tí Ọlọ́run yóò gbégbèésẹ̀. Ìyẹn ha dín ìtara rẹ̀ kù nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ kọ́! Nígbà tí wọ́n rí bí Jésù ṣe ń fi ìtara sọ tẹ́ńpìlì di mímọ́, “àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ìtara fún ilé rẹ yóò jẹ mí run.’” (Jòhánù 2:17; Sáàmù 69:9) Ọwọ́ Jésù dí gan-an lẹ́nu iṣẹ́ tí a rán an pé kí ó wá ṣe, ó sì fi ìtara tí kì í yẹ̀ ṣe é. Ó tún sin Ọlọ́run pẹ̀lú ayérayé lọ́kàn.
8, 9. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn béèrè nípa mímú Ìjọba náà padà bọ̀ sípò, kí ni ohun tí a sọ fún wọn, báwo sì ni wọ́n ṣe hùwà padà?
8 Bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tòótọ́ pẹ̀lú. Jésù bá wọn ṣe ìpàdé kí ó tó gòkè re ọ̀run. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Wàyí o, nígbà tí wọ́n ti péjọ, wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Olúwa, ìwọ ha ń mú ìjọba padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yìí bí?’” Bí ti Ọ̀gá wọn, wọ́n yán hànhàn pé kí Ìjọba náà dé. Síbẹ̀, Jésù fèsì pé: “Kì í ṣe tiyín láti mọ àwọn ìgbà tàbí àsìkò tí Baba ti fi sí abẹ́ àṣẹ òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:6-8.
9 Kò sí ohun tí ó fi hàn pé ìdáhùn yìí mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀, tìtara-tìtara ni ọwọ́ wọn fi di nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, wọ́n ti fi ẹ̀kọ́ wọn kún Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 5:28) Láàárín 30 ọdún, wọ́n sì ti mú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù wọn gbòòrò tó bẹ́ẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù fi lè sọ pé ìhìn rere náà ni a ti wàásù “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kólósè 1:23) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìjọba náà ni a kò ‘mú padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì’ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ti fi àṣìṣe fojú sọ́nà, a kò sì gbé e kalẹ̀ ní ọ̀run nígbà ayé wọn, wọ́n ń bá a nìṣó ní fífi ìtara sin Jèhófà pẹ̀lú ayérayé lọ́kàn.
Yíyẹ Ìsúnniṣe Wa Wò
10. Bí a kò ṣe mọ àkókò náà tí Ọlọ́run yóò pa ètò Sátánì run mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti fi kí ni hàn?
10 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní pẹ̀lú ń yán hànhàn láti rí òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí. Ṣùgbọ́n, ìgbàlà wa sínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí kì í ṣe olórí àníyàn wa. A fẹ́ rí i pé orúkọ Jèhófà ni a sọ di mímọ́ tí a sì dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre. Nítorí èyí, inú wa dùn pé Ọlọ́run kò sọ ‘ọjọ́ tàbí wákàtí’ tí òun ti yàn láti pa ètò Sátánì run fún wa. Èyí mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti fi hàn pé a ti pinnu láti máa bá Ọlọ́run rìn títí ayérayé nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí kì í sì í ṣe nítorí pé a ní góńgó onígbà kúkúrú, tí ó jẹ́ ti onímọtara-ẹni-nìkan lọ́kàn.
11, 12. Báwo ni a ṣe pe ìwà títọ́ Jóòbù níjà, báwo sì ni ìpèníjà yẹn ṣe kàn wá?
11 Jíjẹ́ kí ìwà títọ́ wa sí Ọlọ́run máa bá a lọ tún ń ṣèrànwọ́ láti fi hàn pé Èṣù kò tọ̀nà nígbà tí ó fẹ̀sùn kan Jóòbù adúróṣinṣin—àti àwọn ènìyàn bí tirẹ̀—pé wọn ń sin Ọlọ́run nítorí ìfẹ́ ti ara wọn nìkan. Lẹ́yìn tí Jèhófà ti ṣàpèjúwe ìránṣẹ́ rẹ̀ Jóòbù gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́bi, adúróṣánṣán, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, Sátánì fi ẹ̀mí burúkú sọ pé: “Lásán ha ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run bí? Ìwọ fúnra rẹ kò ha ti ṣe ọgbà ààbò yí i ká, àti yí ilé rẹ̀ ká, àti yí ohun gbogbo tí ó ní ká? Ìwọ ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, àní ohun ọ̀sìn rẹ̀ ti tàn káàkiri ilẹ̀. Ṣùgbọ́n, fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fọwọ́ kan ohun gbogbo tí ó ní, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.” (Jóòbù 1:8-11) Nípa pípa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ lábẹ́ àdánwò, Jóòbù fi hàn pé èké ni ọ̀rọ̀ burúkú yìí.
12 Bákan náà, nípa bíbá a lọ láti máa tọ ipa ọ̀nà ìwà títọ́, a lè fi hàn pé èké ni ẹ̀sùn èyíkéyìí tí Sátánì bá fi kàn wá pé ńṣe ni a ń sin Ọlọ́run kìkì nítorí pé a mọ̀ pé èrè kan ń bọ̀ láìpẹ́ jọjọ. Bí a kò ṣe mọ àkókò náà gan-an tí a óò mú ẹ̀san Ọlọ́run ṣẹ lórí àwọn ẹni burúkú fún wa ní àǹfààní láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ní tòótọ́, a sì fẹ́ láti máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ títí ayérayé. Ó fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, a sì gbọ́kàn lé ọ̀nà tí ó ń gbà bójú tó àwọn ọ̀ràn. Síwájú sí i, bí a kò ṣe mọ ọjọ́ àti wákàtí náà ń mú kí a wà lójúfò, kí a sì jí kalẹ̀ nípa tẹ̀mí nítorí tí a mọ̀ pé òpin lè dé nígbàkigbà, bí olè lóru. (Mátíù 24:42-44) Nípa bíbá Jèhófà rìn lójoojúmọ́, a ń mú kí ọkàn-àyà rẹ̀ yọ̀, a sì ń fún Èṣù tí ń ṣáátá rẹ̀ lésì.—Òwe 27:11.
Wéwèé Pẹ̀lú Ayérayé Lọ́kàn!
13. Kí ni Bíbélì sọ nípa wíwéwèé fún ọjọ́ ọ̀la?
13 Àwọn tí ń bá Ọlọ́run rìn mọ̀ pé ó bọ́gbọ́n mu láti wéwèé fún ọjọ́ ọ̀la lọ́nà tí ó mọ́gbọ́n dání. Ríronú nípa àwọn ìṣòro àti ìkálọ́wọ́kò tí ọjọ́ ogbó ń mú wá ń mú kí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa gbìyànjú láti lo ìgbà èwe àti okun wọn dáadáa kí wọ́n bàa lè ní owó tí ó pọ̀ tó nígbà tí wọ́n bá ti darúgbó. Ọjọ́ ọ̀la wa nípa tẹ̀mí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ńkọ́? Òwe 21:5 sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” Wíwéwèé ṣáájú pẹ̀lú ayérayé lọ́kàn ń ṣàǹfààní ní tòótọ́. Níwọ̀n bí a kò ti mọ àkókò náà gan-an tí òpin ètò àwọn nǹkan yìí yóò dé, ó yẹ kí a ronú nípa ohun tí a óò nílò lọ́jọ́ ọ̀la. Ṣùgbọ́n, kí a jẹ́ ẹni tí ó wà déédéé, kí a sì fi ire ti Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé. Àwọn tí kò nígbàgbọ́ lè parí èrò sí pé jíjẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ ohun pàtàkì tí a nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ jẹ́ ṣíṣàìronújinlẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ha rí bẹ́ẹ̀ bí?
14, 15. (a) Àpèjúwe wo ni Jésù ṣe nípa wíwéwèé fún ọjọ́ ọ̀la? (b) Èé ṣe tí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ inú àpèjúwe Jésù fi jẹ́ ẹni tí kò ronú jinlẹ̀?
14 Jésù ṣe àpèjúwe kan tí ó lani lóye nínú èyí. Ó sọ pé: “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan mú èso jáde dáadáa. Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí rò nínú ara rẹ̀, pé, ‘Kí ni èmi yóò ṣe, nísinsìnyí tí èmi kò ní ibì kankan láti kó àwọn irè oko mi jọ sí?’ Nítorí náà, ó wí pé, ‘Èyí ni èmi yóò ṣe: Ṣe ni èmi yóò ya àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ mi lulẹ̀, èmi yóò sì kọ́ àwọn tí ó tóbi, ibẹ̀ ni èmi yóò sì kó gbogbo ọkà mi jọ sí àti gbogbo àwọn ohun rere mi; ṣe ni èmi yóò sọ fún ọkàn mi pé: “Ọkàn, ìwọ ní ọ̀pọ̀ ohun rere tí a tò jọ pa mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn.”’ Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Aláìlọ́gbọ́n-nínú, òru òní ni wọn yóò fi dandan béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóò wá ni àwọn ohun tí ìwọ tò jọ pa mọ́?’ Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—Lúùkù 12:16-21.
15 Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé kò yẹ kí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà ṣiṣẹ́ kí ó bàa lè ní ohun ìní àbọ̀wábá lọ́la? Rárá o, nítorí pé Ìwé Mímọ́ fúnni níṣìírí pé kí a ṣiṣẹ́ kára. (2 Tẹsalóníkà 3:10) Àṣìṣe ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yìí ni pé kò ṣe ohun tí ó pọndandan láti “ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Ká ní ó tilẹ̀ ti ṣeé ṣe fún un láti gbádùn ọrọ̀ rẹ̀ nípa ti ara fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pàápàá, ì bá kú nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Kò ronú jinlẹ̀, kò ronú nípa ìyè ayérayé.
16. Èé ṣe tí a lè fi tọkàntọkàn gbára lé Jèhófà fún ọjọ́ ọ̀la aláàbò?
16 Bíbá Jèhófà rìn pẹ̀lú ayérayé lọ́kàn jẹ́ ohun tí ó gbéṣẹ́ tí ó sì jẹ́ ti onírònújinlẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti gbà wéwèé fún ọjọ́ ọ̀la. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó bọ́gbọ́n mu láti wéwèé lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ nípa ilé ẹ̀kọ́, iṣẹ́ ṣíṣe, àti àwọn ẹrù iṣẹ́ ìdílé, ìgbà gbogbo ni ó yẹ kí a máa rántí pé Jèhófà kì í fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin sílẹ̀ láé. Dáfídì Ọba kọrin pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” (Sáàmù 37:25) Bákan náà, Jésù fi dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò pèsè fún gbogbo àwọn tí ó ń wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́, tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà òdodo ti Jèhófà.—Mátíù 6:33.
17. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé?
17 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń sin Ọlọ́run pẹ̀lú ayérayé lọ́kàn, a ṣì ń fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí. Lọ́nà tí ó ṣe kedere, ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́rìí sí ìsúnmọ́lé ọjọ́ yẹn. Ogun, àjàkálẹ̀ àrùn, ìsẹ̀lẹ̀, àti àìtó oúnjẹ, pẹ̀lú ṣíṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni tòótọ́ àti wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé, ti sàmì sí ọ̀rúndún ogún yìí. Gbogbo èyí sì jẹ́ àmì àkókò òpin fún ètò àwọn nǹkan burúkú yìí. (Mátíù 24:7-14; Lúùkù 21:11) Ayé yìí kún fọ́fọ́ fún àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ “jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:1-5) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí ó le koko yìí, ìgbésí ayé le koko fún àwa tí a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Ẹ wo bí a ṣe ń yán hànhàn tó fún ọjọ́ náà tí Ìjọba Jèhófà yóò gbá gbogbo ìwà búburú dànù! Títí di ìgbà náà, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti máa bá Ọlọ́run rìn pẹ̀lú ayérayé lọ́kàn.
Sísìn Pẹ̀lú Ayérayé Lọ́kàn
18, 19. Kí ni ó fi hàn pé àwọn olùṣòtítọ́ ìgbà àtijọ́ sin Ọlọ́run pẹ̀lú ayérayé lọ́kàn?
18 Bí a ṣe ń bá Jèhófà rìn, ẹ jẹ́ kí a fi ìgbàgbọ́ Ébẹ́lì, Énọ́kù, Nóà, Ábúráhámù àti Sárà sọ́kàn. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti mẹ́nu kàn wọ́n tán, ó kọ̀wé pé: “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kú nínú ìgbàgbọ́, bí wọn kò tilẹ̀ rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n wọ́n rí wọn lókèèrè réré, wọ́n sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n, wọ́n sì polongo ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ náà.” (Hébérù 11:13) Àwọn olùṣòtítọ́ wọ̀nyí “ń nàgà sí ibi tí ó sàn jù, èyíinì ni, ọ̀kan tí ó jẹ́ ti ọ̀run.” (Hébérù 11:16) Nínú ìgbàgbọ́, wọ́n fojú sọ́nà fún ibi kan tí ó sàn jù lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Mèsáyà ti Ọlọ́run. Ó dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò fi ìyè ayérayé nínú ibi tí ó sàn jù yẹn—Párádísè ilẹ̀ ayé lábẹ́ àkóso Ìjọba náà, san èrè fún wọn.—Hébérù 11:39, 40.
19 Wòlíì Míkà fi ìpinnu àwọn ènìyàn Jèhófà láti sin Ọlọ́run títí ayérayé hàn. Ó kọ̀wé pé: “Gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Míkà 4:5) Títí tí Míkà fi kú, ó fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà. Nígbà tí a bá jí i dìde nínú ayé tuntun, láìsí àní-àní, wòlíì yẹn yóò máa bá a nìṣó ní bíbá Ọlọ́run rìn títí ayérayé. Ẹ wo bí èyí ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó fún àwa tí ń gbé apá ìkẹyìn pátápátá nínú àkókò òpin yìí!
20. Kí ni ó yẹ kí ó jẹ́ ìpinnu wa?
20 Jèhófà mọrírì ìfẹ́ tí a fi hàn fún orúkọ rẹ̀. (Hébérù 6:10) Ó mọ̀ pé ó ṣòro fún wa láti máa bá ìwà títọ́ wa sí òun lọ nínú ayé yìí tí ó wà lábẹ́ ìdarí Èṣù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “ayé ń kọjá lọ,” ṣùgbọ́n, “ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17; 5:19) Nígbà náà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti máa fara da àwọn àdánwò tí a ń dojú kọ lójoojúmọ́. Ǹjẹ́ kí ìrònú wa àti ọ̀nà ìgbésí ayé wa dá lórí àwọn ìbùkún àgbàyanu tí Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ti ṣèlérí. Ìwọ̀nyí lè jẹ́ tiwa bí a bá ń bá a nìṣó láti máa bá Ọlọ́run rìn pẹ̀lú ayérayé lọ́kàn.—Júúdà 20, 21.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni ète Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn onígbọràn?
◻ Èé ṣe tí Jèhófà kò tíì gbé ìgbésẹ̀ láti mú ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí wá sópin?
◻ Èé ṣe tí kò fi yẹ kí ìtara wa dín kù nítorí pé a kò mọ àkókò náà gan-an tí Ọlọ́run yóò gbé ìgbésẹ̀?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní bíbá Ọlọ́run rìn pẹ̀lú ayérayé lọ́kàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Bíbá Ọlọ́run rìn ń béèrè pé kí a fi ìtara sìn ín gẹ́gẹ́ bí ti àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ní ìjímìjí