“Wọ́n Kọ̀ Jálẹ̀ Ó Yẹ Ká Bọ̀wọ̀ fún Wọn”
NÍGBÀ ìṣàkóso rírorò ti ọ̀gbẹ́ni Adolf Hitler, ìyẹn nígbà tó jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè Jámánì, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lẹ́tà làwọn èèyàn kọ sí i. Lọ́dún 1945, ìyẹn ẹ̀yìn ìgbà tí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti ń ṣàkóso àgbègbè Berlin, ọ̀pọ̀ lára àwọn lẹ́tà náà ni wọ́n kó lọ sí Moscow tí wọ́n sì tọ́jú wọn síbẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Henrik Eberle tó jẹ́ òpìtàn ti ṣàyẹ̀wò ẹgbẹẹgbẹ̀rún irú lẹ́tà yìí níbi ìkówèésí tó wà ní Moscow kó lè mọ àwọn tó kọ lẹ́tà náà sí Hitler àti ìdí tí wọ́n fi kọ ọ́. Ọ̀jọ̀gbọ́n Eberle ṣe ìwé kan tó pè ní Briefe an Hitler (ìyẹn Lẹ́tà sí Hitler) jáde, nínú ìwé náà, ó sọ èrò rẹ̀ nípa àwọn lẹ́tà náà.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Eberle sọ pé, “Àwọn olùkọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́, àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, ìyẹn àwọn obìnrin onísìn tí wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìlọ́kọ àtàwọn àlùfáà, àwọn tí kò níṣẹ́ àtàwọn ògbóǹkangí oníṣòwò, àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ológun àtàwọn ọmọ ogun tí kò nípò ni wọ́n kọ lẹ́tà sí Hitler. Àwọn kan pè é ní Mèsáyà tó jẹ́ àtúnbí, àwọn míì pè é ní olubi.” Ǹjẹ́ Hitler rí lẹ́tà gbà látọ̀dọ̀ àwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì, èyí tí wọ́n fi ta kò ó nítorí ìwà òǹrorò tí Ìjọba Násì ń hù sáwọn èèyàn? Ó rí irú àwọn lẹ́tà bẹ́ẹ̀ gbà, àmọ́ èyí tó wá látọ̀dọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kò tó nǹkan.
Ṣùgbọ́n níbi ìkówèésí tó wà ní Moscow, ọ̀jọ̀gbọ́n Eberle rí fáìlì kan tí wọ́n kó àwọn lẹ́tà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ sí Hitler sínú rẹ̀, apá ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè Jámánì ni wọ́n ti kọ lẹ́tà náà ránṣẹ́ láti fi sọ pé ìwà tí kò dáa ni ìjọba Násì ń hù. Kódà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti orílẹ̀-èdè àádọ́ta [50] tí orílẹ̀-èdè Jámánì náà wà lára wọn, fi lẹ́tà àti wáyà tó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún [20,000] ránṣẹ́ sí Hitler láti fi sọ pé ohun tó ń ṣe kò dáa. Wọ́n fi àṣẹ ọba mú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n ṣìkà pa ọgọ́rùn-ún bíi mélòó kan lára wọn, àwọn míì sì kú nítorí ìwà òǹrorò tí ìjọba Násì hù sí wọn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Eberle parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Tá a bá fi iye [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìṣàkóso Násì pọ́n lójú] wéra pẹ̀lú ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí ìṣàkóso náà pọ́n lójú, ó jọ pé iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kéré. Àmọ́ ṣá o, gbogbo èyí ń jẹ́rìí sí i pé ohùn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣọ̀kan, wọ́n sì kọ̀ jálẹ̀ fún Ìjọba Násì, ó yẹ ká bọ̀wọ̀ fún wọn.”