Ohun Tí Amágẹ́dọ́nì Jẹ́ Gan-an
“Àwọn ẹ̀mí èṣù . . . jáde lọ bá àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé . . . , wọ́n sì kó wọn jọpọ̀ sí ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.)—ÌṢÍPAYÁ 16:14, 16.
AMÁGẸ́DỌ́NÌ, èyí tí wọ́n tún ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì nígbà míì, jẹ́ orúkọ ibì kan. Àmọ́ ṣá, kò jọ pé ibì kankan wà ní ayé yìí tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà Amágẹ́dọ́nì? Kí nìdí tí àwọn èèyàn fi sábà máa ń lò ó láti fi júwe ìṣẹ̀lẹ̀ kan, irú bí ogun?
Wọ́n Kó Wọn Jọ Pọ̀ sí Ibi Tí A Ń Pè Ní Amágẹ́dọ́nì
Ọ̀rọ̀ náà Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù àtijọ́, túmọ̀ sí “Òkè Ńlá Mẹ́gídò.” Lóòótọ́, kò sí òkè kankan láyé yìí tó ń jẹ́ Mẹ́gídò, ṣùgbọ́n ibì kan wà tó ń jẹ́ Mẹ́gídò láyé àtijọ́. Ó wà ní oríta mẹ́rin kan lápá àríwá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ọ̀pọ̀ ogun àjàmọ̀gá ni àwọn èèyàn ti jà nítòsí ibẹ̀. Bó ṣe di pé wọ́n ń dárúkọ Mẹ́gídò mọ́ ogun nìyẹn.a
Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe àwọn ogun àjàmọ̀gá tí wọ́n jà ní Mẹ́gídò ló mú kí ibẹ̀ ṣe pàtàkì, bí kò ṣe ìdí tí wọ́n fi ja àwọn ogun náà. Inú Ilẹ̀ Ìlérí tí Jèhófà Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Mẹ́gídò wà. (Ẹ́kísódù 33:1; Jóṣúà 12:7, 21) Ọlọ́run ṣèlérí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé òun yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tó bá dojú ìjà kọ wọ́n, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. (Diutarónómì 6:18, 19) Bí àpẹẹrẹ, Mẹ́gídò ni Jèhófà ti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́nà ìyanu kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Jábínì, ọba kan ní ilẹ̀ Kénáánì, àti Sísérà olórí ogun rẹ̀.—Àwọn Onídàájọ́ 4:14-16.
Nípa báyìí, ọ̀rọ̀ náà “Ha-Mágẹ́dọ́nì” tàbí Amágẹ́dọ́nì dúró fún ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an. Ó jẹ mọ́ ìjà tó máa wáyè láàárín àwọn ẹgbẹ́ ogun alágbára méjì kan.
Àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìṣípayá sọ nípa ọjọ́ iwájú kan tí kò jìnnà mọ́, nígbà tí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù yóò mú kí àwọn ìjọba ayé kó ọmọ ogun wọn jọ, tí á sì fi hàn pé wọ́n kọjú ìjà sí àwọn èèyàn Ọlọ́run àti iṣẹ́ wọn. Nígbà tí Jèhófà bá ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tó gbógun wá yìí, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni yóò ṣègbé.—Ìṣípayá 19:11-18.
Àmọ́, kí nìdí tí Ọlọ́run, ẹni tí Bíbélì sọ pé ó jẹ́ “aláàánú, tí ń lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́,” yóò fi pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn bẹ́ẹ̀? (Nehemáyà 9:17) Ká lè lóye ìdí tí Ọlọ́run fi máa ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti mọ ìdáhùn ìbéèrè mẹ́ta yìí: (1) Ta ló máa bẹ̀rẹ̀ ogun náà? (2) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi máa dá sí i? (3) Àǹfààní tó wà pẹ́ títí wo ni ogun yìí máa ṣe ayé àtàwọn tó wà nínú rẹ̀?
1. TA LÓ MÁA BẸ̀RẸ̀ OGUN NÁÀ?
Ọlọ́run kọ́ ló máa dá ogun Amágẹ́dọ́nì sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Ọlọ́run máa gba àwọn èèyàn rere sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó fẹ́ pa wọ́n run. “Àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá,” ìyẹn àwọn aṣáájú ayé yìí, ló máa kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ogun yẹn. Kí nìdí tí wọ́n fi máa ṣe bẹ́ẹ̀? Sátánì ló máa darí àwọn ìjọba àtàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ayé yìí láti fi gbogbo agbára tí wọ́n ní gbéjà ko àwọn tó ń sin Jèhófà Ọlọ́run.—Ìṣípayá 16:13, 14; 19:17, 18.
Nítorí àwọn èèyàn fi ọwọ́ pàtàkì mú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti òmìnira ẹ̀sìn ní àwọn orílẹ̀-èdè kan lónìí, ó lè ṣòro láti gbà pé àwọn ìjọba yóò dojú ìjà kọ àwọn ẹlẹ́sìn, tàbí pé wọ́n máa fẹ́ láti pa gbogbo ẹ̀sìn run. Àmọ́, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti wáyé láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn, ó sì ń ṣẹlẹ̀ báyìí.b Síbẹ̀, ó kéré tán, ìyàtọ̀ pàtàkì méjì wà láàárín bí àwọn ìjọba ṣe ń gbógun ti ẹ̀sìn látẹ̀yìn wá àti èyí tó máa fa ogun Amágẹ́dọ́nì. Àkọ́kọ́, gbogbo ẹ̀sìn kárí ayé ni wọ́n máa gbógun tì. Ìkejì, ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run máa gbà dá sí ọ̀ràn náà máa le ju gbogbo èyí tó ti ṣe sẹ́yìn lọ. (Jeremáyà 25:32, 33) Bíbélì pe ogun yìí ní “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.”
2. KÍ NÌDÍ TÍ ỌLỌ́RUN FI MÁA DÁ SÍ I?
Jèhófà pàṣẹ pé kí àwọn tó ń sin òun jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn. (Míkà 4:1-3; Mátíù 5:43, 44; 26:52) Nítorí náà, àwọn èèyàn Ọlọ́run kò ní gbé ohun ìjà láti fi gbèjà ara wọn nígbà táwọn ọ̀tá bá kọ lù wọ́n. Bí Ọlọ́run kò bá gbèjà wọn láti gbà wọ́n sílẹ̀, ṣe làwọn ọ̀tá yẹn kàn máa pa wọ́n run. Èyí tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ yẹn wé mọ́ orúkọ Jèhófà Ọlọ́run tàbí irú ẹni tó jẹ́. Tí àwọn ọ̀tá yìí bá lọ pa àwọn èèyàn Ọlọ́run run, ṣe ló máa jẹ́ kó dà bíi pé Jèhófà kì í ṣe onífẹ̀ẹ́ àti onídàájọ́ òdodo, tàbí pé kò lè ranni lọ́wọ́. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò sì lè ṣẹlẹ̀ láé!—Sáàmù 37:28, 29.
Ọlọ́run kò fẹ́ pa ẹnikẹ́ni run, nítorí náà, ó ń kìlọ̀ gidigidi nípa ohun tí òun yóò ṣe. (2 Pétérù 3:9) Ọlọ́run tipasẹ̀ àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì rán àwọn èèyàn létí pé òun gbèjà àwọn èèyàn òun láyé àtijọ́ nígbà tí àwọn ọ̀tá gbéjà kò wọ́n. (2 Àwọn Ọba 19:35) Bíbélì sì tún kìlọ̀ pé nígbà tí Sátánì, àwọn ìjọba àtàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ayé yìí bá gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà yóò tún gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀, yóò sì bá àwọn ọ̀tá náà jà. Kódà, tipẹ́tipẹ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ pé Jèhófà yóò pa àwọn ẹni burúkú run. (Òwe 2:21, 22; 2 Tẹsalóníkà 1:6-9) Nígbà yẹn, ó máa yé àwọn ọ̀tá náà kedere pé Olódùmarè fúnra rẹ̀ làwọn dojú ìjà kọ.—Ìsíkíẹ́lì 38:21-23.
3. ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ PẸ́ TÍTÍ WO NI OGUN YÌÍ MÁA ṢE ARÁYÉ?
Ogun Amágẹ́dọ́nì yìí máa gba ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀mí là. Ká sòótọ́, ogun yìí gan-an ló máa jẹ́ kí àlàáfíà lè jọba ní ayé.—Ìṣípayá 21:3, 4.
Ìwé Ìṣípayá sọ pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” kan tí ẹnì kankan kò mọ iye wọn ló máa la ogun yìí já. (Ìṣípayá 7:9, 14) Ọlọ́run máa mú kí àwọn tó là á já sọ ayé yìí di Párádísè bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
Ǹjẹ́ a mọ ìgbà tí àwọn ọ̀tá yìí yóò wá gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run?
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe nǹkan tuntun pé kí àwọn èèyàn máa fi orúkọ ibi tí wọ́n ti ja ogun kan pe ogun náà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n fi bọ́ǹbù runlérùnnà pa ìlú Hiroshima lórílẹ̀-èdè Japan run, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fi orúkọ ìlú yẹn júwe àjálù tí ogun runlérùnnà lè fà.
b Ìpakúpa rẹpẹtẹ tó wáyé nígbà ìjọba Násì jẹ́ àpẹẹrẹ bí ìjọba kan ṣe gbìyànjú láti pa àwọn ẹlẹ́sìn àtàwọn ẹ̀yà kan run. Bákan náà, láàárín ọdún 1917 sí 1991, ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà tẹ́lẹ̀ rí gbógun ti àwọn ẹ̀sìn tó wà ní orílẹ̀-èdè wọn gidigidi. Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Èèyàn Àlàáfíà Gbèjà Orúkọ Rere Wọn,” èyí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2011. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Jèhófà Ọlọ́run gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ láyé àtijọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Jèhófà yóò tún gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì